Ẹ Jẹ́ Ká Wo Ìrìn Àjò Pọ́ọ̀lù Sí Bèróà
Pọ́ọ̀lù òun Sílà jẹ́ míṣọ́nnárì, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè. Iṣẹ́ tí wọ́n ṣe nílùú Tẹsalóníkà tó wà létíkun kan ní àgbègbè Makedóníà ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni yọrí sí rere gan-an ni. Àmọ́ àwọn èèyànkéèyàn kan gbógun dìde sí wọn. Làwọn ará tó wà níbẹ̀ bá ṣèpinnu kan nítorí ẹ̀mí àwọn míṣọ́nnárì náà àti nítorí ìjọ wọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìdí múlẹ̀. Wọ́n ní kí Pọ́ọ̀lù àti Sílà kúrò nílùú yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí wọ́n lọ sí ìlú Bèróà lóru yẹn. Bí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe sá kúrò ní Tẹsalóníkà nìyẹn, tí wọ́n forí lé Bèróà tí iṣẹ́ ìwàásù wọn kàn.
LÓDE òní, téèyàn bá ń lọ sílùú Bèróà (ìyẹn ìlú Véroia lóde òní), àtòkèèrè léèyàn á ti máa rí i lápá ìlà oòrùn, lọ́wọ́ ìsàlẹ̀ Òkè Bermios tó ní ewéko tútù yọ̀yọ̀, gẹ́lẹ́ bí àwọn tó ń lọ síbẹ̀ látijọ́ ṣe máa ń rí i. Nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́rin ni Bèróà sí ìlú Tẹsalóníkà. Apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn Tẹsalóníkà ló wà, ó sì jẹ́ nǹkan bí ogójì kìlómítà sí Òkun Aegean. Téèyàn bá wà ní Bèróà, èèyàn á máa rí Òkè Olympus lápá gúúsù, ìyẹn òkè tí ìtàn àròsọ sọ pé ó jẹ́ ibùgbé àwọn òrìṣà tí wọ́n kà sí pàtàkì jù lára ẹgbàágbèje òrìṣà ilẹ̀ Gíríìsì ayé àtijọ́.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń fẹ́ mọ̀ nípa ìlú Bèróà nítorí pé ó jẹ́ ibi tí Pọ́ọ̀lù ti wàásù tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì di Kristẹni. (Ìṣe 17:10-15) Ẹ jẹ́ ká wo ìtàn ìlú yẹn àti bí ìrìn àjò Pọ́ọ̀lù síbẹ̀ ṣe lọ.
Ìtàn Ìlú Bèróà
Kò sẹ́ni tó lè sọ pé ìgbà báyìí ni wọ́n tẹ ìlú Bèróà dó. Nǹkan bí ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni làwọn ará Makedóníà lé àwọn tó tẹ̀ ẹ́ dó kúrò níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yà Fíríjíà làwọn tí wọ́n lé kúrò yìí. Ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún lẹ́yìn náà, bí Alẹkisáńdà Ńlá ṣe ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri mú kí ìdàgbàsókè bá ilẹ̀ Makedóníà. Wọ́n kọ́ àwọn ilé àtàwọn ògiri ńláńlá síbẹ̀, títí kan ibi ìjọsìn òrìṣà Súúsì, Átẹ́mísì, Àpólò, Átẹ́nà àtàwọn òrìṣà ilẹ̀ Gíríìsì míì.
Ìwé ìtàn kan sọ pé láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni ìlú Bèróà “ti ń kó ipa pàtàkì ní gbogbo àgbègbè rẹ̀ àti lápá ibi yòókù níhà àríwá ilẹ̀ Gíríìsì.” Òkìkí ìlú náà kàn gan-an lásìkò tí àwọn ọba láti ìlà ìdílé Antigónù ń ṣàkóso ilẹ̀ Makedóníà, ìyẹn láti ọdún 306 sí 168 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ọba láti ìlà ìdílé Antigónù yìí ló ṣàkóso Makedóníà gbẹ̀yìn, ìjọba Róòmù ló sì ṣẹ́gun èyí tó kẹ́yìn lára wọn.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica fi yé wa pé ìgbà táwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Róòmù ṣẹ́gun Ọba Fílípì Karùn-ún lọ́dún 197 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló di pé “àwọn ọba ilẹ̀ Gíríìsì ò lágbára mọ́, tí ilẹ̀ apá ìlà oòrùn òkun Mẹditaréníà sì wá bọ́ sábẹ́ ilẹ̀ Róòmù.” Lọ́dún 168 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọ̀gágun àwọn ará Róòmù kan ṣẹ́gun Pásúsì pátápátá nílùú Pídínà, tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mélòó kan síhà gúúsù ìlú Bèróà. Pásúsì yìí ló jọba kẹ́yìn lórí àpapọ̀ ilẹ̀ Makedóníà ayé àtijọ́. Bí agbára ayé ṣe kúrò lọ́wọ́ ilẹ̀ Gíríìsì tó sì bọ́ sọ́wọ́ ilẹ̀ Róòmù nìyẹn, bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Dáníẹ́lì 7:6, 7, 23) Lẹ́yìn ogun yẹn, Bèróà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ilẹ̀ Makedóníà tó kọ́kọ́ juwọ́ sílẹ̀ fún ìjọba Róòmù.
Ní ọ̀rúndún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ilẹ̀ Makedóníà ni ẹgbẹ́ ogun ọ̀gágun Pọ́ńpè àti ti Júlíọ́sì Késárì ti wá ń bára wọn jà. Kódà, ìtòsí ìlú Bèróà ni ọ̀gágun Pọ́ńpè fi ṣe ibùdó àti orílé iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
Ìdàgbàsókè Ìlú Bèróà Lábẹ́ Ìjọba Róòmù
Láyé ìgbà Pax Romana, tó túmọ̀ sí Àlàáfíà Róòmù, ẹni tó bá dé ìlú Bèróà yóò rí àwọn títì tí wọ́n fi òkúta tẹ́ tí wọ́n sì rí òpó rìbìtì-rìbìtì sí lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́. Àwọn ibi ìwẹ̀ tí wọ́n kọ́ fáwọn aráàlú, gbọ̀ngàn ìṣeré ńláńlá, àwọn ibi ìkówèésí àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń ja ìjà àjàkú-akátá wà nílùú náà. Omi ẹ̀rọ wà níbẹ̀, wọ́n sì tún ní gọ́tà abẹ́ ilẹ̀ pẹ̀lú. Ìlú Bèróà lókìkí gan-an nítorí báwọn oníṣòwò, oníṣẹ́ ọnà, òṣèré àtàwọn eléré ìdárayá ṣe máa ń wá síbẹ̀ nítorí òwò ṣíṣe tó búrẹ́kẹ níbẹ̀, àwọn èèyàn sì máa ń wá síbẹ̀ láti wo ìdíje eré ìdárayá àtàwọn eré míì. Àwọn ilé ìjọsìn táwọn ará ìlú òkèèrè ti lè ṣe ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe níbi tí wọ́n ti wá, wà níbẹ̀. Àní onírúurú ẹ̀sìn tó wà káàkiri ilẹ̀ Róòmù ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀.
Àwọn olú ọba ilẹ̀ Róòmù tí wọ́n sọ dòrìṣà lẹ́yìn ikú wọn wà lára àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ ní Bèróà. Ó ṣeé ṣe kí àṣà bíbọ olú ọba má ṣàjèjì sáwọn ará ìlú Bèróà nítorí pé wọ́n ti máa ń bọ Alẹkisáńdà Ńlá gẹ́gẹ́ bí òrìṣà látẹ̀yìnwá. Ìwé kan tó sọ́rọ̀ nípa ilẹ̀ Gíríìsì sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn Hélénì [ìyẹn àwọn Gíríìkì] tó wà lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ Gíríìsì ti máa ń júbà àwọn ọba wọn tó ṣì wà láàyè bí ẹní júbà òrìṣà, ìyẹn ló jẹ́ kó yá wọn lára láti máa bọ àwọn olú ọba Róòmù pẹ̀lú . . . Wọ́n máa ń yàwòrán olú ọba tí wọ́n ti sọ dòrìṣà sára owó ẹyọ wọn tòun ti adé tó ní ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ lórí. Wọ́n á máa fi onírúurú orin yìn ín nínú àdúrà wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe fáwọn òrìṣà wọn.” Wọ́n máa ń kọ́ tẹ́ńpìlì, wọ́n á mọ pẹpẹ sínú rẹ̀, wọ́n á wá máa rúbọ sí olú ọba tí wọ́n ti sọ dòrìṣà níbẹ̀. Kódà àwọn olú ọba máa ń wá síbi ayẹyẹ bíbọ àwọn olú ọba tó ti kú, onírúurú ìdíje sì máa ń wáyé níbẹ̀, títí kan ìdíje àwọn òṣèré, ti eré ìdárayá, ti iṣẹ́ ọnà, ti ìwé kíkọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Kí ló mú kí Bèróà di ojúkò ìbọ̀rìṣà? Ohun tó jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé ibẹ̀ ni ìgbìmọ̀ Koinon ti ilẹ̀ Makedóníà ti máa ń pàdé. Àwọn aṣojú láti onírúurú ìlú tó wà ní ilẹ̀ Makedóníà ló wà nínú ìgbìmọ̀ yìí. Àwọn aṣojú wọ̀nyí máa ń pàdé déédéé nílùú Bèróà láti jíròrò ọ̀rọ̀ ìlú àti ti àgbègbè wọn gbogbo, wọn á wá bójú tó ọ̀rọ̀ ọ̀hún lábẹ́ ìdarí ìjọba Róòmù. Ọ̀kan pàtàkì lára ojúṣe ìgbìmọ̀ Koinon yìí sì ni bíbójú tó ayẹyẹ bíbọ àwọn olú ọba tí wọ́n ti sọ dòrìṣà.
