ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 12/15 ojú ìwé 22-26
  • Bá A Ṣe Lè La Òpin Ayé Ògbólógbòó Yìí Já Pa Pọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè La Òpin Ayé Ògbólógbòó Yìí Já Pa Pọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • WỌ́N DÚRÓ TI ARA WỌN
  • Ẹ WÀ NÍ ÌṢỌ̀KAN BÍ ỌJỌ́ JÈHÓFÀ ṢE Ń SÚN MỌ́LÉ
  • “Ẹ̀YÀ ARA TÍ Ó JẸ́ TI ARA WA LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ”
  • BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ ‘Ẹ̀YÀ ARA TI ARA WA LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ NI WÁ’
  • Ìṣọ̀kan Àwa Kristẹni Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìdílé Jèhófà Ń Gbádùn Ìṣọ̀kan Ṣíṣeyebíye
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìṣọ̀kan La Fi Ń dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Pa Ìṣọ̀kan Mọ́ Ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Wọ̀nyí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 12/15 ojú ìwé 22-26

Bá A Ṣe Lè La Òpin Ayé Ògbólógbòó Yìí Já Pa Pọ̀

“Ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.”​—ÉFÉ. 4:25.

WÁ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ?

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ ṣọ́ra fún, kí sì nìdí?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká “so pọ̀ nínú ìṣọ̀kanṣoṣo”?

  • Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o fẹ́ wà lára “ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì”?

1, 2. Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, yálà ọmọdé tàbí àgbàlagbà?

ṢÉ Ọ̀DỌ́ ni ẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé a mọrírì bó o ṣe wà lára ìjọ Jèhófà tó wà kárí ayé. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ọ̀dọ́ ló pọ̀ jù nínú àwọn tó ń ṣèrìbọmi. Inú wa dùn gan-an ni bá a ṣe ń rí àìmọye àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ti pinnu láti máa sin Jèhófà!

2 Ǹjẹ́ o fẹ́ràn kó o máa wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ bíi tìẹ? Ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí téèyàn bá wà láàárín àwọn ojúgbà rẹ̀, inú ẹni sábà máa ń dùn yàtọ̀. Àmọ́ o, yálà ọ̀dọ́ ni wá tàbí àgbàlagbà, Ọlọ́run fẹ́ ká máa jọ́sìn òun pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan láìka ipò ìgbésí ayé wa sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:​3, 4) Ìwé Ìṣípayá 7:9 ṣàpèjúwe àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run pé wọ́n jáde wá láti inú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.”

3, 4. (a) Irú ẹ̀mí wo ló wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́ lóde òní? (b) Báwo ni Éfésù 4:25 ṣe lè mú ká ṣọ́ra fún irú ẹ̀mí yẹn?

3 Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà láàárín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà àtàwọn ọ̀dọ́ inú ayé yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò sin Jèhófà ló jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ohun tí wọ́n bá ṣáà ti fẹ́ ló ṣe pàtàkì jù sí wọn. Àwọn aṣèwádìí kan pe àwọn ọ̀dọ́ yìí ní ìran tí kì í ro ti ẹlòmíì mọ́ tiwọn. Ìmúra wọn àti ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wọn fi hàn pé wọn kò ka àwọn àgbàlagbà sí, wọ́n máa ń sọ pé àwọn àgbàlagbà “ò rí ọ̀ọ́kán.”

4 Ibi gbogbo tá a bá yíjú sí la ti máa rí i pé àwọn èèyàn ní irú èrò yìí. Torí náà, àwọn ọ̀dọ́ tó ń sin Jèhófà rí i pé àwọn gbọ́dọ̀ sapá gidigidi káwọn má bàa ní irú èrò yìí àti pé àwọn ní láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn àgbàlagbà wò wọ́n. Kódà, Pọ́ọ̀lù rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí òun gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún kìíní níyànjú pé kí wọ́n ṣọ́ra fún “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn,” èyí tí wọ́n ti “rìn ní àkókò kan rí” nínú rẹ̀. (Ka Éfésù 2:​1-3.) A gbóríyìn fáwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí i pé ó yẹ́ káwọn ṣọ́ra fún irú ẹ̀mí yẹn, tí wọ́n sì ń sìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn ará. Èyí bá ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ mu pé “ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.” (Éfé. 4:25) Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ayé yìí, ó máa túbọ̀ ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe nǹkan pa pọ̀. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan látinú Bíbélì tó máa jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká dúró ti ara wa, ká sì wà níṣọ̀kan.

