ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 4/15 ojú ìwé 3
  • Ìwà Ìkà Pọ̀ Lóde Òní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Ìkà Pọ̀ Lóde Òní
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Sọ Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ǹjẹ́ Ìwà Ìkà Lè Dópin?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ A Lè—Dárí Jì, Ká Sì Gbàgbé?
    Jí!—1998
  • Ojútùú Wo Ni Ọlọ́run Ní fún Ìwà Ìkà?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 4/15 ojú ìwé 3

Ìwà Ìkà Pọ̀ Lóde Òní

MÀRÍÀ jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64]. Ó ń dá gbé ni. Nígbà táwọn kan wọnú ilé ẹ̀ lọ́jọ́ kan, òkú ẹ̀ ni wọ́n bá. Àwọn kan ló lù ú nílùkulù tí wọ́n sì fi wáyà fún un lọ́rùn pa.

Àwọn kan tínú ń bí lu ọlọ́pàá mẹ́ta kan, wọ́n ní wọ́n jí ọmọdé méjì gbé. Wọ́n da bẹntiróò sára méjì lára àwọn ọlọ́pàá náà wọ́n sì dáná sun wọ́n. Agbára káká nìkẹta wọn fi mórí bọ́.

Ẹnì kan fi ẹ̀rọ tẹlifóònù pe iléeṣẹ́ ìjọba kan láìsọ orúkọ ara rẹ̀. Àṣíírí tó bani lẹ́rù kan ló tú fún iléeṣẹ́ yẹn. Òun ló jẹ́ kí wọ́n wú òkú ọkùnrin mẹ́rin kan jáde nínú ọgbà kan. Fàájì làwọn ọkùnrin náà lọ ṣe nílùú náà lákòókò ìsinmi wọn. Nígbà táwọn dókítà ṣàyẹ̀wò àwọn òkú náà, wọ́n rí i pé òòyẹ̀ ni wọ́n sin wọ́n. Àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi ọ̀hún kọ́kọ́ fi nǹkan di ojú àti ọwọ́ wọn kí wọ́n tó sin wọ́n.

Àwọn nǹkan tá a sọ yìí ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ni o, kì í ṣe eré oníwà abèṣe inú fídíò tó ń bani lẹ́rù. Àìpẹ́ yìí ni wọ́n gbé wọn jáde nínú ìròyìn ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà níhà gúúsù ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àmọ́ kì í ṣe orílẹ̀-èdè yẹn nìkan ni irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀ láyé òde òní.

Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn ń hùwà ìkà. Ńṣe ni jíju bọ́ǹbù, ìpànìyàn, ìṣeniléṣe, yíyìnbọn-luni, ìfipábánilòpọ̀ àti ọṣẹ́ táwọn apániláyà ń ṣe wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ nínú onírúurú ìwà ìkà táwọn èèyàn ń hù. Àìmọye ìgbà ni iléeṣẹ́ ìròyìn máa ń sọ nípa ìwà ìkà tó sì máa ń fi àwòrán rẹ̀ hàn. Nípa bẹ́ẹ̀ kò jọ ọ̀pọ̀ èèyàn lójú mọ́ láti máa gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ àti láti máa wò ó.

Ó ṣeé ṣe kó o máa rò ó pé: ‘Ibo tiẹ̀ lọ̀rọ̀ ayé yìí ń lọ gan-an? Ṣé gbogbo èèyàn ti wá di ọ̀dájú ni, tí ẹ̀mí èèyàn ò sì jọ wọ́n lójú mọ́?’ Kí ló dé tí ayé fi rí báyìí ná?

Tóò, ronú nípa ọ̀rọ̀ ọkùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin [69] kan tó ń jẹ́ Harry. Ó ní àrùn jẹjẹrẹ, ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú sì ní àrùn tó máa ń mú iṣan ara le gbagidi. Àmọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jọ ń gbé ládùúgbò fínnúfíndọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́. Harry sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn èèyàn tó wá ń ràn wá lọ́wọ́ yìí, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ kò sí nǹkan tá à bá lè ṣe.” Ìwádìí kan fi hàn pé lórílẹ̀-èdè Kánádà tí Harry ń gbé, tá a bá rí mẹ́wàá lára àwọn tó ń tọ́jú àwọn arúgbó, èyí tó ju márùn-ún nínú wọn ló ń ran àwọn tí kì í ṣe ìbátan wọn lọ́wọ́. Kò sì sí àní-àní pé ìwọ náà máa mọ àwọn èèyàn kan tí wọ́n máa ń ṣenúure sọ́mọnìkejì wọn. Èyí fi hàn pé èèyàn lè jẹ́ aláàánú àti onínúure dípò kó ya ìkà.

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tí ìwà ìkà fi wà? Kí ló ń mú káwọn èèyàn hùwà ìkà? Ǹjẹ́ àwọn òṣìkà lè yí padà? Ǹjẹ́ ìwà ìkà lè dópin? Tó bá máa dópin, báwo ló ṣe máa dópin, ìgbà wo sì ni?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Ọkọ̀ ojú irin: CORDON PRESS

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́