ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 12/1 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Òtítọ́ Ṣì Lérè?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àwọn Kristẹni Ń jọ́sìn Ní Ẹ̀mí Àti Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Fífarawé Ọlọ́run Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Báwo La Ṣe Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 12/1 ojú ìwé 16

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ṣé a lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run?

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù fún ọkùnrin tó jókòó sórí àga

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fẹ́ ká mọ òtítọ́? Ka Jòhánù 17:3

Ọlọ́run bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láyé àtijọ́. Ó lo ẹ̀mí mímọ́ tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ láti fi èrò rẹ̀ sọ́kàn àwọn tó kọ Bíbélì. (2 Pétérù 1:​20, 21) A lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run tá a bá ń ka Bíbélì.​—Ka Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16.

Ọlọ́run lo Bíbélì láti ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ara rẹ̀ fún wa. Ó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi dá àwa èèyàn, ohun tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú àti bó ṣe fẹ́ ká máa gbé ìgbésí ayé wa. (Ìṣe 17:​24-27) Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa òun.​—Ka 1 Tímótì 2:​3, 4.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa ń tẹ́wọ́ gba àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́, ó sì rán Jésù ọmọ rẹ̀ wá sáyé kó lè kọ́ wa ní òtítọ́. Fún ìdí yìí, àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ máa ń wá sọ́dọ̀ Jésù. (Jòhánù 18:37) Irú àwọn tí Ọlọ́run fẹ́ kó máa jọ́sìn òun gan-an nìyẹn.​—Ka Jòhánù 4:​23, 24.

Sátánì Èṣù kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ Ọlọ́run nípa kíkọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí kì í ṣe òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:​3, 4) Àwọn tí kò bá nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ máa ń gba àwọn ẹ̀kọ́ èké yìí gbọ́. (Róòmù 1:25) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó lọ́kàn rere ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí sì tí mú kí wọ́n mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.​—Ka Ìṣe 17:11.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 1 nínú ìwé yìí. Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́