Àwọn Ohun Rere Inú Ètò Jèhófà Ni Kó o Máa Fiyè Sí
“Dájúdájú, àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn.”—SÁÀMÙ 65:4.
1, 2. (a) Ipa wo ni ìgbòkègbodò inú tẹ́ńpìlì yóò ní lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run? (b) Àwọn nǹkan wo ni Dáfídì ṣe fún ìtìlẹyìn iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì?
DÁFÍDÌ ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn pàtàkì jù lọ tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, olórin, wòlíì àti ọba tó fi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run. Àjọṣe tímọ́tímọ́ tóun àti Jèhófà ní ló jẹ́ kó wù ú láti kọ́ ilé kan fún Ọlọ́run. Ńṣe ló fẹ́ kí ilé tàbí tẹ́ńpìlì tó fẹ́ kọ́ náà jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Dáfídì mọ̀ pé ìgbòkègbodò inú tẹ́ńpìlì náà yóò ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run láǹfààní yóò sì fún wọn láyọ̀. Ìyẹn ni Dáfídì fi kọ ọ́ lórin pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ìwọ [Jèhófà] yàn, tí ìwọ sì mú kí ó tọ̀ ọ́ wá, kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ. Dájúdájú, àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn, ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì rẹ.”—Sáàmù 65:4.
2 Jèhófà ò gbà kí Dáfídì bójú tó iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ni Jèhófà gbé iṣẹ́ náà lé lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n Dáfídì ò bẹ̀rẹ̀ sí í kùn nítorí pé Ọlọ́run gbé iṣẹ́ pàtàkì tó jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an yìí fún ẹlòmíì. Ohun tó jẹ ẹ́ lógún ni pé kí tẹ́ńpìlì náà ṣáà di kíkọ́. Ó fi tọkàntọkàn kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́lé náà ní ti pé ó gbé àwòrán bí wọ́n ṣe máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà, tí Jèhófà fi hàn án lé Sólómọ́nì lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Léfì sí ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ lọ́nà tí wọ́n yóò gbà ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì kó wúrà àti fàdákà rẹpẹtẹ sílẹ̀ láti fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì náà.—1 Kíróníkà 17:1, 4, 11, 12; 23:3-6; 28:11, 12; 29:1-5.
3. Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run sí ètò tó wà fún ṣíṣe ìjọsìn tòótọ́?
3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́ náà kọ́wọ́ ti ètò bí wọ́n á ṣe máa ṣe ìjọsìn tòótọ́ nílé Ọlọ́run. Bákan náà làwa ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí ṣe ń kọ́wọ́ ti ètò tó wà fún ṣíṣe ìjọsìn nínú apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà. À ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé irú ẹ̀mí tí Dáfídì ní làwa náà ní. A ò lẹ́mìí ìráhùn rárá. Dípò ìyẹn, àwọn ohun rere inú ètò Ọlọ́run la máa ń fiyè sí. Ǹjẹ́ o tíì ronú rí nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tá a ní tó yẹ ká máa torí ẹ̀ dúpẹ́ tinútinú? Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn.
À Dúpẹ́ fún Àwọn Tó Ń Múpò Iwájú
4, 5. (a) Báwo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe ń ṣe ojúṣe rẹ̀? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn Ẹlẹ́rìí kan sí oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n ń rí gbà?
4 A ní ìdí pàtàkì láti dúpẹ́ fún “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Jésù Kristi yàn kó máa bójú tó àwọn ohun ìní rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ẹgbẹ́ ẹrú yìí, ìyẹn àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere, wọ́n ń ṣètò àwọn ìpàdé ìjọsìn, wọ́n sì ń tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì jáde ní èdè tó ju irinwó [400] lọ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jákèjádò ayé ló ń fi ìdùnnú jẹ “oúnjẹ” tẹ̀mí yìí tá à ń rí gbà “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:45-47) Kò sídìí tó fi yẹ ká máa kùn nítorí ẹ̀ rárá.
