ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 9/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹrú Olóòótọ́’ Náà Yege Nígbà Àbẹ̀wò!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “Ẹrú” Tí ó Jẹ́ Olóòótọ́ Àti Olóye
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Wọ́n “Ń Tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Lẹ́yìn Ṣáá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 9/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ẹrú olóòótọ́ òun yóò jẹ́ “olóye”?

Jésù béèrè ìbéèrè kan, ó ní: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?” (Mátíù 24:45) Ìjọ àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn ni “ẹrú” tó ń pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí. Kí nìdí tí Jésù fi pè wọ́n ní olóye?a

Látinú ẹ̀kọ́ Jésù fúnra rẹ̀, a lè lóye ohun tó ṣeé ṣe kó ní lọ́kàn tó fi lo ọ̀rọ̀ náà “olóye.” Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ó sọ àkàwé kan nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n ń ṣọ́nà láti mọ ìgbà tí ọkọ ìyàwó máa dé. Àwọn wúńdíá wọ̀nyí rán wa létí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣáájú ọdún 1914, tí wọ́n ń retí dídé Ọkọ Ìyàwó ńlá náà, Jésù Kristi, lójú méjèèjì. Àwọn márùn-ún lára àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà kò ní òróró tó pọ̀ tó nígbà tí ọkọ ìyàwó dé, kò sì ṣeé ṣe fún wọn láti wà níbi àsè ìgbéyàwó náà. Àwọn márùn-ún yòókù jẹ́ olóye. Wọ́n ti wá òróró tó máa tó wọn láti lò sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè máa tànmọ́lẹ̀ nìṣó nígbà tí ọkọ ìyàwó dé, ó sì gbà wọ́n láyè láti wọlé síbi àsè náà.—Mátíù 25:10-12.

Nígbà tí Jésù bọ́ sórí ìtẹ́ Ìjọba rẹ̀ lọ́dún 1914, ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló ń retí pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ yẹn làwọn máa lọ bá a lọ́run. Àmọ́, iṣẹ́ rẹpẹtẹ ṣì wà fún wọn láti ṣe lórí ilẹ̀ ayé, èyí sì bá àwọn kan lára wọn lójijì. Bíi tàwọn wúńdíá tó jẹ́ aláìlóye, wọn ò gbára dì rárá nípa tẹ̀mí ṣáájú ìgbà yẹn, nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò sì ní ìmúrasílẹ̀ láti máa tànmọ́lẹ̀ nìṣó. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára wọn ti ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ olóye, pé wọ́n ní ọgbọ́n, pé wọ́n sì jẹ́ ẹni tó ń ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú, èyí mú kí wọ́n wà ní sẹpẹ́ nípa tẹ̀mí. Nígbà tí wọ́n rí i pé iṣẹ́ rẹpẹtẹ ṣì wà níwájú àwọn, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Nípa báyìí, wọ́n fi hàn pé “olóòótọ́ àti olóye” làwọn.

Tún kíyè sí ọ̀nà tí Jésù gbà lo ọ̀rọ̀ náà “olóye” nínú Mátíù 7:24. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí ó sì ń ṣe wọ́n ni a ó fi wé ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.” Ọkùnrin tó jẹ́ olóye kọ́ ilé rẹ̀ lọ́nà tó lágbára, nítorí ó mọ̀ pé ìjì lè dé. Àmọ́ orí iyanrìn ni òmùgọ̀ ọkùnrin lọ kọ́ ilé tirẹ̀ sí, ó sì pàdánù rẹ̀. Nípa báyìí, ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olóye lẹni tó ń kíyè sáwọn ohun búburú tó máa ń tẹ̀yìn ẹ̀ yọ téèyàn bá tẹ̀ lé ọgbọ́n èèyàn. Òye tó ní àti làákàyè rẹ̀ ń mú kó gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀, ìwà rẹ̀, àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ka ohun tí Jésù kọ́ni. Bí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe ń ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn.

Tún kíyè sí ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “olóye” nínú ọ̀pọ̀ ẹsẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Bí àpẹẹrẹ, Fáráò fi Jósẹ́fù ṣe alábòójútó oúnjẹ nílẹ̀ Íjíbítì. Èyí jẹ́ ara ètò tí Jèhófà ṣe láti lè pèsè oúnjẹ fáwọn èèyàn rẹ̀. Kí nìdí tí Fáráò fi yan Jósẹ́fù? Fáráò sọ fún un pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó jẹ́ olóye, tí ó sì gbọ́n tó ọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 41:33-39; 45:5) Bákan náà ni Bíbélì sọ pé Ábígẹ́lì jẹ́ ẹni tó ní “ọgbọ́n inú dáadáa.” Ó pèsè oúnjẹ fún Dáfídì tó jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà, àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 25:3, 11, 18) Bíbélì pe Jósẹ́fù àti Ábígẹ́lì ní olóye nítorí pé wọ́n mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Èyí mú kí wọ́n ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú, wọ́n sì tún jẹ́ onílàákàyè.

Nítorí náà, nígbà tí Jésù sọ pé ẹrú olóòótọ́ yóò jẹ́ olóye, ó ń fi hàn pé àwọn tí ẹrú yẹn dúró fún yóò ní òye, wọ́n á fi hàn pé àwọn ń ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú, àwọn sì ní làákàyè, nítorí pé wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn, àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe, àtàwọn ẹ̀kọ́ wọn karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ òtítọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, phroʹni·mos túmọ̀ sí “olóye.” Ìwé kan tó ń jẹ́ Word Studies in the New Testament, látọwọ́ ọ̀gbẹ́ni M. R. Vincent, ṣàlàyé pé lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ yìí máa ń túmọ̀ sí kéèyàn ní ọgbọ́n àti òye.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́