“Àwọn Ènìyàn Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Wọn”
“Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—SM. 144:15.
1. Kí làwọn kan rò nípa bóyá ó yẹ kí Ọlọ́run ní àwọn èèyàn tó ya ara wọn sọ́tọ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
LÓDE òní, ọ̀pọ̀ èèyàn tó mọnúúrò gbà láìjanpata pé àwọn ìsìn kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe aráyé láǹfààní, yálà ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni o tàbí ti àwọn ẹlẹ́sìn míì. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé ẹ̀kọ́ tí irú àwọn onísìn bẹ́ẹ̀ fi ń kọ́ni àti ìwà wọn fi hàn pé irọ́ ni wọ́n ń pa mọ́ Ọlọ́run, wọn ò sì lè rí ojú rere rẹ̀. Àmọ́, wọ́n gbà pé àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere wà nínú gbogbo ìsìn àti pé Ọlọ́run ń rí wọn ó sì kà wọ́n sí olùjọ́sìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Wọn ò rí ìdí tó fi yẹ pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi ìsìn èké sílẹ̀ kí wọ́n lè ya ara wọn sọ́tọ̀ láti máa jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́, ṣé èrò wọn yìí bá ti Ọlọ́run mu? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo inú Ìwé Mímọ́ ká lè jíròrò díẹ̀ lára ìtàn àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn Jèhófà.
ÀWỌN ÈÈYÀN TÍ ỌLỌ́RUN BÁ DÁ MÁJẸ̀MÚ
2. Àwọn èèyàn wo ní Jèhófà yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀ nígbà tó yá? Kí ló mú kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn èèyàn yòókù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
2 Láti apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún ṣááju Sànmánì Kristẹni ni Jèhófà ti ní àwọn èèyàn tó yà sọ́tọ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Olórí ìdílé ni Ábúráhámù tá a pè ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́,” ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló sì wà nínú agboolé rẹ̀. (Róòmù 4:11; Jẹ́n. 14:14) “Ìjòyè Ọlọ́run” ni àwọn alákòóso ilẹ̀ Kénáánì ka Ábúráhámù sí, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an. (Jẹ́n. 21:22; 23:6) Jèhófà bá Ábúráhámù àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ dá májẹ̀mú. (Jẹ́n. 17:1, 2, 19) Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: “Èyí ni májẹ̀mú mi tí ẹ̀yin yóò pa mọ́, láàárín èmi àti ẹ̀yin, àní irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ: Gbogbo tiyín tí ó jẹ́ ọkùnrin ni a gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́ wọn . . . kí ó sì jẹ́ àmì májẹ̀mú láàárín èmi àti ẹ̀yin.” (Jẹ́n. 17:10, 11) Nítorí náà, Ábúráhámù àti gbogbo ọkùnrin agboolé rẹ̀ dádọ̀dọ́. (Jẹ́n. 17:24-27) Ìdádọ̀dọ́ yẹn ni àmì tó fi hàn pé àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù yàtọ̀, pé àwọn nìkan ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú.
3. Báwo ni àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ṣe di èèyàn púpọ̀?
3 Jékọ́bù, tó tún ń jẹ́ Ísírẹ́lì, tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù ní ọmọkùnrin méjìlá. (Jẹ́n. 35:10, 22b-26) Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n wá di baba ńlá ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì. (Ìṣe 7:8) Àmọ́ nítorí ìyàn kan tó mú nílùú wọn, Jékọ́bù àti agboolé rẹ̀ ṣí lọ sí Íjíbítì níbi tí Jósẹ́fù wà. Jósẹ́fù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù, òun sì ni alábòójútó oúnjẹ àti ẹni tí Fáráò fọkàn tán jù lọ. (Jẹ́n. 41:39-41; 42:6) Àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù di púpọ̀, wọ́n di “ìjọ àwọn ènìyàn.”—Jẹ́n. 48:4; ka Ìṣe 7:17.
ÀWỌN ÈÈYÀN TÍ ỌLỌ́RUN TÚN RÀ PA DÀ
4. Ní ìbẹ̀rẹ̀, báwo ni àjọṣe àárín àwọn ará Íjíbítì àtàwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù ṣe rí?
4 Nǹkan bí igba ọdún ó lé díẹ̀ làwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù fi wà ní Íjíbítì, wọ́n gbé ní Góṣénì, àgbègbè kan tí odò Náílì ti wọnú òkun. (Jẹ́n. 45:9, 10) Ó ṣeé ṣe kó lé díẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn ọmọ Jékọ́bù àtàwọn ará Íjíbítì fi gbé pọ̀ ní àlàáfíà, wọ́n ń gbé láwọn ìlú kéékèèké, wọ́n sì ń bójú tó àwọn agbo ẹran ọ̀sìn wọn. Fáráò gba àwọn èèyàn náà tọwọ́tẹsẹ̀, Fáráò yìí mọ Jósẹ́fù ó sì mọyì rẹ̀ gan-an. (Jẹ́n. 47:1-6) Àmọ́ ní ti àwọn ará Íjíbítì, bí ìgbẹ́ ni wọ́n kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń bójú tó ẹran ọ̀sìn. (Jẹ́n. 46:31-34) Síbẹ̀, ó di dandan kí wọ́n fàyè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
5, 6. (a) Báwo ni ipò àwọn èèyàn Ọlọ́run nílẹ̀ Íjíbítì ṣe yí pa dà? (b) Báwo ni wọ́n ṣe dá ẹ̀mí Mósè sí? Kí ni Jèhófà ṣe fún gbogbo àwọn èèyàn tó jẹ́ tirẹ̀?
5 Àmọ́ nǹkan máa tó yí pa dà bìrí fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ó ṣe, ọba tuntun tí kò mọ Jósẹ́fù jẹ lórí Íjíbítì. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: ‘Ẹ wò ó! Àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀ níye jù wá, wọ́n sì jẹ́ alágbára ńlá jù wá lọ.’ Nítorí náà, àwọn ará Íjíbítì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sìnrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀. Wọ́n sì ń mú ìgbésí ayé korò fún wọn nípa ìsìnrú nínira nídìí àpòrọ́ tí a fi amọ̀ ṣe àti bíríkì àti pẹ̀lú gbogbo oríṣi ìsìnrú nínú pápá, bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo oríṣi ìsìnrú wọn nínú èyí tí wọ́n lò wọ́n bí ẹrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀.”—Ẹ́kís. 1:8, 9, 13, 14.
6 Fáráò tiẹ̀ ṣòfin pé kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin jòjòló tí àwọn Hébérù bí ní gbàrà tí wọ́n bá ti bí wọn. (Ẹ́kís. 1:15, 16) Àsìkò yẹn ni wọ́n bí Mósè. Nígbà tó pé ọmọ oṣù mẹ́ta, ìyá rẹ̀ tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sáàárín àwọn esùsú odò Náílì, ibẹ̀ sì ni ọmọbìnrin Fáráò ti rí i. Nígbà tó yá, ó sọ ọ́ dọmọ. Kẹ́ ẹ sì máa woṣẹ́ Ọlọ́run, Jókébédì olóòótọ́ tó jẹ́ ìyá Mósè gan-an ló tọ́ ọ dàgbà. Mósè sì wá di olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ẹ́kís. 2:1-10; Heb. 11:23-25) Jèhófà ‘kíyè sí’ ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì pinnu pé òun máa dá wọn nídè lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára àti pé Mósè ni aṣáájú tó máa dá wọn nídè. (Ẹ́kís. 2:24, 25; 3:9, 10) Wọ́n a tipa bẹ́ẹ̀ di àwọn èèyàn tí Jèhófà “gbà sílẹ̀,” tàbí tí ó tún rà pa dà.—Ẹ́kís. 15:13; ka Diutarónómì 15:15.
