“Ẹ Ti Gbọ́ Nípa Ìfaradà Jóòbù”
“Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.”—JÁKỌ́BÙ 5:11.
1, 2. Ìyà wo ni wọ́n fi jẹ tọkọtaya kan nílẹ̀ Poland?
KÒ TÍÌ pọ́dún kan tí Harald Abt di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà táwọn ọmọ ogun Hitler gba àkóso ìlú Danzig (ìyẹn ìlú Gdańsk báyìí) ní àríwá orílẹ̀-èdè Poland. Nǹkan wá le gan-an fáwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà níbẹ̀, inú ewu ni wọ́n wà. Àwọn ọlọ́pàá Gestapo fẹ́ fipá mú Harald láti fọwọ́ síwèé pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ṣùgbọ́n Harald kọ̀. Bó ṣe dèrò ẹ̀wọ̀n nìyẹn. Lẹ́yìn tó ti lo ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n mú un kúrò níbẹ̀ lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen níbi tí wọ́n ti lù ú nílùkulù láìmọye ìgbà, tí wọ́n sì ń fikú halẹ̀ mọ́ ọn. Níbẹ̀, ọlọ́pàá kan nawọ́ síbi tí èéfín ń gbà jáde látinú ilé tí wọ́n ti ń sun òkú àwọn èèyàn, ó wá sọ fún Harald pé, “Wò ó, kó tó di ọjọ́ mẹ́rìnlá òní, tó o bá ṣì di ìgbàgbọ́ ẹ mú, ibẹ̀ yẹn lo ti máa jóná kú tí èéfín ẹ á sì gòkè lọ sọ́dọ̀ Jèhófà rẹ.”
2 Lákòókò táwọn ọlọ́pàá wá mú Harald, ìyàwó rẹ̀ Elsa ṣì ń fún ọmọ wọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́wàá lọ́mú. Àmọ́ àwọn ọlọ́pàá Gestapo ò ro gbogbo ìyẹn. Láìpẹ́ sígbà yẹn, wọ́n gba ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n sì mú Elsa lọ síbi táwọn ológun Násì ti ń dá ẹ̀mí àwọn èèyàn légbodò nílùú Auschwitz. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Elsa lò níbẹ̀ àmọ́ kò kú síbẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà ò sì kú ságọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ile-Iṣọ Naa ti April 15, 1980 sọ púpọ̀ sí i nípa bí wọ́n ṣe fara dà á. Harald kọ̀wé pé: “Àpapọ̀ iye ọdún tí mo lò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run jẹ́ ọdún mẹ́rìnlá. Wọ́n máa ń bi mí pé: ‘Ǹjẹ́ ìyàwó rẹ ṣe nǹkan kan tó fún ọ níṣìírí tó o fi lè fara da gbogbo ìyà yẹn?’ Ohun tí mo máa fi ń dáhùn ni pé, ‘Ìṣírí ńlá ni ìyàwó mi jẹ́ fún mi o!’ Àtìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti mọ̀ pé ìyàwó mi ò ní ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ rẹ̀, mímọ̀ tí mo sì mọ èyí ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Mo mọ̀ pé yóò tẹ́ ìyàwó mi lọ́rùn pé kí n kú ju pé kó gbọ́ pé wọ́n ti dá mi sílẹ̀ nítorí pé mo sẹ́ ìgbàgbọ́ mi. . . . Ìyà tí wọ́n fi jẹ Elsa ní gbogbo ọdún tó lò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nílẹ̀ Jámánì kì í ṣe kékeré.”
3, 4. (a) Àpẹẹrẹ àwọn wo ló lè fáwọn Kristẹni níṣìírí láti lẹ́mìí ìfaradà? (b) Kí nìdí tí Bíbélì fi gbà wá níyanjú pé ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù yẹ̀ wò?
