Ṣe Bó O Ti Mọ—Bí O Ṣe Lè Ṣe É
KÁ Ní o ní àgbá kan tí omi kún inú rẹ̀, o kò sì fẹ́ kí omi náà lọ sílẹ̀. Kí lo máa ṣe? Ohun tó o máa ṣe ni pé, gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti bu omi nínú rẹ̀ lo máa pọn òmíràn sí i. Tí omi tí ò ń pọn pa dà sínú àgbá náà bá ṣáà ti lè tó omi tí wọ́n bù kúrò níbẹ̀, omi náà kò ní lọ sílẹ̀.
A lè fi owó tó ń wọlé fún ẹ wé omi tí ò ń pọn sínú àgbá yẹn, a sì lè fi owó tí ò ń ná wé omi tí wọ́n ń bù kúrò níbẹ̀. Báwo lo ṣe máa ṣe é tí owó tí ò ń ná kò fi ní pọ̀ ju owó tí ó ń wọlé fún ẹ?
Òótọ́ ni pé, àǹfààní wà nínú kéèyàn má ṣe ná ju iye owó tó ń wọlé fúnni lọ, àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò rọrùn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò bá máà kó sí ìṣòro àìlówólọ́wọ́ ká ní wọ́n ń ṣe bí wọ́n ti mọ ni. Báwo ni èèyàn ṣe lè ṣe é? Ibo la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó gbéṣẹ́ lórí ọ̀ràn yìí? Bíbélì ló sọ ohun tó pọ̀ jù lọ tó lè ṣèrànwọ́ lórí ọ̀ràn yìí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó sọ.
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Máa Ranni Lọ́wọ́
Ọ̀pọ̀ ìlànà tó wúlò ló wà nínú Bíbélì, èyí tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣọ́wó ná. A ó gbé díẹ̀ lára wọn yẹ̀ wò. Wò ó bóyá àwọn ìlànà náà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bó o ti mọ.
Ní ètò ìnáwó. Kéèyàn tó lè ṣọ́wó ná, èèyàn ní láti mọ iye tó ń wọlé àti ibi téèyàn ń ná owó náà sí. Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Àwọn kan ti lo àwọn àpò ìwé láti ṣètò ìnáwó wọn. Wọ́n máa ń kọ ohun tí wọ́n fẹ́ fi owó náà ṣe sára àpò ìwé kọ̀ọ̀kan, irú bí “Oúnjẹ,” “Ilé gbígbé” tàbí “Aṣọ.” Bóyá ọ̀nà yìí tàbí ọ̀nà míì lo lò, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o mọ ohun tó o fẹ́ fi owó náà ṣe, kó o sì máa fi àwọn ohun tó jẹ́ kò-ṣeé-mánìí ṣáájú àwọn nǹkan tí o kàn nífẹ̀ẹ́ sí.
Yẹra fún owú. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló máa ń fẹ́ ní àwọn nǹkan táwọn tó wà ní orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ní. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ ní àwọn nǹkan táwọn aládùúgbò wọn fi ń ṣe fọ́rífọ́rí. Ìdẹkùn lèyí jẹ́ o. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn aládùúgbò wọn jẹ gbèsè ra àwọn nǹkan náà ni. Kí ló dé tó o fi máa fara wé ìwà òmùgọ̀ tí ẹnì kan hù, tí wàá sì wá tọrùn bọ gbèsè? Bíbélì sọ pé: “Ẹni ti o kanju ati la, o ni oju ilara, kò si rò pe òṣi mbọ̀ wá ta on.”—Owe 28:22, Bibeli Mimọ.
Jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ ọ lọ́rùn. Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n jẹ́ kí ojú wọn “mú ọ̀nà kan.” (Mátíù 6:22) Ẹnì kan tó jẹ́ pé ẹja ebólo àti omi ni agbára rẹ̀ ká láti jẹ, tó wá ń fẹ́ edé àti wáìnì lè kó sí gbèsè. Nínú ìròyìn kan tí báńkì tó ń jẹ́ Asian Development Bank sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Éṣíà, ó ní, lórílẹ̀-èdè Philippines, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta èèyàn ló jẹ́ òtòṣì paraku, bákan náà ní orílẹ̀-èdè Íńdíà, ó lé ní ìdajì àwọn èèyàn ibẹ̀ tó jẹ́ òtòṣì paraku, owó tó ń wọlé fún ẹnì kan lójúmọ́ jẹ́ nǹkan bíi $1.35 owó dọ́là (nǹkan bíi ₦203.00). Nígbà tí irú owó táṣẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ bá ń wọlé lójúmọ́, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn fi owó náà ra àwọn nǹkan tó jẹ́ kò-ṣe-mánìí. Àmọ́ ṣá o, ìlànà kan náà lè ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ pàápàá, kí wọ́n má bàa tọrùn bọ gbèsè.
Jẹ́ kí ohun tó o ní tẹ́ ọ lọ́rùn. Ìmọ̀ràn yìí bára mu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tó sọ pé kéèyàn jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ni lọ́rùn. Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn yìí ní 1 Tímótì 6:8 pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” Àwọn kan lára àwọn èèyàn tó láyọ̀ jù lọ láyé ni kò ní owó tó pọ̀, síbẹ̀ wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ní, àwọn nǹkan náà kì í sì í ṣe ohun ìní tara nìkan, ohun míì tí wọ́n ní tó ń fún wọn láyọ̀ ni ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ìdílé wọn àtèyí tí wọ́n ní fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn.—Òwe 15:17.
Yẹra fún gbèsè tí kò pọn dandan. Ẹ ò rí bí ọ̀rọ̀ Bíbélì ṣe jẹ òótọ́ tó, ó ní: “Ọlọ́rọ̀ ní ń ṣàkóso lórí àwọn aláìnílọ́wọ́, ayá-nǹkan sì ni ìránṣẹ́ awínni”! (Òwe 22:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ipò kan tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lè mú kéèyàn jẹ gbèsè, àmọ́ àwọn tó ń jẹ gbèsè tí kò pọn dandan nítorí àtira ohun tó kàn wù wọ́n sábà máa ń tọrùn bọ gbèsè ńlá. Èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀, pàápàá téèyàn bá ń lo káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Nígbà tá a bá ti mú káàdì wa lọ́wọ́, a ó kàn máa ra nǹkan bó ṣe wù wá láìronú ni.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Eric tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Philippines sọ pé: “Tí mo bá lo káàdì téèyàn fi ń rajà láwìn, mo sábà máa ń ra nǹkan tó pọ̀ ju ti ìgbà tí mo bá ń sanwó lójú ẹsẹ̀. Èyí sì máa ń jẹ́ kí owó máà sí lọ́wọ́ mi lẹ́yìn tí mo bá san gbèsè tí mo jẹ.” Ẹ ò rí i pé ó yẹ kéèyàn ṣọ́ra gan-an nígbà tó bá ń lo káàdì téèyàn fi ń rajà láwìn!—2 Àwọn Ọba 4:1; Mátíù 18:25.
Tọ́jú owó pa mọ́ fún nǹkan tó o fẹ́ rà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé títọ́jú owó pa mọ́ fún nǹkan téèyàn fẹ́ rà lè jọ àṣà ayé àtijọ́, òun ni ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ téèyàn lè gbà yẹra fún gbèsè. Ṣíṣe èyí ti gba ọ̀pọ̀ èèyàn nínú gbèsè àti àìbalẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní, nítorí owó èlé gegere tó má ń wà lórí nǹkan téèyàn rà láwìn. Bíbélì ṣàpèjúwe eèrà pé ó ní “ọgbọ́n” nítorí ó máa ń kó “àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ jọ àní nígbà ìkórè” fún ìlò ọjọ́ iwájú.—Òwe 6:6-8; 30:24, 25.
Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlòmíì
Gbogbo ìmọ̀ràn Bíbélì tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí lè jẹ́ ìlànà tó dára, àmọ́ ṣé òótọ́ ni pé wọ́n ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe bí wọ́n ti mọ? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan tí wọ́n ti tẹ̀ lé irú àwọn ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì borí ìṣòro owó tí wọ́n ní.
Bàbá kan tó ń jẹ́ Diosdado ní ọmọ mẹ́rin, ó sọ pé ọrọ̀ ajé tí kò lọ dáadáa ti jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro fún òun láti gbọ́ bùkátà ìdílé òun. Síbẹ̀, ó mọ̀ pé ohun tó dára ni kéèyàn ṣe ètò ìnáwó. Ó sọ pé: “Mo ṣètò ọ̀nà tí mo máa gbà ná owó tó ń wọlé fún mi. Mo máa ń kọ nǹkan tí mo máa fi owó mi ṣe sórí ìwé.” Ohun tí Danilo náà ṣe nìyẹn. Okòwò kékeré tí òun àti ìyàwó rẹ̀ ń ṣe kò lọ dáadáa. Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wọn láti gbọ́ bùkátà ara wọn torí pé wọ́n fara bálẹ̀ ṣètò ìnáwó wọn. Ó sọ pé: “A wo iye owó tó ń wọlé fún wa lóṣooṣù, a sì tún wo iye tí à ń ná. Lẹ́yìn náà, a wá jíròrò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ iye tí a ó máa ná.”
