ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 11/1 ojú ìwé 6
  • Ẹ̀kọ́ Èké Kẹta: Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ Sí Ọ̀run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Èké Kẹta: Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ Sí Ọ̀run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀kọ́ Èké àbí Òótọ́ Pọ́ńbélé?
    Jí!—2008
  • Báwo Ni Ọ̀run Ṣe Rí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 11/1 ojú ìwé 6

Ẹ̀kọ́ Èké Kẹta: Gbogbo Èèyàn Rere Ló Ń Lọ Sí Ọ̀run

Báwo ni ẹ̀kọ́ èké yìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì Jésù kú, ìyẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni, àwọn Bàbá Ìjọ ayé ìgbàanì di aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì. Ìwé New Catholic Encyclopedia (2003), Ìdìpọ̀ 6, ojú ìwé 687 ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀kọ́ wọn, ó ní: “Ẹ̀kọ́ tó gbòde nígbà náà ni pé ìgbádùn kẹlẹlẹ ló máa wà lọ́run fún àwọn ọkàn tó bá ti fi ara sílẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ tó pọn dandan fún wọn lẹ́yìn ikú.”

Kí ni Bíbélì sọ? “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 5:5.

Òótọ́ ni pé Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun máa “pèsè ibì kan” sílẹ̀ fún wọn ní ọ̀run, ó jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo olódodo kọ́ ló ń lọ síbẹ̀. (Jòhánù 3:13; 14:2, 3) Ìdí nìyẹn tó fi ní ká máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ibi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn olódodo máa jogún. Àwọn díẹ̀ máa lọ jọba pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run, èyí tó sì pọ̀ jù nínú wọn ló máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 5:10.

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ṣọ́ọ̀ṣì ìpilẹ̀ṣẹ̀ yí èrò rẹ̀ pa dà nípa ohun tó yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ìwé The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Kò pẹ́ rárá tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi fi ara wọn rọ́pò Ìjọba Ọlọ́run tí àwọn èèyàn ń retí.” Ni ṣọ́ọ̀ṣì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fìdí agbára rẹ̀ múlẹ̀ nípa lílọ́wọ́ nínú ìṣèlú, kò sì ka ọ̀rọ̀ Jésù tó ṣe kedere sí pé, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun má ṣe jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19; 17:14-16; 18:36) Olú Ọba Ilẹ̀ Róòmù, ìyẹn Kọnsitatáìnì mú kí ṣọ́ọ̀ṣì pa àwọn kan tì lára àwọn ohun tó gbà gbọ́, lára àwọn ẹ̀kọ́ náà ni ẹ̀kọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.

Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí wéra: Sáàmù 37:10, 11, 29; Jòhánù 17:3; 2 Tímótì 2:11, 12

ÒKODORO ÒTÍTỌ́:

Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn rere ló máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, wọn kò ní lọ sí ọ̀run

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]

Art Resource, NY

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́