5 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni àgbà obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Elfi ti ń rí ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ gbà bó ṣe ń fi àwọn ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ tó máa ń wà nínú ìwé ẹgbẹ́ ẹrú náà sílò. Ìmọrírì tí Elfi ní mú kó sọ nínú lẹ́tà tó kọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ ètò Jèhófà lára mi!” Tọkọtaya kan, ìyẹn Peter àti Irmgard, ti ń sin Jèhófà bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún. Irmgard sọ pé òun dúpẹ́ gan-an fún gbogbo ìwé tí “ètò Jèhófà tó jẹ́ ètò onífẹ̀ẹ́ tó ń tọ́jú ẹni” ń tẹ̀ jáde. Lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ làwọn tí ètò Ọlọ́run dìídì ṣe fáwọn tó nírú àwọn ìṣòro kan, irú bí àwọn afọ́jú àtàwọn adití.
6, 7. (a) Báwo la ṣe ń bójú tó àwọn ìjọ tó wà jákèjádò ayé? (b) Kí làwọn kan sọ nípa apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà?
6 Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣojú fún ‘ẹrú olóòótọ́.’ Àwọn tó sì para pọ̀ jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí yìí ni àwọn ọkùnrin mélòó kan lára àwọn ẹni àmì òróró, tí wọ́n ń sìn ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, nílùú New York. Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá yan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìrírí sí àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ láti máa bójú tó àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98,000] jákèjádò ayé. Wọ́n máa ń yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú òṣùwọ̀n ohun tí Bíbélì sọ sípò alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú àwọn ìjọ yìí. (1 Tímótì 3:1-9, 12, 13) Àwọn alàgbà ń múpò iwájú wọ́n sì ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Ìbùkún ńlá ló jẹ́ o láti wà nínú agbo náà àti láti jàǹfààní ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará”!—1 Pétérù 2:17; 5:2, 3.
7 Ńṣe làwọn ará sábà máa ń dúpẹ́ fún ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ táwọn alàgbà ń fún wọn, wọn kì í ráhùn. Bí àpẹẹrẹ, wo Kristẹni kan tó ń jẹ́ Birgit tó ti lé lọ́mọ ọgbọ̀n ọdún tó sì jẹ́ ìyàwó ilé. Nígbà tó kù díẹ̀ kó pé ọmọ ogún ọdún ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, díẹ̀ ló sì kù kó ṣèṣekúṣe. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn tó ṣe kedere táwọn alàgbà fún un látinú Bíbélì àti ìrànlọ́wọ́ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ kó o yọ. Kí wá ni ìṣarasíhùwà Birgit nísinsìnyí? Ó ní: “Mo dúpẹ́ gan-an ni pé mo ṣì wà nínú ètò Jèhófà tó tayọ lọ́lá.” Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó ń jẹ́ Andreas náà sọ pé: “Jèhófà ló ni ètò yìí lóòótọ́, òun lètò tó dára jù lọ lágbàáyé.” Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa dúpẹ́ fún àwọn ohun rere tó wà nínú apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà?
Aláìpé Làwọn Tó Ń Múpò Iwájú
8, 9. Irú ìwà wo làwọn kan hù nígbà ayé Dáfídì, kí sì ni ìṣarasíhùwà Dáfídì sí wọn?
8 Kò sí àní-àní pé aláìpé làwọn tí ètò Ọlọ́run yàn kí wọ́n máa múpò iwájú nínú ìjọsìn tòótọ́. Gbogbo wọn ló ń ṣàṣìṣe, òmíràn lára wọn sì ní kùdìẹ̀-kudiẹ tó ń bá jìjàkadì lójú méjèèjì. Ṣé ó yẹ kí èyí máa bí wa nínú? Rárá o. Àwọn kan tí wọ́n ń múpò iwájú ní Ísírẹ́lì ìgbàanì pàápàá ṣe àṣìṣe tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì ṣì wà ní ọ̀dọ́, wọ́n ní kó máa fi háàpù kọrin fún Sọ́ọ̀lù Ọba nígbà tó wà nínú ìnira kára lè máa tù ú. Àmọ́ nígbà tó yá, ńṣe ni Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti pa Dáfídì, kódà sísá ni Dáfídì sá fẹ́mìí ẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 16:14-23; 18:10-12; 19:18; 20:32, 33; 22:1-5.
