ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g19 No. 3 ojú ìwé 10-11
  • Gbígbọ́ Bùkátà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbígbọ́ Bùkátà
  • Jí!—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • NÍ ÈTÒ TÓ DÁA
  • ṢỌ́RA FÁWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ KÓ BÁ Ẹ
  • ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìṣòro Owó Tàbí Tí Mo Bá Jẹ Gbèsè?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Ṣe Bó O Ti Mọ—Bí O Ṣe Lè Ṣe É
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • 2 | Ṣe Ohun Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Àtijẹ Àtimu Nira Fún Ẹ
    Jí!—2022
Àwọn Míì
Jí!—2019
g19 No. 3 ojú ìwé 10-11
Àwọn òṣìṣẹ́ nílé iṣẹ́ káfíńtà

Gbígbọ́ Bùkátà

Ìlànà Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti dín ìṣòro àtirówó gbọ́ bùkátà kù.

NÍ ÈTÒ TÓ DÁA

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere, àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.”​—Òwe 21:5.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ó yẹ kó o sapá gidigidi láti máa tẹ̀ lé ètò ìnáwó tó o bá ṣe. Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í náwó, rí i dájú pé o ṣètò bó o ṣe máa ná an. Máa rántí pé kì í ṣe gbogbo ohun tó o fẹ́ lo lè rà lẹ́ẹ̀kan náà. Torí náà, á dáa kó o fọgbọ́n ná owó ẹ.

OHUN TÓ O LÈ ṢE:

  • Máa ṣọ́wó ná. Kọ gbogbo ohun tó o fẹ́ rà sílẹ̀, kó o sì pín wọn sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Lẹ́yìn náà, pín owó tó o fẹ́ ná sí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan. Tó o bá ná ju iye tó o pín sórí ìsọ̀rí kan lọ, yọ díẹ̀ lára owó tó o pín sórí ìsọ̀rí míì láti fi dí i. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ná ju iye tó o rò lọ sórí epo mọ́tò rẹ, yọ lára owó tó o fẹ́ ná sórí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan láti fi dí i, bóyá kó o mú lára owó tó o fẹ́ fi ṣe fàájì.

  • Má ṣe jẹ gbèsè. Tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti má ṣe yáwó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. Ńṣe ni kó o sapá láti tọ́jú owó pa mọ́ fúnra ẹ títí tó fi máa pé iye tó o fẹ́ fi ra ohun tó o nílò. Tó o bá gbàwìn ọjà, tètè wá bó o ṣe máa sanwó ọjà náà, tó bá sì jẹ́ pé ńṣe lo yáwó, tètè san owó náà pa dà kí èlé tó bẹ̀rẹ̀ sí í gorí ẹ̀. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àkókò tó o dá ti kọjá, ṣe ìwé fún ẹni tó o jẹ ní gbèsè láti sọ bí wàá ṣe máa san owó náà, kó o sì rí i pé o mú àdéhùn rẹ ṣẹ.

    Ìwádìí kan sọ pé àwọn tó máa ń fi káàdì rajà àwìn máa ń náwó púpọ̀ tí wọ́n bá ń ràjà. Torí náà, o ní láti máa kó ara ẹ níjàánu gan-an tó o bá nírú káàdì bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́.

ṢỌ́RA FÁWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ KÓ BÁ Ẹ

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù, tó bá dìgbà ìkórè, á máa tọrọ torí pé kò ní nǹkan kan.”​—Òwe 20:4.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ìṣẹ́ ló máa ń gbẹ̀yìn ọ̀lẹ. Torí náà, máa ṣiṣẹ́ kára, kó o sì máa ṣọwó ná kó o lè lówó tí wàá ná lẹ́yìnwá ọ̀la.

OHUN TÓ O LÈ ṢE:

  • Ṣiṣẹ́ kára. Tó o bá gbájú mọ́ṣẹ́, tó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, ọgá ẹ á fẹ́ràn ẹ, kò sì ní fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀.

  • Jẹ́ olóòótọ́. Má ṣe ja ọ̀gá ẹ lólè. Ìwà àìṣòótọ́ lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́, kó sì mú kó ṣòro fún ẹ láti ríṣẹ́ míì.

  • Má ṣe jẹ́ olójúkòkòrò. Tó o bá ń lépa owó lójú méjéèjì, o ò ní gbádùn ara ẹ, àjọṣe ẹ pẹ̀lú àwọn míì sì lè bà jẹ́. Máa rántí pé ẹ̀mí ju owó lọ.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ

Ọkùnrin kan ń ka Bíbélì lórí ìkànnì

Ka Bíbélì lórí ìkànnì, ó wà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè lórí jw.org

MÁ ṢE FI ÀKÓKÒ ÀTI OWÓ ṢÒFÒ LÓRÍ OHUN TÍ KÒ NÍ LÁÁRÍ.

“Ọ̀mùtí àti alájẹkì yóò di òtòṣì, ìtòògbé yóò sì sọni di alákìísà.”—ÒWE 23:21.

MÁ ṢE MÁA RONÚ JÙ NÍPA OWÓ.

“Ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.”—MÁTÍÙ 6:25.

MÁ ṢE ÌLARA ẸNIKẸ́NI.

“Onílara èèyàn ń wá bó ṣe máa di olówó, kò mọ̀ pé òṣì máa ta òun.”—ÒWE 28:22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́