Christophe Plantin Ọ̀kan lára Àwọn Òléwájú Nínú Títẹ Bíbélì
JOHANNES GUTENBERG (tó gbé ayé láàárín nǹkan bí ọdún 1397 sí 1468) gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta nítorí bó ṣe jẹ́ pé òun ló kọ́kọ́ fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé táwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò tẹ Bíbélì. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ Christophe Plantin ní tiẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òléwájú nínú ìwé títẹ̀ tó kópa tó jọjú nínú mímú kí ìwé àti Bíbélì dé ọwọ́ àwọn èèyàn káàkiri ayé láàárín ọdún 1500 sí 1559.
Nǹkan bí ọdún 1520 ni wọ́n bí Christophe Plantin ní ìlú Saint-Avertin lórílẹ̀-èdè Faransé. Ó fẹ́ràn ibi tí wọ́n bá ti fààyè gba onírúurú èrò nípa ẹ̀sìn, tí òwò sì ti lè búrẹ́kẹ́ dáadáa ju ilẹ̀ Faransé lọ. Torí náà nígbà tó kù díẹ̀ kó pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún, ó lọ tẹ̀dó sí ìlú Antwerp láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù, lágbègbè Faransé, Jámánì, Netherlands àti Luxembourg.
Iṣẹ́ lílẹ ìwé pọ̀ àti iṣẹ́ awọ ni Plantin kọ́kọ́ jí sí nígbèésí ayé ẹ̀. Àwọn olówó ń gba ti iṣẹ́ tó jojú ń gbèsè tó ń fawọ ṣe. Àmọ́, ohun kan ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1555 tó mú kí Plantin yí iṣẹ́ ẹ̀ padà. Lọ́jọ́ kan, ó fẹ́ gbé báàgì aláwọ tí wọ́n ní kó ṣe fún Ọba Philip Kejì tó jẹ́ alákòóso ilẹ̀ Sípéènì lọ, ni wọ́n bá dá a lọ́nà lójú ọ̀nà kan nílùú Antwerp. Àwọn kan tó ti mutí yó gún un ní ọ̀kọ̀ léjìká. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ọgbẹ́ Plantin san àmọ́ ojú àpá ò jojú ara, kò lè siṣẹ́ agbára mọ́, ó sì di dandan fún un pé kó pa òwò tó ń ṣe tì. Pẹ̀lú ìtìlẹyìn owó látọ̀dọ̀ Hendrik Niclaes tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀ya ìsìn Ánábatíìsì kan báyìí, Plantin bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwé títẹ̀.
“Iṣẹ́ àti Ìrọ́jú”
Orúkọ tí Plantin pe ibi tó ti ń tẹ̀wé ni De Gulden Passer tó túmọ̀ sí Kọ́ńpáàsì Olómi Góòlù. Ó fi àwọ̀ omi góòlù ya kọ́ńpáàsì ó sì kọ ọ̀rọ̀ tó ń lò gẹ́gẹ́ bí àkọmọ̀nà fún iṣẹ́ ajé rẹ̀ síbẹ̀. Ohun tó kọ síbẹ̀ ni “Labore et Constantia,” tó túmọ̀ sí “Iṣẹ́ àti Ìrọ́jú.” Ó dà bíi pé àkọmọ̀nà rẹ̀ yìí bá òun fúnra rẹ̀ mu torí pé ẹni tó jára mọ́ṣẹ́ ni.
Plantin mọ̀ pé ètò ẹ̀sìn àti òṣèlú ò fara rọ rárá lákòókò yẹn nílẹ̀ Yúróòpù, ó ń ṣọ́ra kó máa bàa kó sínú ìjàngbọ̀n. Iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ló wà lórí ẹ̀mí ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lòdì sí Ẹgbẹ́ Alátùn-úntò Ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, síbẹ̀ òǹkọ̀wé Maurits Sabbe sọ pé “èèyàn ò lè mọ ibi tó dúró sí lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn.” Ohun tó jẹ́ kí wọ́n máa gbéborùn kiri nípa ẹ̀ pé ó tẹ ìwé tó ń tan ẹ̀kọ́ òdì kálẹ̀ nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fi máa di ọdún 1562, ó di dandan fún un pé kó sá lọ sí ìlú Paris fún ohun tó lé lọ́dún kan.
