‘Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Gbòòrò Sí I’
1. Kí ni ojúṣe wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
1 Láàárín àwa Kristẹni tá a jọ jẹ́ ará, ojúṣe wa ni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti mú kí ìjọ jẹ́ ibi tí ìfẹ́ wà. (1 Pét. 1:22; 2:17) Ìfẹ́ yìí á gbilẹ̀ nígbà tá a bá mú kí ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ wa fún ara wa “gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́r. 6:12, 13) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa dunjú?
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká bá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ dọ́rẹ̀ẹ́?
2 Ọ̀rẹ́ Wa Á Ṣe Tímọ́tímọ́ Sí I: Bí a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ la óò túbọ̀ máa mọyì ìgbàgbọ́, ìfaradà àtàwọn ànímọ́ dáradára mìíràn tí wọ́n ní. A ò ní máa ka ìkùdíẹ̀-káàtó wọn sí bàbàrà, ọ̀rẹ́ wa á sì túbọ̀ wọ̀ sí i. Bá a bá mọ ara wa dáadáa, a ó lè túbọ̀ máa gbé ara wa ró a ó sì túbọ̀ máa tu ara wa nínú. (1 Tẹs. 5:11) A lè di “àrànṣe afúnnilókun” fún ara wa kí á lè dènà àwọn ohun tó lè múni hùwà àìtọ́ nínú ayé Sátánì. (Kól. 4:11) Bá a ṣe ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó kún fún pákáǹleke wọ̀nyí, a mà dúpẹ́ o pé a ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dára láàárín àwọn èèyàn Jèhófà!—Òwe 18:24.
3. Báwo la ṣe lè jẹ́ àrànṣe afúnnilókun fún àwọn ẹlòmíràn?
3 Àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ lè fún wa lókun, kí wọ́n sì tù wá nínú nígbà tá a bá ní ìṣòro lílekoko. (Òwe 17:17) Kristẹni kan tó máa ń fìgbà gbogbo ronú pé òun kò já mọ́ nǹkan kan sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tó máa ń sọ ohun tó dára nípa mi fún mi kí n lè mú èrò òdì tí mo ní kúrò lọ́kàn.” Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Òwe 27:9.
4. Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọ àwọn ẹlòmíràn dunjú nínú ìjọ?
4 Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Ẹlòmíràn: Báwo la ṣe lè mú kí ìfẹ́ wa fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ gbòòrò sí i? Yàtọ̀ sí pé kó o kí àwọn ẹlòmíràn ní ìpàdé Kristẹni, o tún lè gbìyànjú láti máa bá wọn sọ ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀. Máa fi ìfẹ́ hàn sí wọn láìsí pé ò ń tojú bọ ọ̀ràn wọn. (Fílí. 2:4; 1 Pét. 4:15) Ọ̀nà mìíràn láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn ni pé kó o pè wọ́n wá jẹun nílé rẹ. (Lúùkù 14:12-14) Tàbí bóyá kó o ṣètò láti bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (Lúùkù 10:1) Bá a ṣe ń lo ìdánúṣe láti túbọ̀ mọ àwọn ará wa dunjú, à ń mú kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.—Kól. 3:14.
5. Ọ̀nà wo la lè gbà mú kí àwọn ọ̀rẹ́ wa pọ̀ sí i?
5 Ǹjẹ́ kìkì àwọn ojúgbà wa tàbí àwọn tá a jọ nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan náà la máa ń fẹ́ bá dọ́rẹ̀ẹ́? Kò yẹ ká jẹ́ kí èyí ṣèdíwọ́ fún wa láti máa bá àwọn yòókù nínú ìjọ ṣọ̀rẹ́. Dáfídì àti Jónátánì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, bákan náà ni Rúùtù àti Náómì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí wọn àti ibi tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti dàgbà yàtọ̀ síra. (Rúùtù 4:15;1 Sám. 18:1) Ǹjẹ́ o lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ pọ̀ sí i? Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí lè mú ọ̀pọ̀ ìbùkún tó ò retí tẹ́lẹ̀ wá fún ọ.
6. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú mímú kí ìfẹ́ wa fún àwọn ará wa gbòòrò sí i?
6 Bá a ṣe ń mú kí ìfẹ́ wa fún àwọn ẹlòmíràn gbòòrò sí i, à ń fún ara wa lókun lẹ́nì kìíní-kejì, a sì ń mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. Síwájú sí i, Jèhófà fúnra rẹ̀ á bù kún wa nítorí ìfẹ́ tá à ń fi hàn sí àwọn ará wa. (Sm. 41:1, 2; Héb. 6:10) O ò ṣe pinnu pé wàá túbọ̀ gbìyànjú láti mọ àwọn ará púpọ̀ sí i dunjú?