Ìrànwọ́ Láti Ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run Tí Ń Pèsè Ìfaradà àti Ìtùnú”
NÍ NǸKAN bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú.” (Róòmù 15:5) Níwọ̀n bí Bíbélì ti mú un dá wa lójú pé Jèhófà kì í yí padà, ó dá wa lójú pé Ọlọ́run ṣì ń tu àwọn tó ń sìn ín nínú. (Jákọ́bù 1:17) Kódà, Bíbélì fi hàn kedere pé Jèhófà máa ń pèsè ìtùnú lónírúurú ọ̀nà fáwọn tó nílò rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó ń gbà pèsè rẹ̀? Ọlọ́run máa ń fi okun fún àwọn tó ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ó tún máa ń lo àwọn Kristẹni tòótọ́ láti tu àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nínú. Jèhófà sì tún mú kí wọ́n kọ àwọn ìtàn tó ń tuni nínú sílẹ̀ nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyí sì máa ń fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ikú ọmọ wọn lókun gan-an. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́tà tí wọ́n lè gbà rí ìtùnú yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
“Jèhófà Tìkára Rẹ̀ sì Gbọ́”
Dáfídì Ọba kọ̀wé nípa Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà pé: “Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà. Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi fún wa.” (Sáàmù 62:8) Kí nìdí tí Dáfídì fi gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Ẹni yìí tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pè, Jèhófà tìkára rẹ̀ sì gbọ́. Ó sì gbà á là nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.” (Sáàmù 34:6) Nígbà tí Dáfídì wà nínú gbogbo ìṣòro yìí, ó máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́, Jèhófà sì máa ń ràn án lọ́wọ́. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì sẹ́yìn jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ran òun lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro náà, kò sì ní fi òun sílẹ̀.
Ó yẹ káwọn òbí tó ń ṣọ̀fọ̀ mọ̀ pé Jèhófà yóò ran àwọn lọ́wọ́ nínú ìbànújẹ́ lílékenkà táwọn wà bó ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́. Wọ́n lè bá “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé yóò ran àwọn lọ́wọ́. (Sáàmù 65:2) William, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣe mí bíi pé láìsí ọmọ mi, mi ò lè wà láàyè mọ́, mo sì máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Gbogbo ìgbà ló máa ń fún mi lókun, ó sì ń jẹ́ kí n máa wà láàyè nìṣó.” Tíwọ náà bá gbàdúrà sí Jèhófà tó o sì nígbàgbọ́, ó dájú pé Ọlọ́run alágbára tó wà lókè ọ̀run kò ní fi ọ́ sílẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn tó ń sa gbogbo ipá wọn láti sìn ín pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísáyà 41:13.
Ìrànlọ́wọ́ Máa Ń Wá Látọ̀dọ̀ Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́
Àwọn òbí tọ́mọ wọn kú nílò àkókò láti dá wà kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ wọn tó kú, kára lè tù wọ́n. Àmọ́ ṣá o, kò ní bọ́gbọ́n mu rárá kí wọ́n máa dá wà fúngbà pípẹ́ láìdá sí ẹnikẹ́ni. Òwe 18:1 sọ pé, “ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀” lè pa ara rẹ̀ lára. Nítorí náà, àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe máa dá nìkan wà ní gbogbo ìgbà.
Àwọn ọ̀rẹ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó wà nínú ìbànújẹ́. Òwe 17:17 sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Arábìnrin Lucy, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, rí ìtùnú gbà látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ lẹ́yìn ikú ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ, ó sọ pé: “Wíwá tí wọ́n ń wá sílé wa ṣèrànwọ́ gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ ni wọ́n máa ń sọ nígbà míì. Ọ̀rẹ́ mi kan máa ń wá sọ́dọ̀ mi láwọn ọjọ́ témi nìkan bá dá wà. Ó mọ̀ pé ilé ni mo máa wà tí màá máa sunkún, ó sì sábà máa ń wá sọ́dọ̀ mi, tá a ó jọ máa sunkún. Ojoojúmọ́ ni ọ̀rẹ́ mi mìíràn sì máa ń pè mí lórí fóònù láti fún mi níṣìírí. Àwọn mìíràn tiẹ̀ máa ń pè wá pé ká wá jẹun nílé wọn, wọ́n ò sì yé pè wá.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbànújẹ́ táwọn òbí máa ń ní nígbà tọ́mọ wọn bá kú kì í tán bọ̀rọ̀, síbẹ̀ àdúrà gbígbà àti sísúnmọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ yóò fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ní ojúlówó ìtùnú. Ọ̀pọ̀ òbí tó jẹ́ Kristẹni tọ́mọ wọn kú ló ti rí i pé Jèhófà ò fàwọn sílẹ̀. Dájúdájú, Jèhófà “ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.”—Sáàmù 147:3.
