Kí Lohun Tó Dára Jù Lọ Tó O Lè Fayé Rẹ Ṣe?
ILÉ iṣẹ́ káràkátà kan tó ti rọ́wọ́ mú ni Kenny ti ń ṣiṣẹ́, ọkọ̀ bọ̀gìnnì olówó ńlá kan ló ń lò, ó sì ní ilé gogoro kan sí àdúgbò táwọn olówó ń gbé nílùú ńlá kan. Gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagí nínú eré bíbẹ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ òfuurufú, ó máa ń dùn mọ́ ọn bó ṣe máa ń bẹ́ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹsẹ̀ bàtà látojú sánmà, táá sì máa já bọ̀ nílẹ̀ dòò. Ǹjẹ́ gbogbo ohun tó ṣe yìí mú kó ní ìtẹ́lọ́rùn nígbèésí ayé rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Wall Street Journal ṣe sọ, ó ní: “Mo ti pé ọmọ ọdún márùndínláàádọ́ta báyìí, mi ò mọ̀ bóyá ọjọ́ ọ̀la mi á dára . . . Ìgbésí ayé mi ò lórí kò nídìí.”
Gbogbo ọkàn ni Elyn fi múra sí eré orí yìnyín kó bàa lè ṣe é débi èrè. Ó ti rọ́wọ́ mú nídìí ẹ̀. Elyn sì ti lókìkí tó fẹ́ ní. Àmọ́ ó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pé: “Ṣé bó ṣe yẹ kí n láyọ̀ mọ rèé? Ṣe ni mo dà bí aláìlẹ́bí àti aláìlárá. Bópẹ́bóyá, màá darúgbó. Òótọ́ ni pé olówó ni mí, àmọ́ tó bá jẹ́ pé owó nìkan ni mo fi gbogbo ayé mi wá, asán ni gbogbo ìgbésí ayé mi.”
Olókìkí ni Hideo nínú iṣẹ́ fífi oríṣiríṣi ọ̀dà dárà, àwòrán yíyà ló sì gbájú mọ́ nígbèésí ayé rẹ̀. Kò ta oríṣiríṣi àwọn ohun tó yà nítorí ó gbà pé tóun bá ń tà wọ́n, iṣẹ́ òun ò ní gbayì tó bó ṣe yẹ. Nígbà tó wà lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún, tó sì ti sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀, ó fi ọ̀pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ ọnà rẹ̀ ta ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí kan lọ́rẹ. Iṣẹ́ ọnà ló fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Síbẹ̀, kò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ó gbà pé tóun bá tiẹ̀ ṣiṣẹ́ ọ̀hún títí ayé, òun ò lè mọ̀ ọ́n débi tó yẹ kóun mọ̀ ọ́n dé.
Àwọn kan wà tó jẹ́ pé tiwọn ni kí wọ́n máa ṣe àwọn èèyàn lóore. Bí àpẹẹrẹ, wo tẹnì kan tó jẹ́ ọ̀gá kan nílé iṣẹ́ fíìmù tó lókìkí gan-an nílùú Hollywood nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Nítorí ó jẹ́ igbá kejì ọ̀gá àgbà ọ̀kan lára ilé iṣẹ́ fíìmù tó tóbi jù lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn gbajúgbajà ló ń bá rìn, ilé olówó ńlá tó dà bí ààfin ló sì ń gbé. Nígbà tó lọ lo àkókò ìsinmi lórílẹ̀-èdè Cambodia, ọmọbìnrin kan wá tọrọ owó lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tó ń jẹun lọ́wọ́ nílé oúnjẹ kan nílùú Phnom Penh. Ó fún un ní dọ́là kan owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò kan. Inú ọmọbìnrin yẹn dùn. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ kejì, ó rí i pé ọmọbìnrin yẹn tún ti wà níbẹ̀, tó sì ń tọrọ báárà. Ó wá rí i pé òun ní láti ṣe ju kóun kàn máa fáwọn èèyàn ní tọ́rọ́ kọ́bọ̀ lọ.
Lẹ́yìn ọdún kan, ọkùnrin yìí, tó jẹ́ ọ̀gá nílé iṣẹ́ fíìmù, pinnu láti pa iṣẹ́ amúlùúdùn tó yàn láàyò náà tì, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn tálákà tó wà lórílẹ̀-èdè Cambodia lọ́wọ́. Ó dá iléèwé kan sílẹ̀ fáwọn ọmọ orílẹ̀-èdè náà, ó fún àwọn ọmọ iléèwé náà nílé ọ̀fẹ́ láti máa gbé, ó sì tún ń fún wọn lóúnjẹ ọ̀fẹ́. Síbẹ̀, bínú ẹ̀ ṣe ń dùn ni inú ẹ̀ tún ń bà jẹ́. Ìdí ni pé ohun tó ń gbé ṣe ń múnú ẹ̀ dùn, àmọ́ àwọn òkè ìṣòro tó wà níwájú ẹ̀ ń kó ìbànújẹ́ bá a, ó sì jẹ́ kí gbogbo nǹkan sú u.
Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn yìí gbà pé àwọn mọ ohun táwọn fẹ́ fi ìgbésí ayé àwọn ṣe. Síbẹ̀, nígbà tọ́wọ́ wọn tẹ ohun tí wọ́n ń wá náà tán, gbogbo nǹkan tojú sú wọn. Kí nìwọ fẹ́ fìgbésí ayé rẹ ṣe? Kí lo kà sí pàtàkì jù lọ láyé rẹ? Ṣó dá ọ lójú pé o ò ní kábàámọ̀ lórí ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ?