Ìfẹ́ Máa Ń jẹ́ Kéèyàn Nígboyà Gan-an
“Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.”—2 TÍMÓTÌ 1:7.
1, 2. (a) Kí ni ìfẹ́ lè mú kí ẹnì kan ṣe? (b) Kí ló mú kí ìgboyà Jésù jẹ́ àrà ọ̀tọ̀?
NÍTÒSÍ ìlú kan létíkun ìlà oòrùn ilẹ̀ Ọsirélíà, tọkọtaya kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ń wẹ̀ lábẹ́ òkun. Bí wọ́n ṣe fẹ́ yọrí jáde ni ẹja ńlá kan pa kuuru mọ́ èyí ìyàwó. Ni ọkọ rẹ̀ bá hùwà akin, ó ti ìyàwó rẹ̀ kúrò, ẹja náà sì gbé òun fúnra rẹ̀ mì. Níbi ìsìnkú ọkùnrin náà, ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Ó kú nítorí mi.”
2 Dájúdájú, ìfẹ́ máa ń jẹ́ káwa èèyàn lè fìgboyà hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Kò tíì pé wákàtí mẹ́rìnlélógún tí Jésù sọ gbólóhùn yìí tó fi fẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀, kì í ṣe fún ẹyọ ẹnì kan o, àmọ́ fún gbogbo aráyé. (Mátíù 20:28) Ìyẹn nìkan kọ́, kì í ṣe pé ìgboyà mú kí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láìronú dáadáa. Ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn yóò fòun ṣe yẹ̀yẹ́ wọ́n á sì hùwà tí kò dára sóun, bákan náà, wọ́n á dá òun lẹ́jọ́ lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n á sì pa òun lórí igi oró. Kódà ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Àwa nìyí, tí a ń tẹ̀ síwájú gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, a ó sì fa Ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá a lẹ́bi ikú, wọn yóò sì fà á lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, wọn yóò sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọn yóò sì tutọ́ sí i lára, wọn yóò sì nà án lọ́rẹ́, wọn yóò sì pa á, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, yóò dìde.”—Máàkù 10:33, 34.
3. Kí ló mú kí Jésù ní ìgboyà tó tayọ?
3 Kí làwọn ohun tó mú kí Jésù ní ìgboyà lọ́nà tó tayọ? Ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run kópa tó pọ̀. (Hébérù 5:7; 12:2) Àmọ́, ìfẹ́ tí Jésù ní fún Ọlọ́run àtàwọn ẹ̀dá èèyàn ni olórí ohun tó jẹ́ kó ní ìgboyà. (1 Jòhánù 3:16) Bá a bá ní irú ìfẹ́ yìí láfikún sí ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run, àwa náà á lè máa fi irú ìgboyà bíi ti Kristi hàn. (Éfésù 5:2) Báwo la ṣe lè ní irú ìfẹ́ yẹn? A gbọ́dọ̀ mọ Ẹni tí ìfẹ́ ti ọ̀dọ́ rẹ̀ wá.
“Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìfẹ́ Ti Wá”
4. Kí nídìí tá a fi lè sọ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìfẹ́ ti wá?
4 Jèhófà gangan ni ìfẹ́, ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni ìfẹ́ ti wá. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì nífẹ̀ẹ́ ni a ti bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì jèrè ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:7, 8) Nípa bẹ́ẹ̀, kí ẹnì kan tó lè ní irú ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní, onítọ̀hún ní láti sún mọ́ Jèhófà nípa níní ìmọ̀ pípéye kó sì máa fi ìmọ̀ náà sílò nípa fífi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣègbọràn.—Fílípì 1:9; Jákọ́bù 4:8; 1 Jòhánù 5:3.
5, 6. Kí ló ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí lọ́wọ́ láti ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní?