ÀWỌN ÈÈYÀN NÁÀ DI ORÍLẸ̀-ÈDÈ
7, 8. Báwo ni àwọn èèyàn Jèhófà ṣe di orílẹ̀-èdè mímọ́?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò tíì ṣètò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti di orílẹ̀-èdè kan, ó gbà pé èèyàn òun ni wọ́n. Torí náà, ó ní kí Mósè àti Áárónì sọ fún Fáráò pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Rán àwọn ènìyàn mi lọ, kí wọ́n lè ṣe àjọyọ̀ fún mi ní aginjù.’”—Ẹ́kís. 5:1.
8 Ìgbà tí ìyọnu mẹ́wàá kọ lu àwọn ará Íjíbítì tí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì kú sínú Òkun Pupa ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára yẹn. (Ẹ́kís. 15:1-4) Ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú ní Òkè Sínáì, ó sì ṣe ìlérí mánigbàgbé kan, pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, . . . orílẹ̀-èdè mímọ́.”—Ẹ́kís. 19:5, 6.
9, 10. (a) Gẹ́gẹ́ bí Diutarónómì 4:5-8 ti sọ, báwo ni Òfin Mósè ṣe mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yàtọ̀ sí àwọn èèyàn yòókù? (b) Ọ̀nà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà fi hàn pé àwọn jẹ́ “ènìyàn mímọ́ lójú Jèhófà”?
9 Nígbà táwọn Hébérù ṣì wà ní Íjíbítì kí wọ́n tó sọ wọ́n dẹrú, wọ́n ṣètò ara wọn lọ́nà tó fi jẹ́ pé ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní olórí ìdílé tàbí baba ńlá tó ń bójú tó àwọn nǹkan. Àwọn olórí ìdílé yẹn jẹ́ alákòóso, adájọ́ àti àlùfáà nínú agboolé wọn, bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà ṣáájú wọn ti jẹ́. (Jẹ́n. 8:20; 18:19; Jóòbù 1:4, 5) Àmọ́, Jèhófà tipasẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni àkójọ òfin táá mú kí wọ́n yàtọ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù. (Ka Diutarónómì 4:5-8; Sm. 147:19, 20.) Òfin náà sọ pé kí wọ́n ya àwọn kan sọ́tọ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà, àwọn ọ̀ràn ẹjọ́ sì wà lábẹ́ àbójútó àwọn “àgbà ọkùnrin” tí àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún nítorí ìmọ̀ àti ọgbọ́n tí wọ́n ní. (Diu. 25:7, 8) Òfin yìí sọ ohun tí orílẹ̀-èdè tuntun náà á máa ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run àti bí wọ́n á ṣe máa bá ara wọn gbé.
10 Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà rán wọn létí òfin náà. Mósè sọ fún wọn pé: “Jèhófà . . . ti sún ọ láti sọ lónìí pé ìwọ yóò di ènìyàn rẹ̀, àkànṣe dúkìá, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ gan-an, àti pé ìwọ yóò pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́, àti pé òun yóò gbé ọ ga lékè gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tí ó ṣe, ní yíyọrí sí ìyìn àti ìfùsì àti ẹwà, bí o ti ń fi ara rẹ hàn ní ènìyàn mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”—Diu. 26:18, 19.
WỌ́N GBÀ KÍ ÀWỌN ÀTÌPÓ DARA PỌ̀ MỌ́ WỌN
11-13. (a) Àwọn wo ló dara pọ̀ mọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí ni ẹni tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ jọ́sìn Jèhófà?
11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti wá ní orílẹ̀-èdè tó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kò tìtorí ẹ̀ ní kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn òun. Ó gbà kí àwọn míì dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn tó dá wọn nídè ní Íjíbítì. Bíbélì pè wọ́n ní “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata,” ìyẹn àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn kan tó jẹ́ ará Íjíbítì. (Ẹ́kís. 12:38) Nígbà tí ìyọnu keje fẹ́ jà, àwọn kan “láàárín àwọn ìránṣẹ́ Fáráò” bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Jèhófà, ó sì dájú pé wọ́n wà lára onírúurú ènìyàn tó tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.—Ẹ́kís. 9:20.
