ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 160
  • Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ǹjẹ́ Jésù ti gbé ọ̀run kí wọ́n tó bí i sáyé?
  • Kí ni Jésù ń ṣe kó tó wá sáyé?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ṣé Ọmọ Ọlọ́run Ni Jésù Lóòótọ́?
    Jí!—2006
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 160
Jésù ń gbàdúrà sí Baba rẹ̀ ọ̀run

Kí Nìdí Tí A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì máa ń pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run” (Jòhánù 1:49) Ọ̀rọ̀ náà, “Ọmọ Ọlọ́run” fi hàn pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo tàbí Orísun gbogbo ẹ̀mí, títí kan ti Jésù. (Sáàmù 36:9; Ìfihàn 4:11) Bíbélì kò kọ́ni pé Ọlọ́run ní bàbá Jésù bí ìgbà téèyàn bímọ.

Bíbélì tún pe àwọn áńgẹ́lì ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́”. (Jóòbù 1:6) Bíbélì tún sọ pé èèyàn àkọ́kọ́, Ádámù jẹ́ “Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Àmọ́, torí pé Jésù jẹ́ àkọ́bí nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá àti pé òun nìkan ni Ọlọ́run dá ní tààràtà, Bíbélì pe Jésù ní àkọ́kọ́ Ọmọ Ọlọ́run.

  • Ǹjẹ́ Jésù ti gbé ọ̀run kí wọ́n tó bí i sáyé?

  • Kí ni Jésù ń ṣe kó tó wá sáyé?

Ǹjẹ́ Jésù ti gbé ọ̀run kí wọ́n tó bí i sáyé?

Bẹ́ẹ̀ ni. Jésù jẹ́ ẹ̀mí ní ọ̀run kí wọ́n tó bí i sáyé ní èèyàn. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun “sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.”​—Jòhánù 6:38; 8:23.

Ọlọ́run dá Jésù kó tó dá ohunkóhun míì. Bíbélì sọ nípa Jésù pé:

  • “Òun ni . . . àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.”​—Kólósè 1:15.

  • Òun ni “ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.”​—Ìfihàn 3:14.

Àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa “ẹni tó ti wà láti ìgbà àtijọ́, láti àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́” ṣẹ sí Jésù lára​—Míkà 5:2; Mátíù 2:4-6.

Kí ni Jésù ń ṣe kó tó wá sáyé?

Ó wà ní ipò gíga ní ọ̀run. Jésù sọ nípa ipò yìí nígbà tó ń gbàdúrà, ó ní: “Bàbá ṣe mí lógo . . . pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà”​—Jòhánù 17:5.

Ó ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ láti dá ohun gbogbo yòókù. Jésù ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run “gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.” (Òwe 8:30) Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ipasẹ̀ rẹ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé.”​—Kólósè 1:16.

Ọlọ́run lo Jésù láti dá ohun gbogbo yòókù. Ara àwọn ohun náà ni gbogbo àwọn áńgẹ́lì yòókù títí kan ayé àti ọ̀run. (Ìfihàn 5:11) Láwọn ọ̀nà kan, irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run àti Jésù dà bí ti ayàwòrán ilé àti kọ́lékọ́lé. Ayàwòrán ilé yóò yàwòrán bí ilé kan ṣe máa rí, kọ́lékọ́lé á kọ́ ilé tó rí nínú àwòrán náà.

Jésù ni Ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí a sọ nípa ìgbésí ayé Jésù kó tó wá sáyé, Bíbélì pe Jésù ní “Ọ̀rọ̀ náà.” (Jòhánù 1:1) Dájúdájú, èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run lo Ọmọ rẹ̀ láti sọ àwọn nǹkan àti ẹ̀kọ́ fún àwọn ẹ̀dá yòókù tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí.

Ó jọ pé Jésù tún ṣe Agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láyé. Ó ṣeéṣe kí Ọlọ́run lo Jésù tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ nígbà tó ń sọ àwọn nǹkan fún Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ó lè jẹ́ Jésù ni áńgẹ́lì tó darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ nínú aginjù, ó sì lè jẹ́ ohùn rẹ̀ ni wọ́n ṣègbọràn sí nígbà náà​—Ẹ́kísódù 23:20-23.a

a Kìí ṣe “Ọ̀rọ̀ náà” nìkan ni áńgẹ́lì tí Ọlọ́run gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lo àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ áńgẹ́lì tí wọn kì í ṣe àkọ́bí rẹ̀ láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ní Òfin rẹ̀ ​—Ìṣe 7:53; Gálátíà 3:19; Hébérù 2:2, 3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́