Ǹjẹ́ Ìwà Ìkà Lè Dópin?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló máa gbà láìjanpata pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ń mú káwọn èèyàn máa hùwà ìkà láyé òde òní. Bó ṣe jẹ́ pé òwú tí ìyá gbọ̀n lọmọ ń ran, ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan táwọn ará ìṣáájú hù lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn òde ìwòyí náà ń hù. Ó wá di pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, tẹlòmíì ò jẹ́ nǹkan kan lójú wọn. Àní kò sóhun táwọn míì ò lè ṣe kọ́wọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá, ì báà gba pé kí wọ́n ṣe ẹlòmíì níkà. Kì í wá ṣe àwọn aráàlú nìkan ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ o, odindi orílẹ̀-èdè pàápàá ń ṣe é.
Àfi bíi pé ẹ̀mí ọmọnìkejì ò já mọ́ nǹkan kan mọ́. Ìwà ìkà tiẹ̀ máa ń dùn mọ́ àwọn kan. Wọ́n sọ pé ó máa ń gbádùn mọ́ àwọn, bíi tàwọn ọ̀daràn kan tí wọ́n jẹ́wọ́ pé ohun tó ń mú káwọn ṣe èèyàn léṣe ni pé ó máa ń dùn mọ́ àwọn. Kò mọ síbẹ̀ o, àwọn èèyàn tó jẹ́ pé eré fídíò tó ń fi ìwà abèṣe hàn ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí pọ̀ gan-an, èyí tó mú káwọn iléeṣẹ́ tó ń gbé irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ jáde máa pawó ńlá. Gbígbọ́ táwọn èèyàn máa ń gbọ́ nípa ìwà ìkà nínú ìròyìn tí wọ́n sì máa ń wò ó nínú eré lọ́pọ̀ ìgbà ti sọ ọ̀pọ̀ wọn di ọ̀dájú.
Ìwà ìkà tí wọ́n hù sáwọn kan sábà máa ń ṣàkóbá fún wọn nípa sísọ àwọn náà di ìkà èèyàn. Nígbà tí Noemí Díaz Marroquín tó jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì kan tó wà ní Mẹ́síkò, ìyẹn National Autonomous University, ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà abèṣe táwọn òṣìkà máa ń hù, ó ní: “Ńṣe làwọn èèyàn máa ń kọ́ ìwà ìkà, kì í ṣe nǹkan tá a bí mọ́ni . . . Àwọn èèyàn máa ń di oníwà abèṣe tí àyè bá gbà wọ́n táwọn tó wà láyìíká wọn sì ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀.” Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti hùwà ìkà sí máa ń hùwà ìkà sáwọn ẹlòmíì, ó sì lè jẹ́ pé irú ìwà ìkà tí wọ́n hù sí wọn gan-an làwọn náà á máa hù.
Ohun tó mú káwọn míì máa hùwà ìkà ni lílo oògùn olóró, ọtí àmujù àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Àwọn kan sì wà tí inú wọn ò dùn sí ìjọba ilẹ̀ wọn nítorí wọ́n ń wò ó pé ìjọba ò pèsè ohun tó yẹ fáwọn aráàlú. Àwọn kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fẹ́ láti fi ìhónú wọn hàn, wọ́n á wá dẹni tó ń hùwà abèṣe, wọ́n á sì máa lọ́wọ́ sí ìpániláyà, àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ lèyí sì sábà máa ń pa lára.
Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn kàn fúnra wọn di ẹni tó ń hùwà ìkà ni? Kí ló fa ìwà ìkà tí wọ́n ń hù láyé òde òní?’
Ta Lẹni Náà Gan-an Tó Fa Ìwà Ìkà?
Bíbélì sọ fún wa pé Sátánì Èṣù ń lo agbára gan-an lórí ayé, ó pè é ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Òun ló ya onímọtara-ẹni-nìkan jù láyé àtọ̀run, kò sì sẹ́ni tó níkà nínú tó o. Jésù sọ irú ẹni tó jẹ́, ó ní “apànìyàn” ni àti “baba irọ́.”—Jòhánù 8:44.
