ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 2/1 ojú ìwé 3
  • Ṣé Àwọn Mìíràn Nìkan Lo Fẹ́ Kó Máa Sọ Òótọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àwọn Mìíràn Nìkan Lo Fẹ́ Kó Máa Sọ Òótọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tí Irọ́ Pípa Máa Ń Fà
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Sọ Òótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ṣé Òtítọ́ Ṣì Lérè?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Jèhófà, Ọlọ́run Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Eeṣe Ti Ó Fi Rọrùn Tobẹẹ Lati Purọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 2/1 ojú ìwé 3

Ṣé Àwọn Mìíràn Nìkan Lo Fẹ́ Kó Máa Sọ Òótọ́?

“MO KÓRÌÍRA irọ́, mi ò sì fẹ́ kéèyàn máa parọ́ fún mi.” Ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ló sọ bẹ́ẹ̀. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára ọ̀pọ̀ jù lọ wa nìyẹn. Ohun tá a máa ń fẹ́ ni pé, kí ohunkóhun táwọn èèyàn bá sọ fún wa jóòótọ́, ì báà jẹ́ èyí tí wọ́n sọ lọ́rọ̀ ẹnu tàbí èyí tí wọ́n kọ sínú ìwé. Àmọ́ ṣé àwa náà máa ń sọ òótọ́ tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Jámánì, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé “kò sóhun tó burú nínú kéèyàn parọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan láti lè yọ ara ẹni tàbí àwọn mìíràn nínú wàhálà. Kódà, wọ́n ní irọ́ pọn dandan kí àjọṣe àárín àwọn èèyàn má bàa dàrú.” Ohun tí akọ̀ròyìn kan sì kọ sínú ìwé ìròyìn kan ni pé: “Kéèyàn máa sọ òótọ́ nígbà gbogbo dára gan-an, àmọ́ kì í jẹ́ káyé dùn.”

Àbí ó lè jẹ́ pé ńṣe la fẹ́ káwọn èèyàn máa sòótọ́ àmọ́ táwa fúnra rò pé nígbà mìíràn, ìdí pàtàkì wà tí kò fi yẹ káwa sọ òótọ́? Ǹjẹ́ ó já mọ́ ohunkóhun yálà a parọ́ tàbí a sọ òótọ́? Téèyàn kì í bá sọ òótọ́, àwọn nǹkan wo ló lè jẹ́ àbájáde rẹ̀?

Àwọn Ohun Tí Irọ́ Pípa Máa Ń Fà

Ìwọ wo àwọn nǹkan burúkú tó máa ń tìdí irọ́ pípa jáde. Irọ́ kì í jẹ́ kí ọkọ àti aya lè fọkàn tán ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí òbí àti ọmọ, tàbí ẹ̀gbọ́n àti àbúrò, lè gba ara wọn gbọ́. Sísọ ohun tí kò dáni lójú nípa ẹnì kan lè jẹ́ káwọn èèyàn máa fojú burúkú wo onítọ̀hún. Káwọn òṣìṣẹ́ máa lu iléeṣẹ́ ní jìbìtì máa ń mú kówó tí iléeṣẹ́ náà ń ná túbọ̀ ga sí i, ńṣe lèyí sì máa ń mú káwọn ohun tí wọ́n ń ṣe jáde túbọ̀ gbówó lórí sí i. Táwọn èèyàn bá parọ́ nígbà tí wọ́n bá ń dáhùn àwọn ìbéèrè inú fọ́ọ̀mù owó orí kì í jẹ́ kí ìjọba rí owó tó tó láti pèsè ohun tí aráàlú nílò. Táwọn olùwádìí bá ń parọ́, ó lè ba iṣẹ́ wọn jẹ́, ó sì lè ba orúkọ rere tí ilé iṣẹ́ tàbí ilé ìwé tí wọ́n ń bá ṣiṣẹ́ ti ní jẹ́. Àwọn okòwò tí kò mọ́, tí wọ́n sọ pé ó lè sọ èèyàn dolówó òjijì, máa ń mú káwọn tó rọrùn láti tàn jẹ pàdánù gbogbo owó tí wọ́n ní nígbèésí ayé wọn, tàbí kí ohun tó tiẹ̀ burú jùyẹn lọ ṣẹlẹ̀ sí wọn. Abájọ tí Bíbélì fi sọ fún wa pé lára àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run kórìíra ni “ahọ́n èké” àti “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ”!—Òwe 6:16-19.

Nígbà táwọn kan bá tan irọ́ kálẹ̀, ó lè ṣàkóbá fáwọn èèyàn àti fún àwùjọ lódindi. Ṣàṣà èèyàn ni yóò sọ pé èyí kì í ṣòótọ́. Bọ́rọ̀ bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé táwọn èèyàn fi máa ń mọ̀ọ́mọ̀ parọ́? Àti pé, ṣé gbogbo àìsọ òótọ́ ni irọ́? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè mìíràn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Irọ́ kì í jẹ́ kí ọkọ àti aya lè fọkàn tán ara wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́