Àwọn Ìtàn Bíbélì Tó Ń Tuni Nínú
Yàtọ̀ sí àdúrà àtàwọn ọ̀rẹ́ tó ń gbéni ró, àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ tún lè rí ìtùnú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ìtàn inú Bíbélì fi hàn pé ó wu Jésù tọkàntọkàn láti mú ìbànújẹ́ àwọn òbí tó ń ṣọ̀fọ̀ kúrò nípa jíjí àwọn ọmọ wọn tó kú dìde, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ máa ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú gan-an. Ẹ jẹ́ ká gbé méjì yẹ̀ wò lára irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀.
Lúùkù orí keje sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù pàdé àwọn kan nílùú Náínì tí wọ́n ń gbé òkú kan lọ síbi tí wọ́n ti máa sin ín. Ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí opó kan bí ni òkú tí wọ́n fẹ́ lọ sin yìí. Ẹsẹ kẹtàlá sọ pé: “Nígbà tí Olúwa sì tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé: ‘Dẹ́kun sísunkún.’”
Bóyá la fi rẹ́ni tó lè sọ fún ìyá kan tí wọ́n fẹ́ lọ sìnkú ọmọ rẹ̀ pé kó dẹ́kun sísunkún. Kí nìdí tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀? Nítorí ó mọ̀ pé ìbànújẹ́ ìyá náà kò ní pẹ́ dópin ni. Ìtàn náà ń bá a lọ pé: “[Jésù] sún mọ́ ọn, ó sì fọwọ́ kan agà ìgbókùú náà, àwọn tí wọ́n gbé e sì dúró jẹ́ẹ́, ó sì wí pé: ‘Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!’ Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì fi í fún ìyá rẹ̀.” (Lúùkù 7:14, 15) Ó dájú pé ìyá ọmọkùnrin náà yóò tún padà sunkún lójú ẹsẹ̀ yẹn, àmọ́ ẹkún ayọ̀ nìyẹn máa jẹ́.
Ìgbà kan tún wà tí ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù wá sọ́dọ̀ Jésù, tó ń bẹ̀ ẹ́ pé kó wá ran òun lọ́wọ́ láti wo ọmọ òun obìnrin sàn. Ọmọ ọdún méjìlá lọmọ rẹ̀ obìnrin yìí, àìsàn tó ń ṣe é sì lágbára gan-an. Kò pẹ́ sí àkókò yẹn táwọn kan wá sọ́ fún un pé ọmọ náà ti kú. Ohun tí wọ́n sọ yìí ba Jáírù lọ́kàn jẹ́ gan-an, àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, sáà ti lo ìgbàgbọ́.” Nígbà tí Jésù dé ilé Jáírù, ó lọ síbi tí òkú ọmọbìnrin náà wà. Ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì sọ pé: “Omidan, mo wí fún ọ, Dìde!” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, omidan náà sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn.” Kí làwọn òbí rẹ̀ wá ṣe? “Wọn kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” Ìdùnnú ṣubú layọ̀ lọ́kàn Jáírù àti ìyàwó rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dì mọ́ ọmọ wọn. Ńṣe ló dà bíi pé àlá ni wọ́n ń lá.—Máàkù 5:22-24, 35-43.
Irú àwọn ìtàn inú Bíbélì wọ̀nyí tó sọ nípa àjíǹde àwọn ọmọdé jẹ́ káwọn òbí tó ń ṣọ̀fọ̀ lóde òní mọ ohun táwọn náà lè máa retí lọ́jọ́ iwájú. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Jèhófà ti pinnu pé Ọmọ òun yóò jí àwọn tó ti kú dìde. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọdé tó ti kú ni yóò “gbọ́ ohùn rẹ̀” nígbà tó bá sọ fún wọn pé: “Mo wí fún ọ, Dìde!” Àwọn ọmọdé wọ̀nyẹn yóò tún bẹ̀rẹ̀ sí í rìn, wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀. Bíi ti Jáírù àti ìyàwó rẹ̀ làwọn òbí àwọn ọmọ wọ̀nyẹn náà ò ṣe ní “mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà [á] pọ̀ jọjọ.”
Tó o bá ni ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan tó ti kú, a fẹ́ kó o mọ̀ pé Jèhófà lè sọ ìbànújẹ́ rẹ dayọ̀ nípasẹ̀ àjíǹde. Tó o bá fẹ́ jàǹfààní àwọn ohun àgbàyanu tá à ń retí yìí, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn onísáàmù tó sọ pé: “Ẹ máa wá Jèhófà àti okun rẹ̀. Ẹ máa wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe, àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.” (Sáàmù 105:4, 5) Bẹ́ẹ̀ ni o, sin Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, kó o sì máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tí inú rẹ̀ dùn sí.
Àǹfààní wo ni wàá kọ́kọ́ rí tó o bá “wá Jèhófà”? Wàá rí okun gbà nípasẹ̀ àdúrà sí Ọlọ́run, ìfẹ́ táwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni tòótọ́ ń fi hàn sí ọ yóò tù ọ́ nínú, ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣara gírí. Kò tán síbẹ̀ o, láìpẹ́, wàá rí ‘àwọn iṣẹ́ àgbàyanu àtàwọn iṣẹ́ ìyanu’ tí Jèhófà yóò ṣe, tí yóò jẹ́ àǹfààní ayérayé fún ìwọ àti ọmọ rẹ tó kú.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
“Mo Fẹ́ Rí Obìnrin Tí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Méjì Kú Lẹ́ẹ̀kan Náà”
Méjì lára àwọn ọmọ Kehinde àti Bintu ló kú sínú jàǹbá ọkọ̀ kan. Ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà ni tọkọtaya yìí, wọ́n sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Látìgbà yẹn ni wọ́n ti ní ẹ̀dùn ọkàn nítorí àjálù burúkú yìí. Síbẹ̀, ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú Jèhófà fún wọn lókun, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa sọ ìhìn rere tó ń fúnni nírètí látinú Bíbélì fáwọn aládùúgbò wọn.
Àwọn èèyàn rí i bí Kehinde àti Bintu ṣe ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n ò sì kó ìṣòro wọn lọ́kàn. Lọ́jọ́ kan, obìnrin kán tó ń jẹ́ Ìyáàfin Ukoli sọ fún ọkàn lára àwọn ọ̀rẹ́ Bintu pé: “Mo fẹ́ rí obìnrin táwọn ọmọ rẹ̀ méjì kú lẹ́ẹ̀kan náà tó ṣì tún ń wàásù ohun tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn. Mo fẹ́ mọ ohun tó fún un lágbára láti fara da ìṣòro náà.” Nígbà tí Bintu dé ilé Ìyáàfin Ukoli, ó sọ fún Bintu pé: “Mo fẹ́ mọ ìdí tó o ṣì fi ń wàásù nípa Ọlọ́run tó pa àwọn ọmọ rẹ. Ọlọ́run pa ọmọbìnrin kan ṣoṣo tí mo bí. Àtìgbà yẹn ni mi ò ti ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́.” Bintu lo Bíbélì láti jẹ́ kó mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń kú àti ìdí tó fi yẹ ká nírètí tó dájú pé àwọn èèyàn wa tó ti kú yóò jíǹde.—Ìṣe 24:15; Róòmù 5:12.