WỌ́N DÚRÓ TI ARA WỌN

5, 6. Báwo ni ìtàn Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé ó yẹ ká dúró ti ara wa?

5 Láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, inú Jèhófà dùn láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n pawọ́ pọ̀ ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní, yálà ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára irú àpẹẹrẹ yìí ni ti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì.

6 Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ wà nínú ewu torí pé Ọlọ́run fẹ́ pa ìlú Sódómù tí wọ́n ń gbé run. Áńgẹ́lì Ọlọ́run rọ Lọ́ọ̀tì pé kó jáde nílùú náà, kó sì sá lọ sí àgbègbè ilẹ̀ olókè ńláńlá, ó sọ pé: “Sá àsálà fún ọkàn rẹ!” (Jẹ́n. 19:​12-22) Lọ́ọ̀tì ṣègbọràn, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì náà sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n kúrò nílùú náà. Ó ṣeni láàánú pé, àwọn tó sún mọ́ wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Lójú àwọn àfẹ́sọ́nà àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì, ńṣe ni bàbá àgbàlagbà yẹn “dà bí [ẹni] tí ń ṣàwàdà.” Àmọ́, ẹ̀mí wọn lọ sí i. (Jẹ́n. 19:14) Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í nìkan ló là á já.

7. Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà níṣọ̀kan nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì?

7 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ míì. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọn kò pín ara wọn sí àwùjọ kéékèèké, kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan wá máa dá lọ. Bákan náà, nígbà tí Mósè “na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun” tí Jèhófà sì pín òkun pupa sí méjì, Mósè nìkan kọ́ ló gba inú òkun náà kọjá, kì í sì í ṣe òun àti ìwọ̀nba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ló lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ìjọ àwọn èèyàn náà ló gbà á kọjá torí pé Jèhófà dáàbò bò wọ́n. (Ẹ́kís. 14:​21, 22, 29, 30) Wọ́n fi hàn pé àwọn wà níṣọ̀kan, “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” ló sì tẹ̀ lé wọn, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dúró tì wọ́n. (Ẹ́kís. 12:38) Kò tiẹ̀ ṣeé ronú kàn rárá pé káwọn bíi mélòó kan, bóyá kí àwọn ọ̀dọ́ kan ya ara wọn sọ́tọ̀, kí wọ́n sì dorí kọ ọ̀nà ibòmí ì tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ló máa jẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì wá kúrò lábẹ́ ààbò Jèhófà.​—1 Kọ́r. 10:1.

8. Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe fi hàn pé àwọn wà níṣọ̀kan nígbà ayé Jèhóṣáfátì?

8 Nígbà ayé Jèhóṣáfátì Ọba, àwọn ọ̀tá búburú kan tí wọ́n jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” láti àwọn àgbègbè tó yí àwọn èèyàn Ọlọ́run ká wá gbógun jà wọ́n. (2 Kíró. 20:​1, 2) Ó dùn mọ́ni pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò gbára lé agbára tára wọn láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni wọ́n yíjú sí. (Ka 2 Kíróníkà 20:​3, 4.) Olúkúlùkù wọn ò kàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó rò pé ó tọ́ tàbí nǹkan tó wù ú. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ti Júdà wà lórí ìdúró níwájú Jèhófà, àní àwọn ọmọ wọn kéékèèké, àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn pàápàá.” (2 Kíró. 20:13) Àtọmọdé àtàgbà wọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, ó sì dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. (2 Kíró. 20:​20-27) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni èyí jẹ́ nípa bó ṣe yẹ káwọn èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìṣòro!

9. Kí ni ìwà àti ìṣe àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni kọ́ wa nípa ìṣọ̀kan?

9 Àwọn èèyàn mọ àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni pé wọ́n máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe di Kristẹni, wọ́n fi ara wọn “fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì àti ṣíṣe àjọpín pẹ̀lú ara wọn, nínú jíjẹ oúnjẹ àti nínú àdúrà.” (Ìṣe 2:42) Ó túbọ̀ wá hàn kedere pé wọ́n wà níṣọ̀kan pàápàá nígbà tí wọ́n dojú kọ inúnibíni, ìgbà yẹn sì ni wọ́n nílò ara wọn gan-⁠an ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Ìṣe 4:​23, 24) Ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà pé ó ṣe pàtàkì pé ká dúró ti àwọn ará wa nígbà ìṣòro?

Ẹ WÀ NÍ ÌṢỌ̀KAN BÍ ỌJỌ́ JÈHÓFÀ ṢE Ń SÚN MỌ́LÉ

10. Ìgbà wo ló máa ṣe pàtàkì gan-⁠an pé ká wà ní ìṣọ̀kan?

10 Àkókò tí nǹkan máa burú jáì fún ìran èèyàn ti sún mọ́lé. Wòlíì Jóẹ́lì ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ “ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù.” (Jóẹ́lì 2:​1, 2; Sef. 1:14) Àmọ́, àkókò láti wà níṣọ̀kan nìyẹn máa jẹ́ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ẹ rántí ohun tí Jésù sọ, ó ní: “Gbogbo ìjọba tí ó bá pínyà sí ara rẹ̀ a máa wá sí ìsọdahoro.”​—Mát. 12:25.

11. Ìfiwéra wo la rí nínú Sáàmù 122:​3, 4 tó kan àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

11 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan ní àkókò tí wàhálà ń bọ̀ lórí ètò nǹkan ìsinsìnyí. A lè fi ìṣọ̀kan tẹ̀mí tó yẹ kó wà láàárín wa wé bí wọ́n ṣe máa ń kọ́lé sún mọ́ra ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì. Àwọn ilé náà máa ń sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí débi pé onísáàmù kan ṣàpèjúwe Jerúsálẹ́mù pé ó jẹ́ “ìlú ńlá tí a ti so pọ̀ nínú ìṣọ̀kanṣoṣo.” Èyí mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó ń gbé ìlú náà láti ran ara wọn lọ́wọ́ àti láti dáàbò bo ara wọn. Bákan náà, bí ilé wọn ṣe sún mọ́ra tún lè jẹ́ àpẹẹrẹ bí gbogbo orílẹ̀-èdè náà ṣe máa ń wà ní ìṣọ̀kan nípa tẹ̀mí nígbà tí gbogbo “àwọn ẹ̀yà Jáà” bá pé jọ láti jọ́sìn Jèhófà. (Ka Sáàmù 122:​3, 4.) Lónìí àti láwọn àkókó lílekoko tó ń bọ̀, àwa náà ní láti “so pọ̀ nínú ìṣọ̀kanṣoṣo.”

12. Kí ló máa jẹ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ ìjà tí “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” máa gbé ko àwọn èèyàn Ọlọ́run?

12 Kí nìdí tó fi máa ṣe pàtàkì pé ká “so pọ̀” tàbí wà níṣọ̀kan lákòókò yẹn? Ìsíkíẹ́lì orí 38 sọ tẹ́lẹ̀ pé “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Kò yẹ ká jẹ́ kí ohunkóhun fa ìpínyà láàárín wa nígbà yẹn. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ké gbàjarè sí ayé Sátánì pé kó ràn wá lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa fẹ́ sún mọ́ àwọn ará wa pẹ́kípẹ́kí nígbà yẹn. Àmọ́ ṣá o, ti pé a wà lára àwùjọ kan kọ́ ló máa pinnu bóyá a máa là á já. Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ máa pa àwọn tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà mọ́ láàyè la àkókò ìdààmú yẹn já. (Jóẹ́lì 2:32; Mát. 28:20) Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti rò pé àwọn tí kò kọ́wọ́ ti ìṣọ̀kan tó wà láàárín agbo Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó ṣáko lọ máa là á já bí?​—Míkà 2:12.

13. Àwọn ẹ̀kọ́ wo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run lè kọ́ látinú àwọn ohun tá a ti jíròrò?

13 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ǹjẹ́ o rí i kedere báyìí pé ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ tó o bá ń ṣe bíi tàwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe nǹkan tó wù wọ́n? A ti ń sún mọ́ àkókò tá a máa ní láti ran ara wa lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní-kejì. Èyí sì kan gbogbo wa pátá, àtèwe-àtàgbà! Torí náà, ó yẹ ká kọ́ bí a ó ṣe máa ṣe nǹkan pa pọ̀ báyìí, ká lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wa, èyí sì máa ṣe pàtàkì gan-an lọ́jọ́ iwájú.

“Ẹ̀YÀ ARA TÍ Ó JẸ́ TI ARA WA LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ”

14, 15. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń dá àtàgbà àtọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ lóde òní? (b) Ìmọ̀ràn Jèhófà wo ló máa fún wa níṣìírí láti wà níṣọ̀kan?

14 Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa “sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sef. 3:​8, 9) Ó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè kúnjú ìwọ̀n lójú rẹ̀ nígbà tó bá mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run? Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kí ó “kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi.” (Ka Éfésù 1:​9, 10.) Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá láyé àti lọ́run wà ní ìṣọ̀kan, ó sì máa ṣe èyí láṣeyọrí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, ǹjẹ́ èyí mú kí o rí ìdí tó fi yẹ kó o máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan pẹ̀lú ètò Jèhófà?

15 Jèhófà ń kọ́ wa ká lè wà ní ìṣọ̀kan báyìí, ó sì fẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wa títí láé. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa léraléra pé ká “ní aájò kan náà fún ara [wa]” lẹ́ni kìíní-kejì, ká “ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì,” ká máa “tu ara [wa] nínú lẹ́nì kìíní-kejì,” ká sì “máa gbé ara [wa] ró lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Kọ́r. 12:25; Róòmù 12:10; 1 Tẹs. 4:18; 5:11) Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni àwọn Kristẹni, èyí sì lè jẹ́ kó nira fún wa láti wà níṣọ̀kan, torí náà, a gbọ́dọ̀ fi kọ́ra láti máa “dárí ji ara [wa] fàlàlà.”​—Éfé. 4:32.

16, 17. (a) Kí ni ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń ṣe ìpàdé ìjọ? (b) Kí làwọn ọ̀dọ́ lè kọ́ lára Jésù nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́?

16 Jèhófà tún ṣètò pé ká máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ká lè kọ́ bí a ó ṣe máa dúró ti ara wa. A mọ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú ìwé Hébérù 10:​24, 25 dáadáa. Ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń ṣe ìpàdé ni pé, ó ń jẹ́ kí a “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Àmọ́, ó ṣe kedere pé Jèhófà ṣètò àwọn ìpàdé náà ká lè “máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí [a] ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”

17 Nígbà tí Jésù wà lọ́dọ̀ọ́, ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti bó ṣe mọyì ètò tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yìí. Lọ́mọ ọdún méjìlá, ó tẹ̀ lé àwọn òbí rẹ̀ lọ sí àpéjọ ńlá tí wọ́n ti lọ jọ́sìn Jèhófà. Nígbà tó yá, wọn ò rí i mọ́, àmọ́ kì í ṣe pé ó kàn ṣeré lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bíi tiẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù àti Màríà rí i níbi tó ti ń jíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn olùkọ́ nínú tẹ́ńpìlì.​—Lúùkù 2:​45-47.

18. Báwo ni àdúrà wa ṣe lè túbọ̀ jẹ́ ká wà ní ìṣọ̀kan?

18 Ní àfikún sí ìfẹ́ tó yẹ ká ní fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì àti àwọn ìpàdé tó máa jẹ́ ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan, a lè máa gbàdúrà fún ara wa. Tá a bá sọ ní pàtó ohun tá a fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún àwọn ará wa, ńṣe nìyẹn ń rán wa létí pé ó yẹ kí ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún. Àwọn àgbàlagbà lè máa ṣe èyí, kódà ohun tó yẹ kí wọ́n máa ṣe nìyẹn, àmọ́ kì í ṣe àwọn nìkan o. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ǹjẹ́ o máa ń lo àwọn ọ̀nà yìí kó o lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kó han gbangba pé o kì í ṣe apá kan ayé ògbólógbòó yìí nígbà tó bá pa run.

[Aworan oju iwe 25]

Gbogbo wa le gbadura fawon ara (Wo ipinro 18)

BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ ‘Ẹ̀YÀ ARA TI ARA WA LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ NI WÁ’

19-21. (a) Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà fi han pé a jẹ́ ‘ẹ̀yà ara ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì’? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan. (b) Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ nínú ohun táwọn ará kan ṣe nígbà tí àjálù ṣẹlẹ̀?