3 Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti fìyà jẹ ló lè jẹ́rìí sí i pé ìyà kì í ṣe omi ọbẹ̀. Ìdí nìyí tí Bíbélì fi gba gbogbo Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi àwọn wòlíì, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà ṣe àpẹẹrẹ jíjìyà ibi àti mímú sùúrù.” (Jákọ́bù 5:10) Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ṣe inúnibíni sí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láìnídìí. Àpẹẹrẹ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” yìí lè jẹ́ ìṣírí fún wa káwa náà lè máa fi ìfaradà sá eré ìje Kristẹni wa lọ láìdáwọ́ dúró.—Hébérù 11:32-38; 12:1.
4 Nínú gbogbo àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn pé ó lẹ́mìí ìfaradà, Jóòbù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ta yọ tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Wò ó! Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jákọ́bù 5:11) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù jẹ́ ká mọ irú èrè tí ń bẹ fáwọn olóòótọ́ èèyàn tí wọ́n rí ojú rere Jèhófà. Èyí tó tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ni pé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tó máa ṣe wá láǹfààní lákòókò ìṣòro. Ìwé Jóòbù bá wa dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tó fi yẹ ká máa rántí ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro? Àwọn ànímọ́ àti ìwà wo ló máa jẹ́ ká lè lẹ́mìí ìfaradà? Báwo la ṣe lè fún àwọn Kristẹni bíi tiwa lókun nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìpọ́njú?
Ó Yẹ Ká Lóye Ọ̀ràn Tó Wà Nílẹ̀
5. Kí ni ọ̀ràn pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro tàbí tí ohun kan bá dán ìgbàgbọ́ wa wò?
5 Ká tó lè dúró gbọn-in nígbà tí ìṣòro ńlá bá dé, a ní láti lóye ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ dáadáa. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ìṣòro wa lè gbà wá lọ́kàn débi pé a ò ní fiyè sí àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ ìdúróṣinṣin wa sí Ọlọ́run ló sì ṣe pàtàkì jù. Baba wa ọ̀run sọ̀rọ̀ kan fún wa tó yẹ ká fi sọ́kàn, ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Àǹfààní yìí mà ga o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dá aláìpé ni wá a sì ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, a lè múnú Ẹlẹ́dàá wa dùn. Ọ̀nà tá a sì lè gbà ṣe èyí ni pé kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà mú ká dúró gbọn-in nígbà ìṣòro àti nígbà tí ohun kan bá dán ìgbàgbọ́ wa wò. Irú ìfẹ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí máa ń jẹ́ kéèyàn lè fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ yìí kì í sì í kùnà láé.—1 Kọ́ríńtì 13:7, 8.
6. Báwo ni Sátánì ṣe ń ṣáátá Jèhófà, ibo ló sì ti bá ìṣáátá yìí dé?
6 Kedere kèdèrè ni ìwé Jóòbù fi hàn pé Sátánì lẹni tó ń ṣáátá Jèhófà. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé olubi ni ẹ̀dá ẹ̀mí yìí àti pé ńṣe ló fẹ́ ba àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù fi hàn pé gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ni Sátánì ń fẹ̀sùn kàn pé kì í ṣe tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń sin Ọlọ́run, ó sì ń wá ọ̀nà tó máa gbà fi hàn pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run lè di tútù. Sátánì ò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣáátá Ọlọ́run o, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ló ti ń bá a bọ̀. Nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run, ohùn kan láti ọ̀run wá pè é ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa,” ó ní ńṣe ló ń fẹ̀sùn kàn wọ́n “tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa.” (Ìṣípayá 12:10) Torí náà, tá a bá ń fara da ìṣòro èyíkéyìí láìyẹsẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé irọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn tí Sátánì fi ń kàn wá.
7. Kí ni ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà gbógun ti àárẹ̀ nípa tara?
7 Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Èṣù á fẹ́ lo ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa láti fi mú wa jìnnà sí Jèhófà. Ṣebí ìgbà tí ebi ń pa Jésù lẹ́yìn tó ti gbààwẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ni Èṣù dán an wò. (Lúùkù 4:1-3) Àmọ́, okun tí Jésù ní nítorí àjọṣe tó dán mọ́rán tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run mú kó lè borí ìdánwò Èṣù. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà ká lè ní okun tí a ó fi lè gbógun ti àárẹ̀ nípa tara tí a bá ní, bóyá nítorí àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó! Àní, “bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro,” a ò ní juwọ́ sílẹ̀ nítorí pé “ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—2 Kọ́ríńtì 4:16.