9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì míì náà hùwà àdàkàdekè. Bí àpẹẹrẹ, Jóábù olórí ogun Dáfídì pa Ábínérì ìbátan Sọ́ọ̀lù. Ábúsálómù dìtẹ̀ láti gbapò ọba mọ́ Dáfídì baba rẹ̀ lọ́wọ́. Áhítófẹ́lì tó jẹ́ bọ́bajíròrò tí Dáfídì finú tán da Dáfídì. (2 Sámúẹ́lì 3:22-30; 15:1-17, 31; 16:15, 21) Síbẹ̀, Dáfídì ò tìtorí nǹkan wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn ṣáá, bẹ́ẹ̀ ni kò torí ìyẹn kẹ̀yìn sí ìsìn tòótọ́. Ohun tí Dáfídì ṣe yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo ìyẹn. Ńṣe ni ìpọ́njú Dáfídì mú kó túbọ̀ rọ̀ mọ́ Jèhófà, kò sì fi ìwà rere tó ń hù kó tó di pé ó sá fún Sọ́ọ̀lù sílẹ̀. Orin tí Dáfídì kọ lásìkò yẹn ni pé: “Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, fi ojú rere hàn sí mi, nítorí pé ìwọ ni ọkàn mi sá di; òjìji ìyẹ́ apá rẹ sì ni mo sá di títí àwọn àgbákò fi ré kọjá.”—Sáàmù 57:1.
10, 11. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni kan tó ń jẹ́ Gertrud nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, kí ló sì sọ nípa àṣìṣe àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀?
10 Kò sídìí tá a fi lè sọ pé àdàkàdekè wà nínú ètò Ọlọ́run lónìí rárá. Jèhófà, àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí ò jẹ́ fàyè gba àwọn èèyàn burúkú tó jẹ́ aládàkàdekè nínú ìjọ Kristẹni. Àmọ́ ṣá o, gbogbo wa pátá làìpé máa ń yọ lẹ́nu, yálà àìpé tiwa tàbí tàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì.
11 Nígbà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Gertrud tó ti ń sin Jèhófà látìgbà pípẹ́ wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé irọ́ ló pa pé aṣáájú-ọ̀nà lòun, wọ́n ní ẹlẹ̀tàn ẹ̀dá ni. Kí ni arábìnrin yìí ṣe? Ǹjẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í kùn nípa ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án? Rárá o. Kó tó di pé ó kú lẹ́ni ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún lọ́dún 2003, ó wo irú ìgbésí ayé tóun gbé, ó wá sọ pé: “Àwọn ìrírí yẹn àtàwọn míì bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí n rí i pé bí àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tiẹ̀ ń ṣàṣìṣe, Jèhófà ló ṣì ń darí iṣẹ́ bàǹtà-banta rẹ̀, àwa èèyàn aláìpé ló sì ń lò láti ṣe é.” Tí Gertrud bá rí i pé àìpé mú kí ẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣìwà hù sóun, ńṣe ló máa ń fi taratara gbàdúrà sí Jèhófà.
12. (a) Ohun àìdáa wo làwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe? (b) Orí àwọn nǹkan wo ló yẹ ká pọkàn pọ̀ sí?
12 Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni tó jẹ́ olóòótọ́ àti olùfọkànsìn gidigidi pàápàá ti máa ń ṣàṣìṣe, tí ẹnì kan tí ètò Ọlọ́run yàn sípò bá ṣàṣìṣe, ẹ má ṣe jẹ́ ká tìtorí ìyẹn ṣíwọ́ ṣíṣe “ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú.” (Fílípì 2:14) Yóò burú gan-an o tá a bá lọ ṣe bíi tàwọn kan tí wọ́n ṣe ohun tí kò dáa nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní! Ọmọ ẹ̀yìn náà Júdà sọ pé àwọn olùkọ́ni èké ìgbà ayé rẹ̀ “ń ṣàìka ipò olúwa sí, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú.” Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aláìdáa èèyàn ayé ìgbà náà jẹ́ “oníkùnsínú, àwọn olùráhùn nípa ìpín wọn nínú ìgbésí ayé.” (Júúdà 8, 16) Yóò dára pé ká má ṣe ṣe bíi tàwọn oníkùnsínú tó ń ráhùn yẹn, ká sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan àtàtà tá à ń rí gbà nípasẹ̀ ‘ẹrú olóòótọ́’ náà. Ẹ jẹ́ ká máa fójú iyebíye wo àwọn nǹkan rere tó wà nínú ètò Jèhófà, ká sì máa bá a lọ láti “ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú.”
