“Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Aya Ìgbà Èwe Rẹ”
“Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ . . . Ọmọ mi, èé ṣe tí ìwọ yóò fi máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú àjèjì obìnrin?”—ÒWE 5:18, 20.
1, 2. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ àárín ọkọ àti aya ní ìbùkún?
BÍBÉLÌ ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Ìwé Òwe 5:18, 19 sọ pé: “Jẹ́ kí orísun omi rẹ jẹ́ èyí tí ó ní ìbùkún, kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ, egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá. Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà. Kí o máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.”
2 Ọ̀rọ̀ náà “orísun omi” tí ẹsẹ yìí sọ túmọ̀ sí ohun tó ń fún èèyàn ní ìgbádùn ìbálòpọ̀. Ó sì ní ìbùkún nítorí pé ìfẹ́ àárín ọkọ àti aya àti ayọ̀ tí ìyẹn ń fún wọn jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, àárín ọkọ àti aya nìkan ni irú ìfẹ́ yìí gbọ́dọ̀ mọ sí o. Ìdí rèé tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì tó kọ ìwé Òwe fi béèrè ìbéèrè mọ̀ọ́nú yìí pé: “Ọmọ mi, èé ṣe tí ìwọ yóò fi máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú àjèjì obìnrin tàbí tí ìwọ yóò fi gbá oókan àyà obìnrin ilẹ̀ òkèèrè mọ́ra?”—Òwe 5:20.
3. (a) Kí lohun tí ń bani nínú jẹ́ tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó? (b) Ojú wo ni Ọlọ́run fi wo panṣágà?
3 Lọ́jọ́ tí ọkùnrin àtobìnrin kan bá ń ṣe ìgbéyàwó, ńṣe làwọn méjèèjì máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn yóò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, àwọn ò sì ní dalẹ̀ ara wọn. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ló ti tú ká nítorí panṣágà. Àní lẹ́yìn tí olùṣèwádìí kan ti gbé ìwádìí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí wọ́n ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó yẹ̀ wò, ó ní, “ìdá mẹ́rin àwọn aya àti nǹkan bí ìdajì àwọn ọkọ ló ti ṣe panṣágà.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀ . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ yẹn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni panṣágà jẹ́ lójú Ọlọ́run, ìdí nìyẹn táwa olùjọ́sìn tòótọ́ tá a ti ṣègbéyàwó fi gbọ́dọ̀ yẹra fún ohunkóhun tó bá lè mú ká ṣe panṣágà. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ‘kí ìgbéyàwó ní ọlá, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin’?—Hébérù 13:4.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọkàn Rẹ Tàn Ọ́ Jẹ
4. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Kristẹni tó ti níyàwó tàbí tó ti lọ́kọ lè gbà máa fa ojú ẹlòmíì mọ́ra láìfura?
4 Nínú ayé tó kún fún ìwàkiwà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló “ní ojú tí ó kún fún panṣágà, tí [wọn] kò sì lè yọwọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.” (2 Pétérù 2:14) Wọ́n máa ń mọ̀ọ́mọ̀ fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn mọ́ra. Láwọn ibì kan, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló ń lọ síbi iṣẹ́. Bí àwọn obìnrin àtàwọn ọkùnrin sì ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ níbi iṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó rọrùn fáwọn tó tiẹ̀ máa ń tijú gan-an pàápàá láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ ìfẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti níyàwó tàbí tí wọ́n ti lọ́kọ ló ti jìn sínú irú àwọn ọ̀fìn báwọ̀nyí láìfura.
5, 6. Kí ló mú kí arábìnrin kan fẹ́rẹ̀ẹ́ kó sí páńpẹ́ panṣágà, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i?
5 Wo bí arábìnrin kan tí a ó pè ní Màríà nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe ṣe ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kó ṣe panṣágà. Ọkọ arábìnrin yìí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa ìdílé rẹ̀. Màríà sọ pé ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn òun pàdé ọkùnrin kan tí òun àti ọkọ òun ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà. Ọkùnrin náà níwà tó dáa, ó tiẹ̀ sọ fún Màríà nígbà tó yá pé òun á fẹ́ láti mọ̀ nípa ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ ń kọ́ni. Màríà sọ pé: “Ọkùnrin náà ṣèèyàn gan-an ni, ìwà rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti ọkọ mi.” Láìpẹ́ láìjìnnà, ìfẹ́ kó sí Màríà àti ọkùnrin yìí lórí. Màríà ní: “Mi ò sáà kúkú ṣe panṣágà, ńṣe lọkùnrin náà sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bóyá màá lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.”