Nígbà tí Plantin padà sí ìlú Antwerp lọ́dún 1563, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn oníṣòwò tó ti rọ́wọ́ mú dòwò pọ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn laráyé mọ̀ sí ẹlẹ́sìn Calvin. Láàárín ọdún márùn-ún, ọ̀tàlénígba ìwé ni Plantin fàwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ẹ̀ tẹ̀. Lára ohun tó tẹ̀ ni Bíbélì lédè Hébérù, Gíríìkì àti Látìn tó fi mọ́ Bíbélì kan lédè Dutch tó dára rèǹtèrente, ìyẹn Dutch Catholic Louvain.
“Iṣẹ́ Tó Yọrí Ọlá Jù Lọ Tí Òǹtẹ̀wé Kan Ṣoṣo Tíì Dá Ṣe”
Lọ́dún 1567, lákòókò táwọn tó ń ta ko ìjọba Sípéènì ń pọ̀ sí i láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù, Ọba Philip Kejì ti orílẹ̀-èdè Sípéènì rán Mọ́gàjí ìlú Alba lọ ṣe alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ta kò ó. Níwọ̀n bí mọ́gàjí náà ti ní àṣẹ tó tó látọ̀dọ̀ ọba, ó fẹ́ paná àtakò àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ìyẹn ló mú kí Plantin dáwọ́ lé iṣẹ́ ńlá kan tó nírètí pé ó máa mú gbogbo ìfura pé òun polongo ẹ̀kọ́ òdì kúrò nílẹ̀. Ó fẹ́ tẹ Bíbélì kan lédè ìpilẹ̀ṣẹ̀, èyí tó máa wúlò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́. Láti lè tẹ Bíbélì yìí jáde, Plantin dọ́gbọ́n tí Ọba Philip Kejì fi tì í lẹ́yìn. Ọba ṣèlérí ìtìlẹ́yìn ó sì rán gbajú gbajà ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Arias Montano láti lọ ṣe alábòójútó iṣẹ́ náà.
Montano lẹ́bùn èdè, wákàtí mọ́kànlá ló sì fi ń ṣiṣẹ́ lójúmọ́. Àwọn ìjìmì nínú èdè tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Sípéènì, Belgium àti Faransé sì ràn án lọ́wọ́. Àfojúsùn wọn ni láti ṣe àkọ̀tun Bíbélì elédè púpọ̀, ìyẹn Complutensian Polyglot,a èyí tó gbayì nígbà náà. Lára ohun tó wà nínú Bíbélì Elédè púpọ̀ ti Plantin la ti rí Latin Vulgate, Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sínú Bíbélì Septuagint yìí látilẹ̀ wá lédè Hébérù. Àwọn ohun tó tún wà nínú ẹ̀ ni Aramaic Targum àti Syriac Peshitta, tó fi mọ́ àwọn ìtumọ̀ olówuuru tí wọ́n ṣe fún wọn lédè Látìn.
Ọdún 1568 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ ẹ́. Ọdún 1573 ni wọ́n sì tó parí arabaríbí iṣẹ́ yìí. Tá a bá wo àkókò tí irú iṣẹ́ yẹn máa ń gbà nígbà yẹn, a óò rí i pé ó yá wọn gan-an ni. Nínú lẹ́tà tí Montano kọ sí Ọba Philip Kejì, ó sọ pé: “Ohun tá à ń ṣe níbì yìí lóṣù kan ju ohun tí wọ́n ń fi ọdún kan ṣe ní orílẹ̀-èdè Róòmù lọ.” Ẹ̀dà ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàlá [1,213] Bíbélì Elédè Púpọ̀ yìí ni Plantin tẹ̀, gbogbo wọn ló sì wà ní ìdìpọ̀ ńláńlá mẹ́jọ-méjọ. Ní ojú ewé tí wọ́n kọ àkọlé ìwé náà sí, wọ́n ya àwòrán kìnnìún, màlúù, ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn tí gbogbo wọn jùmọ̀ ń jẹ̀ lálàáfíà níbì kan náà. Ohun tí Aísáyà 65:25 sọ tẹ́lẹ̀ ni ibẹ̀ yẹn ń fi hàn. Àádóje owó guilder ló máa ná ẹni tó bá fẹ́ ra gbogbo ẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Owó tó jọjú lówó yìí lákòókò yẹn torí pé nǹkan bí àádọ́ta guilder lowó tó ń wọlé fún ìdílé kan lọ́dún. Ìdìpọ̀ ẹ̀ lódindi ni wọ́n wá mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn sí Bíbélì Antwerp Elédè Púpọ̀. Wọ́n tún pè é ní Biblia Regia (ìyẹn Bíbélì Ọba) torí pé Ọba Philip Kejì ló gbówó tí wọ́n fi ṣe iṣẹ́ yẹn kalẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Póòpù Gregory Kẹtàlá fọwọ́ sí Bíbélì náà, wọ́n dojú àtakò tó gbóná kọ Arias Montano torí iṣẹ́ tó ṣe. Ìdí kan tí wọ́n fi ta kò ó