5 Nínú àdúrà ìkẹyìn tí Jésù gbà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ó sọ bí mímọ Ọlọ́run ṣe máa ń mú kí ìfẹ́ èèyàn pọ̀ sí i. Ó ní: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀, kí ìfẹ́ tí ìwọ fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.” (Jòhánù 17:26) Jésù ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní irú ìfẹ́ tó wà láàárín òun àti Bàbá rẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí orúkọ Ọlọ́run dúró fún, ìyẹn àwọn àgbàyanu ànímọ́ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòhánù 14:9, 10; 17:8.
6 Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló máa ń jẹ́ kéèyàn ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní. (Gálátíà 5:22) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn Kristẹni ìjímìjí gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ tí Jésù ṣèlérí, kì í ṣe pé èyí jẹ́ kí wọ́n lè rántí ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù ti kọ́ wọn nìkan ni, ó tún jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́ ní kíkún. Ó dájú pé òye tó túbọ̀ jinlẹ̀ tí wọ́n ní yìí ló mú kí ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run pọ̀ sí i. (Jòhánù 14:26; 15:26) Kí lèyí wá yọrí sí? Wọ́n fi ìgboyà àti ìtara wàásù ìhìn rere bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí wọn wà nínú ewu.—Ìṣe 5:28, 29.
Bí Wọ́n Ṣe Fi ìgboyà àti Ìfẹ́ Hàn
7. Kí ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fara dà nígbà tí wọ́n jọ wà lẹ́nu ìrìn-àjò míṣọ́nnárì?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.” (2 Tímótì 1:7) Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ló mú kó sọ gbólóhùn yìí. Ìwọ wo ohun tójú Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rí nígbà tí wọ́n jọ wà lẹ́nu ìrìn-àjò míṣọ́nárì wọn. Wọ́n wàásù ní ọ̀pọ̀ ìlú, lára àwọn ìlú náà sì ni Áńtíókù, Íkóníónì, àti Lísírà. Àwọn kan di onígbàgbọ́ láwọn ìlú wọ̀nyí, àmọ́ àwọn kan jẹ́ alátakò gidi. (Ìṣe 13:2, 14, 45, 50; 14:1, 5) Nílùú Lísírà, àwùjọ àwọn èèyàn kan tí inú ń bí tiẹ̀ sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọn sì fi í sílẹ̀ nígbà tí wọ́n rò pé ó ti kú! “Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yí i ká, ó dìde, ó sì wọ ìlú ńlá náà. Ní ọjọ́ kejì, òun pẹ̀lú Bánábà lọ sí Déébè.”—Ìṣe 14:6, 19, 20.
8. Báwo ni ìgboyà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ní ṣe fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an?
8 Ǹjẹ́ báwọn èèyàn ṣe fẹ́ pa Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí ẹ̀rù ba òun àti Bánábà, ṣé ó sì mú kí wọ́n dáwọ́ ìwàásù dúró? Rárá o! Lẹ́yìn táwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyí ti ‘sọ àwọn èèyàn tó pọ̀ díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn’ nílùú Déébè, “wọ́n padà sí Lísírà àti Íkóníónì àti sí Áńtíókù.” Kí nìdí tí wọ́n fi padà? Nítorí kí wọ́n lè fún àwọn ẹni tuntun níṣìírí láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.” Ó ṣe kedere pé ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní sáwọn “àgùntàn [Jésù] kéékèèké” ló mú kí wọ́n nígboyà. (Ìṣe 14:21-23; Jòhánù 21:15-17) Lẹ́yìn táwọn arákùnrin méjì yìí ti yan àwọn alàgbà nínú àwọn ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yẹn, wọ́n gbàdúrà, “wọ́n [sì] fi wọ́n lé Jèhófà lọ́wọ́, ẹni tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ nínú rẹ̀.”
