ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 7/1 ojú ìwé 17-19
  • Inú Wọn Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Inú Wọn Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Fún Wọn Níṣìírí Láti Máa Ṣe Ohun Tí Jèhófà Fẹ́
  • Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Wọ́n Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì Pé Kí Wọ́n “Máa Walẹ̀ Jìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìfẹ́ Sún Wọn Láti Ṣiṣẹ́ Sìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Wọ́n Ń Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 7/1 ojú ìwé 17-19

Inú Wọn Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

JÉSÙ fi àpẹẹrẹ tó yẹ kí gbogbo Kristẹni máa tẹ̀ lé lélẹ̀ nígbà tó gbàdúrà sí Baba rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Gbólóhùn yìí fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìtẹríba hàn fún Jèhófà. A sì ń rí ẹ̀rí èyí nínú ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí. Lára wọn ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìléláàádọ́ta tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì Ọgọ́fà nílé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù March ọdún 2006, inú àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà dùn gan-an bí wọ́n ti ń fojú sọ́nà láti lọ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní onírúurú orílẹ̀-èdè láìka àwọn ìnira tí wọ́n máa bá pàdé sí.

Kí ló mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́yege wọ̀nyẹn jẹ́ kí ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà darí ìgbésí ayé wọn? Tọkọtaya tó ń jẹ́ Chris àti Leslie, tí wọ́n yàn láti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Bolivia sọ ohun tó mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ní: “Níwọ̀n ìgbà tá a ti sẹ́ ara wa, a fẹ́ láti yọ̀ǹda ara wa láti ṣe ohunkóhun tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú ètò Jèhófà.” (Máàkù 8:34) Jason àti Chere tí wọ́n rán lọ sílẹ̀ Albania náà sọ pé: “Kò sí iṣẹ́ ìsìn kankan tá a ti gbà látọ̀dọ̀ ètò Jèhófà tí kò láwọn ìṣòro tirẹ̀. Àmọ́ a ti rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni tá a lè fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé.”

Wọ́n Fún Wọn Níṣìírí Láti Máa Ṣe Ohun Tí Jèhófà Fẹ́

Arákùnrin George Smith, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó sì ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọnà ló gba àdúrà tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà. Stephen Lett, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sì tún jẹ́ alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ọjọ́ náà, kí gbogbo àwọn tó wà níkàlẹ̀ káàbọ̀. Orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ti rìnrìn àjò wá síbi ayẹyẹ aláyọ̀ yìí, èyí tó wáyé ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní Patterson, ìpínlẹ̀ New York. Arákùnrin Lett sọ fáwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà pé “ohun kan tó lágbára gan-an” ni wọ́n fẹ́ lọ gbé ṣe. Ó pe àfiyèsí sí “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in,” irú bí àwọn ẹ̀kọ́ èké, táwọn míṣọ́nárì tuntun náà máa lè fi agbára Ìwé Mímọ́ dojú wọn dé. (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Ó kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ayọ̀ rẹpẹtẹ ló dájú pé yóò jẹ́ tiyín pé Jèhófà ń lò yín láti dojú àwọn nǹkan tó fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé, ìyẹn àwọn nǹkan tó ti fìdí rinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọlọ́kàn rere èèyàn tẹ́ ẹ máa bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn yín!”

Arákùnrin Harold Jackson tó ń sìn ní orílé-iṣẹ́, sọ̀rọ̀ lórí àkòrí náà, “Àwọn Nǹkan Díẹ̀ Tó Yẹ Láti Máa Rántí.” Ó sọ pé àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láti máa ‘wá ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Wọ́n ní láti máa rántí pé “ìfẹ́ a máa gbéni ró” ó sì jẹ́ ọ̀nà tó dájú láti ṣàṣeyọrí. (1 Kọ́ríńtì 8:1) Ó sọ pé: “Ìfẹ́ ni kẹ́ ẹ jẹ́ kó máa darí ọ̀nà tí ẹ̀ ń gbà bá àwọn mìíràn lò.”

Lẹ́yìn náà ni arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó sì tún ṣe iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì láàárín ọdún 1979 sí ọdún 2003 béèrè lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà pé, “Ǹjẹ́ Ojúṣe Yín Ni?” Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní èrò tó tọ́ nípa ara rẹ̀ àti nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ojúṣe àwọn Kristẹni ni pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n máa gbin irúgbìn òtítọ́ kí wọ́n sì máa bomi rin ín. Àmọ́ Jèhófà ló ni iṣẹ́ mímú ìdàgbàsókè tẹ̀mí wá, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé “Ọlọ́run [ló] ń mú kí ó dàgbà.” (1 Kọ́ríńtì 3:6-9) Arákùnrin Jackson wá fi kún un pé: “Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ jẹ́ ẹni tó lókun nípa tẹ̀mí. Àmọ́ kí ni ojúṣe yín tó tóbi jù lọ? Òun ni pé, kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kẹ́ ẹ sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tẹ́ ẹ fẹ́ lọ ràn lọ́wọ́.”

Arákùnrin Lawrence Bowen tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ̀rọ̀ lórí àkòrí tó sọ pé: “Ẹ Mọ Bó Ṣe Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Hùwà.” Ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé ọ̀nà ìyanu ni Jèhófà gbà ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó sì gbà dáàbò bò wọ́n nígbà tí wọ́n ń la aginjù kọjá. (Ẹ́kísódù 13:21, 22) Jèhófà ń ṣamọ̀nà àwa náà ó sì ń dáàbò bò wá lónìí, ọ̀kan lára ọ̀nà tó sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tó jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:14, 15) Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di míṣọ́nnárì yìí ní láti rọ̀ mọ́ òtítọ́ dáadáa, èyí tó ń fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ìtọ́sọ́nà tó sì ń dáàbò bò wọ́n.

Arákùnrin Wallace Liverance tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege níyànjú pé kí wọ́n má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà “lẹ́yìn” wọn. Ọ̀nà tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wà lẹ́yìn wa ni pé, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti kọ Bíbélì. Bí olùṣọ́ àgùntàn tó ń bá agbo àgùntàn sọ̀rọ̀ láti ẹ̀yìn ni Jèhófà ṣe wà lẹ́yìn àwọn èèyàn rẹ̀, tó ń fún wọn ní ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Aísáyà 30:21; Mátíù 24:45-47) Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ran àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege náà lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọrírì ẹgbẹ́ ẹrú náà. Kódà “ẹrú” yìí tún pèsè Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Olùbánisọ̀rọ̀ náà rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà pé: “Ẹ máa fi ìsọfúnni oníyebíye yìí kọ́ àwọn èèyàn.”—Mátíù 13:52.

Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

Nínú apá tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Wọ́n Hára Gàgà Láti Sọ Ìhìn Rere,” Arákùnrin Mark Noumair tó jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ díẹ̀ lára ìrírí táwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lákòókò tí wọ́n fi wà nílé ẹ̀kọ́ náà. (Róòmù 1:15) Ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi wá àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà lẹ́nu wò fi hàn pé lóòótọ́ ni wọ́n nítara gan-an láti máa wàásù ní gbogbo ìgbà.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà tún rí ìṣírí gbà sí i nígbà tí arákùnrin Kenneth Flodin fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò mẹ́ta kan tí wọ́n ń sìn báyìí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Arákùnrin Richard Keller àti Alejandro Lacayo, tí wọ́n ti sìn ní Amẹ́ríkà Gúúsù àti Amẹ́ríkà Àárín nígbà kan rí, ṣàlàyé báwọn ṣe fara da onírúurú àdánwò, wọ́n sì tún mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn ìbùkún táwọn rí gbà nígbà táwọn wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Arákùnrin Moacir Felisbino ní tiẹ̀ sọ ẹ̀kọ́ tóun rí kọ́ nígbà tóun ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Brazil, ìyẹn ibi tó dàgbà sí.

Arákùnrin David Schafer fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn míṣọ́nnárì mẹ́ta kan tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn tó fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò náà ni Robert Jones, Woodworth Mills, àti Christopher Slay. Àwọn arákùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí sọ bí wọ́n ṣe kọ́ láti máa fi hàn pé àwọn gbẹ̀kẹ́ lé Jèhófà nígbà táwọn bá wà nínú ìṣòro. Wọ́n mú un dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lójú pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Jèhófà fún wọn ti múra wọn sílẹ̀ dáadáa fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì wọn. Arákùnrin Mills wá ṣàkópọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Kì í ṣe àwọn ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì nígbà tí mo wá sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló ràn mí lọ́wọ́ jù lọ bí kò ṣe ohun tí ilé ẹ̀kọ́ yìí kọ́ mi nípa níní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́.”

