Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Sọ Òótọ́?
NÍGBÀ tí Manfred wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, ń kọ́ nípa iṣẹ́ ọ́fíìsì ní ilé iṣẹ́ kan tó ti ń ṣíṣẹ́.a Ilé iṣẹ́ tó ń bá ṣiṣẹ́ yìí ṣètò pé lọ́jọ́ méjì láàárín ọ̀sẹ̀, kóun àtàwọn mìíràn tí wọ́n jọ ń kọ́ ẹ̀kọ́ náà lọ máa gba ẹ̀kọ́ sí i ní kọ́lẹ́ẹ̀jì kan. Lọ́jọ́ kan, ní kọ́lẹ́ẹ̀jì náà, wọ́n ní káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà máa lọ kó tó tó àkókò tó yẹ kí wọ́n ṣe tán. Òfin iléeṣẹ́ náà ni pé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbọ́dọ̀ padà sẹ́nu iṣẹ́ láti lọ ṣiṣẹ́ títí iṣẹ́ ọjọ́ náà á fi parí. Àmọ́ dípò kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni gbogbo wọ́n gba ibòmíràn lọ tí wọ́n lọ gbádùn ara wọn, àyàfi Manfred nìkan ló padà síbi iṣẹ́. Lọ́jọ́ yẹn, ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀ràn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bá dédé wá síbi iṣẹ́. Nígbà tó rí Manfred, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí o ò lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì lónìí? Ibo làwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù sì wà?” Báwo ló ṣe yẹ kí Manfred dáhùn?
Àwọn èèyàn sábà máa ń bára wọn nírú ipò tí Manfred bára rẹ̀ yìí: Ṣé kó sọ òótọ́ ni, àbí kó bo àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ láṣìírí? Tó bá sọ òótọ́, wàhálà bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nìyẹn, wọn ò sì ní fẹ́ràn rẹ̀. Ṣé kò sóhun tó burú níbẹ̀ bó bá parọ́ nínú irú ipò yìí? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni, kí ni wàá ṣe? A ó padà sórí ọ̀rọ̀ Manfred tó bá yá, àmọ́ ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun kan, ìyẹn ni àwọn ohun tó rọ̀ mọ́ ọn nígbà tó bá di dandan ká pinnu bóyá ká sọ òótọ́ tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀.
Òótọ́ àti Irọ́ Ta Kora
Nígbà tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá èèyàn sórí ilẹ̀ ayé, orí òótọ́ lohun gbogbo dá lé. Kò sí fífi irọ́ lú òótọ́, kò sí àyínìke, kò sì sí pípe ohun tó jẹ́ irọ́ ní òótọ́. “Ọlọ́run òtítọ́” ni Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀; Ọlọ́run kò lè parọ́, ó sì kórìíra irọ́ àtàwọn tó ń parọ́.—Sáàmù 31:5; Jòhánù 17:17; Títù 1:2.
Báwo wá ni àìsọ òótọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀? Jésù Kristi fún wa ní ojúlówó ìdáhùn nígbà tó sọ fáwọn onísìn tí wọ́n ń ṣàtakò rẹ̀ tí wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín. Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Kò sí àní-àní pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ni Jésù ń tọ́ka sí, ìyẹn nígbà tí Sátánì tan tọkọtaya àkọ́kọ́ láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì kú.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5; Róòmù 5:12.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn kedere pé Sátánì ni “baba irọ́,” òun ló dá irọ́ pípa àti àìsọ òótọ́ sílẹ̀. Sátánì ṣì ni olórí àwọn tó ń gbé irọ́ lárugẹ, kódà, ó “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Òun ló ni ẹ̀bi gbogbo aburú tí irọ́ tó gbòde kan ti fà bá ọmọ aráyé lónìí.—Ìṣípayá 12:9.
Àtìgbà tí irọ́ ti wà, ìyẹn nígbà tí Sátánì Èṣù bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni irọ́ àti òótọ́ kì í ti í ṣe ọ̀rẹ́ ara wọn, bó sì ṣe rí títí dòní olónìí nìyẹn. Kò síbi tí kò sí láàárín àwùjọ èèyàn, gbogbo èèyàn pátá ló sì kàn. Bí ẹnì kan ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lè mú kó wà níhà òtítọ́ tàbí àìṣòótọ́. Òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn Bíbélì, ló ń darí ìgbésí ayé àwọn tó wà níhà ti Ọlọ́run. Ńṣe lẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀ lé ọ̀nà òtítọ́ á ṣubú sọ́wọ́ Sátánì, yálà ẹni náà mọ̀ tàbí kò mọ̀, torí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19; Mátíù 7:13, 14.
Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Máa Ń Fẹ́ Láti Parọ́?
Ìdí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn fi máa ń parọ́ ni pé “gbogbo ayé” wà lábẹ́ agbára Sátánì. Àmọ́, a lè béèrè pé, ‘Kí nìdí tí Sátánì, tó jẹ́ “baba irọ́,” fi ṣe bẹ́ẹ̀?’ Sátánì mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ lórí gbogbo ohun tó dá, títí kan tọkọtaya tó kọ́kọ́ dá. Síbẹ̀, Sátánì fẹ́ kí ipò ńlá tí kò lẹ́gbẹ́ yìí di tòun, àmọ́ kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Nítorí ojúkòkòrò àti nítorí ìfẹ́ láti dé ipò ńlá, ó pète láti gbapò mọ́ Jèhófà lọ́wọ́. Kọ́wọ́ Sátánì lè tẹ ohun tó ń fẹ́ yìí, ó lo irọ́ àti ẹ̀tàn.—1 Tímótì 3:6.
Lọ́jọ́ òní ńkọ́? Ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà pé ojúkòkòrò àti ìfẹ́ láti dé ipò ńlá lohun tó ṣì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa parọ́? Àwọn okòwò tí ojúkòkòrò ń súnni ṣe, ètò ìṣèlú tó kún fún èrú, àti ìsìn èké, gbogbo wọn ló kún fún irọ́, ẹ̀tàn àti àyínìke. Kí ló fà á? Lọ́pọ̀ ìgbà, ǹjẹ́ kì í ṣe torí pé àwọn èèyàn lẹ́mìí ojúkòkòrò, ìfẹ́ láti dé ipò ńlá, tàbí láti di ẹni tó ní ọrọ̀, agbára tàbí ipò, èyí tí wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí, ló ń sún wọn ṣe bẹ́ẹ̀? Sólómọ́nì Ọba, ẹni tó ní ọgbọ́n gan-an tó sì jẹ́ alákòóso lórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe kánkán láti jèrè ọrọ̀ kì yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.” (Òwe 28:20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sì kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” (1 Tímótì 6:10) A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí tẹ́nì kan bá ń wá bóun ṣe máa dé ipò agbára tàbí ipò ńlá lójú méjèèjì.
Ohun mìíràn tó tún ń mú káwọn èèyàn parọ́ ni ìbẹ̀rù, ìyẹn ìbẹ̀rù ohun tó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ tàbí ohun táwọn èèyàn á rò táwọn bá sọ òtítọ́. Àwa èèyàn máa ń fẹ́ káwọn mìíràn fẹ́ràn wa tàbí kí wọ́n gba tiwa. Àmọ́ ohun táwa èèyàn fẹ́ yìí lè mú káwọn kan parọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ irọ́ díẹ̀, kí wọ́n lè bo kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, kí wọ́n lè fi àwọn ohun tí wọ́n ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa wọn pa mọ́, tàbí ó kéré tán, káwọn èèyàn lè máa fojú tó dáa wò wọ́n. Abájọ tí Sólómọ́nì fi kọ̀wé pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.”—Òwe 29:25.
Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ọlọ́run Òtítọ́
Kí ni Manfred sọ nígbà tí ọ̀gá iléeṣẹ́ yẹn béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ibo làwọn yòókù rẹ̀ wà? Manfred sọ òótọ́. Ó ní: “Olùkọ́ yẹn tètè fi wá sílẹ̀ lónìí, mo sì ń bọ̀ níbi iṣẹ́. Ní tàwọn tó kù, mi ò lè dáhùn fún wọn. Bóyá ẹ lè bi àwọn fúnra wọn.”