9. Kí ni àwọn alàgbà láti ìlú Éfésù ṣe nítorí ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní sí wọn?
9 Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an tó sì tún nígboyà débi pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ìjímìjí ló wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìpàdé kan tó ṣe pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Éfésù, níbi tó ti lo ọdún mẹ́ta tó sì rí àtakò gan-an. (Ìṣe 20:17-31) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo tí Ọlọ́run fi síkàáwọ́ wọn, ó kúnlẹ̀ pẹ̀lú wọn ó sì gbàdúrà. Lẹ́yìn èyí, “ẹkún sísun tí kò mọ níwọ̀n bẹ́ sílẹ̀ láàárín gbogbo wọn, wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọrùn Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kì yóò tún rí ojú òun mọ́, dùn wọ́n ní pàtàkì.” Àwọn arákùnrin yẹn mà nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an o! Àní, nígbà tí àkókò tó fún wọn láti pínyà, Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò ní láti “já ara [wọn] gbà” lọ́wọ́ àwọn alàgbà náà nítorí pé kò wu àwọn alàgbà yẹn kí wọ́n lọ rárá.—Ìṣe 20:36–21:1.
10. Ọ̀nà wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ń gbà fìfẹ́ hàn síra wọn tìgboyàtìgboyà?
10 Lákòókò tiwa yìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn alàgbà, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn gan-an nítorí ìgboyà tí wọ́n ń fi hàn nítorí àwọn àgùntàn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, láwọn orílẹ̀-èdè tí ogun abẹ́lé ti bà jẹ́, tàbí láwọn ibi tí ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn aya wọn máa ń lọ bẹ àwọn ìjọ wò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé àwọn aláṣẹ lè mú àwọn kí wọ́n sì fi àwọn sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n pa àwọn. Bákan náà, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí lojú wọn ti rí màbo lọ́wọ́ àwọn alákòóso tó ń ṣàtakò àti lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà wọn nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà kọ̀ láti dárúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹ́gbẹ́ wọn tàbí sọ ibi tí oúnjẹ tẹ̀mí ti ń wá. Wọ́n ṣenúnibíni sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn, wọ́n dá wọn lóró, kódà wọn pa àwọn kan nítorí pé wọ́n ò yéé wàásù ìhìn rere tàbí nítorí pé àwọn àtàwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn jọ ń pàdé pọ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni. (Ìṣe 5:28, 29; Hébérù 10:24, 25) Ẹ jẹ́ ká fara wé ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n nígboyà yìí!—1 Tẹsalóníkà 1:6.
Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Di Tútù
11. Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì ń gbà bá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ja ogun tẹ̀mí, kí ló sì yẹ kí wọ́n ṣe?
11 Nígbà tí Jésù lé Sátánì kúrò lọ́run, kò sóhun méjì tó wà lọ́kàn Èṣù ju pé kó fìkanra mọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nítorí pé wọ́n “ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ wọ́n sì ń jẹ́rìí nípa Jésù.” (Ìṣípayá 12:9, 17) Ọ̀kan lára ohun tí Sátánì ń lò ni inúnibíni. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, òdìkejì ohun tó ní lọ́kàn ló máa ń ṣẹlẹ̀. Nítorí pé ńṣe lèyí máa ń jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ sún mọ́ra gan-an, kí ìdè ìfẹ́ àárín wọn túbọ̀ lágbára sí i, kí ọ̀pọ̀ lára wọn sì túbọ̀ jára mọ́ṣẹ́ ìwàásù. Nǹkan mìíràn tí Sátánì tún ń lò ni èrò tó máa ń wá sí wa lọ́kàn láti dẹ́ṣẹ̀. Ká tó lè kọ èrò yìí, a gbọ́dọ̀ ní irú ìgboyà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí pé ogun yìí kì í ṣe èyí téèyàn lè fojú rí, àwọn èrò tí kò tọ́ tó ń lọ nínú ọkàn wa tó jẹ́ ‘aládàkàdekè tó sì ń gbékútà’ là ń bá ja ogun ọ̀hún.—Jeremáyà 17:9; Jákọ́bù 1:14, 15.