19 Ní báyìí, àwọn èèyàn Jèhófà ń fi ìlànà tó wà nínú Róòmù 12:5 sílò nígbèésí ayé wọn, ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: ‘Ẹ̀yà ara ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.’ A máa ń rí ẹ̀rí èyí nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní oṣù December ọdún 2011, ìjì lílé kan fa omíyalé ní erékùṣù kan tí wọ́n ń pè ní Mindanao, ní orílẹ̀-èdè Philippines. Lóru ọjọ́ kan ṣoṣo, ó ju ọ̀kẹ́ méjì [40,000] ilé tí omi bò mọ́lẹ̀, títí kan ọ̀pọ̀ ilé àwọn ará wa. Àmọ́, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè náà sọ pé, “kódà kí ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ lákòókò àjálù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn, àwọn ará tó wà lágbègbè náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi nǹkan ránṣẹ́.”

20 Bákan náà, nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ tó lágbára fa ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Japan, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ló pàdánù àwọn ohun ìní wọn. Ẹlòmíì ò ní nǹkan kan mọ́ rárá. Bí àpẹẹrẹ, ilé Yoshiko bá ìsẹ̀lẹ̀ náà lọ, ó ń gbé ní nǹkan bí ogójì [40] kìlómítà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó sọ pé: “Ẹnu yà wá láti rí alábòójútó àyíká wa àtàwọn arákùnrin míì tí wọ́n wá wò wá lọ́jọ́ kejì ìsẹ̀lẹ̀ náà.” Ó rẹ́rìn-⁠ín, ó wá sọ pé: “A mọrírì rẹ̀ gan-⁠an pé àwọn ìjọ fún wa ní ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n fún wa ní oríṣiríṣi aṣọ, bàtà, báàgì àti aṣọ téèyàn ń wọ̀ sùn.” Ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ lákòókò àjálù sọ pé: “Gbogbo àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè Japan ló ń ṣe bí ọmọ ìyá, wọ́n ń ran ara wọn lọ́wọ́. Kódà, àwọn ará wá láti ìyànníyàn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti wá ṣèrànwọ́. Nígbà tá a bi wọ́n pé kí ló mú kí wọ́n rìnrìn àjò tó jìn tó bẹ́ẹ̀, wọ́n fèsì pé, ‘Ọ̀kan náà ni wá pẹ̀lú àwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè Japan, a sì rí i pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ wa.’” Ǹjẹ́ kò wú ẹ lórí láti wà lára ètò kan tí kò fọ̀rọ̀ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ṣeré? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà dùn gan-an láti rí i pé àwọn èèyàn rẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan.

21 Bá a ṣe wà níṣọ̀kan yìí máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé àwa àtàwọn ará wa máa pawọ́ pọ̀ kojú àwọn ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, bá ò tiẹ̀ láǹfààní láti kàn sáwọn ará wa kan láwọn apá ibì kan láyé. Kódà, bá a ṣe wà níṣọ̀kan yìí ń múra wa sílẹ̀ de àwọn àkókò lílekoko tó ṣeé ṣe kó dé bá wa bí ètò ògbólógbòó yìí ṣe ń kógbá sílé. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Fumiko, tí ìjì lílé tó jà ní orílẹ̀-èdè Japan ba nǹkan ìní rẹ̀ jẹ́ sọ pé: “Òpin ti sún mọ́lé gan-an. A ní láti máa bá a nìṣó láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́ bá a ṣe ń retí àkókò náà tí kò ní sí àjálù mọ́.”

22. Àǹfààní tó wà pẹ́ títí wo ló máa yọrí sí táwa Kristẹni bá wà ní ìṣọ̀kan?

22 Àtọmọdé àtàgbà tó bá ń sapá báyìí láti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará ń múra sílẹ̀ kí wọ́n lè la ìparun ètò nǹkan burúkú yìí tí kò sí níṣọ̀kan já. Àmọ́, bíi ti àtẹ̀yìnwá, Ọlọ́run wa yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. (Aísá. 52:​9, 10) Máa rántí nígbà gbogbo pé o lè wà lára àwọn tí Ọlọ́run máa dá nídè tó o bá ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti wà lára àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan. Ohun míì tó tún lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká túbọ̀ mọyì àwọn ohun tá a ti rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. A máa jíròrò kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́