ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 12/1 ojú ìwé 15
  • Kí Ló Burú Nínú Ọdún Kérésì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Burú Nínú Ọdún Kérésì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Kérésìmesì
    Jí!—2011
  • Kérésìmesì—Èé Ṣe Táwọn Ará Ìlà Oòrùn Ayé Pàápàá Fi Ń Ṣe É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 12/1 ojú ìwé 15

ÀWỌN ÒǸKÀWÉ WA BÉÈRÈ PÉ . . .

Kí Ló Burú Nínú Ọdún Kérésì?

Ọjọ́ pẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni kárí ayé ti ń fi ọdún Kérésì ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn àṣà tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ọdún Kérésì máa ń mú káwọn èèyàn ronú nípa bó sẹ tan mọ́ ìbí Jésù.

Ọ̀kan nínú irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ni Bàbá Kérésì, ìyẹn bàbá oníkùn gbẹ̀ǹdù, onírùngbọ̀n funfun, tó máa ń wọ aṣọ tó pupa fòò. Iléeṣẹ́ tó ń ṣe ohun mímú ẹlẹ́rìndòdò ní Àríwá Amẹ́ríkà lo fi Bàbá Kérésì polówó ọjà ní ọdún 1931. Láwọn ọdún 1950, àwọn kan láti ilẹ̀ Brazil tiẹ̀ gbìyànjú láti fi akọni míì tí wọ́n ń pè ní Grandpa Indian rọ́pò Bàbá Kérésì. Ṣùgbọ́n wọn ò ṣàṣeyọrí torí pé ńṣe ni Bàbá Kérésì lé Grandpa Indian wọlé. Kódà, Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Carlos E. Fantinati sọ pé “Jésù gan-an ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó Bàbá Kérésì nígbà ayẹyẹ December 25.” Àmọ́, ṣé Bàbá Kérésì nìkan ni ohun tó ń kọni lóminú nípa ọdún Kérésì? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká pa dà sí ìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.

Bàbá Kérésì gbé báàgì fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan kọ́ èjìká

Ìwé Encyclopedia Britannica sọ pé “lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún méjì tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀, àwọn Kristẹni kò fara mọ́ ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹnikẹ́ni, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti Jésù.” Kí nìdí? Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn gbà pé àṣà àwọn kèfèrí ni ṣíṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí, kò sì yẹ káwọn lọ́wọ́ nínú rẹ̀ rárá. Kódà, a ò lè rí déètì ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù nínú Bíbélì.

Láìka bí àwọn Kristẹni ìgbàanì ṣe kọ̀ láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù, síbẹ̀ nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì dá ayẹyẹ Kérésì sílẹ̀. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fẹ́ fi ayẹyẹ Kérésì fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra kí ìtẹ̀síwájú lè bá ìjọ wọn. Lára ohun tí kò jẹ́ kí ìjọ Kátólíìkì gbèrú nígbà yẹn ni bí àwọn èèyàn ṣe ń gbádùn àwọn àṣà ẹ̀sìn Róòmù àtàwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe lóṣù December. Ìwé kan tó ń jẹ́ Christmas in America, látọwọ́ Penne L. Restad sọ pé, lọ́dọọdún láti December 17 sí January 1, “ọ̀pọ̀ àwọn ará Róòmù máa ń jẹ àjẹkì, wọ́n á ta tẹ́tẹ́, wọ́n á ṣe àríyá, wọ́n á tún máa sẹ fàájì kiri, wọ́n á sì máa rúbọ sí àwọn òrìṣà wọn.” Ní December 25, àwọn ará Róòmù máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí oòrùn. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì wá fi ayẹyẹ Kérésì sí ọjọ́ yìí kí wọ́n lè fa ojú àwọn ara Róòmù mọ́ra láti máa ṣàjọyọ̀ ìbí Jésù dípò ṣíṣe ọjọ́ ìbí oòrùn. Gerry Bowler wá sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Santa Claus, a Biography pé àwọn àṣà kan náà tí àwọn ará Róòmù fi ń ṣàjọyọ̀ ọjọ́ ìbí oòrùn ni wọn fi ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù.

Èyí fi hàn gbangba pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ni àwọn àṣà Kérésì ti wá. Stephen Nissenbaum wá sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Battle for Christmas pé ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n kàn fún lórúkọ Kristẹni ni Kérésì. Torí náà, ayẹyẹ Kérésì ń tàbùkù sí Ọlọ́run àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Ṣé nǹkan kékeré tá a kàn lè gbójú fò ni? Bíbélì sọ pé: “Àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Bí ẹja gbígbẹ tí kò ṣe é ká, àwọn àṣà Kérésì ti wọ́ wá látilẹ̀ kò sì ní àtúnṣe, ó ti di ohun ‘wíwọ́ tí a kò lè mú tọ́.’​—Oníwàásù 1:15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́