ni pé Montano gbà pé ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ látinú èdè Hébérù ṣe pàtàkì ju Latin Vulgate lọ. Olórí alátakò ẹ̀ ni León de Castro, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì, torí pé ìgbàgbọ́ Castro yìí ni pé Latin Vulgate ló láṣẹ Ọlọ́run. De Castro fẹ̀sùn kan Montano pé ó ń ki èrò tó ta ko ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan bọ inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, de Castro sọ ní pàtàkì pé Bíbélì Syriac Peshitta yọ 1 Jòhánù 5:7, tí wọ́n fèrú ki bọ Bíbélì kúrò. Bó ṣe kà nínú Bibeli Ajuwe nìyí, “ni ọrun, Baba, Ọrọ ati Ẹmi Mimọ; awọn mẹẹtẹta yii si jasi ọkan.” Àmọ́ ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀ràn àdámọ̀ nílẹ̀ Sípéènì sọ pé Montano ò jẹ̀bi ẹ̀sùn àdámọ̀. Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp làwọn kan kà sí “iṣẹ́ tó yọrí ọlá jù lọ tí òǹtẹ̀wé kan ṣoṣo tíì dá ṣe ní ọ̀rúndún kẹ́rìndínlógún.”
Àǹfààní Iṣẹ́ Ọwọ́ Ẹ̀ Ò Pa Rẹ́
Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé méjì tàbí mẹ́ta péré ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn òǹtẹ̀wé ayé ìgbà yẹn máa ń ní. Àmọ́ ìgbà kan wà tí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí Plantin ní á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó méjìlélógún táwọn òṣíṣẹ́ ẹ̀ á sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́jọ [160]. Wọ́n wá mọ̀ ọ́n jákèjádò gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Spanish sí ọ̀kan lára àwọn òléwájú nínú iṣẹ́ ìwé títẹ̀.
Ní gbogbo àkókò yìí, àwọn èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Yúróòpù ò tíì yé ta ko ìṣàkóso ilẹ̀ Sípéènì. Rògbòdìyàn yìí dé ìlú Antwerp. Lọ́dún 1576, àwọn ajaguntà orílẹ̀-èdè Sípéènì tí ò tíì gbowó iṣẹ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́júujà sí ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í run ún. Ó ju ẹgbẹ̀ta ilé lọ tí wọ́n jó, wọ́n sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùgbé ilú Antewerp. Ńṣe làwọn oníṣòwò sá kúrò nílùú. Kékeré kọ́ ni Àdánù owó tí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn kó bá Plantin. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún di dandan fún un kó san owó ìṣákọ́lẹ̀ tó pọ̀ fáwọn ajaguntà yìí.
Lọ́dún 1583, Plantin kó lọ sí ìlú Leiden, tó fi nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà (ọgọ́ta máìlì) jìnnà sí àríwá ìlú Antwerp. Ó dá ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé sílẹ̀ níbẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di atẹ̀wé fún ilé ìwé gíga Leiden University táwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítántì tó ń tẹ̀ lé Calvin dá sílẹ̀. Bó ṣe di pé wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kàn án lẹ́ẹ̀kan sí i pé ó ń tan ẹ̀kọ́ tó lòdì sí ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kálẹ̀ nìyẹn. Nítorí náà, Plantin ní láti padà sí ìlú Antwerp ní ìparí ọdún 1585 ní kété tí ìlú náà tún padà bọ́ sábẹ́ ìṣàkóso Sípéènì. Nígbà yẹn, ó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún, ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé tó dá sílẹ̀ sì ti ń kógbá sílé díẹ̀díẹ̀, òṣìṣẹ́ mẹ́rin péré ló kù níbẹ̀ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan ṣoṣo. Plantin bẹ̀rẹ̀ sí í tún ilé ìtẹ̀wé yẹn gbé dìde. Ó mà ṣe o, kò padà sí bó ṣe wà tẹ̀lẹ́ mọ́, nígbà tó sì di July 1, ọdún 1589, Plantin kú.