Àwọn kan rí i pé ó pọn dandan láti dín iye táwọn ń ná sórí àwọn nǹkan kan kù kó bàa lè ṣeé ṣe láti tẹ̀ lé ètò ìnáwó tí wọ́n ṣe. Obìnrin opó kan tó ń jẹ́ Myrna tó ń tọ́ ọmọ mẹ́ta sọ pé: “Dípò kí èmi àtàwọn ọmọ mi wọ ọkọ̀ èrò lọ sí ìpàdé, ẹsẹ̀ la fi ń rìn ní báyìí.” Myrna ti sapá láti jẹ́ káwọn ọmọ rẹ̀ mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn. Ó sọ pé: “Mo ti sapá láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wọn nínú lílo ìlànà tó wà ní 1 Tímótì 6:8-10, tó sọ pé ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí ohun téèyàn ní tẹ́ni lọ́rùn.”
Ohun tí bàbá kan tó ń jẹ́ Gerald tó ní ọmọ méjì náà ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí ìdílé wa bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa ń jíròrò nípa àwọn Kristẹni tí wọ́n gbájú mọ́ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run. Àbájáde èyí múnú wa dùn, nítorí pé àwọn ọmọ wa kì í sọ pé ká ṣe àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan.”
Obìnrin kan tí kò lọ́kọ tó ń jẹ́ Janet ń fi ọ̀pọ̀ àkókò kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílẹ̀ Philippines. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ ó máa ń ṣe bó ti mọ, ó ní: “Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé, gbogbo ohun tí mo bá rí kọ́ ni mò ń rà, mo sì máa ń ṣọ́wó ná. Dípò kí n lọ sí ilé ìtajà ńláńlá tí ọjà wọ́n gbówó lórí, mo máa ń wá àwọn ilé ìtajà kéékèèké tí ọjà wọn kò gbówó lórí. Kò sídìí tí màá fi lọ máa ra ọjà tó wọ́n nígbà tí mo lè rí ọjà náà rà lówó pọ́ọ́kú. Mi ò kì í ra ohun kan láìjẹ́ pé mo ti ronú nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀.” Janet rí ọgbọ́n tó wà nínú títọ́jú owó pa mọ́ fún nǹkan tó fẹ́ rà. Ó sọ pé: “Tí mo bá ní owó tó ṣẹ́ kù sí mi lọ́wọ́, ì bá tiẹ̀ jẹ́ owó táṣẹ́rẹ́, mo máa ń tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ kí n lè rí nǹkan lò nígbà tí ìnáwó pàjáwìrì bá yọjú.”
Nígbà tí Eric tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú ń sọ nípa káàdì téèyàn lè fi rajà láwìn, ó ní: “Mo ti sọ pé mi ò ní máa lo káàdì yìí, àyàfi tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀.” Diosdado náà sọ pé: “Kó má bàa jẹ́ pé gbogbo nǹkan tí mo bá rí ni mo máa rà, ńṣe ni mo máa ń fi káàdì tí mo fi ń rajà láwìn sílẹ̀ ní ibi iṣẹ́ mi.”
Ìwọ Náà Lè Ṣe Bó O Ti Mọ
Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé, yàtọ̀ sí pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, ó tún fúnni láwọn ìlànà tó lè ṣe wá láǹfààní nípa ohun ti ara. (Òwe 2:6; Mátíù 6:25-34) Tó o bá ń lo àwọn ìlànà tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tí wọ́n ti jàǹfààní látinú àwọn ìlànà náà, ìwọ náà á lè ṣe bó o ti mọ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àníyàn àti ìbànújẹ́ tó ń bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn fínra lónìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
‘A jíròrò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ iye tí a ó máa ná’
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
‘Dípò ká wọ ọkọ̀ èrò lọ sí ìpàdé, ẹsẹ̀ la fi ń rìn ní báyìí’
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
‘Mi ò kì í ra ohun kan láìjẹ́ pé mo ti ronú nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀’