ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 2/15 ojú ìwé 27-30
  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Bí A Ṣe Lè Bójútó Ìṣòro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Bí A Ṣe Lè Bójútó Ìṣòro
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Fífúnni Ní Ìmọ̀ràn Tí Kò Gbéṣẹ́
  • Bí A Ṣe Ń Fúnni Ní Ìmọ̀ràn
  • Jèhófà Wò Ó Sàn
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Èrè Jobu—Orísun kan Fún Ìrètí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóòbù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 2/15 ojú ìwé 27-30

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Bí A Ṣe Lè Bójútó Ìṣòro

ÀWỌN ènìyàn díẹ̀ ni wọ́n tí ì kojú gbogbo ìṣòro tí Jobu ní rí. Láàárín àkókò kúkúrú, ìpàdánù ọrọ̀ rẹ̀ àti ọ̀nà àtigbọ́ bùkátà, ikú òjijì tí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ kú, àti níkẹyìn òkùnrùn ríronilára mú àdánù dé bá a. Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ̀ ta á nù tán, aya rẹ̀ rọ̀ ọ́ láti “bú Ọlọrun, kí ó sì kú”!—Jobu 2:9; 19:13, 14.

Bí ó ti wù kí ó rí, Jobu jẹ́ orísun ìṣírí aláìlẹ́gbẹ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń nírìírí irú àdánwò bẹ́ẹ̀. Àbájáde ṣíṣàǹfààní tí ìrírí rẹ̀ tí ń dánniwò mú wá fihàn pé ìfaradà lójú ìpọ́njú ń mú ọkàn-àyà Jehofa yọ̀, nígbà tí ojúlówó ìfọkànsìn Ọlọrun bá sún wa ṣe é, dípò kí ó jẹ́ nítorí àǹfààní ti ara-ẹni.—Jobu, orí 1, 2; 42:10-17; Owe 27:11.

Àkọsílẹ̀ Bibeli yìí tún ní àwọn ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ṣíṣeyebíye nínú nípa bí a ṣe lè bójútó àwọn ìṣòro. Ó pèsè àwọn àpẹẹrẹ tí ń fanimọ́ra nípa bí a ṣe níláti—àti bí a kò ṣe níláti—fún ẹnì kan tí ó dojúkọ àdánwò ní ìmọ̀ràn. Síwájú síi, ìrírí ti Jobu fúnra rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti hùwàpadà ní ọ̀nà tí ó wàdéédéé nígbà tí àwọn àyíká ipò tí ń pọ́nnilójú bá dà wá ríborìbo.

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Fífúnni Ní Ìmọ̀ràn Tí Kò Gbéṣẹ́

Gbólóhùn náà “àwọn onítùnú Jobu” ti di orúkọ tí a sábà máa ń lò fún ẹnì kan tí ó jẹ́ pé, dípò kí ó bánikẹ́dùn ní àkókò àgbákò, ńṣe ni ó máa ń fẹ ọ̀ràn lójú. Ṣùgbọ́n láìka irú ìfùsì tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ṣe fún ara wọn sí, a kò níláti tànmọ́ọ̀ pé gbogbo ète-ìsúnniṣe wọn pátá ni ó burú. Dé ìwọ̀n àyè kan wọ́n ti lè fẹ́ láti ran Jobu lọ́wọ́, ní ìbámu pẹ̀lú ojú-ìwòye wọn tí ó lòdì. Èéṣe tí wọ́n fi kùnà? Báwo ni wọn ṣe di irin-iṣẹ́ fún Satani, tí ó pinnu láti ba ìwàtítọ́ Jobu jẹ́?

Ó dára, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìmọ̀ràn wọn ni wọ́n gbékarí ìméfò tí kò tọ̀nà: pé kìkì àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ ni ìyà ń jẹ. Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, Elifasi wí pé: “Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀, tàbí níbo ni a gbé ké olódodo kúrò rí? Àní bí èmi ti rí i pé: àwọn tí ń ṣe ìtúlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fọ́n irúgbìn ìwà búburú, wọ́n a sì ká èso rẹ̀ náà.” (Jobu 4:7, 8) Elifasi fi àṣìṣe gbàgbọ́ pé àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ní àjẹsára tí kì í jẹ́ kí àjálù-ibi ṣẹlẹ̀ sí wọn. Ó ronu pé níwọ̀n bí Jobu ti wà nínú wàhálà ìpọ́njú lílekoko, ó ti gbọ́dọ̀ dẹ́sẹ̀ sí Ọlọrun.a Bákan náà ni Bildadi àti Sofari rinkinkin mọ́ ọn pé kí Jobu ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—Jobu 8:5, 6; 11:13-15.

Àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tún mú un lọ́kàn gbọgbẹ́ síwájú síi nípa sísọ èrò ti ara wọn jáde dípò ọgbọ́n Ọlọrun. Elifasi lọ jìnnà débi tí ó fi sọ pé ‘Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀’ àti pé kò jámọ́ nǹkankan fún Jehofa yálà Jobu jẹ́ olódodo tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. (Jobu 4:18; 22:2, 3) Ó ṣòro láti ronú nípa ọ̀rọ̀ àkíyèsí tí ó tún lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni—tàbí tí kò ní òtítọ́ nínú—ju ìyẹn lọ! Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn Jehofa fi Elifasi àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bú nítorí ọ̀rọ̀-òdì yìí. Ó wí pé: “Ẹ̀yin kò sọ̀rọ̀ níti èmi, ohun tí ó tọ́.” (Jobu 42:7) Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń banijẹ́ jùlọ ṣì ń bọ̀.

Níkẹyìn Elifasi ṣe àṣerégèé débi tí ó fi fi ẹ̀sùn kàn án ní tààràtà. Níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe fún un láti mú kí Jobu gbà pé òun jẹ̀bi, ó fàbọ̀ sórí híhùmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ronú pé Jobu ti níláti dá. Elifasi béèrè pé: “Ìwà-búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ láìníye? Nítòótọ́ ìwọ gba ohun ẹ̀rí ní ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì tú oníhòòhò ni aṣọ wọn. Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.” (Jobu 22:5-7) Àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí kò lẹ́sẹ̀nílẹ̀ rárá. Jehofa fúnra rẹ̀ ti ṣàpèjúwe Jobu gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan “tíí ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúróṣinṣin.”—Jobu 1:8.

Báwo ni Jobu ṣe dáhùnpadà sí àwọn àtakò tí a gbé dìde sí ìwàtítọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan yìí? Lọ́nà tí ó ṣeé lóye, wọ́n mú ọkàn rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì wọ́n sì mú kí ó soríkọ́ lọ́nà kan ṣáá ṣùgbọ́n wọ́n túbọ̀ mú kí ó pinnu ju ti ìgbàkígbà rí lọ láti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí jẹ́ èké. Níti tòótọ́, dídá ara rẹ̀ láre jẹ ẹ́ lógún tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, ní ọ̀nà kan, ó bẹ̀rẹ̀ síí dẹ́bi fún Jehofa nítorí ìṣòro rẹ̀. (Jobu 6:4; 9:16-18; 16:11, 12) Ọ̀ràn àríyànjiyàn náà gan-an tí ó wà nílẹ̀ ni wọ́n gbójúfòdá, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà sì di ìjiyàn tí kò múnádóko níti yálà Jobu jẹ́ olódodo, tàbí kì í ṣe olódodo. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni àwọn Kristian lè rí kọ́ láti inú àkókò ìgbaninímọ̀ràn tí ó burú jáì yìí?

1. Kristian tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ kì í méfò ní ìbẹ̀rẹ̀ pé ìṣòro arákùnrin kan jẹ́ àfọwọ́fà ara rẹ̀. Ìbániwí lọ́nà lílekoko nípa àwọn àṣìṣe tí ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá—yálà níti gidi tàbí tí a ronúwòye—lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹnì kan tí ń jìjàkadì láti lè máa bá a nìṣó. Ọkàn tí ó soríkọ́ ni ó yẹ kí a ‘rẹ̀lẹ́kún’ dípò kí a já a ní pàṣán ọ̀rọ̀. (1 Tessalonika 5:14, NW) Jehofa fẹ́ kí àwọn alábòójútó jẹ́ “ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù,” kì í ṣe “ayọnilẹ́nu onítùnú” bíi ti Elifasi, Bildadi, àti Sofari.—Isaiah 32:2; Jobu 16:2.

2. A kò gbọdọ̀ fẹ̀sùnkanni láìsí ẹ̀rí tí ó ṣe kedere. Ọ̀rọ̀ àgbọ́sọ tàbí ìméfò—bíi ti Elifasi—kì í ṣe ìdí yíyèkooro fún fífúnni ní ìbáwí. Fún àpẹẹrẹ, bí alàgbà kan bá ń fi ẹ̀sùn èké kanni, ó tún ṣeé ṣe kí ó pàdánù ìṣeégbáralé kí ó sì tún ṣokùnfà pákáǹleke èrò ìmọ̀lára. Báwo ni ìmọ̀lára Jobu ti rí níti títẹ́tísílẹ̀ sí irú ìmọ̀ràn tí a gbé gbòdì bẹ́ẹ̀? Ó sọ̀rọ̀ jáde nípa làásìgbò rẹ̀ pẹ̀lú ìpolongo bí ẹni dápàárá pé: “Bawo ni ìwọ [ṣe] ń ṣe ìrànlọ́wọ́ [fún] ẹni tí kò ní ipá”! (Jobu 26:2) Alábòójútó tí ó ní ìdàníyàn yóò “mú awọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ . . . nàró ṣánṣán,” kì yóò sì mú kí ìṣòro burú síi.—Heberu 12:12, NW.

3. A níláti gbé ìmọ̀ràn karí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe èrò ti ara-ẹni. Ìjiyàn àwọn ọ̀rẹ́ Jobu kò tọ̀nà wọ́n sì ń panilára. Dípò kí wọ́n mú Jobu súnmọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí síi, wọ́n sún un láti ronú pé ìdínà kan wà tí ó yà á nípa sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run. (Jobu 19:2, 6, 8) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, lílo Bibeli lọ́nà gbígbéṣẹ́ lè mú àwọn nǹkan tọ́, kí ó fún àwọn ẹlòmíràn lókun, kí ó sì nawọ́ ìtùnú tòótọ́ jáde.—Luku 24:32; Romu 15:4; 2 Timoteu 3:16; 4:2.

Nígbà tí ìwé Jobu ran àwọn Kristian lọ́wọ́ láti lóye àwọn ọ̀fìn kan, ó tún pèsè ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wíwúlò nípa bí a ṣe lè fúnni ní ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́.

Bí A Ṣe Ń Fúnni Ní Ìmọ̀ràn

Ìmọ̀ràn Elihu yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, níti ohun tí ó ní nínú àti ọwọ́ tí Elihu fi mú Jobu. Ó lo orúkọ Jobu ó sì bá a sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, kí í ṣe bí onídàájọ́ Jobu. “Ǹjẹ́ nítorí náà, Jobu, èmi bẹ̀ ọ́, gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí o sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi! Kíyèsí i, bí ìwọ ti jẹ́ ti Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà.” (Jobu 33:1, 6) Ó tún yá Elihu lára láti gbóríyìn fún Jobu nítorí ipa-ọ̀nà ìdúróṣinṣin rẹ̀. Ó mú Jobu lọ́kàn le pé: “Òdodo rẹ mú inú mi dùn.” (Jobu 33:32, NW) Yàtọ̀ si ti ọ̀nà ìgbà fúnni ní ìmọ̀ràn bí ọ̀rẹ́ yìí, Elihu ṣàṣeyọrí nítorí àwọn ìdí mìíràn.

Lẹ́yìn tí ó ti fi sùúrù dúró títí tí àwọn yòókù fi parí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ, ó túbọ̀ ṣeé ṣe fún Elihu láti lóye àríyànjiyàn náà ṣáájú kí ó tó mú ìmọ̀ràn wá. Bí ó bá jẹ́ pé olódodo ni Jobu, Jehofa yóò ha fìyà jẹ ẹ́ bí? “Ó doódì fún Ọlọrun tí ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olodumare, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!” ni Elihu ké tantan. “Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo.”—Jobu 34:10; 36:7.

Òdodo Jobu ha ni pàtàkì àríyànjiyàn náà bí? Elihu pe àfiyèsí Jobu sí ojú-ìwòye kan tí kò wàdéédéé. Ó ṣàlàyé pé: “Ìwọ wí pé, òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọrun . . . Ṣíjú wo ọ̀run, kí o rí i, kí o sì bojúwo àwọsánmà tí ó ga jù ọ́ lọ.” (Jobu 35:2, 5) Bí ó ti jẹ́ pé àwọsánmà ga fíofío jù wá lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀nà Jehofa ṣe ga ju ọ̀nà wa lọ. Àwa kò sí ní ipò láti ṣèdájọ́ ọ̀nà tí ó ń gbà ṣe nǹkan. Elihu parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nítorí náà ènìyàn a máa bẹ̀rù rẹ̀, òun kì í ṣojúsàájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní inú.”—Jobu 37:24; Isaiah 55:9.