Manfred lè dáhùn ìbéèrè yẹn lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí, kó sọ ohun tí kò tọ̀nà, káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù lè fẹ́ràn rẹ̀. Àmọ́, àwọn ìdí kan wà tó mú kó rọ̀ mọ́ òtítọ́. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Manfred. Jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ jẹ́ kó ní ẹ̀rí ọkàn rere. Ó tún mú kí ọ̀gá tó gbà á síṣẹ́ fọkàn tán an. Gẹ́gẹ́ bí ara ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń fún Manfred, wọ́n yàn án sí ẹ̀ka ohun ọ̀ṣọ́, tó jẹ́ ibi tí wọn kì í sábà gba akẹ́kọ̀ọ́ láyè láti ṣiṣẹ́. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n gbé Manfred sípò tó ga níléeṣẹ́ náà, ọ̀gá tó béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ yẹn pè é lórí fóònù, ó bá a yọ̀, ó sì rán an létí bó ṣe sọ òótọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run òtítọ́ ni Jèhófà, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ gbọ́dọ̀ “fi èké ṣíṣe sílẹ̀” kó sì máa “sọ òtítọ́.” Ẹni tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n yẹn sọ pé: “Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ kì yóò purọ́.” Àmọ́, kí ni irọ́?—Éfésù 4:25; Òwe 14:5.
Kí Ni Irọ́?
Gbogbo irọ́ ló jẹ́ àìsọ òótọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo àìsọ òótọ́ ló jẹ́ irọ́. Kí nìdí? Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé irọ́ ni “kéèyàn máa sọ ohun téèyàn mọ̀ tàbí tó gbà gbọ́ pé kì í ṣe òótọ́ láti tan ẹlòmíràn jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni, lára ohun tí irọ́ ní nínú ni kéèyàn ní in lọ́kàn láti tan ẹlòmíràn jẹ. Nípa báyìí, téèyàn bá sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ láìmọ̀ọ́mọ̀, irú bíi kéèyàn ṣàṣìṣe nígbà tó ń sọ nǹkan kan fún ẹnì kan tàbí kéèyàn ṣèèṣì pe iye kan tí kò pé pérépéré, ìyẹn kì í ṣe irọ́.
Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún yẹ ká mọ̀ bóyá ẹni tó ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wa lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọ̀gá iléeṣẹ́ mìíràn ló béèrè àwọn ìbéèrè tí ọ̀gá Manfred béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ yẹn. Ǹjẹ́ ó pọn dandan kí Manfred sọ gbogbo ohun tó mọ̀ fún un? Rárá o. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀gá yẹn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀ nípa ọ̀ràn náà, kò pọn dandan kí Manfred sọ fún un. Àmọ́ síbẹ̀ náà o, kò tọ̀nà kí Manfred parọ́, bí ẹni náà kì í tiẹ̀ ṣe ọ̀gá rẹ̀.
Àpẹẹrẹ wo ni Jésù Kristi fi lélẹ̀ lórí èyí? Nígbà kan, Jésù ń bá àwọn kan sọ̀rọ̀ tí wọn kì í ṣe ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fẹ́ mọ̀ nípa bó ṣe fẹ́ rin ìrìn rẹ̀. Wọ́n gbà á nímọ̀ràn, wọ́n ní: “Ré kọjá kúrò ní ìhín, kí o sì lọ sí Jùdíà.” Báwo ni Jésù ṣe dá wọn lóhùn? Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ẹ máa gòkè lọ sí àjọyọ̀ náà [ní Jerúsálẹ́mù]; kò tíì yá mi tí èmi yóò gòkè lọ sí àjọyọ̀ yìí, nítorí àkókò yíyẹ mi kò tíì dé ní kíkún.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Jésù wá lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọyọ̀ yẹn. Kí nìdí tó fi dá wọn lóhùn lọ́nà yẹn? Nítorí pé wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀ nípa bó ṣe fẹ́ rin ìrìn rẹ̀ ni. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò sọ ohun tí kì í ṣòótọ́, síbẹ̀ ìdáhùn tó fún wọn kò kún, torí àtilè dín jàǹbá tó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe fóun tàbí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kù. Èyí kì í ṣe irọ́, nítorí pé àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé nípa Kristi pé: “Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.”—Jòhánù 7:1-13; 1 Pétérù 2:22.