6 Màríà pe orí ara rẹ̀ wálé kó tó di pé ìfẹ́ àárín wọn mú kó ṣe panṣágà. (Gálátíà 5:19-21; Éfésù 4:19) Ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gún un ní kẹ́ṣẹ́, ó sì ṣàtúnṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin yìí fi hàn pé “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 4:23) Báwo la ṣe lè ṣèyẹn?
‘Afọgbọ́nhùwà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Fi Ara Rẹ̀ Pa Mọ’
7. Tá a bá fẹ́ ṣèrànlọ́wọ́ fún ẹnì kan tí ìṣòro wà láàárín òun àti ọkọ tàbí aya rẹ̀, ìmọ̀ràn Bíbélì wo ni yóò dára kéèyàn tẹ̀ lé kó má bàa kó sí wàhálà?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” (1 Kọ́ríńtì 10:12) Ìwé Òwe 22:3 náà sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” Má ṣe dá ara rẹ lójú jù, kó o máa ronú pé: ‘Kò sóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí mi,’ kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o ronú ṣáájú nípa àwọn ipò tó lè mú kó o kó sí páńpẹ́ ìṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jẹ́ ọkùnrin, má ṣe jẹ́ kí obìnrin tí ìṣòro wà láàárín òun àti ọkọ rẹ̀ sọ ọ́ di alábàárò rẹ̀ tàbí kí ọkùnrin tí ìṣòro wà láàárín òun àti aya rẹ̀ sọ ìwọ obìnrin di alábàárò rẹ̀. (Òwe 11:14) Sọ fún un pé ọkọ tàbí aya ẹni lẹni tó dáa jù lọ téèyàn lè bá jíròrò ìṣòro tó bá wà láàárín tọkọtaya. Tàbí kẹ̀ kéèyàn fi ọ̀rọ̀ náà lọ arábìnrin bíi tiẹ̀ tàbí arákùnrin bíi tiẹ̀ tó dàgbà dénú, tàbí àwọn alàgbà. (Títù 2:3, 4) Àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá di irú ọ̀rọ̀ bí èyí. Tó bá pọndandan kí alàgbà kan bá arábìnrin kan sọ̀rọ̀ lóun nìkan, ibi táwọn èèyàn ti lè rí wọn ló ti máa bá a sọ̀rọ̀, irú bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba.
8. Kí ló yẹ kéèyàn ṣọ́ra fún níbi iṣẹ́?
8 Tó o bá wa níbi iṣẹ́ tàbí láwọn ibòmíì, yẹra fún àwọn ipò tó lè mú kí ọkàn rẹ máa fà sí obìnrin tàbí ọkùnrin míì. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá dúró lẹ́yìn iṣẹ́ láti ṣe àfikún iṣẹ́ tó sì jẹ́ pé obìnrin tàbí ọkùnrin mìíràn lẹ jọ fẹ́ ṣiṣẹ́ ọ̀hún, èyí lè jẹ́ ìdẹwò fún ọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti lọ́kọ tàbí tó ti níyàwó, tó o bá wà níbi iṣẹ́, ó yẹ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ pé o ò gbàgbàkugbà. Ó dájú pé ìwọ tó ò ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ò ní fẹ́ fa ojú ẹlòmíràn mọ́ra nípa bíbá a tage tàbí nípa wíwọṣọ tàbí mímúra lọ́nà tí kò bójú mu. (1 Tímótì 4:8; 6:11; 1 Pétérù 3:3, 4) Tó o bá fi fọ́tò ọkọ tàbí aya rẹ àti tàwọn ọmọ rẹ sí ibi iṣẹ́ rẹ, èyí á jẹ́ kí ìwọ àtàwọn ẹlòmíì máa rántí pé ìdílé rẹ ló ṣe pàtàkì sí ọ jù. Pinnu pé o ò ní ṣe ohun táá jẹ́ kí ẹlòmíì fẹ́ láti fa ojú rẹ mọ́ra, tẹ́nì kan bá sì wá fẹ́ fa ojú ẹ mọ́ra, má ṣe gbà fún un.—Jóòbù 31:1.
“Máa Gbádùn Ìgbésí Ayé Pẹ̀lú Aya Tí O Nífẹ̀ẹ́”
9. Àwọn ohun wo ló lè ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé tó lè mú kí ọkàn ọkọ tàbí aya fà sí ẹlòmíì?