12. Báwo ni Sátánì ṣe ń lo “ẹ̀mí ayé” bó ti ń gbìyànjú láti sọ ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run di ahẹrẹpẹ?
12 Sátánì tún ní nǹkan ìjà mìíràn tó lágbára gan-an níkàáwọ́, ìyẹn ni “ẹ̀mí ayé.” Èrò tàbí ìfẹ́ tó gbòde kan tó ń sún àwọn èèyàn ṣe nǹkan ni ẹ̀mí ayé yìí, ó sì lòdì sí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gan-an. (1 Kọ́ríńtì 2:12) Ẹ̀mí ayé máa ń mú káwọn èèyàn ní “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú,” ìyẹn ojúkòkòrò àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. (1 Jòhánù 2:16; 1 Tímótì 6:9, 10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tara àti owó fúnra wọn kò burú, bí ìfẹ́ tá a ní fún wọn bá rọ́pò ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run, a jẹ́ pé Sátánì ti ṣẹ́gun nìyẹn. Ọ̀nà tí ẹ̀mí ayé gbà ní agbára tàbí “ọlá àṣẹ” ni pé, ó máa ń lo ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ wa, ó ń lo àwọn ọ̀nà àyínìke, kì í fini lọ́rùn sílẹ̀, ó sì wà káàkiri bí afẹ́fẹ́. Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ayé sọ ọkàn rẹ dìdàkudà o!—Éfésù 2:2, 3; Òwe 4:23.
13. Ìdánwò wo ló lè dojú kọ wá tá a bá nígboyà láti máa hùwà mímọ́?
13 Àmọ́, ká tó lè kọ ẹ̀mí burúkú tó wà nínú ayé lákọ̀tán, a gbọ́dọ̀ ní ìgboyà láti máa hùwà mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, ìgboyà ló máa jẹ́ kéèyàn lè dìde kó sì fi ilé sinimá sílẹ̀ tàbí kéèyàn pa kọ̀ǹpútà tàbí tẹlifíṣọ̀n nígbà tí wọ́n bá gbé àwòrán tí kò bójú mu jáde. Èèyàn tún gbọ́dọ̀ nígboyà kéèyàn tó lè yàgò fún ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó lè ṣàkóbá fúnni, tàbí kéèyàn jáwọ́ nínú bíbá àwọn èèyàn burúkú kẹ́gbẹ́. Bákan náà, a nílò ìgboyà tá ò bá ní tẹ àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run lójú nígbà táwọn èèyàn bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Yálà àwọn tó ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ náà jẹ́ àwọn ọmọ iléèwé wa, àwọn ará ibi iṣẹ́ wa, àwọn aládùúgbò wa, tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wa.—1 Kọ́ríńtì 15:33; 1 Jòhánù 5:19.
14. Kí ló yẹ ká ṣe bí ẹ̀mí ayé bá ti ń nípa lórí wa?
14 Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká jẹ́ kí ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti fún àwọn arákùnrin wa àtàwọn arábìnrin wa túbọ̀ lágbára gan-an! Fara balẹ̀ wo àwọn ohun tó ò ń lépa nígbèésí ayé rẹ àti ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ bóyá ẹ̀mí ayé ti ń nípa lórí rẹ lọ́nà kan. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé lọ́nà díẹ̀ ló gbà rí bẹ́ẹ̀, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ọ nígboyà láti fa ẹ̀mí yìí tu pátápátá kúrò lọ́kàn rẹ, má sì ṣe jẹ́ kó padà síbẹ̀ mọ́. Jèhófà kò ní ṣàìdáhùn àdúrà tó o bá fi gbogbo ọkàn gbà yìí. (Sáàmù 51:17) Ìyẹn nìkan kọ́, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lágbára gan-an ju ẹ̀mí ayé lọ.—1 Jòhánù 4:4.
Bí Ìgboyà Ṣe Lè Jẹ́ Ká Borí Àwọn Àdánwò Wa
15, 16. Báwo ni ìfẹ́ bíi ti Kristi ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.