Pétérù fúnra rẹ̀ ńkọ́? Lálẹ́ ọjọ́ táwọn ọ̀tá mú Jésù, ǹjẹ́ ìgbà mẹ́ta kọ́ ni Pétérù parọ́ tó sì sẹ́ pé òun ò mọ Jésù rárá? Bẹ́ẹ̀ ni, ìbẹ̀rù èèyàn mú kí Pétérù ṣojo, ó sì parọ́. Àmọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló “sunkún kíkorò” tó sì ronú pìwà dà, Jésù wá darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í. Kò tán síbẹ̀ o, ó kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe rẹ̀. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà ló sọ̀rọ̀ nípa Jésù níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn tó sì kọ̀ láti dákẹ́ nígbà táwọn olórí àwọn Júù ní Jerúsálẹ́mù halẹ̀ mọ́ ọn. Dájúdájú, ó yẹ kí fífà tí Pétérù fà sẹ́yìn fúngbà díẹ̀ yìí àti bó ṣe yára ronú pìwà dà, jẹ́ ìṣírí fún gbogbo wa, nítorí pé ó rọrùn ká ṣe ohun tí kò tọ́ nítorí kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ká sì kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tàbí nínú ìṣe.—Mátíù 26:69-75; Ìṣe 4:18-20; 5:27-32; Jákọ́bù 3:2.
Òótọ́ Yóò Fìdí Múlẹ̀ Títí Láé
Ìwé Òwe 12:19 sọ ní kedere pé: “Ètè òtítọ́ ni a ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in títí láé, ṣùgbọ́n ahọ́n èké yóò wà fún kìkì ìwọ̀nba ìṣẹ́jú kan.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ òótọ́ kì í yí padà, ńṣe ló máa ń wà bẹ́ẹ̀ títí láé. Àárín àwọn èèyàn túbọ̀ máa ń gún régé ayọ̀ sì túbọ̀ máa ń wà nígbà tí wọ́n bá ń sọ òótọ́ nígbà gbogbo tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n sọ náà. Láìsí àní-àní, sísọ òótọ́ máa ń mú èrè ojú ẹsẹ̀ wá. Lára èrè yìí ni pé èèyàn á ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, èèyàn á ní orúkọ rere, ó ń jẹ́ kí àárín tọkọtaya gún régé, ó ń jẹ́ kí ìdílé ṣọ̀kan, ó sì ń jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ lè fọkàn tán ara wọn, kódà ó tún ń jẹ́ káwọn tó ń bára wọn ṣiṣẹ́ lè fọkàn tán ara wọn.
Àmọ́ ní ti irọ́, bópẹ́bóyá, ó máa ń já ni. Ahọ́n irọ́ lè tan àwọn èèyàn jẹ fúngbà díẹ̀, àmọ́ irọ́ kì í lékè. Síwájú sí i, Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ ti yan àkókò kan tí kò ní fàyè gba irọ́ àtàwọn tó ń gbé irọ́ lárugẹ mọ́. Bíbélì ṣèlérí pé gbogbo ohun tí Sátánì Èṣù, baba irọ́, tó ń tan gbogbo ayé jẹ ti dá sílẹ̀ ni Jèhófà yóò mú kúrò. Láìpẹ́, Jèhófà yóò fòpin sí gbogbo irọ́ àtàwọn tó ń parọ́.—Ìṣípayá 21:8.
Ẹ ò rí i pé ìtura ńlá ni yóò wà nígbà tí Ọlọ́run bá mú kí “ètè òtítọ́” fìdí múlẹ̀ títí láé!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gangan.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ojúkòkòrò àti ìfẹ́ láti dé ipò ńlá ló máa ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn parọ́
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Gbogbo irọ́ ló jẹ́ àìsọ òótọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo àìsọ òótọ́ ló jẹ́ irọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Kí la rí kọ́ nínú sísẹ́ tí Pétérù sẹ́ Kristi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Sísọ òótọ́ máa ń jẹ́ kí àjọṣe àárín àwọn èèyàn gún régé ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n láyọ̀