Láàárín ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n péré, Christophe Plantin tẹ ìwé ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀sàn ó lé mẹ́ta [1,863] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Èyí túmọ̀ sí pé á máa tó márùndínlọ́gọ́ta tó ń tẹ̀ lọ́dún. Kódà lójúmọ́ tó mọ́ lónìí, ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé aládàáni tó máa tẹ irú ẹ̀ á múra! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Plantin fúnra ẹ̀ ò bá wọn fọwọ́ dan-in dan-in mú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, iṣẹ́ tó ṣe sílẹ mú ìtẹ́síwájú bá iṣẹ́ ìtẹ̀wé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tó ní ìmísí. (2 Tímótì 3:16) Àní sẹ́, Plantin àtàwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ ìtẹ̀wé lákòókò kan náà ṣe bẹbẹ nínú mímú kí Bíbélì dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọdún 1517 ni wọ́n tẹ Bíbélì elédè púpọ̀ yìí. Ó ní àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù, Gíríìkì àti Látìn tó fi mọ́ àwọn apá kan tí wọ́n kọ ní èdè Árámáíkì nínú. Wo àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Elédè Púpọ̀ Ti Complutensian—Ohun Èlò Pàtàkì Nínú Ìtàn,” tó wà ní ojú ìwé 28 sí 31 nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2004.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
IBI ÌKÓHUN-ÌṢẸ̀ǸBÁYÉ-SÍ PLANTIN-MORETUS
Lọ́dún 1877, wọ́n ṣí ilé tí Plantin àtàwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ gbé tí wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ láàárín ọdún 1576 sí ọdún 1871 ní ìlú Antwerp, wọ́n sì sọ ọ́ di ilé ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí táwọn èèyàn lè máa lọ wò. Kò sí ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé míì tó tíì wà látayé ìgbà yẹn tó ṣì tún dúró dáadáa mọ́. Àpapọ̀ ilé ìtẹ̀wé márùn-ún tó ti wà láti ọ̀rúndún kẹ́tàdínlógún àti ìkejìdínlógún ni wọ́n ṣàfihàn rẹ̀. Àwọn méjì míì, tí wọ́n tíì pẹ́ jù láyé, ti wà láti àkókò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ pẹ́ tó àkókò Plantin. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] àpótí tí wọ́n ń lò fún ọnà ìwé títẹ̀, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] igi tí wọ́n gbẹ́ tí wọ́n fi ń ṣe ọnà ìwé títẹ̀ àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] àtẹ bàbà fínfín ló wà ní ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí náà. Òjílélẹ́gbẹ̀ta ó dín méjì [638] ìwé tí wọ́n fọwọ́ kọ tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ tó ọrúndún kẹ́sàn-án sí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àti ìwé mẹ́rìnlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀jọ [154] tí wọ́n ti tẹ̀ ṣáájú ọdún 1501 tún wà níbi ìkóhun-ìṣèǹbáyé-sí náà. Lára wọn ni Bíbélì Guntenberg tí wọ́n ti ṣe ṣáájú ọdún 1461 àti ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Plantin tó lókìkí, ìyẹn Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Arias Montano
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Lára àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì Elédè Púpọ̀ tí wọ́n ṣe ní Antwerp ni àwọn Bíbélì èdè Hébérù bíi Latin “Vulgate,” àti Bíbélì “Septuagint,” lédè Gíríìkì tó fi mọ́ Syriac “Peshitta” àti Aramaic Targum títí kan àwọn ìtumọ̀ wọn tó wà lédè Látìn
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Museum Plantin-Moretus/Stedelijk Prentenkabinet Antwerpen
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwòrán méjèèjì: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Museum Plantin-Moretus/Stedelijk Prentenkabinet Antwerpen