ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 3/1 ojú ìwé 5-7
  • Bá A Ṣe Lè Dá Ìjọsìn Tòótọ́ Mọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Dá Ìjọsìn Tòótọ́ Mọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwé Tó Sọ Nípa Ìfẹ́
  • Kí La Fi Ń Dá Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Mọ̀?
  • Wá Ìjọsìn Tòótọ́ Rí
  • Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Kí Ìfẹ́ Máa Gbé Yín Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Bá a Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọmọnìkejì Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 3/1 ojú ìwé 5-7

Bá A Ṣe Lè Dá Ìjọsìn Tòótọ́ Mọ̀

Ọ̀PỌ̀ ìsìn ló máa ń sọ pé ohun táwọn fi ń kọ́ni wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ó yẹ ká kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Jòhánù tó jẹ́ àpọ́sítélì Jésù, tó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.” (1 Jòhánù 4:1) Báwo la ṣe lè dán ohun kan wò ká lè mọ̀ bóyá ó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

Gbogbo ohun tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló máa ń fi ànímọ́ rẹ̀ hàn, àgàgà ìfẹ́, tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ tó ta yọ jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, gbígbọ́ tá a lè gbọ́ òórùn, èyí tó máa ń jẹ́ kínú wa dùn nígbà tá a bá gbọ́ òórùn àwọn ewéko, àwọn òdòdó, tàbí ti búrẹ́dì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tán, jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Bó ti ṣeé ṣe fún wa láti rí oòrùn tó ń wọ̀, tá a lè rí labalábá kan, tá a tún lè rí ẹ̀rín músẹ́ ẹnu ọmọ kékeré kan jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí pẹ̀lú gbígbọ́ tá a lè gbọ́ orin tó dùn, tá a lè gbọ́ ohùn ẹyẹ, tàbí ohùn ẹnì kan tá a fẹ́ràn. Kódà bí Ọlọ́run ṣe dá àwa fúnra wa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń rí i pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni ohun tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, nítorí pé “àwòrán Ọlọ́run” ni a dá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ní àwọn ànímọ́ mìíràn tó pọ̀ gan-an, síbẹ̀ ìfẹ́ ni èyí tó ta yọ jù lọ nínú wọn.

Àwọn àkọsílẹ̀ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ. Àwọn ìsìn ayé ní ọ̀pọ̀ ìwé àtayébáyé tí wọ́n máa ń lò. Àmọ́ báwo ni irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn tó?

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìwé ìsìn wọ̀nyẹn ni kò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tàbí bí àwa náà ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Abájọ tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kì í fi í rí ìdáhùn gbà nígbà tí wọ́n bá ń béèrè pé, “Kí nìdí tá a fi ń rí ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú àwọn ohun tó dá àmọ́ tí ìyà àti ìwà ibi kò dáwọ́ dúró?” Bíbélì nìkan ṣoṣo ni ìwé ìsìn àtayébáyé tó ṣàlàyé ìfẹ́ Ọlọ́run ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́. Ó tún kọ́ wa bá a ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn.

Ìwé Tó Sọ Nípa Ìfẹ́

Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fi hàn pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run ìfẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Bíbélì ṣàlàyé pé ìfẹ́ ló mú kí Jèhófà dá tọkọtaya àkọ́kọ́ láìsí pé wọ́n ń ṣàìsàn tàbí pé wọ́n ń kú. Àmọ́, ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ṣe, tó fi hàn pé wọn ò fara mọ́ àṣẹ Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé. (Diutarónómì 32:4, 5; Róòmù 5:12) Jèhófà wá ṣe ohun kan láti yanjú ọ̀ràn náà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ìwé Mímọ́ tún fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn síwájú sí i nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ìjọba pípé kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tí Jésù máa ṣàkóso lé lórí, kí àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn lè padà ní àlàáfíà.—Dáníẹ́lì 7:13, 14; 2 Pétérù 3:13.

Bí Bíbélì ṣe ṣàkópọ̀ ohun tó yẹ kéèyàn ṣe rèé, ó ní: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́.” (Mátíù 22:37-40) Bíbélì jẹ́ ìwé tí Ọlọ́run mí sí. Níwọ̀n bí Bíbélì sì ti gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ kedere, ó dájú pé ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run ìfẹ́” ló ti wá.—2 Tímótì 3:16.

Ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ ti tó láti mọ èyí tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá lára àwọn ìwé ìgbàanì. Ìfẹ́ la tún fi ń dá àwọn olùjọsìn tòótọ́ mọ̀, nítorí pé wọ́n máa ń fara wé Ọlọ́run nínú fífi ìfẹ́ hàn.

Kí La Fi Ń Dá Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Mọ̀?

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an máa ń yàtọ̀, àgàgà nísinsìnyí tó jẹ́ pé àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà. Ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń di “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Tímótì 3:1-4.

Báwo lo ṣe lè mọ àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Bíbélì sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòhánù 5:3) Ìfẹ́ táwọn èèyàn ní fún Ọlọ́run máa ń mú kí wọ́n fi àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà rere sílò. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àwọn òfin lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó. Kìkì àwọn tó bá ṣègbéyàwó nìkan ló yẹ kó ní ìbálòpọ̀, tọkọtaya sì gbọ́dọ̀ máa wà pa pọ̀ títí lọ. (Mátíù 19:9; Hébérù 13:4) Nígbà tí obìnrin kan tó ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìsìn nílẹ̀ Sípéènì wá sípàdé kan níbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà tí Bíbélì gbé kalẹ̀ lórí ọ̀ràn ìwà rere, ohun tó sọ ni pé: “Ìpàdé náà gbé mi ró gan-an, yàtọ̀ sí pé mo gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ túbọ̀ yéni yékéyéké, ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn wọ̀nyí, ìwà rere wọn, àti bí wọ́n ṣe jẹ́ ọmọlúwàbí tún wú mi lórí gan-an.”

Yàtọ̀ sí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ohun mìíràn tó tún máa ń jẹ́ ká tètè dá wọn mọ̀ ní bí wọ́n ṣe máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọnìkejì wọn. Olórí iṣẹ́ wọn ni pé kí wọ́n máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí kan ṣoṣo tí ọmọ aráyé ní, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Kò sí nǹkan mìíràn tó lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní ayérayé ju pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ Ọlọ́run. (Jòhánù 17:3) Àwọn Kristẹni tòótọ́ tún máa ń fìfẹ́ hàn láwọn ọ̀nà mìíràn. Wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó níṣòro. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ kan wáyé lórílẹ̀-èdè Ítálì, ìwé ìròyìn kan nílùú náà ròyìn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “ṣe ohun tó jọni lójú gan-an, wọ́n ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù náà bá láì tiẹ̀ ronú nípa ẹ̀sìn táwọn èèyàn náà ń ṣe.”

Yàtọ̀ sí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn, wọ́n tún nífẹ̀ẹ́ ara wọn pẹ̀lú. Jésù sọ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35.

Ǹjẹ́ ìfẹ́ táwọn Kristẹni ní láàárín ara wọn tiẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé wọ́n yàtọ̀? Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ema tó ń ṣiṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ gbà pé bẹ́ẹ̀ ni. Ó ń ṣiṣẹ́ nílùú La Paz, lórílẹ̀-èdè Bolivia, níbi tí olówó àti tálákà kò ti ń da ohunkóhun pọ̀ nítorí ọ̀ràn kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Ó ní: “Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo rí ọkùnrin kan tó múra dáadáa tó jókòó tó ń bá obìnrin ará Íńdíà kan sọ̀rọ̀. Mi ò rírú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí láyé mi. Ojú ẹsẹ̀ yẹn ni mo mọ̀ pé èèyàn Ọlọ́run làwọn aráabí yìí.” Bákan náà ni ọmọbìnrin ará Brazil kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Miriam sọ pé: “Mi ò kì í láyọ̀, kódà nínú ìdílé mi pàápàá. Àárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo tí kọ́kọ́ rí i báwọn èèyàn ṣe ń fìfẹ́ hàn síra wọn.” Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ẹnì kan tó máa ń darí ìròyìn fún ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan kọ̀wé pé: “Táwọn èèyàn bá ń gbé ìgbésí ayé wọn bíi tàwọn ọmọ ìjọ yín, orílẹ̀-èdè yìí ì bá máà sí nípò tó wà yìí rárá. Oníròyìn ní mi, mo sì mọ̀ pé orí ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ẹlẹ́dàá lẹ gbé ètò yín kà.”

Wá Ìjọsìn Tòótọ́ Rí

Ìfẹ́ ni olórí ohun tá a fi ń dá ìjọsìn tòótọ́ mọ̀. Jésù fi wíwá ìjọsìn tòótọ́ wé kéèyàn rí ọ̀nà tó dára kó sì múra tán láti rìn ní ọ̀nà náà. Ọ̀nà yìí nìkan ṣoṣo ni ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Kìkì àwùjọ kan tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ ló ń bá Ọlọ́run rìn níṣọ̀kan lọ́nà ìjọsìn tòótọ́ yìí. Nítorí náà, kì í ṣe ẹ̀sìn tó bá ṣáà ti wu èèyàn ló lè ṣe. Tó o bá rí ọ̀nà yẹn tó o sì yàn láti rìn níbẹ̀, a jẹ́ pé o ti rí ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ nìyẹn, nítorí pé ọ̀nà ìfẹ́ ni.—Éfésù 4:1-4.

Fojú inú wo bó o ṣe máa láyọ̀ tó, tó o bá ń rìn ní ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́! Ńṣe ló dà bíi kéèyàn máa bá Ọlọ́run rìn. O lè kọ́ ọgbọ́n àti ìfẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run èyí a si jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àtàwọn ẹlòmíràn lè gún régé. Àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run lo ti lè kọ́ nípa ìdí tá a fi wà lórí ilẹ̀ ayé, o sì tún lè lóye àwọn ìlérí Ọlọ́run, tí wàá sì nírètí pé ọ̀la á dára. O ò ní kábàámọ̀ láé pé o wá ìjọsìn tòótọ́ rí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Nínú gbogbo àwọn ìwé ìsìn àtayébáyé, Bíbélì nìkan ló jẹ́ ká mọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn èèyàn máa ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́