Àwọn Èèyàn Ń Wá Ìdáhùn Tó Tọ̀nà
Kí ni mo lè ṣe tí mi ò ní fọwọ́ ara mi fa àìsàn?
Kí ni mo lè ṣe tí ayọ̀ á fi túbọ̀ wà nínú ìdílé mi?
Kí ni mo lè ṣe tí iṣẹ́ ò fi ní bọ́ lọ́wọ́ mi?
ǸJẸ́ o tiẹ̀ ti béèrè èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí rí? Ǹjẹ́ o rí ìdáhùn tó ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an? Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì onírúurú ìwé tó ń fúnni nímọ̀ràn lórí àwọn ọ̀ràn yìí àtàwọn ọ̀ràn mìíràn tó ṣe pàtàkì làwọn èèyàn ń ṣe jáde lọ́dọọdún. Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìkan ṣoṣo, ọdọọdún làwọn òǹkàwé ń ná nǹkan bí àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù owó dọ́là sórí àwọn ìwé tó ń fúnni nímọ̀ràn nípa ohun téèyàn lè ṣe sáwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] mílíọ̀nù dọ́là ló ń wọlé lọ́dún lórí àwọn ìwé afúnni-nímọ̀ràn. Ó dájú pé ìwọ nìkan kọ́ ló ń wá ìmọ̀ràn tó dára láti mọ ọ̀nà tó o máa gbà bójú tó àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé rẹ lójoojúmọ́.
Nígbà tí òǹṣèwé kan ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn ìwé tó pọ̀ jaburata yìí, ó ní: “Ohun tó wà nínú àwọn ìwé tí wọ́n ti ṣe jáde tẹ́lẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ìwé tuntun wulẹ̀ ń tún sọ.” Ká sòótọ́, èyí tó pọ̀ jù lára ìmọ̀ràn inú àwọn ìwé yìí ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn ń ṣàtúnsọ ọgbọ́n tó wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé tọ́jọ́ wọn pẹ́ jù lọ láyé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má síbì kan lágbàáyé téèyàn ò ti lè rí ìwé tá a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Wọ́n ti túmọ̀ rẹ̀ lódindi tàbí lápá kan sáwọn èdè tó tó ẹgbẹ̀rún méjì ó lé irínwó [2,400]. Lápapọ̀, iye tí wọ́n ti tẹ̀ jáde kárí ayé ń lọ sí bílíọ̀nù márùn-ún. Bíbélì ni ìwé tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.
Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Àmọ́ o, Bíbélì kì í ṣe ìwé tó kàn ń fúnni nímọ̀ràn lásán. Olórí ohun tó wà fún ni pé káwọn èèyàn lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Bíbélì sọ nípa ọ̀nà tá a lè gbà kojú àwọn ìṣòro táwa èèyàn sábà máa ń ní. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó bá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Bíbélì á jàǹfààní. (Aísáyà 48:17, 18) Láìka ẹ̀yà téèyàn ti wá tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹni sí, tàbí yálà èèyàn jẹ́ ọ̀mọ̀wé tàbí púrúǹtù, téèyàn bá ń fi ìmọ̀ràn inú Bíbélì sílò, ó máa ń ṣeni láǹfààní gan-an. O ò ṣe ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí kó o sì wá fúnra rẹ pinnu bóyá ohun tí Bíbélì sọ wúlò lórí àwọn nǹkan bí ọ̀rọ̀ ìlera, ìdílé àti iṣẹ́?