ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 1/1 ojú ìwé 9-11
  • Ǹjẹ́ O Lè Mú Kí Ìfẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Mú Kí Ìfẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Mọyì Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́
  • “Àyè Há fún” Àwọn Ará Kọ́ríńtì
  • Bí Ìfẹ́ Wa Ṣe Lè Gbòòrò Sí I Lóde Òní
  • Sapá Láti Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tuntun
  • Kọbi Ara Sóhun Táwọn Ẹlòmíràn Nílò
  • ‘Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Gbòòrò Sí I’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tó O Ní Fáwọn Ará Máa Pọ̀ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan fún Ara Yín”
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 1/1 ojú ìwé 9-11

Ǹjẹ́ O Lè Mú Kí Ìfẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I?

Ẹ̀WỌ̀N tí wọ́n máa ń so mọ́ ìdákọ̀ró ọkọ̀ òkun kan gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó lè kojú ìgbì omi òkun kí ọkọ̀ náà má bàa sú lọ. Àmọ́, kìkì ohun tó lè mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé kí ibi tí ẹ̀wọ̀n náà ti so kọ́ra wọn sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí kó sì lágbára gan-an. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀wọ̀n náà á já.

Bákan náà ni ọ̀ràn ìjọ Kristẹni ṣe rí. Kí ìjọ kan tó lè lágbára kó sì dúró sán-ún, àwọn tó wà níbẹ̀ ní láti wà níṣọ̀kan. Kí ló máa so wọ́n pọ̀? Ìfẹ́ ni. Òun ló lágbára jù lọ láti mú kí ìṣọ̀kan wà. Abájọ tí Jésù Kristi fi sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” Láìsí àní-àní, ìfẹ́ táwọn Kristẹni ní sí ara wọn kọjá ti àárín àwọn ọ̀rẹ́ lásán, ó sì kọjá pé a kàn ń bọ̀wọ̀ fúnni lásán. Ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ni.—Jòhánù 13:34, 35.

Bá A Ṣe Lè Mọyì Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́

Ọ̀pọ̀ ìjọ ni ọjọ́ orí àwọn tó wà níbẹ̀ yàtọ̀ síra, tí ẹ̀yà wọn, orílẹ̀-èdè wọn, àṣà wọn, àti èdè wọn sì yàtọ̀ síra, títí kan ipò tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n wà. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló láwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì lóhun tó ń mọ́kàn rẹ̀ balẹ̀ àtohun tó ń bà á lẹ́rù, bó sì ṣe máa ń rí, gbogbo wọn ló ń níṣòro tó ń bá wọn fínra, irú bí àìsàn tàbí àìrówóná. Bí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra yìí lè mú kó ṣòro fún wọn láti wà níṣọ̀kan. Kí ló wá lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìfẹ́ wa gbòòrò sí i ká sì wà níṣọ̀kan láìfi àwọn ìṣòro wa pè? Mímọyì gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìfẹ́ àárín ara wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.

Àmọ́, báwo la ṣe ń mọyì ẹnì kan? A lè fi hàn pé a mọyì ẹnì kan tá a bá ń ṣọ̀yàyà sí onítọ̀hún tá a sì ń buyì fún un bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Tá a bá mọyì àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, àwọn ìṣòro wọn á máa ká wa lára, a ó kà wọ́n sẹ́ni tó ṣe pàtàkì sí wa gan-an, a ó mọ ibi tí wọ́n dára sí, inú wa yóò sì máa dùn pé àwa àtàwọn jùmọ̀ ń jọ́sìn Ọlọ́run kan náà. Nípa bẹ́ẹ̀, a óò nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Gbígbé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ní ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò ní ṣókí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tá a lè gbà fi ìfẹ́ Kristẹni hàn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

“Àyè Há fún” Àwọn Ará Kọ́ríńtì

Pọ́ọ̀lù kọ̀wé rẹ̀ kìíní sí àwọn ará Kọ́ríńtì ní ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, ó sì kọ ìkejì ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé àwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì kò mọyì àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn. Ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí rèé, ó ní: “A ti la ẹnu wa sí yín, ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, ọkàn-àyà wa ti gbòòrò síwájú. Àyè kò há fún yín ní inú wa, ṣùgbọ́n àyè há fún yín ní inú ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ẹ̀yin fúnra yín.” (2 Kọ́ríńtì 6:11, 12) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ayé há fún” wọn?