12 Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá odò Jọ́dánì láti gba ilẹ̀ Kénáánì, Mósè sọ fún wọn pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ àtìpó” tó wà láàárín wọn. (Diu. 10:17-19) Ọlọ́run ní kí àwọn àyànfẹ́ òun fàyè gba àwọn àtìpó, ìyẹn àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè èyíkéyìí láti máa bá wọn gbé, bí wọ́n bá ṣe tán láti máa pa àwọn òfin tí òun fún Mósè mọ́. (Léf. 24:22) Àwọn àtìpó kan di olùjọsìn Jèhófà, tí ọ̀rọ̀ wọn sì jọ ti Rúùtù tó wá láti ilẹ̀ Móábù, tó sọ fún Náómì ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.” (Rúùtù 1:16) Àwọn àtìpó yẹn di aláwọ̀ṣe, àwọn ọkùnrin wọn sì gbà láti dádọ̀dọ́. (Ẹ́kís. 12:48, 49) Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n, ó sì kà wọ́n mọ́ àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.—Núm. 15:14, 15.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ àwọn àtìpó (Wo ìpínrọ̀ 11 sí 13)
13 Nígbà tí wọ́n ń ya tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì sí mímọ́ fún Jèhófà, ètò wà fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì láti wá máa jọ́sìn Jèhófà, bí Sólómọ́nì ṣe sọ nínú àdúrà rẹ̀, ó ní: “Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí kì í ṣe ara àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì, tí ó sì ti ilẹ̀ jíjìnnà wá ní tòótọ́ nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ líle rẹ àti apá rẹ nínà jáde, tí wọ́n sì wá ní tòótọ́, tí wọ́n sì gbàdúrà síhà ilé yìí, ni kí ìwọ alára fetí sí nígbà náà láti ọ̀run, láti ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè náà ké pè ọ́ sí; kí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì lè máa bẹ̀rù rẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé yìí tí mo kọ́.” (2 Kíró. 6:32, 33) Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí Jésù wà láyé, ọmọ ilẹ̀ òkèèrè èyíkéyìí tó bá fẹ́ sin Jèhófà ní láti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú.—Jòh. 12:20; Ìṣe 8:27.
ORÍLẸ̀-ÈDÈ TÓ JẸ́ ẸLẸ́RÌÍ
14-16. (a) Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà? (b) Kí ló pọn dandan pé kí àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní máa ṣe?
14 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run wọn, àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń sin àwọn òrìṣà wọn. Lásìkò wòlíì Aísáyà, Jèhófà fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ìgbà yẹn wé ìgbà tí ẹni méjì lọ jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́. Ó pe àwọn òrìṣà tí àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ń sìn níjà pé kí wọ́n kó àwọn ẹlẹ́rìí wọn jáde kí aráyé lè mọ̀ pé ọlọ́run ni wọ́n. Ó sọ pé: “Kí a kó orílẹ̀-èdè gbogbo jọpọ̀ sí ibì kan, kí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì kóra jọpọ̀. Ta ní ń bẹ nínú wọn [àwọn òrìṣà yẹn] tí ó lè sọ èyí? Tàbí kẹ̀, wọ́n ha lè mú kí a gbọ́ àní àwọn ohun àkọ́kọ́? Kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn jáde wá, kí a lè polongo wọn ní olódodo, tàbí kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n sì wí pé, ‘Òtítọ́ ni!’”—Aísá. 43:9.
15 Àwọn òrìṣà tí àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ń sìn kò lè mú ẹ̀rí jáde pé ọlọ́run làwọn. Ère lásán ni wọ́n, wọn ò lè sọ̀rọ̀, wọn ò sì lè dá fi ẹsẹ̀ ara wọn rìn. (Aísá. 46:5-7) Àmọ́, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn, kí ẹ lè mọ̀, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, àti pé kí ẹ lè lóye pé Ẹnì kan náà ni mí. Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run kankan tí a ṣẹ̀dá, àti lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan tí ó ṣì wà nìṣó. Èmi—èmi ni Jèhófà, yàtọ̀ sí mi, kò sí olùgbàlà kankan. . . . Nítorí náà, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . èmi sì ni Ọlọ́run.”—Aísá. 43:10-12.
16 Ọ̀ràn ẹjọ́ kan wà tó kan ayé àti ọ̀run tí wọ́n fẹ́ yanjú, ọ̀ràn náà ni, “Ta ni Ọlọ́run Gíga Jù Lọ?” Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn àyànfẹ́ Jèhófà jẹ́ kí aráyé mọ̀ kedere pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́. Ó pè wọ́n ní “àwọn ènìyàn tí mo ti ṣẹ̀dá fún ara mi, kí wọ́n lè máa ròyìn ìyìn mi lẹ́sẹẹsẹ.” (Aísá. 43:21) Àwọn ni wọ́n ń jẹ́ orúkọ rẹ̀. Torí pé Jèhófà dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì, ó pọn dandan pé kí wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn tó wà láyé mọ̀ pé òun ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Torí náà, ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn jọ èyí tí wòlíì Míkà wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní máa ṣe, ó sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Míkà 4:5.
ÀWỌN Ọ̀DÀLẸ̀ ÈÈYÀN
17. Lójú Jèhófà, báwo ni Ísírẹ́lì ṣe di ‘àjàrà ilẹ̀ òkèèrè tó ti bàjẹ́’?
17 Ó bani nínú jẹ́ pé Ísírẹ́lì di aláìṣòótọ́ torí pé wọ́n kẹ̀yìn sí Jèhófà, Ọlọ́run wọn. Wọ́n jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bọ igi àti òkúta mú kí àwọn náà máa bọ̀rìṣà. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wòlíì Hóséà sọ pé: “Àjàrà jíjẹrà bàjẹ́ ni Ísírẹ́lì . . . Ó . . . sọ àwọn pẹpẹ rẹ̀ di púpọ̀ . . . Ọkàn-àyà wọ́n ti di alágàbàgebè; nísinsìnyí wọn yóò jẹ̀bi.” (Hós. 10:1, 2) Ní nǹkan bí àádọ́jọ [150] ọdún lẹ́yìn náà, Jeremáyà kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run tó jẹ́ aláìṣòótọ́, ó ní: “Mo ti gbìn ọ́ bí ààyò àjàrà pupa, gbogbo rẹ̀ irúgbìn tòótọ́. Báwo ni a ṣe yí ọ padà di ọ̀mùnú àjàrà ilẹ̀ òkèèrè tí ó jẹrà bàjẹ́ sí mi? . . . Àwọn ọlọ́run rẹ tí o ti ṣe fún ara rẹ dà? Kí wọ́n dìde bí wọ́n bá lè gbà ọ́ là ní àkókò ìyọnu àjálù rẹ . . . àwọn ènìyàn mi—wọ́n ti gbàgbé mi.”—Jer. 2:21, 28, 32.
18, 19. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun máa kó àwọn èèyàn míì jọ fún orúkọ òun? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe ìsìn tòótọ́ tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà, wọ́n ì bá so èso rere, àmọ́ èso búburú ni wọ́n so nítorí òrìṣà tí wọ́n ń bọ. Torí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ fún àwọn alágàbàgebè aṣáájú àwọn Júù pé: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mát. 21:43) Àwọn tó wà nínú “májẹ̀mú tuntun” tí Jèhófà tipasẹ̀ Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nìkan ló máa wà nínú orílẹ̀-èdè tuntun yẹn, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó máa mú wọnú májẹ̀mú tuntun yẹn, ó ní: “Èmi yóò . . . di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.”—Jer. 31:31-33.
19 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti di aláìṣòótọ́, Jèhófà sọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí di àwọn èèyàn rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, bá a ṣe sọ ṣáájú. Àmọ́, àwọn wo ni èèyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí? Báwo ni àwọn olóòótọ́ ọkàn ṣe lè mọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run lóòótọ́? A máa jíròrò kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.