Lẹ́yìn náà, Ìyáàfin Ukoli sọ pé: “Ohun tí mo máa ń rò tẹ́lẹ̀ ni pé Ọlọ́run ló ń fikú pa àwọn èèyàn. Àmọ́ mo ti wá mọ òótọ́ ibẹ̀ báyìí.” Ó pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó lè túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
‘Mo Fẹ́ Ṣèrànwọ́, Àmọ́ Mi O Mọ Bí Mo Ṣe Lè Ṣe É’
Nígbà tí ìbànújẹ́ bá dorí òbí, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ọmọ kan tó kú kodò, àwọn ọ̀rẹ́ lè má mọ ohun tó yẹ káwọn ṣe. Wọ́n fẹ́ ran ìdílé náà lọ́wọ́, àmọ́ ẹ̀rù ń bà wọ́n káwọn má lọ sọ ohun kan tàbí káwọn má lọ ṣe ohun kan tó máa túbọ̀ mú kí ìbànújẹ́ náà pọ̀ sí i. Àwọn tó lè máa ronú pé, ‘mo fẹ́ ṣèrànwọ́, àmọ́ mi ò mọ bí mo ṣe lè ṣe é’ lè tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn díẹ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí.
❖ Má ṣe sọ pé o ò ní lọ kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ torí pé o ò mọ ohun tó o máa sọ tàbí ohun tó o máa ṣe. Pé o tiẹ̀ wà lọ́dọ̀ wọn lè fún wọn lókun. Ká ní o ò tiẹ̀ mọ ohun tó o máa sọ, tó o bá gbá wọn mọ́ra tó o sì sọ pé “ẹ pẹ̀lẹ́ o” látọkànwá, ìyẹn á fi hàn pé ọ̀ràn wọn ká ọ lára. Àbí ò ń bẹ̀rù pé tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, wàá túbọ̀ jẹ́ kí ìbànújẹ́ wọn pọ̀ sí i? Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Èyí á fi hàn pé ìwọ náà ń bá wọn ṣọ̀fọ̀, ìyẹn sì lè tù wọ́n nínú.
❖ Ronú nǹkan tó o lè ṣe. Ǹjẹ́ o lè ṣe oúnjẹ díẹ̀ fún wọn? Ǹjẹ́ o lè bá wọn fọ abọ́? Ṣé o lè jẹ́ kí wọ́n rán ọ láwọn iṣẹ́ kan? Má ṣe sọ pé, “Tẹ́ ẹ bá nílò ohunkóhun, ẹ jẹ́ kí n gbọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkàntọkàn lo fi sọ ọ́, ohun tírú ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí fáwọn òbí tó ń ṣọ̀fọ̀ ni pé ọwọ́ ẹ ti dí jù láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Dípò ìyẹn, béèrè pé, “Kí ni mo lè bá a yín ṣe nísinsìnyí?” kó o sì ṣe ohun tí wọ́n bá ní kó o báwọn ṣe. Àmọ́, ìyẹn ò ní kó o tojú bọ ibi tí wọ́n ò bá fẹ́ kó o dé nínú ilé wọn tàbí kó o dá sí ohun tí wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ẹ̀.
❖ Má ṣe sọ pé, “Mo mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára yín.” Bí ọ̀ràn ikú èèyàn ẹ̀ni ṣe máa ń rí lára oníkálukú yàtọ̀ síra. Bí ọmọ kan tiẹ̀ ti kú lọ́wọ́ rẹ rí, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára tiwọn.
❖ Àkókò díẹ̀ á kọjá kí ìdílé náà tó tún padà bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé wọn bíi ti tẹ́lẹ̀. Ìwọ ṣáà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tágbára rẹ bá gbé e dé. Ní gbàrà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ nínú ilé kan, àwọn èèyàn á máa rọ́ wá síbẹ̀ láti ṣaájò láwọn àkókò yẹn, àmọ́ kì í ṣe àárín ọjọ́ díẹ̀ tàbí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ yẹn nìkan ni wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn èèyàn. Rí i pé ò ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn àkókò yẹn.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ wọn tó kú, wo àkòrí tó sọ pé “Báwo Ni Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?” ní ojú ìwé 20 sí 24 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ìtàn inú Bíbélì fi hàn pé Jésù lágbára láti mú káwọn ọmọdé tó ti kú padà wà láàyè, ó sì wù ú gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