Àtìgbà tí Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ ti ṣàìgbọràn tí wọ́n sì kẹ̀yìn sí Jèhófà laráyé ti wà lábẹ́ agbára Sátánì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7, 16-19) Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n di ọlọ̀tẹ̀ gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n sì wá ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin. Ni wọ́n bá bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tí Bíbélì pè ní Néfílímù. Irú èèyàn wo làwọn Néfílímù yìí jẹ́? Orúkọ wọn fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn. Orúkọ wọn yìí, ìyẹn Néfílímù, túmọ̀ sí “àwọn Abiniṣubú.” Ó hàn gbangba pé oníjàgídíjàgan làwọn Néfílímù, wọ́n sì mú kí ìwà ìkà àti ìṣekúṣe tàn kálẹ̀, èyí tó jẹ́ pé Ìkún Omi tí Ọlọ́run mú wá nìkan ló lè fòpin sí i. (Jẹ́nẹ́sísì 6:4, 5, 17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìkún Omi pa àwọn Néfílímù náà run, àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ bàbá wọn padà sí ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, wọ́n sì di ẹ̀mí èṣù téèyàn ò lè fojú rí.—1 Pétérù 3:19, 20.
Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin kan tó ní ẹ̀mí èṣù nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ kó hàn kedere pé ìkà làwọn ọlọ̀tẹ̀ áńgẹ́lì. Ẹ̀mí èṣù tó wà nínú ọmọ náà máa ń mú kí gìrì gbé e, ó sì máa ń jù ú sínú iná àti omi láti lè pa á. (Máàkù 9:17-22) Kò sí àní-àní pé ńṣe ni irú àwọn “ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” bẹ́ẹ̀ fìwà jọ ọ̀gá wọn Sátánì Èṣù tó jẹ́ ọ̀dájú àti ìkà.—Éfésù 6:12.
Lóde òní, àwọn ẹ̀mí èṣù ṣì ń ti àwọn èèyàn hùwà ìkà. Bíbélì sọ èyí tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . ajọra-ẹni-lójú, onírera, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.”—2 Tímótì 3:1-5.
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ohun tó mú kí àkókò tá a wà yìí le gan-an ni pé lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi Jésù jẹ́ Ọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ lọ́dún 1914, Jésù lé Sátánì àti ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:5-9, 12.
Ǹjẹ́ èyí wá fi hàn pé àwọn tó ń hùwà ìkà kò ní lè jáwọ́ nínú rẹ̀? Olùkọ́ kan tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan, ìyẹn Díaz Marroquín, sọ pé “àwọn èèyàn lè jáwọ́” nínú ìwà tí kò dára. Àmọ́ nítorí bí Sátánì ṣe ń lo agbára rẹ̀ lórí ayé lóde òní, ó lè má ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti jáwọ́ nínú ìwà abèṣe, àyàfi tó bá jẹ́ kí ẹ̀mí mìíràn tó lágbára ju ti Èṣù lọ máa darí ìrònú òun àti ìwà òun. Ẹ̀mí wo nìyẹn?
Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Yí Padà?
Ohun ayọ̀ ló jẹ́ pé nínú àwọn ẹ̀mí tó máa ń súnni ṣe nǹkan, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló lágbára jù lọ, kò sì sí agbára ẹ̀mí èṣù tí kò lè borí. Ó máa ń mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ kí wọ́n sì máa ṣe dáadáa síra wọn. Táwọn tó fẹ́ láti máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà bá fẹ́ rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà, wọn ò gbọ́dọ̀ ṣìkà, kódà wọn ò gbọ́dọ̀ rìn ní bèbè ìwà ìkà. Èyí gba pé kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jáwọ́ nínú gbogbo ìwà tí Ọlọ́run kò fẹ́, kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Kí sì lohun tí Ọlọ́run fẹ́? Ohun tó fẹ́ ni pé ká máa sa gbogbo ipá wa láti fara wé òun. Lára ohun tí èyí sì ń béèrè ni pé bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn ẹlòmíì lò ni káwa náà máa bá wọn lò.—Éfésù 5:1, 2; Kólósè 3:7-10.
Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣe nǹkan, wàá rí i pé kò tíì sígbà kan tí Jèhófà ò bìkítà nípa àwọn ẹlòmíì. Kò ṣàìdáa séèyàn kankan rí, kódà, kò ṣe é sẹ́ranko pàápàá.a (Diutarónómì 22:10; Sáàmù 36:7; Òwe 12:10) Jèhófà kórìíra ìwà ìkà àti gbogbo àwọn tó ń ṣìkà. (Òwe 3:31, 32) Àkópọ̀ ìwà tuntun tí Jèhófà sọ pé gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ gbé wọ̀ ń ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti ka àwọn ẹlòmíì sí ẹni tó sàn ju àwọn lọ, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. (Fílípì 2:2-4) Lára àkópọ̀ ìwà tuntun Kristẹni ni “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra.” Ohun míì tó tún jẹ́ kòṣeémáàní ni ìfẹ́, “nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:12-14) Ǹjẹ́ o ò gbà pé ayé ò ní rí báyìí ká ní gbogbo èèyàn ló ní àwọn ànímọ́ rere yìí?
Àmọ́ ṣá o, ó ṣeé ṣe kó o béèrè pé: ‘Ṣé ó lè ṣeé ṣe lóòótọ́ pé kéèyàn jáwọ́ pátápátá nínú ìwà tí kò dára?’ Ó dáa, wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Martín.b Ó máa ń jágbe mọ́ ìyàwó rẹ̀ níṣojú àwọn ọmọ wọn ó sì máa ń lù ú nílùkulù. Ó lù ú gan-an lọ́jọ́ kan débi pé àwọn ọmọ wọn sáré lọ pe àwọn ará àdúgbò. Àmọ́ lẹ́yìn ọdún mélòó kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìdílé yìí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Martín wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa irú ẹni tó yẹ kóun jẹ́ àti irú ìwà tó yẹ kóun máa hù sáwọn ẹlòmíì. Ǹjẹ́ ó yí padà? Ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ńṣe lọkọ mi máa ń gboró tínú bá ń bí i. Nítorí èyí, ìdílé wa ò tòrò fún ìgbà pípẹ́. Àmọ́ ní báyìí, ó ti di bàbá rere àti ọkọ àtàtà. Áà, ọpẹ́ ni fún Jèhófà tó mú kó yí padà.”
Àpẹẹrẹ kan péré nìyẹn o. Jákèjádò ayé, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló tí jáwọ́ nínú ìwà ìkà. Dájúdájú, èèyàn lè jáwọ́ nínú ìwà tí kò dára.
Òpin Gbogbo Ìwà Ìkà Sún Mọ́lé
Jèhófà ti gbé Ìjọba kan kalẹ̀ lọ́run tá a mọ̀ sí Ìjọba Ọlọ́run, Kristi Jésù Ọba aláàánú sì ni ọba Ìjọba náà. Láìpẹ́ Ìjọba yìí á máa ṣàkóso gbogbo ayé. Ìjọba yìí ti lé Sátánì tó jẹ́ olùdásílẹ̀ gbogbo ìwà ìkà àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò yanjú gbogbo ìṣòro àwọn èèyàn tí yóò ṣàkóso lé lórí, ìyẹn àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà. (Sáàmù 37:10, 11; Aísáyà 11:2-5) Ìjọba yẹn nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. Àmọ́, bí àwọn kan bá hùwà ìkà sí ẹ bó o ṣe ń dúró de Ìjọba yìí, kí ló yẹ kó o ṣe?