8. (a) Àkóbá wo ni àròdùn ọkàn lè ṣe fún wa? (b) Ìtẹ̀sí èrò orí tàbí ìwà wo ni Jésù ní?
8 Yàtọ̀ síyẹn, àròdùn ọkàn lè jẹ́ kí àárẹ̀ mú wa nípa tẹ̀mí. Ẹnì kan lè ronú pé, ‘Jèhófà ṣe jẹ́ kéyìí ṣẹlẹ̀ sí mi?’ Bí wọ́n bá ti hùwà àìdáa sẹ́lòmíì, ó lè máa sọ pé, ‘Báwo ni arákùnrin ṣe lè ṣe irú nǹkan yìí sí mi?’ Irú èrò bẹ́ẹ̀ lè má jẹ́ ká fiyè sí ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀, kó jẹ́ pé ọ̀ràn tara wa ló máa ká wa lára. Ẹ̀dùn ọkàn tí Jóòbù ní látàrí inú tó bí i nítorí ọ̀rọ̀ táwọn mẹ́ta tó pera wọn ní ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìrora tó ní nítorí àìsàn rẹ̀. (Jóòbù 16:20; 19:2) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi yé wa pé inú àbíjù lè mú kéèyàn “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfésù 4:26, 27) Torí náà, dípò tí àwa Kristẹni á fi máa bínú sẹ́nì kan tàbí kó jẹ́ pé ìwà àìdáa tí wọ́n hù sí wa ni a óò máa ronú nípa rẹ̀ ṣáá, á dára ká ṣe bíi Jésù ká ‘fi ara wa lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo,’ ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. (1 Pétérù 2:21-23) Tá a bá ní “ìtẹ̀sí èrò orí” bíi ti Jésù tàbí à ń hùwà bíi tirẹ̀, Sátánì ò ní lè rí wa mú.—1 Pétérù 4:1.
9. Kí ni Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò bá wa ṣe sí àwọn ẹrù ìnira tàbí ìdẹwò wa?
9 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kò yẹ ká máa wo ìṣòro wa gẹ́gẹ́ bí àmì pé Ọlọ́run ti kọ̀ wá sílẹ̀. Irú èrò tí kò tọ̀nà yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jóòbù nígbà táwọn tó yẹ kó tù ú nínú ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. (Jóòbù 19:21, 22) Bíbélì sọ ọ̀rọ̀ kan tó fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Dípò ìyẹn, Jèhófà sọ pé òun yóò bá wa gbé ẹrù ìnira èyíkéyìí, òun yóò sì yọ wá nínu gbogbo ìdẹwò. (Sáàmù 55:22; 1 Kọ́ríńtì 10:13) Tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run nígbà ìṣòro, a óò lè fi ojú tó tọ́ wo ìṣòro wa, a óò sì lè kọjú ìjà sí Èṣù.—Jákọ́bù 4:7, 8.
Àwọn Ohun Tó Lè Jẹ́ Ká Lẹ́mìí Ìfaradà
10, 11. (a) Kí ló jẹ́ kí Jóòbù lè fara da ìṣòro rẹ̀? (b) Báwo ni ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ ṣe ran Jóòbù lọ́wọ́?
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro tó lékenkà dé bá Jóòbù, tí àwọn tó pera wọn ní olùtùnú bẹ̀rẹ̀ sí í bú u, tí ọkàn rẹ̀ sì dà rú nítorí kò mọ ohun tó fa gbogbo ìṣòro yìí, síbẹ̀ Jóòbù ò fi Ọlọ́run sílẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìfaradà Jóòbù yìí? Láìsí àní-àní, olórí ohun tó mú kí Jóòbù lè fara da gbogbo ìṣòro yẹn ni pé tọkàntọkàn ló fi ń sin Jèhófà. ‘Ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì yà kúrò nínú ohun búburú.’ (Jóòbù 1:1) Ìwà Jóòbù nìyẹn. Kò fi Jèhófà sílẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ìdí tí gbogbo ìṣòro wọ̀nyẹn fi dé bá òun. Jóòbù mọ̀ pé kò sígbà tí kò yẹ kóun máa sin Ọlọ́run, yálà nǹkan rọgbọ ni o tàbí kò rọgbọ.—Jóòbù 1:21; 2:10.