Ìmọ̀ràn yíyèkooro ti Elihu pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún Jobu láti gba àfikún ìtọ́ni síi láti ọ̀dọ̀ Jehofa fúnra rẹ̀. Níti tòótọ́, ìbáradọ́gba tí ó fanimọ́ra wà láàárín ọ̀nà tí Elihu gbà sọ̀rọ̀ nípa “iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun,” ní orí 37, àti ọ̀rọ̀ tí Jehofa fúnra rẹ̀ sọ fún Jobu, èyí tí a ròyìn rẹ̀ nínú orí 38 sí 41. Ó ṣe kedere pé, Elihu fi ojú Jehofa wo àwọn ọ̀ràn. (Jobu 37:14) Báwo ni àwọn Kristian ṣe lè ṣàfarawé àpẹẹrẹ rere ti Elihu?

Bíi ti Elihu, àwọn alábòójútó ní pàtàkì yóò fẹ́ láti ní ẹ̀mí ìfọ̀ràn-rora-ẹni àti inúrere, kí wọ́n sì rántí pé àwọn pẹ̀lú jẹ́ aláìpé. Wọn yóò ṣe dáradára láti farabalẹ̀ tẹ́tísílẹ̀ kí wọ́n baà lè lóye àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kí wọ́n sì lóye àwọn ọ̀ràn kí wọ́n tó fúnni nímọ̀ràn. (Owe 18:13) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nípa lílo Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Ìwé Mímọ́, wọ́n lè rí i dájú pé ojú-ìwòye Jehofa ni ó borí.—Romu 3:4.

Yàtọ̀ sí pípèsè ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n gbígbéṣẹ́ wọ̀nyí fún àwọn alàgbà, ìwé Jobu kọ́ wa bí a ṣe lè kojú ìṣòro ní ọ̀nà wíwàdéédéé.

Bí Kò Ṣe Yẹ Kí A Hùwàpadà sí Àwọn Àyíká Ipò Tí Kò Báradé

Bí ìjìyà rẹ̀ tí dà á ríborìbo tí àwọn onítùnú èké rẹ̀ sì ti já a kulẹ̀, ọkàn Jobu korò ó sì soríkọ́. Ó kédàárò pé: “Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé . . . Agara ìwà ayé mi dá mi tán.” (Jobu 3:3; 10:1) Bí kò ti mọ̀ pé Satani ni ọ̀daràn náà, ó tànmọ́ ọ̀n pé Ọlọrun ni ó ń ṣokùnfà àjálù-ibi òun. Ó dàbí ẹni pé kò bá ìdájọ́-òdodo mu pé kí òun—olódodo—jìyà. (Jobu 23:10, 11; 27:2; 30:20, 21) Ìṣarasíhùwà yìí fọ́ Jobu lójú sí àwọn ohun mìíràn tí ìbá gbé yẹ̀wò ó sì sún un láti ṣe lámèyítọ́ nípa ìbálò Ọlọrun pẹ̀lú aráyé. Jehofa béèrè pé: “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ kí ó lè ṣe olódodo?”—Jobu 40:8.

Bóyá ìhùwàpadà wa ojú-ẹsẹ̀ nígbà tí ìpọ́njú bá dojúkọ wá ni láti nímọ̀lára pé a jẹ́ ẹni ti a ń fòòró, gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn kedere pé Jobu ṣe. Ìhùwàpadà tí ó wọ́pọ̀ ni láti béèrè pé, ‘Èéṣe tí ó fi jẹ́ èmi? Èéṣe tí àwọn ẹlòmíràn—tí wọn kò sàn tó mi—fi ń gbádùn ìgbésí-ayé tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìṣòro nínú?’ Ìwọ̀nyí jẹ́ ìrònú òdì tí a lè gbéjàkò nípa ṣíṣe àṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

Láìdàbí ti Jobu, a wà ní ipò láti lóye àríyànjiyàn ńláǹlà tí ó wémọ́ ọn. A mọ̀ pé Satani “ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ.” (1 Peteru 5:8, NW) Gẹ́gẹ́ bí ìwé Jobu ti ṣí i payá, yóò dùn mọ́ Èṣù nínú láti ba ìwàtítọ́ wa jẹ́ nípa fífa ìṣòro fún wa. Ó ṣì wonkoko mọ́ fífi ẹ̀rí ti ìjẹ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn pé Ẹlẹ́rìí Jehofa olùláwọ́-epo lásán ni wá. (Jobu 1:9-11; 2:3-5) Àwa yóò ha ní ìgboyà láti gbé ipò-ọba-aláṣẹ Jehofa ró kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ fi Èṣù hàn gẹ́gẹ́ bí elékèé bí?