15 Àwọn ìṣòro mìíràn táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tún ń dojú kọ ni àwọn ohun tí àìpé àti ọjọ́ ogbó ń fà. Èyí sábà máa ń yọrí sí àìsàn, àléébù ara, ìdààmú ọkàn, àti ọ̀pọ̀ ìṣòro mìíràn. (Róòmù 8:22) Irú ìfẹ́ tí Kristi ní ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti lè fara da àwọn àdánwò wọ̀nyí. Wo àpẹẹrẹ Namangolwa tí wọ́n tọ́ dàgbà nínú ìdílé Kristẹni lórílẹ̀-èdè Zambia. Ìgbà tí Namangolwa wà lọ́mọ ọdún méjì ló yarọ. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe rí ni mo máa ń ronú nípa rẹ̀ ṣáá, pé ńṣe làwọn èèyàn yóò máa sá fún mi nítorí ìrísí mi. Àmọ́ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti borí ìṣòro yìí, nígbà tó sì yá mo ṣèrìbọmi.”
16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Namangolwa ní kẹ̀kẹ́ arọ tó máa ń lò, lọ́pọ̀ ìgbà, ó ní láti máa fi ọwọ́ àti orúnkún rẹ̀ rá nílẹ̀ tó bá ń lọ lójú ọ̀nà tó kún fún iyanrìn tó sì dọ̀tí. Síbẹ̀, ó máa ń ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó kéré tán lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Nígbà tí Namangolwa wàásù fún obìnrin kan, ńṣe lobìnrin náà bú sẹ́kún. Kí ló fà á? Nítorí pé ìgbàgbọ́ àti ìgboyà arábìnrin wa wú u lórí gan-an. Ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà ń bù kún Namangolwa gan-an, nítorí pé márùn-ún lára àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ṣèrìbọmi, alàgbà sì ni ọ̀kan lára wọn. Namangolwa sọ pé: “Ẹsẹ̀ mi méjèèjì máa ń ro mí gan-an, àmọ́ mi ò kì í jẹ́ kí ìyẹn dá mi dúró.” Ọ̀kan péré ni arábìnrin yìí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ aláìlera káàkiri ayé àmọ́ tí wọ́n nítara fún iṣẹ́ ìwàásù. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn bíi tiwọn ló sì ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà!—Hágáì 2:7.
17, 18. Kí ló ń ran ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti fara da àìsàn tàbí àwọn àdánwò mìíràn? Sọ àpẹẹrẹ àwọn kan tó o mọ̀ lágbègbè rẹ.
17 Àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tún lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì, kódà ó lè fa ìdààmú ọkàn. Alàgbà kan nínú ìjọ kan sọ pé: “Ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ tí mò ń dara pọ̀ mọ́, arábìnrin kan wà tí àrùn àtọ̀gbẹ ń yọ lẹnu, tí kíndìnrín rẹ̀ kò sì tún ṣiṣẹ́ dáadáa. Òmíràn ní àrùn jẹjẹrẹ, àwọn méjì sì ní àrùn oríkèé-ara-ríro tó le gan-an. Arábìnrin mìíràn tún ní àìsàn tó ń ba awọ ara àti iṣan jẹ́ tó sì ń mára roni gidigidi. Nígbà mìíràn, ọkàn wọn máa ń bà jẹ́. Síbẹ̀, àfi tí ara wọn ò bá yá gan-an tàbí tí wọ́n bá wà nílé ìwòsàn nìkan ni wọn kì í wá sípàdé. Gbogbo wọn ló ń jáde òde ẹ̀rí déédéé. Wọ́n máa ń rán mi létí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tó sọ pé: ‘Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.’ Ìfẹ́ wọn àti ìgbàgbọ́ wọn máa ń wú mi lórí. Bóyá àìsàn wọn ló jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ ohun tó yẹ kéèyàn gbájú mọ́ nígbèésí ayé àtohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.—2 Kọ́ríńtì 12:10.