“Ọ̀rọ̀ Yìí Ń Múni Gbọ̀n Rìrì”
13. Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn kan sí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi?
13 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan kùn sí àwọn tí ètò Ọlọ́run yàn sípò ni, nígbà tí àwọn míì kùn sí ẹ̀kọ́ Jésù. Nínú Jòhánù 6:48-69, Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń fi ẹran ara mi ṣe oúnjẹ jẹ, tí ó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Nígbà tí “ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀” gbọ́ èyí, wọ́n ní: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?” Jésù mọ̀ pé “àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ń kùn nípa èyí.” Àní, “ní tìtorí èyí, ọ̀pọ̀ nínú [wọn] lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.” Ṣùgbọ́n gbogbo ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kọ́ ló kùn. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bi àwọn àpọ́sítélì méjìlá pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” Àpọ́sítélì Pétérù dá a lóhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun; àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”
14, 15. (a) Kí ló fà á tí àwọn kan lára ẹ̀kọ́ tí ètò Ọlọ́run ń kọ́ wa ò fi tẹ́ àwọn kan lọ́rùn? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Emanuel?
14 Láyé òde òní, àlàyé tí apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà ṣe nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan ò tẹ́ àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́rùn, wọ́n wá ń kùn. Kí ló máa ń fa irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Ohun tó sábà máa ń fa irú ìkùnsínú bẹ́ẹ̀ ni àìlóye ọ̀nà tí Ọlọ́run máa ń gbà ṣe àwọn nǹkan. Ńṣe ni Ẹlẹ́dàá máa ń ṣí òtítọ́ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé fàwọn èèyàn rẹ̀. Nítorí náà, àyípadà á máa bá òye wa nípa Ìwé Mímọ́ láwọn ìgbà míì. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn Jèhófà ni irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ máa ń fún láyọ̀. Àmọ́ àwọn díẹ̀ kan máa ń di “olódodo àṣelékè,” wọn kì í fara mọ́ àwọn àyípadà wọ̀nyẹn. (Oníwàásù 7:16) Ìgbéraga tún lè fà á tàbí kó jẹ́ pé òmíràn nínú wọn fẹ́ gbé ìmọ̀ ti ara wọn kalẹ̀. Ohun yòówù tí ì báà fà á, irú ìkùnsínú bẹ́ẹ̀ léwu gan-an nítorí ó lè fani padà sínú ayé àtàwọn ọ̀nà ayé.
15 Bí àpẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Emanuel ṣe lámèyítọ́ àwọn nǹkan kan tó kà nínú ìwé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45) Nígbà tó yá, kò ka àwọn ìwé ètò Jèhófà mọ́, níkẹyìn ó sọ fáwọn alàgbà ìjọ rẹ̀ pé òun kò fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí Emanuel fi rí i pé ẹ̀kọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an ló tọ̀nà. Ló bá lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí, ó gba àṣìṣe rẹ̀ láṣìṣe, wọ́n sì gbà á padà sínú ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá padà dẹni tó láyọ̀.
16. Kí ló lè jẹ́ ká borí iyèméjì tá a bá ní nípa àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni kan?
16 Tó bá di pé a fẹ́ máa kùn nítorí pé à ń ṣiyèméjì nípa àwọn ẹ̀kọ́ kan táwa èèyàn Jèhófà gbà gbọ́ ńkọ́? Ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù. Nígbà tó bá yá ‘ẹrú olóòótọ́’ lè tẹ nǹkan kan jáde nígbà tó bá yá tó máa wá yanjú àwọn ohun tá à ń ṣiyèméjì nípa rẹ̀, kí iyèméjì wa sì pòórá. Ó tún bọ́gbọ́n mu pé ká lọ bá àwọn alàgbà ìjọ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. (Júúdà 22, 23) Àdúrà gbígbà, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìfararora pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lọ́kàn tún lè mú iyèméjì wa kúrò, kó sì jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró tá a ti kọ́ nípasẹ̀ ètò tí Jèhófà ń lò láti fi bá wa sọ̀rọ̀.