9 Kì í ṣe kéèyàn yẹra fún àwọn ohun tó lè múni kó sí páńpẹ́ panṣágà nìkan léèyàn fi ń ṣọ́ ọkàn rẹ̀ o, àwọn nǹkan míì tún wà téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe. Tí ọkàn baálé ilé kan tàbí ìyàwó ilé kan bá lọ ń fà sí ẹlòmíì, èyí lè jẹ́ àmì pé wọn kì í ṣe ojúṣe wọn sí ara wọn nínú ilé. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ọkọ ti pa ìyàwó ẹ̀ tì, tàbí kó jẹ́ pé kò sóhun tí ọkọ ṣe tó ń tẹ́ ìyàwó rẹ̀ lọ́rùn. Ó lè wá di pé ọkọ tàbí aya dédé pàdé ẹlòmíì nibi iṣẹ́ tàbí nínú ìjọ pàápàá tó dà bíi pé ó ní àwọn ìwà tó sọ pé ẹnì kejì òun ò ní. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ lè wá kó sí àwọn méjèèjì lórí débi pé wọ́n á fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè fi ara wọn sílẹ̀ mọ́. Ohun tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ yìí tó sì ń bá a lọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lẹ́yìn náà jẹ́ ká rí i kedere pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.”—Jákọ́bù 1:14.
10. Kí ni ọkọ àti aya lè ṣe tí àjọṣe àárín wọn á fi túbọ̀ lágbára?
10 Dípò tí ọkọ tàbí aya á fi máa fa ojú ẹlòmíì mọ́ra nítorí pé ó ń wá ẹni tó máa gbọ́ tòun, bóyá ẹni tó máa fi ìfẹ́ hàn sí i, ẹni tó máa bá dọ́rẹ̀ẹ́, tàbí ẹni tó máa jẹ́ alábàárò rẹ̀ nígbà ìṣòro, ńṣe ló yẹ káwọn méjèèjì sapá láti mú kí àjọṣe àárín wọn túbọ̀ dán mọ́rán. Nítorí náà, ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń wà pa pọ̀, kẹ́ ẹ sì máa ṣe ohun táá jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ fà mọ́ ara yín. Ronú nípa ohun tó mú kẹ́ ẹ fẹ́ra yín. Ronú nípa ìfẹ́ tó o ní sí ẹnì kejì rẹ nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Ronú nípa àwọn àkókò tẹ́ ẹ ti jọ gbádùn pa pọ̀. Gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa ọ̀ràn náà. Onísáàmù náà Dáfídì bẹ Jèhófà pé: “Dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sáàmù 51:10) Pinnu láti ‘máa gbádùn ìgbésí ayé pẹ̀lú aya tí o nífẹ̀ẹ́ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ tí Ọlọ́run fi fún ọ lábẹ́ oòrùn.’—Oníwàásù 9:9.
11. Báwo ni ìmọ̀, ọgbọ́n, àti ìfòyemọ̀ ṣe lè ran ọkọ àti aya lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe wọn túbọ̀ dán mọ́rán?
11 Àwọn ohun pàtàkì míì tá ò gbọ́dọ̀ gbójú fò, tó lè ran ọkọ àti aya lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe wọn túbọ̀ dán mọ́rán sí i ni ìmọ̀, ọgbọ́n, àti ìfòyemọ̀. Ìwé Òwe 24:3, 4 sọ pé: “Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró, nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. Nípa ìmọ̀ sì ni àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún yóò fi kún fún gbogbo ohun oníyelórí tí ó ṣeyebíye tí ó sì wuni.” Lára àwọn ohun iyebíye tó kúnnú ìdílé aláyọ̀ ni àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìdúróṣinṣin, ìbẹ̀rù Ọlọ́run, àti ìgbàgbọ́. Èèyàn ní láti ní ìmọ̀ Ọlọ́run kó tó lè ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn. Ìdí rèé tí àwọn lọ́kọláya fi gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì. Báwo ni ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ṣe ṣe pàtàkì tó? Kéèyàn tó lè mọ bóun ṣe lè borí àwọn ìṣòro ojoojúmọ́, ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní ọgbọ́n, ìyẹn ni pé kéèyàn mọ bóun ṣe lè fi ìmọ̀ Bíbélì sílò. Ẹni tó bá ní ìfòyemọ̀ á lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára ọkọ tàbí aya òun àti ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. (Òwe 20:5) Jèhófà tipasẹ̀ Sólómọ́nì sọ pé: “Ọmọ mi, fetí sí ọgbọ́n mi. Dẹ etí rẹ sí ìfòyemọ̀ mi.”—Òwe 5:1.
Ìgbà Tí Ọkọ àti Aya Bá Wà Nínú “Ìpọ́njú”
12. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yani lẹ́nu bí àwọn lọ́kọláya bá ní ìṣòro?
12 Kò sí tọkọtaya tó pé tán. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé àwọn lọ́kọláya yóò ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Àníyàn ìgbésí ayé, àìsàn, inúnibíni, àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀ lè kó ìdààmú bá ọkọ àti aya. Àmọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé, ńṣe ló yẹ kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ tẹ́ ẹ fẹ́ múnú Jèhófà dùn jọ wá ojútùú sí ìṣòro ọ̀hún.
13. Kí làwọn ohun tí ọkọ tàbí aya lè gbé yẹ̀ wò nípa ara rẹ̀?
13 Tó bá wá jẹ́ pé ọ̀nà tí ọkọ àti aya gbà ń bá ara wọn lò ló fa ìṣòro náà ńkọ́? Kí irú ìṣòro báyìí tó lè yanjú, ó gba pé kí àwọn méjèèjì sapá gidigidi. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ó ti ń mọ́ wọn lára láti máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí ara wọn. (Òwe 12:18) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè da àárín ọkọ àti aya rú. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ó sàn láti máa gbé ní ilẹ̀ aginjù ju gbígbé pẹ̀lú aya alásọ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú pákáǹleke.” (Òwe 21:19) Tó o bá jẹ́ aya nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ìwà mi máa ń lé ọkọ mi sá nílé?’ Bíbélì sọ fáwọn ọkọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) Tó bá sì jẹ́ pé ọkọ ni ọ́, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń le koko mọ́ ìyàwó mi jù débi táá fi máa ronú àtilọ wá ẹni tó lè fara mọ́ níta?’ Àmọ́ o, pé nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ kò ní kí ọkọ tàbí aya lọ ṣèṣekúṣe. Síbẹ̀, pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ yẹ kó mú kí ọkọ àti aya jọ sọ ọ̀rọ̀ náà pa pọ̀.
14, 15. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe kí ọkọ tàbí aya kan máa fa ojú ọkùnrin tàbí obìnrin míì mọ́ra ló máa yanjú ìṣòro wọn?
14 Kì í ṣe kí ẹnì kan máa fa ojú obìnrin tàbí ọkùnrin míì mọ́ra ló máa yanjú ìṣòro àárín òun àti ọkọ tàbí aya rẹ̀. Tó bá lọ ń fa ojú ẹlòmíì mọ́ra, ibo ló lè já sí ná? Àwọn kan lè máa rò pé táwọn bá fẹ́ ẹlòmíì àwọn ò ní níṣòro kankan mọ́. Wọ́n lè máa sọ pé, ‘Ó ṣe tán, irú èèyàn tí mò ń wá gan-an nìyẹn.’ Àmọ́, irú èrò bẹ́ẹ̀ ò tọ̀nà, nítorí pé ẹni tó bá lè fi ọkọ tàbí ìyàwó ẹ̀ sílẹ̀ tàbí tó bá gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kó o fi ọkọ tàbí ìyàwó ẹ sílẹ̀, tẹ́ńbẹ́lú ìgbéyàwó tó jẹ́ ohun mímọ́. Kò bọ́gbọ́n mu kẹ́nì kan máa rò pé tóun bá fi ọkọ tàbí aya òun sílẹ̀ nítorí ẹlòmíì, ẹni tóun ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ á sàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
15 Màríà tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ronú nípa àkóbá tí nǹkan tó dáwọ́ lé yẹn lè ṣe. Lára àkóbá ọ̀hún sì ni pé ó lè mú kí òun tàbí ẹlòmíràn dẹni tí kò rí ojú rere Ọlọ́run mọ́. (Gálátíà 6:7) Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bí ọkàn mi ṣe ń fà sí ọkùnrin tóun àti ọkọ mi ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà yìí, mo rí i pé tó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe kí ọkùnrin náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ohun tí mò ń ṣe kò ní jẹ́ kó kọ́ ọ. Kò sí àní-àní pé gbogbo àwọn tó bá lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò dáa ló máa jìyà rẹ̀, yóò sì tún mú àwọn míì kọsẹ̀!”—2 Kọ́ríńtì 6:3.
Olórí Ohun Tó Yẹ Kó Mú Wa Sá fún Panṣágà
16. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ń jẹ́ àbájáde ìṣekúṣe?
16 Bíbélì sọ pé: “Ètè àjèjì obìnrin ń kán tótó bí afárá oyin, òkè ẹnu rẹ̀ sì dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ju òróró lọ. Ṣùgbọ́n ohun tí ó máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ korò bí iwọ; ó mú bí idà olójú méjì.” (Òwe 5:3, 4) Àwọn ohun tó máa ń jẹ́ àbájáde ìṣekúṣe burú jáì, ó tiẹ̀ lè yọrí sí ikú. Lára wọn ni ẹ̀rí ọkàn tí ń dani láàmú, àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìṣekúṣe, àti ẹ̀dùn ọkàn tí ọkọ tàbí aya máa ń ní nígbà tí ẹnì kejì rẹ̀ bá ṣe panṣágà. Dájúdájú, èyí jẹ́ ìdí kan tó fi yẹ kéèyàn yàgò fún ìwà tàbí ìṣe tó lè múni ṣe panṣágà.
17. Kí ni olórí ohun tó yẹ kó mú ọkọ tàbí aya jìnnà sí panṣágà?
17 Olórí ohun tó mú kí panṣágà burú ni pé, Jèhófà tí í ṣe Olùdásílẹ̀ ètò ìgbéyàwó tó sì fún ọmọ èèyàn lágbára àtiní ìbálòpọ̀, sọ pé ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ó tipa wòlíì Málákì sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì sún mọ́ yín fún ìdájọ́, èmi yóò sì di ẹlẹ́rìí yíyára kánkán lòdì sí . . . àwọn panṣágà.” (Málákì 3:5) Nígbà tí ìwé Òwe 5:21 ń sọ ohun tí Jèhófà lè rí, ó ní: “Àwọn ọ̀nà ènìyàn ń bẹ ní iwájú Jèhófà, ó sì ń ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo òpó ọ̀nà rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Nítorí náà, olórí ohun tó yẹ kó mú ká jìnnà sí panṣágà ni pé bó ti wù ká dẹ́ṣẹ̀ ọ̀hún ní ìkọ̀kọ̀ tó, àti bó ti wù kí àkóbá tó lè ṣe fún wa dà bíi pé ó kéré tó, ńṣe ni ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ máa ń ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
18, 19. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jósẹ́fù àti ìyàwó Pọ́tífárì?
18 Àpẹẹrẹ Jósẹ́fù ọmọ baba ńlá náà Jákọ́bù fi hàn pé tí ọkọ àti aya bá jẹ́ kí àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ wọ́n lógún, wọ́n á jìnnà sí panṣágà. Pọ́tífárì tó jẹ́ olóyè láàfin Fáráò fẹ́ràn Jósẹ́fù gan-an, ìyẹn ló jẹ́ kó fi Jósẹ́fù sí ipò ńlá ní àgbàlá rẹ̀. Jósẹ́fù tún jẹ́ “ẹlẹ́wà ní wíwò àti ẹlẹ́wà ní ìrísí,” ìyàwó Pọ́tífárì sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ìdí rèé tó fi ń dá oríṣiríṣi ọgbọ́n lójoojúmọ́ láti mú kí Jósẹ́fù bá òun lò pọ̀, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà fún un. Kí ni ò jẹ́ kí Jósẹ́fù gbà fún un? Bíbélì sọ fún wa pé: “Òun yóò kọ̀, yóò sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé: ‘Kíyè sí i, ọ̀gá mi . . . [kò] fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi, bí kò ṣe ìwọ, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Nítorí náà, báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?’”—Jẹ́nẹ́sísì 39:1-12.
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù ò tíì níyàwó lákòókò yẹn, kò jẹ́ bá ìyàwó oníyàwó ní àjọṣepọ̀ kankan. Ìwé Òwe 5:15 sọ pé: “Mu omi láti inú ìkùdu tìrẹ, àti omi tí ń sun láti inú kànga tìrẹ.” Má ṣe ṣe ohunkóhun tó máa fi hàn pé ńṣe lò ń fa ojú ẹlòmíràn mọ́ra láìfura. Gbìyànjú láti mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ lágbára sí i, kó o sì pinnu láti yanjú ìṣòro èyíkéyìí tó bá jẹ yọ láàárín yín. Rí i dájú pé ò ń “yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ.”—Òwe 5:18.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè dẹni tó ń fa ojú ẹlòmíràn mọ́ra láìfura?
• Kí làwọn nǹkan tó yẹ kí ọkọ tàbí aya ṣọ́ra fún kó má bàa di pé ọkàn rẹ̀ ń fà sí ẹlòmíràn?
• Nígbà tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ọkọ àti aya, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?
• Kí ni olórí ohun tó yẹ kó mú kí ọkọ tàbí aya sá fún panṣágà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ó bani nínú jẹ́ pé ibi iṣẹ́ ti di ibi táwọn èèyàn ti ń dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
‘Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá inú lọ́hùn-ún yóò fi kún fún ohun tí ó ṣeyebíye tí ó sì wuni’