18 Bí ìwọ náà bá ní àìlera ara kan, àìsàn, tàbí àwọn ìṣòro mìíràn tó ń bá ọ fínra, máa “gbàdúrà láìdabọ̀” pé kí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. (1 Tẹsalóníkà 5:14, 17) Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà kan á wà tínú rẹ á bà jẹ́, àmọ́ gbìyànjú láti jẹ́ kí ìrònú rẹ máa dá lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí tó lè fún ọ níṣìírí, pàápàá jù lọ, ìrètí ṣíṣeyebíye tá a ní, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. Arábìnrin kan sọ pé: “Oògùn ajẹ́bíidán ni iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ fún mi.” Sísọ ìhìn rere fáwọn èèyàn ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún arábìnrin yìí láti máa ní èrò tó dára lọ́kàn.
Ìfẹ́ Ń Ran Àwọn Tó Dẹ́ṣẹ̀ Lọ́wọ́ Láti Padà Sọ́dọ̀ Jèhófà
19, 20. (a) Kí ló lè ran àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ láti fìgboyà padà sọ́dọ̀ Jèhófà? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 Kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ àwọn tí àjọṣe àárín wọn àti Jèhófà kò dán mọ́rán mọ́ tàbí tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ láti padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tí wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ wọn fún Jèhófà sọjí padà, wọ́n á ní ìgboyà. Wo àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ń jẹ́ Marioa tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó fi ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀, ó di ọ̀mùtí àti ajoògùnyó, lẹ́yìn ogún ọdún tó sì ti ń ṣe èyí, ó bára rẹ̀ lẹ́wọ̀n. Mario sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa ọjọ́ ọ̀la mi, mo sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Nígbà tó yá, mo wá mọrírì àwọn ànímọ́ Jèhófà, pàápàá àánú rẹ̀, mo sì ń gbàdúrà sí i gan-an pé kó fi àánú yìí hàn sí mi. Lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, mo yẹra fáwọn ti mò ń bá rìn tẹ́lẹ̀, mo sì ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ, nígbà tó sì yá wọ́n gbà mí padà. Nínú àgọ́ ara mi, mò ń kórè àwọn ohun tí mo ti gbìn, àmọ́ mo ní àgbàyanu ìrètí. Ẹnu mi ò gbọpẹ́ fún ìyọ́nú àti ìdáríjì tí Jèhófà fi hàn sí mi.—Sáàmù 103:9-13; 130:3, 4; Gálátíà 6:7, 8.
20 Ká sòótọ́, àwọn tó wà nírú ipò tí Mario wà yìí ní láti sapá gan-an kí wọ́n tó lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́, ìfẹ́ wọn tó sọ jí padà nítorí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà, àti ṣíṣe àṣàrò, yóò fún wọn ní ìgboyà, á sì jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ìrètí Ìjọba Ọlọ́run tún wà lára ohun tó fún Mario lágbára. Òótọ́ ni, láfikún sí ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ìrètí jẹ́ ohun kan tó lágbára tó ń mú ká lè ṣe ohun tó dára nígbèésí ayé wa. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a ó gbé ẹ̀bùn tẹ̀mí tó ṣeyebíye yìí yẹ̀ wò fínnífínní.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?
• Báwo ni ìfẹ́ ṣe mú kí Jésù ní ìgboyà tó tayọ?
• Báwo ni ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ní fáwọn arákùrin ṣe mú kí wọ́n nígboyà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì ń lò láti sọ ìfẹ́ táwa Kristẹni ní fún Ọlọ́run di ahẹrẹpẹ?
• Àwọn àdánwò wo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á jẹ́ ká lè fara dà tìgboyàtìgboyà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní sáwọn èèyàn jẹ́ kó nígboyà láti máa wàásù nìṣó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ó gba ìgboyà láti máa fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Arábìnrin Namangolwa Sututu