Àpẹẹrẹ Jesu, àti ti àìlóǹkà àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ Jehofa mìíràn, fihàn pé irú àwọn ìjìyà kan fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. Jesu wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ múratán láti ‘gbé òpó igi oró wọn’ bí wọ́n bá fẹ́ láti tọ òun lẹ́yìn. (Luku 9:23, NW) “Òpó igi oró” wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan lè jẹ́ ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìpọ́njú tí Jobu faradà—àìlera, ikú olólùfẹ́ ẹni, ìsoríkọ́, ipò-ìṣòro ìṣúnná-owó, tàbí àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Irú ìṣòro yòówù kí a máa dojúkọ, ó ní apá kan tí ó ṣàǹfààní. A lè wo àwọn àyíká ipò wa gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti lo ìfaradà àti ìdúróṣinṣin tí kì í yẹ̀ èyí tí a ní fún Jehofa.—Jakọbu 1:2, 3.

Bí àwọn aposteli Jesu ṣe hùwàpadà nìyẹn. Ní kété lẹ́yìn Pentekosti a nà wọ́n lẹ́gba nítorí wíwàásù nípa Jesu. Dípò kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n bá ọ̀nà wọn lọ “wọ́n ń yọ̀.” Wọ́n ní ìdùnnú-ayọ̀, kì í ṣe nítorí ìjìyà náà fúnra rẹ̀, bíkòṣe nítorí pé “a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nitori orúkọ rẹ̀ [Kristi].”—Iṣe 5:40, 41.

Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe gbogbo ìṣòro wa ni ó ń dé bá wa nítorí pé a ń ṣiṣẹ́sin Jehofa. Ìṣòro wa lè jẹ́ àfọwọ́fà—dé ìwọ̀n àyè kan ó kérétán. Tàbí bóyá, nítorí àṣìṣe kan tí kì í ṣe tiwa, ìṣòro náà ti lè nípa lórí ìwàdéédéé wa nípa tẹ̀mí. Bí ó ti wù kí ọ̀ràn náà rí, ìṣarasíhùwà onírẹ̀lẹ̀-ọkàn bíi ti Jobu yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi òye mọ ibi tí a ti ṣe àṣìṣe. Jobu jẹ́wọ́ níwájú Jehofa pé: “Èmi . . . ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀.” (Jobu 42:3) Ó ṣeé ṣe jùlọ fún ẹni tí ó bá mọ àwọn ìṣìnà rẹ̀ ní ọ̀nà yìí láti yẹra fún irú ìṣòro kan náà ní ọjọ́-iwájú. Gẹ́gẹ́ bí òwe ti sọ, “ọlọgbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó sì pa ara rẹ̀ mọ́.”—Owe 22:3.

Èyí tí ó ṣe pàtàkì jù, ìwé Jobu rán wa létí pé àwọn ìṣòro wa kì yóò máa bá a lọ títíláé. Bibeli sọ pé: “Awọn wọnnì tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nipa ìfaradà Jobu ẹ sì ti rí àbárèbábọ̀ tí Jehofa mú wá, pé Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jakọbu 5:11, NW) A lè ní ìdánilójú pé bákan náà ni Jehofa yóò ṣe san èrè-ẹ̀san fún ìṣòtítọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lónìí.

A tún ń fojúsọ́nà fún àkókò tí onírúurú ìṣòro gbogbo—“awọn ohun àtijọ́”—yóò ti kọjá lọ. (Ìṣípayá 21:4, NW) Títí ti ọ̀yẹ̀ ọjọ́ yẹn yóò fi là, ìwé Jobu ń bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí atọ́nà ṣíṣeyebíye kan tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n àti okun ìfàyàrán bójútó àwọn ìṣòro.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà tí Bibeli sọ pé “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni oun yoo ká pẹlu,” èyí kò túmọ̀sí pé ìjìyà ẹnì kan gbọ́dọ̀ jẹ́ ìyà-ibi láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. (Galatia 6:7, NW) Nínú ayé ti Satani jọba lé lórí yìí, àwọn olódodo sábà máa ń dojúkọ ìṣòro púpọ̀ ju àwọn ènìyàn burúkú lọ. (1 Johannu 5:19) Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin yoo sì jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítìtorí orúkọ mi.” (Matteu 10:22, NW) Àìsàn àti irú àwọn àgbákò mìíràn lè ṣe ẹnikẹ́ni nínú àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun.—Orin Dafidi 41:3; 73:3-5; Filippi 2:25-27.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

“Bojúwo àwọsánmà tí ó ga jù ọ́ lọ.” Elihu tipa báyìí ran Jobu lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ọ̀nà Ọlọrun ga ju ọ̀nà ènìyàn lọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́