11 Nǹkan míì tó tu Jóòbù nínú tó jẹ́ kó lè fara da ìṣòro rẹ̀ ni ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó mọ́. Nígbà tó dà bíi pé ọjọ́ ikú rẹ̀ ti sún mọ́lé, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé òun ti sa gbogbo ipá òun láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, pé òun ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà, àti pé òun ò lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké èyíkéyìí.—Jóòbù 31:4-11, 26-28.
12. Kí ni ìṣarasíhùwà Jóòbù sí ìmọ̀ràn àti ìbáwí tí Élíhù fún un?
12 Àmọ́ ṣá o, Jóòbù ní àwọn èrò kan tí kò tọ̀nà tó gba pé kí wọ́n bá a wí kó lè yí padà. Nígbà tí wọ́n sì bá a wí, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gbà á. Fífi tó fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí yìí ni ohun mìíràn tó jẹ́ kó lè fara da ìṣòro rẹ̀. Ó fara balẹ̀ gbọ́ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Élíhù fún un, ó sì gba ìbáwí tí Jèhófà fún un. Ó sọ pé: ‘Mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò lóye. Mo yíhùn padà, mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.’ (Jóòbù 42:3, 6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó kọ lù ú kò tíì fi í sílẹ̀, síbẹ̀ inú rẹ̀ dùn nítorí pé yíyí tó yí èrò rẹ̀ padà yìí mú kó túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Jóòbù sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé [Jèhófà] lè ṣe ohun gbogbo.” (Jóòbù 42:2) Àlàyé tí Jèhófà ṣe nípa bí òun ṣe tóbi lọ́ba jẹ́ kí Jóòbù túbọ̀ lóye dáadáa pé Ẹlẹ́dàá ga ju èèyàn lọ fíìfíì.
13. Báwo ní ẹ̀mí ìdáríjini ṣe ṣe Jóòbù láǹfààní?
13 Paríparí rẹ̀, tó bá dọ̀rọ̀ ká dárí jini, Jóòbù jẹ́ àpẹẹrẹ kan tó ta yọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn olùtùnú èké mẹ́ta náà ṣe dun Jóòbù gan-an, síbẹ̀ nígbà tí Jèhófà ní kó gbàdúrà fún wọn, Jóòbù ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, Jèhófà mú Jóòbù lára dá. (Jóòbù 42:8, 10) Ó ṣe kedere pé tá a bá ń ní ọmọnìkejì wa sínú, a ò ní lè lẹ́mìí ìfaradà àmọ́ tá a bá nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa tá a sì ń dárí jì wọ́n, a ó lè lẹ́mìí ìfaradà. Ara á tù wá bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, ohun tí Jèhófà sì ń fẹ́ nìyẹn.—Máàkù 11:25.
Àwọn Ọlọgbọ́n Agbaninímọ̀ràn Tó Ń Ranni Lọ́wọ́ Láti Lẹ́mìí Ìfaradà
14, 15. (a) Àwọn ànímọ́ wo ló máa jẹ́ kí ẹni tó ń gbani nímọ̀ràn lè gbéni ró? (b) Ṣàlàyé ohun tó jẹ́ kí Élíhù lè fún Jóòbù nímọ̀ràn tí Jóòbù sì gba ìmọ̀ràn ọ̀hún.
14 Ẹ̀kọ́ mìíràn tá a lè kọ́ látinú ìtàn Jóòbù ni pé àwọn agbaninímọ̀ràn ọlọgbọ́n wúlò gan-an. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dà bí àwọn arákùnrin “tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bí ìtàn Jóòbù ṣe fi hàn, ńṣe làwọn agbaninímọ̀ràn míì máa ń dá kún ìṣòro ẹni dípò kí wọ́n gbéni ró. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ńṣe ló yẹ kí ẹni tó ń gbani nímọ̀ràn ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, ọ̀wọ̀ àti inú rere bíi ti Élíhù. Láwọn ìgbà míì, àwọn alàgbà tàbí àwọn Kristẹni mìíràn tó dàgbà dénú máa ń fún àwọn kan tí ìṣòro wọ̀ lọ́rùn nímọ̀ràn, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ló sì wà nínú ìwé Jóòbù tí irú àwọn agbaninímọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè rí kọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè máa fúnni nímọ̀ràn.—Gálátíà 6:1; Hébérù 12:12, 13.
15 Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lèèyàn lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Élíhù gbà bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Ó fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò tọ́ táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń sọ kó tó fún wọn lésì. (Jóòbù 32:11; Òwe 18:13) Élíhù lo orúkọ Jóòbù nígbà tó ń bá a sọ̀rọ̀, ó sì pàrọwà sí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́. (Jóòbù 33:1) Kò ronú pé òun sàn ju Jóòbù lọ gẹ́gẹ́ bí àwọn olùtùnú èké mẹ́ta yẹn ti ṣe. Ó ní: “Amọ̀ ni a fi mọ mí jáde, èmi pẹ̀lú.” Élíhù ò fẹ́ dá kún ẹ̀dùn ọkàn Jóòbù, ìdí nìyẹn tí kò fi sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé kankan. (Jóòbù 33:6, 7; Òwe 12:18) Dípò tí Élíhù á fi máa dá Jóòbù lẹ́bi nítorí ìwà tó hù tẹ́lẹ̀, ńṣe ló yìn ín fún ìwà òdodo rẹ̀. (Jóòbù 33:32) Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan ni Élíhù fi wò ó, ó fi yé Jóòbù pé Jèhófà ò ní hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu láé. (Jóòbù 34:10-12) Ó gba Jóòbù nímọ̀ràn pé kó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́ dípò táá fi máa fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí olódodo. (Jóòbù 35:2; 37:14, 23) Ó dájú pé àwọn alàgbà àtàwọn míì lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àpẹẹrẹ yìí.
16. Báwo ni Sátánì ṣe lo àwọn olùtùnú èké tó wá sọ́dọ̀ Jóòbù?
16 Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n ni Élíhù fún Jóòbù àmọ́ ọ̀rọ̀ tí ń gúnni bí idà ni Élífásì, Bílídádì, àti Sófárì sọ sí Jóòbù. Jèhófà sọ fún wọn pé: “Ẹ kò sọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa mi.” (Jóòbù 42:7) Àní bí wọ́n tiẹ̀ sọ pé èrò tó dáa làwọn ní lọ́kàn, ohun tí wọ́n ṣe fi hàn pé wọ́n jẹ́ kí Sátánì lò wọ́n dípò tí wọ́n á fi máa bá Jóòbù dárò. Látìbẹ̀rẹ̀ làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti sọ ọ́ pé Jóòbù ló fọwọ́ ara rẹ̀ fa ìṣòro tó dé bá a. (Jóòbù 4:7, 8; 8:6; 20:22, 29) Élífásì sọ pé Ọlọ́run ò fọkàn tán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó ní kò séyìí tó kan Ọlọ́run yálà a jẹ́ olóòótọ́ tàbí a ò jẹ́ bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 15:15; 22:2, 3) Ó tiẹ̀ tún fẹ̀sùn ohun tí Jóòbù ò ṣe kàn án. (Jóòbù 22:5, 9) Àmọ́ ńṣe ni Élíhù gbé e ró kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run tún lè dán mọ́rán, ohun tó sì máa ń jẹ agbaninímọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ lógún nìyẹn.
17. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tí àdánwò bá dé?