Tó o bá hùwà ìkà sáwọn tó ṣe ọ́ níkà, kò ṣàǹfààní kankan. Ńṣe nìyẹn á kàn mú kí ìwà ìkà pọ̀ sí i. Ohun tí Bíbélì rọ̀ wá láti ṣe ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tí àkókò tí Jèhófà yàn bá tó, yóò san ẹ̀san “fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú èso ìbálò rẹ̀.” (Jeremáyà 17:10) (Wo àpótí tó ní àkọlé náà, “Ohun Tó Yẹ Kéèyàn Ṣe Tí Wọ́n Bá Hùwà Ìkà sí I.”) Ká sòótọ́, tí wọ́n bá hùwà ìkà sí ẹ, ìyẹn lè fa ìrora fún ẹ. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́ Ọlọ́run lè mú kéèyàn bọ́ nínú gbogbo nǹkan burúkú tí àwọn ìkà èèyàn ṣe sí i. Kódà bó jẹ́ pé ńṣe lèèyàn kú, ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí Ọlọ́run, àwọn tí ìkà èèyàn pa tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run yóò jíǹde.—Jòhánù 5:28, 29.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì ṣeé ṣe kí wọ́n hùwà ìkà sí wa, tá a bá ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run tá a sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí rẹ̀, èyí á tù wá nínú. Wo àpẹẹrẹ Sara. Ó tọ́ ọmọkùnrin méjì láìsí ìrànlọ́wọ́ ọkọ ó sì rí i pé wọ́n lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga. Àmọ́ nígbà tó darúgbó, àwọn ọmọ rẹ̀ yìí pa á tì. Wọn kì í gbọ́ àtijẹ àtimu rẹ̀ àti bó ṣe máa wọṣọ, wọn kì í sì í tọ́jú rẹ̀ tára rẹ̀ ò bá yá. Sara tó ti di Kristẹni báyìí sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú mi máa ń bà jẹ́, Jèhófà ò fi mí sílẹ̀. Mo rí i pé ó máa ń ràn mí lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn arákùnrin àtarábìnrin mi tí wọ́n máa ń tọ́jú mi nígbà gbogbo. Ó dá mi lójú pé láìpẹ́, yóò yanjú ìṣòro mi, kì í sì í ṣe tèmi nìkan, àmọ́ ti gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé agbára rẹ̀ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.”
Àwọn wo ni Sara pè ní arákùnrin àtarábìnrin rẹ̀? Àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé. Wọ́n láàánú lójú, ó sì dá wọn lójú pé ìwà ìkà yóò dópin láìpẹ́. (1 Pétérù 2:17) Sátánì Èṣù tó wà lẹ́yìn gbogbo ìwà ìkà àtàwọn tó ń ṣìkà bíi tiẹ̀ yóò pa run, kò ní ṣẹ́ ku ìkankan lára wọn. “Sànmánì ìwà ìkà” tá a wà yìí, bí ẹnì kan ṣe pè é, yóò dópin. O ò ṣe bá ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí yìí?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti irú ẹni tó jẹ́ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ka ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
b A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Ohun Tó Yẹ Kéèyàn Ṣe Tí Wọ́n Bá Hùwà Ìkà sí I
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nípa ohun tó yẹ kéèyàn ṣe tí wọ́n bá hùwà ìkà sí i. Ronú nípa bó o ṣe lè fi àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó tẹ̀ lé e yìí sílò:
“Má ṣe wí pé: ‘Dájúdájú, èmi yóò san ibi padà!’ Ní ìrètí nínú Jèhófà, òun yóò sì gbà ọ́ là.”—Òwe 20:22.
“Bí ìwọ bá rí ìnilára èyíkéyìí tí a ṣe sí ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ àti fífi ipá mú ìdájọ́ àti òdodo kúrò . . . , má ṣe jẹ́ kí kàyéfì ṣe ọ́ lórí àlámọ̀rí náà, nítorí ẹni tí ó ga ju ẹni gíga ń wò ó.”—Oníwàásù 5:8.
“Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 5:5.
“Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.
“Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”—Róòmù 12:17-19.
“Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. . . . Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.”—1 Pétérù 2:21-23.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni Jèhófà ti kọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà ìkà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