Má Ṣe Lẹ́mìí Ìráhùn
17, 18. Dípò tí a ó fi máa kùn, irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní, kí sì nìdí rẹ̀?
17 Lóòótọ́, a sábà máa ń ṣẹ̀ nítorí aláìpé ni wá, àwọn kan sì wà tó fẹ́ràn àtimáa ráhùn láìnídìí. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Róòmù 5:12) Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, tó bá ti mọ́ wa lára láti máa kùn, ìyẹn lè ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé a ò gba ẹ̀mí ìkùnsínú láyé rárá.
18 Dípò tí a ó fi máa kùn nípa ìṣètò inú ìjọ, ńṣe ni ká fiyè dénú, ká lẹ́mìí tó dáa. Ká wá tara bọ ìgbòkègbodò tẹ̀mí táá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí, táá jẹ́ ká máa láyọ̀, ká bẹ̀rù Ọlọ́run, ká wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí ìgbàgbọ́ wa sì lágbára. (1 Kọ́ríńtì 15:58; Títù 2:1-5) Ìkáwọ́ Jèhófà ni gbogbo nǹkan tó ń lọ nínú ètò Ọlọ́run wà, Jésù sì mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú gbogbo ìjọ lónìí bó ṣe mọ̀ ọ́n ní ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣípayá 1:10, 11) Fi sùúrù dúró de Ọlọ́run àti Kristi tó jẹ́ Orí ìjọ. Ọlọ́run lè lo àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó yàn láti fi ṣe àtúnṣe àwọn ohun tó bá kù díẹ̀ káàtó.—Sáàmù 43:5; Kólósè 1:18; Títù 1:5.
19. Kó tó di pé Ìjọba Mèsáyà gba àkóso ayé, kí ló yẹ ká máa fiyè sí?
19 Láìpẹ́ láìjìnnà, ètò àwọn nǹkan búburú yìí yóò dópin, Ìjọba Mèsáyà yóò sì gba àkóso ayé. Ṣùgbọ́n kó tó dìgbà yẹn, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí ẹnikẹ́ni nínú wa má ṣe lẹ́mìí ìráhùn! Ìyẹn á jẹ́ ká lè máa rí ìwà rere àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa dípò tí a ó fi máa wá àṣìṣe wọn. Tá a bá ń wo ibi tí wọ́n dáa sí, a óò máa láyọ̀. Ìyẹn á máa fún wa níṣìírí á sì máa gbé wa ró nípa tẹ̀mí dípò tí ìkùnsínú á fi máa bà wá lọ́kàn jẹ́.
20. Tá ò bá lẹ́mìí ìráhùn, àwọn ìbùkún wo la máa ní?
20 Tá ò bá lẹ́mìí ìráhùn, a ó tún lè máa fiyè sí ọ̀pọ̀ ìbùkún tá à ń rí gbà nítorí pé a wà nínú ètò Jèhófà. Ètò yìí nìkan ṣoṣo ló jẹ́ olóòótọ́ sí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Báwo ni mímọ̀ tó o mọ̀ bẹ́ẹ̀ àti àǹfààní tó o ní láti máa sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, ṣe rí lára rẹ? Ǹjẹ́ kí ìṣarasíhùwà rẹ dà bíi ti Dáfídì tó kọrin pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá. Aláyọ̀ ni ẹni tí ìwọ yàn, tí ìwọ sì mú kí ó tọ̀ ọ́ wá, kí ó lè máa gbé inú àwọn àgbàlá rẹ. Dájúdájú, àwọn ohun rere inú ilé rẹ yóò tẹ́ wa lọ́rùn.”—Sáàmù 65:2, 4.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ nítori àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ?
• Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa nígbà táwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ bá ṣàṣìṣe?
• Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn àyípadà tó ń bá òye wa nípa Ìwé Mímọ́?
• Kí ló lè mú kí Kristẹni kan borí iyèmejì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Dáfídì gbé àwòrán bí wọ́n ṣe máa kọ́ tẹ́ńpìlì lé Sólómọ́nì lọ́wọ́ ò sí fi tọkàntọkàn ṣètìlẹyìn fún ìsìn tòótọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn alàgbà ìjọ máa ń fi ìdùnnú ṣe ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí fún àwọn ará