Bí nǹkan ṣe rí nìyẹn nílùú Bèróà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà forí lé nígbà tí wọ́n sá kúrò ní Tẹsalóníkà. Nígbà tá à ń wí yìí, ọgọ́rùn-ún ọdún méjì ni ìlú Bèróà ti wà lábẹ́ ìjọba Róòmù.
Ìhìn Rere Dé Bèróà
Inú sínágọ́gù ni Pọ́ọ̀lù ti bẹ̀rẹ̀ ìwàásù rẹ̀ nílùú Bèróà. Ìhà wo làwọn èèyàn ibẹ̀ kọ sí i? Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn Júù tó wà níbẹ̀ “ní ọkàn-rere ju àwọn ti Tẹsalóníkà lọ, nítorí pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” (Ìṣe 17:10, 11) Nítorí pé wọ́n “ní ọkàn-rere,” wọn ò wonkoko mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ yẹn rí, wọn ò ṣiyèméjì nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọn ò sì bínú sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀ tọkàntara, láìsí ẹ̀tanú kankan.
Báwo làwọn Júù yẹn ṣe wá mọ̀ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń kọ́ àwọn? Ńṣe ni wọ́n lo Ìwé Mímọ́, tó jẹ́ ohun ìṣàyẹ̀wò tó ṣeé gbára lé jù lọ, láti fi ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n fara balẹ̀ ṣèwádìí dáadáa nínú Ìwé Mímọ́. Ìyẹn ni ọ̀mọ̀wé Matthew Henry tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì fi sọ pé: “Níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti ń fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó ń tọ́ka sí Májẹ̀mú Láéláé láti fi ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, wọ́n padà lọ gbé Bíbélì wọn, wọ́n ṣí àwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí, wọ́n kà á pa pọ̀ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà láyìíká ibẹ̀, wọ́n wá gbé wọn yẹ̀ wò síwá sẹ́yìn, wọ́n fi wọ́n wé àwọn ibòmíì nínú Ìwé Mímọ́ láti mọ̀ bóyá àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa wọn bá a mu ó sì jóòótọ́, wọ́n wá gbà pé òdodo ọ̀rọ̀ ni.”
Kì í ṣe pé àwọn ará Bèróà kàn ń sáré yẹ Ìwé Mímọ́ wò láìronú lé e o. Ńṣe ni wọ́n ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ náà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lójoojúmọ́, wọn ò fi mọ sọ́jọ́ Sábáàtì nìkan.
Ohun téyìí wá yọrí sí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù tó wà ní Bèróà tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà wọ́n sì di onígbàgbọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ Gíríìkì náà di onígbàgbọ́, ó sì ṣeé ṣe káwọn aláwọ̀ṣe Júù kan wà lára wọn. Àmọ́ ìròyìn èyí ò ṣàì dé ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá. Nígbà táwọn Júù tó wà ní Tẹsalóníkà gbọ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Bèróà, wọ́n sáré wá síbẹ̀ “láti ru àgbájọ ènìyàn náà lọ́kàn sókè àti láti kó ṣìbáṣìbo bá wọn.”—Ìṣe 17:4, 12, 13.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí mú kó di dandan fún Pọ́ọ̀lù láti kúrò ní Bèróà, ó ń bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ níbòmíì. Ìlú Áténì ló wọkọ̀ òkun lọ lọ́tẹ̀ yìí. (Ìṣe 17:14, 15) Ṣùgbọ́n, inú rẹ̀ á dùn gan-an ni pé iṣẹ́ ìwàásù òun ni Bèróà mú kí ẹ̀sìn Kristẹni fìdí múlẹ̀ níbẹ̀. Ẹ̀sìn Kristẹni sì ń so èso níbẹ̀ lóde òní.
Láìsí àní-àní, àwọn èèyàn ṣì ń bẹ ní Bèróà (ìlú Véroia) lóde òní tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ láti “wádìí ohun gbogbo dájú” àti láti “di” ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó dájú hán-ún-hán-ún “mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì tó ń tẹ́ síwájú dáadáa ló wà nílùú náà báyìí tí wọ́n ń wàásù bíi ti Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n ń sọ ìhìn rere inú Bíbélì fáwọn èèyàn. Wọ́n ń wá àwọn olóòótọ́ èèyàn kàn, wọ́n sì ń fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún wọn, kí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó ń sa agbára lè ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti mọ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́.—Hébérù 4:12.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Díẹ̀ lára ibi tí Pọ́ọ̀lù dé nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì
MÁÍSÍÀ
Tíróásì
Neapólísì
Fílípì
MAKEDÓNÍÀ
Áńfípólì
Tẹsalóníkà
Bèróà
GÍRÍÌSÌ
Áténì
Kọ́ríńtì
ÁKÁYÀ
ÉṢÍÀ
Éfésù
RÓDÉSÌ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Owó fàdákà kan tí wọ́n ya Alẹkisáńdà Ńlá sí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára òrìṣà àwọn ará Gíríìsì
[Credit Line]
Owó ẹyọ: Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ẹnubodè kan tó wọ àdúgbò àwọn Júù ní Bèróà (Véroia)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Sínágọ́gù ìgbàanì kan tó wà nílùú Bèróà (Véroia) òde òní