17 Ẹ̀kọ́ mìíràn tún wà nípa ìfaradà tá a lè rí kọ́ látinú ìwé Jóòbù. Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ rí ipò tá a wà, kì í sì í ṣe pé ó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ nìkan ni, ó tún lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ ní onírúurú ọ̀nà. Níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin Elsa Abt. Wo ohun tó sọ lẹ́yìn gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní: “Káwọn ọlọ́pàá tó wá mú mi, mo ti ka lẹ́tà arábìnrin kan tó sọ pé nígbà téèyàn bá wà nínú ìṣòro, ẹ̀mí Jèhófà máa ń mú kí ọkàn ẹni balẹ̀. Mo rò pé àsọdùn ni arábìnrin yẹn ń sọ. Àmọ́ nígbà tí àdánwò dé bá èmi alára, mo wá rí i pé òótọ́ ni. Bó ṣe sọ ọ́ yẹn gan-an ló rí. Tí kò bá tíì ṣẹlẹ̀ síni rí, èèyàn á rò pé kò lè rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi ni. Jèhófà ń ranni lọ́wọ́ lóòótọ́.” Kì í ṣe ohun tí Jèhófà lè ṣe tàbí ohun tó ti ṣe nígbà ayé Jóòbù ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Elsa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ o. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò tiwa yìí ló ń sọ. Àní sẹ́ “Jèhófà ń ranni lọ́wọ́ lóòótọ́!”
Aláyọ̀ Ni Ẹni Tó Lẹ́mìí Ìfaradà
18. Àwọn àǹfààní wo ni ìfaradà Jóòbù ṣe fún un?
18 Ṣàṣà lára wa ló máa ní irú ìṣòro tó le koko bíi ti Jóòbù. Àmọ́ o, yálà ìṣòro ńlá ló dé bá wa tàbí kékeré, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kó sún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run bíi ti Jóòbù. Ká sòótọ́, ìfaradà ṣe Jóòbù láǹfààní gan-an. Ó mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, ó sì jẹ́ kí Jóòbù pé pérépéré. (Jákọ́bù 1:2-4) Ó mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ dán mọ́rán sí i. Jóòbù sọ pé: “Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.” (Jóòbù 42:5) Ọ̀rọ̀ Sátánì já sí irọ́ nítorí pé kò lè ba ìwà títọ́ Jóòbù jẹ́. Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà ṣì sọ̀rọ̀ Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ó jẹ́ olódodo téèyàn lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Ìsíkíẹ́lì 14:14) Ìṣírí ni ìwà títọ́ àti ìfaradà rẹ̀ jẹ́ fáwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní.
19. Kí nìdí tó o fi rò pé ó dára kéèyàn lẹ́mìí ìfaradà?
19 Nígbà tí Jákọ́bù kọ̀wé sáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nípa ìfaradà, ó fi yé wọn pé ìfaradà máa ń fúnni ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ó sì fi Jóòbù ṣe àpẹẹrẹ láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́pọ̀ yanturu. (Jákọ́bù 5:11) Jóòbù 42:12 sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ó bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.” Ọlọ́run fún Jóòbù ní ìlọ́po méjì gbogbo nǹkan tó pàdánù, Jóòbù sì tún gbé ìgbé ayé aláyọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. (Jóòbù 42:16, 17) Bákan náà, Ọlọ́run yóò mú ìrora, ìyà, tàbí ẹ̀dùn ọkàn tó lè máa pọ́n wa lójú nínú ètò àwọn nǹkan yìí kúrò, wọn yóò sì di ohun ìgbàgbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Aísáyà 65:17; Ìṣípayá 21:4) A ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, a sì ti pinnu pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a óò ní ìfaradà bíi tirẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè, èyí tí Jèhófà ṣèlérí fún àwọn tí ń bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—Jákọ́bù 1:12.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo la ṣe lè múnú Jèhófà dùn?
• Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ronú pé àwọn ìṣòro wa jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ti kọ̀ wá sílẹ̀?
• Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ kí Jóòbù lè fara da ìṣòro tó ní?
• Báwo la ṣe lè máa gbé àwọn ará wa ró gẹ́gẹ́ bí Élíhù ti ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ó yẹ kẹ́ni tó ń gbani nímọ̀ràn ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, ọ̀wọ̀ àti inú rere
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Elsa àti Harald Abt rèé