Arákùnrin Guy Pierce tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá sọ àsọyé kan tó ṣe pàtàkì gan-an tó pe àkòrí rẹ̀ ní, “Jèhófà Kò Lè Kùnà Láéláé.” Ádámù kùnà, àmọ́ ṣé ó wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kùnà nìyẹn? Ṣé Ọlọ́run kò dá Ádámù ní pípé ni, gẹ́gẹ́ báwọn kan ṣe máa ń sọ? Rárá o, nítorí pé “Ọlọ́run tòótọ́ ṣe aráyé ní adúróṣánṣán.” (Oníwàásù 7:29) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ adúróṣinṣin nígbà tó dojú kọ ìdánwò tó le jù lọ lórí ilẹ̀ ayé fi hàn pé “Ádámù kò ní àwáwí kankan, kò sí ìdí kankan tó fi yẹ kó kùnà.” Ìdánwò tí Ádámù rí nínú ọgbà Édẹ́nì kò le rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tí Jésù fojú winá rẹ̀ tó sì ṣàṣeyọrí. Síbẹ̀ Ádámù kùnà. Àmọ́ o, Jèhófà kò lè kùnà láéláé. Ohun tó ní lọ́kàn yóò nímùúṣẹ dandan. (Aísáyà 55:11) Arákùnrin Pierce wá sọ fáwọn míṣọ́nnárì tuntun náà pé: “Ẹ láǹfààní láti fi ọlá fún Jèhófà pẹ̀lú ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni tẹ́ ẹ ní. Kí Jèhófà wà pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níbikíbi tẹ́ ẹ bá ti ń sìn ín gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì.”

Lẹ́yìn tí Arákùnrin Lett tó jẹ́ alága ka àwọn ọ̀rọ̀ ìkíni tó wá láti onírúurú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ní ìwé ẹ̀rí wọn àti ibi tí wọ́n ti máa sìn. Arákùnrin Vernon Wisegarver, tó ti jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tipẹ́ wá gba àdúrà ìparí.

Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìléláàádọ́rin èèyàn tó pésẹ̀ síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà rí i pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà mú kí ìtara wọn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ pọ̀ sí i. (Sáàmù 40:8) Andrew àti Anna tí wọ́n wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà sọ pé: “A ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà. A ṣèlérí fún Jèhófà láti ṣe ohunkóhun tó bá sọ pé ká ṣe. Báyìí Jèhófà ti sọ fún wa pé ká lọ sí orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù nílẹ̀ Áfíríkà.” Ara wọn àti ara àwọn yòókù wọn tí wọ́n jọ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì náà ti wà lọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó máa fún wọn láyọ̀ tó sì máa mú káyé wọn nítumọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, inú wọn dùn gan-an láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 6

Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 20

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 52

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 35.7

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 18.3

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún: 14.5

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Kíláàsì Ọgọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Wright, S.; Suárez, B.; Croisant, B.; Davenport, L. (2) Johnson, A.; Ali, C.; Cady, K.; Guerrero, P.; Ases, A. (3) Ortiz, L.; Lyall, K.; Uzeta, M.; Perez, R.; Backus, K.; Caterina, C. (4) Palmer, B.; Loving, D.; Macdonough, J.; Bostock, D.; Benetatos, L. (5) Jasicki, M.; Sarafianos, E.; Stelter, C.; Vaira, R.; Woon, J.; Prentice, K. (6) Davenport, H.; Croisant, H.; Perez, M.; Vaira, E.; Suárez, A.; Caterina, I.; Wright, C. (7) Cady, K.; Macdonough, J.; Ortiz, M.; Woon, J.; Ali, J.; Ases, M. (8) Sarafianos, G.; Lyall, D.; Uzeta, C.; Stelter, P.; Prentice, G.; Johnson, A.; Benetatos, C. (9) Palmer, J.; Jasicki, W.; Backus, J.; Bostock, S.; Guerrero, J. M.; Loving, S.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́