ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w13 3/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Rán Jésù Wá Sí Ayé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ṣé Ọmọ Ọlọ́run Ni Jésù Lóòótọ́?
    Jí!—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
w13 3/1 ojú ìwé 16
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí nìdí tí wọ́n fi ń pe Jésù ní Ọmọ Ọlọ́run?

Kì í ṣe pé Ọlọ́run ní ìyàwó tó ń bímọ fún un. Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo láyé àti lọ́run. Ó dá àwa èèyàn lọ́nà tí a fi lè fìwà jọ ọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe èèyàn àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run dá, ìyẹn Ádámù, ní “ọmọkùnrin Ọlọ́run.” Lọ́nà kan náà, Bíbélì pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run” nítorí pé Ọlọ́run dá a lọ́nà táá fi fìwà jọ òun pátápátá.—Ka Lúùkù 3:38; Jòhánù 1:14, 49.

Ìgbà wo ni Ọlọ́run dá Jésù?

Ọlọ́run ti dá Jésù kí ó tó dá Ádámù. Kódà lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Jésù, òun ni Ọlọ́run lò láti fi dá gbogbo nǹkan yòókù, títí kan àwọn ańgẹ́lì. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jésù ní “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” tí Ọlọ́run dá.—Ka Kólósè 1:15, 16.

Ẹ̀dá ẹ̀mí tó ń gbé ní ọ̀run ni Jésù tẹ́lẹ̀, kí wọ́n tó bí i ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tí ó tó àkókò, Ọlọ́run fi ẹ̀mí Jésù ní ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ Màríà ní ayé, kí Màríà lè bí i gẹ́gẹ́ bí èèyàn.—Ka Lúùkù 1:30-32; Jòhánù 6:38; 8:23.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí wọ́n bí Jésù ní èèyàn sí ayé? Ipa pàtàkì wo ni Jésù kó láti mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ? Inú Bíbélì ni o ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí. Àwọn ìdáhùn náà á mú kí òye rẹ nípa ohun tí Ọlọ́run àti Jésù ti ṣe fún ọ pọ̀ sí i, wàá sì túbọ̀ mọyì rẹ̀.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 4 nínú ìwé yìí Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́