ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 3/1 ojú ìwé 3-4
  • Ṣé Ẹ̀sìn Tó Bá Ṣáà Ti Wù Ẹ́ Ló Yẹ Kó O Ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹ̀sìn Tó Bá Ṣáà Ti Wù Ẹ́ Ló Yẹ Kó O Ṣe?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Làwọn Ìsìn Ṣe Máa Ń Bẹ̀rẹ̀?
  • Tá Làwọn Ìsìn Fẹ́ Tẹ́ Lọ́rùn?
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ̀sìn Èké Kò Ṣojú fún Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìròyìn Ayọ̀ Wo Ló Wà Nípa Ìsìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àǹfààní Wo Ni Ìsìn Ń Ṣeni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 3/1 ojú ìwé 3-4

Ṣé Ẹ̀sìn Tó Bá Ṣáà Ti Wù Ẹ́ Ló Yẹ Kó O Ṣe?

KÒ SẸ́NI tí kì í fẹ́ wá ohun tó dáa rà lọ́jà. Nígbà tí onírúurú èso àti ewébẹ̀ bá wà lọ́jà, àwọn tá a fẹ́ràn jù lọ àtàwọn tá a rí i pé ó dára fún ìdílé wa la máa ń rà. Tí ilé ìtajà kan tó ń ta aṣọ bá kó onírúurú aṣọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbówó lórí jọ fún títà, èyí tá a mọ̀ pé ó máa dáa lára wa jù lọ la máa rà. Àwọn ohun kan lára àwọn ohun tá a máa ń yàn nígbèésí ayé wa wulẹ̀ jẹ́ ohun tó wu kálukú wa ni. Àmọ́ àwọn mìíràn lára àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ èyí tó ṣe pàtàkì fún àlàáfíà ara wa. Bí àpẹẹrẹ, àǹfààní wà nínú ká yan oúnjẹ aṣaralóore tàbí ká yan àwọn ọrẹ́ tó jẹ́ ọlọgbọ́n. Ẹ̀sìn tá a yàn wá ńkọ́? Ṣé ó yẹ kí ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn jẹ́ èyí tó kàn wù wá lásán ni? Tàbí ńṣe ló yẹ ká gbà pé ọ̀ràn pàtàkì tó máa nípa lórí ìgbésí ayé wa ni?

Àwọn ìsìn pọ̀ gan-an téèyàn ti lè yan èyí tó bá wù ú. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti fọwọ́ sí òmìnira ìsìn báyìí, ìyẹn ló wá jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ lómìnira láti fi ẹ̀sìn àwọn òbí wọn sílẹ̀. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ẹni mẹ́jọ nínú ẹni mẹ́wàá lára àwọn ará Amẹ́ríkà “ló gbà pé kì í ṣe ẹyọ ẹ̀sìn kan ṣoṣo ló lè múni rí ìgbàlà.” Ìwádìí kan náà yẹn tún fi hàn pé, “ẹnì kan lára ẹni márùn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé òun yí ẹ̀sìn òun padà nígbà tóun dàgbà.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Brazil fi hàn pé ìdá kan nínú mẹ́rin gbogbo àwọn ará Brazil ló ti yí ẹ̀sìn wọn padà.

Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn máa ń jiyàn gan-an lórí àwọn ẹ̀kọ́ tó mú kí ẹ̀sìn kan yàtọ̀ sí òmíràn. Àmọ́ lóde òní, èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, ‘Ẹ̀sìn tó bá ṣáà ti wu èèyàn ló lè ṣe.’ Àmọ́ ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Ǹjẹ́ ẹ̀sìn tó o yàn lè nípa lórí rẹ?

Gẹ́gẹ́ bí òǹrajà kan tó jẹ́ ọlọgbọ́n ṣe máa béèrè ìbéèrè nípa ibi tí wọ́n ti ṣe ọjà náà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe bọ́gbọ́n mu láti béèrè pé, ‘Báwo làwọn onírúurú ìsìn wọ̀nyí ṣe bẹ̀rẹ̀, kí sì nìdí?’ Bíbélì dáhùn ìbéèrè yẹn.

Báwo Làwọn Ìsìn Ṣe Máa Ń Bẹ̀rẹ̀?

Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Jèróbóámù Ọba bẹ̀rẹ̀ ìsìn tuntun kan ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú àkókò tí Jésù wá sórí ilẹ̀ ayé. Jèróbóámù ni ọba tó kọ́kọ́ jẹ lórí ìjọba Ísírẹ́lì ti ìhà àríwá. Àmọ́ ọba yìí ní ìṣòro kan, ìyẹn ni bó ṣe máa mú káwọn èèyàn máa ṣe ohun tó wu òun. “Ọba gbìmọ̀, ó sì ṣe ọmọ màlúù wúrà méjì, ó sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ó ti pọ̀ jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run rẹ rèé, ìwọ Ísírẹ́lì.’” (1 Àwọn Ọba 12:28) Ó hàn gbangba pé ńṣe ni ọba náà fẹ́ lo ọ̀rọ̀ ìsìn láti mú káwọn èèyàn náà jáwọ́ nínú lílọ sí Jerúsálẹ́mù, níbi tí wọ́n ti máa ń jọ́sìn. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ìsìn tí Jèróbóámù dá sílẹ̀ yìí fi wà, òun ló sì yọrí sí ìparun ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nígbà tí Ọlọ́run wá dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó di apẹ̀yìndà lẹ́jọ́ níkẹyìn. Kí Jèróbóámù lè rọ́wọ́ mú nídìí ọ̀ràn ìṣèlú ló ṣe dá ìsìn yìí sílẹ̀. Bákan náà làwọn ìsìn kan tó wà títí dòní olónìí ṣe bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n sì di èyí tíjọba fọwọ́ sí, nítorí àtimú kí ọ̀ràn ìṣèlú fẹsẹ̀ múlẹ̀.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún sọ ìdí mìíràn tó ń mú káwọn èèyàn dá ìsìn tuntun sílẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Àwọn aṣáájú kan tó jọra wọn lójú sábà máa ń dá ìsìn sílẹ̀ kí wọ́n lè gbayì lójú àwọn èèyàn. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ aláfẹnujẹ́ Kristẹni ti pín sí onírúurú ẹ̀ya ìsìn báyìí.

Tá Làwọn Ìsìn Fẹ́ Tẹ́ Lọ́rùn?

Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń fẹ́ tún lè mú káwọn kan dá ìsìn tuntun sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn The Economist ròyìn ohun tó ń lọ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì táwọn èèyàn ń pè ní ṣọ́ọ̀ṣì ńlá ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó ní ohun tó ń mú káwọn èèyàn tó ń lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyẹn túbọ̀ máa pọ̀ sí i ni pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì náà ń gbé ọ̀rọ̀ wọn “ka ohun kan náà tí gbogbo àwọn oníṣòwò tó ń rọ́wọ́ mú máa ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kà, ìyẹn ni pé: ohun tí oníbàárà bá fẹ́ làwa náà fẹ́.” Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ máa ń ṣe “àwọn ohun tí wọ́n fi ń dá àwọn èèyàn lára yá nínú ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n á fi fídíò han àwọn èèyàn, wọ́n á ṣeré orí ìtàgé, wọ́n á tún máa kọ àwọn orin àsìkò.” Àwọn aṣáájú ìsìn kan nínú irú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yìí tiẹ̀ sọ pé àwọn máa ń kọ́ àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì àwọn bí “wọ́n ṣe máa di olówó, tí ara wọ́n á le, tí wọn ò sì ní í ní ìṣòro kankan mọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń pe irú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì bẹ́ẹ̀ ní ilé ìdárayá tàbí “ibi tí wọ́n ti ń kọ́ni bá a ti ń ṣòwò,” síbẹ̀ ìwé ìròyìn kan náà yẹn sọ pé, “kò sóhun tí wọ́n ń ṣe ju pé wọ́n fẹ́ tẹ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn lọ́run.” Ìwé ìròyìn yẹn wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Dída òwò pọ̀ mọ́ ìsìn ti wá kẹ́sẹ járí gan-an báyìí.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìsìn mìíràn lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣe tiwọn bí ẹni ń ṣòwò, síbẹ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó “fẹ́ tẹ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn lọ́rùn” rán wa létí ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù. Ó kọ̀wé pé: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé a óò mú wọn yà sínú ìtàn èké.”—2 Tímótì 4:3, 4.

Ọ̀pọ̀ ìsìn làwọn èèyàn dá sílẹ̀ nítorí kí wọ́n lè rọ́wọ́ mú nídìí ìṣèlú, kí wọ́n lè wà nípò iyì, kí wọ́n sì lè gbajúmọ̀ láwùjọ, kì í ṣe tìtorí kí wọ́n lè múnú Ọlọ́run dùn. Nítorí náà kò yà wá lẹ́nu pé ìsìn ń lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ibi bíi bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe, lílu àwọn èèyàn ní jìbìtì, jíja ogun, tàbí ìpániláyà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ẹ̀tàn ni ìsìn jẹ́. Báwo ni wọn ò ṣe ní rí ẹ tàn jẹ́?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Ọ̀pọ̀ ìsìn làwọn èèyàn dá sílẹ̀ nítorí kí wọ́n lè rọ́wọ́ mú nídìí ìṣèlú, kí wọ́n lè wà nípò iyì, kí wọ́n sì lè gbajúmọ̀ láwùjọ, kì í ṣe tìtorí kí wọ́n lè múnú Ọlọ́run dùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́