Ohun tó ń sọ ni pé ara wọn ò yá mọ́ọ̀yàn, wọn ò sì lẹ́mìí ọ̀làwọ́. Ọ̀mọ̀wé kan lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì gbà pé àwọn ará Kọ́ríńtì “ò nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù nítorí ìfura òdì tí wọ́n ní sí i . . . àti nítorí pé wọ́n lérò pé Pọ́ọ̀lù ò ka àwọn sí.”

Kíyè sí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wọn, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí èrè iṣẹ́ ní ìdápadà—mo ń sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀—ẹ̀yin, pẹ̀lú, ẹ gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́ríńtì 6:13) Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ túbọ̀ gbòòrò sí i. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí tó dára kí wọ́n sì jẹ́ ọ̀làwọ́ dípò bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹni tí kì í fọkàn tán ara wọn tí wọ́n sì máa ń ka ẹ̀sùn kéékèèké sí ara wọn lọ́rùn.

Bí Ìfẹ́ Wa Ṣe Lè Gbòòrò Sí I Lóde Òní

Inú wa dùn gan-an pé àwọn tó ń fi òtítọ́ inú jọ́sìn Ọlọ́run lóde òní ń sa gbogbo ipá wọn láti jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní láàárín ara wọn gbòòrò sí i. Ká sòótọ́, ó gba ìsapá gidi kéèyàn tó lè jẹ́ kí ìfẹ́ òun gbòòrò sí i. Kì í ṣe ohun téèyàn kàn ń fẹnu lásán sọ. Mímú kí ìfẹ́ wa gbòòrò sí i túmọ̀ sí pé a ó máa hùwà lọ́nà tó yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í ka àwọn ẹlòmíràn sí. Wọn kì í bìkítà nípa ẹnikẹ́ni, kò sẹ́ni tó jọ wọ́n lójú, kòbákùngbé ọ̀rọ̀ ló sì máa ń tẹnu wọn jáde. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ní irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ láé. Ẹ ò rí i pé kò ní bójú mu tá a bá lọ ń ṣe bíi tàwọn ará Kọ́ríńtì, tá ò jẹ́ kí ìfẹ́ wa gbèrú nítorí àìfọkàntán àwọn ará wa! Èyí lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé àṣìṣe arákùnrin kan la máa ń rí tá ò kì í rí àwọn ànímọ́ rere tó ní. Ó tún lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá jẹ́ kí ìfẹ́ wa gbòòrò dé ọ̀dọ̀ àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwa.

Ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ gbòòrò gan-an máa ń mọyì àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ gan-an. Ńṣe ló máa ń gbé wọn gẹ̀gẹ̀, tó máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn, tí ọ̀ràn wọn sì máa ń ká a lára. Kódà bí wọ́n tiẹ̀ ṣe ohun tó lè mú kó bínú sí wọn, kíá ló máa ń dárí jì wọ́n, kò sí ní bá wọn yodì. Dípò ìyẹn, yóò gbà pé àwọn onígbàgbọ́ bíi tòun yìí ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí wọ́n ṣe náà. Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó ní yóò ràn án lọ́wọ́ láti ní irú ìfẹ́ tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

Sapá Láti Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tuntun

Ìfẹ́ àtọkànwá yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun yàtọ̀ sáwọn tá a ti ní tẹ́lẹ̀, yóò sì tún mú ká wá ọ̀nà bí àjọṣe àárín àwa àtàwọn tá ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ra nínú ìjọ yóò ṣe túbọ̀ dára sí i. Àwọn wo nìyẹn? Wọ́n lè jẹ́ àwọn kan lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n máa ń tijú, tàbí tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́ nítorí àwọn ìdí kan. A lè kọ́kọ́ máa rò pé kò sóhun tí ọ̀rọ̀ àwa àti irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi bára mu ju pé a jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà. Àmọ́ ṣé kì í ṣòótọ́ ni pé ipò àwọn kan tó bára wọn ṣọ̀rẹ́ nínú Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ jọra?

Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ orí Rúùtù àti ti Náómì jìnnà síra fíìfíì, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá yàtọ̀ síra, àṣà ìbílẹ̀ wọn ò pa pọ̀, kódà èdè kan náà kọ́ ni wọ́n ń sọ. Síbẹ̀ gbogbo ìyẹn ò ní kí wọ́n máà jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn. Ọmọ ọba tí wọ́n tọ́ dàgbà láàfin ni Jónátánì, àmọ́ olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì ní tiẹ̀. Ọjọ́ orí wọn ò sún mọ́ra rárá, síbẹ̀ àárín wọn gún régé débi pé, ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn wà lára èyí tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn. Àwọn tá a mẹ́nu kàn pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ wọ̀nyí láyọ̀ gan-an wọ́n sì tún gbé ara wọn ró nípa tẹ̀mí.—Rúùtù 1:16; 4:15; 1 Sámúẹ́lì 18:3; 2 Sámúẹ́lì 1:26.

Kódà lóde òní pàápàá, àwọn Kristẹni tòótọ́ tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra tí nǹkan ò sì rí bákan náà fún wọn máa ń bára wọn ṣọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Regina jẹ́ ìyá tó ń dá nìkan tọ́ àwọn ọmọ méjì tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún.a Ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí gan-an, kò sì fi bẹ́ẹ̀ ráyè láti máa lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn. Àgbàlagbà ni Harald àti Ute ní tiwọn, wọ́n ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, wọn ò sí bímọ. Tá a bá wò ó, a ó rí i pé ọ̀ràn àwọn ìdílé méjèèjì yìí kò fi bẹ́ẹ̀ jọra. Àmọ́ Harald àti Ute fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé kí wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́ wọn gbòòrò sí i. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe Regina àtàwọn ọmọ rẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe, wọ́n jọ máa ń jáde òde ẹ̀rí, wọ́n sì tún máa ń ṣeré ìnàjú pa pọ̀.

Ǹjẹ́ a lè jẹ́ kí ìfẹ́ wa gbòòrò sí i, ká láwọn ọ̀rẹ́ mìíràn pẹ̀lú àwọn tá a ti ní tẹ́lẹ̀? Kí ló dé tá ò kúkú fi wá bá a ṣe máa túbọ̀ sún mọ́ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa, tí orílẹ̀-èdè wọn, àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ sí tiwa?

Kọbi Ara Sóhun Táwọn Ẹlòmíràn Nílò

Jíjẹ́ onínúure a jẹ́ ká kọbi ara sóhun táwọn ẹlòmíràn nílò. Àwọn nǹkan bíi kí ni? Láti mọ̀, kíyè sí àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni. Àwọn ọ̀dọ́ nílò ìtọ́sọ́nà, àwọn àgbàlagbà nílò ìṣírí, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nílò oríyìn àti ìtìlẹ́yìn, àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí ìbànújẹ́ da orí wọn kodò nílò ẹni tí wọ́n lè fọ̀rọ̀ lọ̀ tó sì máa tẹ́tí sí wọn. Kò sẹ́ni tí kò nílò ìrànlọ́wọ́. A fẹ́ kọbi ara sóhun táwọn ará wa nílò wọ̀nyí débi tágbára wa bá gbé e dé.

Kí ìfẹ́ èèyàn gbòòrò sí i tún túmọ̀ sí pé a ó máa fòye bá àwọn tó láwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ lò. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tó ń ṣàìsàn líle tàbí tó ń dojú kọ àdánwò líle? Mímú kí ìfẹ́ rẹ gbòòrò sí i àti jíjẹ́ onínúure yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn tó níṣòro, wàá sì lè ṣèrànwọ́ fún wọn.

Níwọ̀n bí àwọn ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú yóò ti nímùúṣẹ láìpẹ́, wíwà ní ìrẹ́pọ̀ nínú ìjọ yóò jẹ́ ohun tó ṣeyebíye gan-an ju ohun ìní, ẹ̀bùn àbínibí, tàbí àṣeyọrí èyíkéyìí lọ. (1 Pétérù 4:7, 8) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè jẹ́ kí ìṣọ̀kan yìí túbọ̀ lágbára sí i nínú ìjọ wa nípa jíjẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ túbọ̀ gbòòrò sí i. Ó dá wa lójú pé a ó rí ìbùkún rẹpẹtẹ gbà lọ́dọ̀ Jèhófà tá a bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, tó sọ pé: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.”—Jòhánù 15:12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

Mímọyì àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa túmọ̀ sí pé wọ́n ṣe pàtàkì sí wa gan-an, wọ́n níyì lọ́wọ́ wa, a ó sì máa jẹ́ kí ìṣòro wọn ká wa lára

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́