Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi sọ nínú ìwé Diutarónómì 31:2 pé: ‘A kì yóò tún gba Mósè láyè mọ́ láti máa jáde àti láti máa wọlé’ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nígbà táwọn Bíbélì mìíràn sọ pé Mósè kò lágbára mọ́ láti ṣe aṣáájú?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò níbi yìí lè túmọ̀ sí ohun méjèèjì yẹn, ńṣe lọ̀rọ̀ táwọn Bíbélì kan lédè Yorùbá lò fi hàn pé nígbà tí Mósè darúgbó, kò lágbára kò sì lókun mọ́ láti ṣe aṣáájú. Bí àpẹẹrẹ, Bibeli Mimọ sọ ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ, ó ní: “Emi di ẹni ọgọfa ọdun li oni; emi kò le ma jade ki nsi ma wọle mọ́.”
Bẹ́ẹ̀ ohun tí Diutarónómì 34:7 ń fi yé wa ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè ti dàgbà gan-an, ara rẹ̀ ṣì le. Ó sọ pé: “Mósè sì jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà ikú rẹ̀. Ojú rẹ̀ kò di bàìbàì, okun agbẹ́mìíró rẹ̀ kò sì pòórá.” Nítorí náà, Mósè ṣì lágbára láti máa ṣe aṣáájú orílẹ̀-èdè náà, àmọ́ Jèhófà kò fẹ́ kó máa bá iṣẹ́ náà lọ mọ́. A rí ẹ̀rí èyí nínú ohun tí Mósè sọ bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Jèhófà ti wí fún mi pé, ‘Ìwọ kì yóò sọdá Jọ́dánì yìí.’” Ó ṣe kedere pé ńṣe ni Jèhófà ń tún ohun tó ti kọ́kọ́ sọ níbi omi Mẹ́ríbà sọ.—Númérì 20:9-12.
Ẹ̀mí Mósè gùn gan-an, ó sì ṣe àwọn ohun ribiribi nígbèésí ayé rẹ̀. A lè pín iye ọdún tó lò láyé àti bó ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀ sí ọ̀nà mẹ́ta. Ó fi ogójì ọdún gbé ní Íjíbítì, níbi tó ti gba “ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì” tó sì tún “jẹ́ alágbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.” (Ìṣe 7:20-22) Ó tún fi ogójì ọdún mìíràn gbé nílẹ̀ Mídíánì. Ibẹ̀ ló ti ní àwọn ànímọ́ tó bá ìlànà Ọlọ́run mu, èyí tí yóò fi máa ṣe aṣáájú àwọn èèyàn Jèhófà. Níkẹyìn, ó wá fi ogójì ọdún tó kù tọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà, ó sì ṣàkóso wọn. Àmọ́ báyìí, Jèhófà ti pinnu pé dípò Mósè, Jóṣúà ni yóò ṣe aṣáájú orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n á fi sọdá Odò Jọ́dánì bọ́ sí Ilẹ̀ Ìlérí.—Diutarónómì 31:3.
Nípa báyìí, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ló túmọ̀ Diutarónómì 31:2 lọ́nà tó tọ́. Nítorí náà, kì í ṣe torí pé Mósè kò lágbára mọ́ ni kò fi ṣe aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́, àmọ́ nítorí pé Jèhófà kò gbà á láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni.