Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀
KÍ LÈRÒ RẸ?
Nǹkan máa ń nira nínú ayé tá a wà yìí. Ǹjẹ́ ibì kan wà tá a ti lè rí ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú?
Bíbélì sọ pé: “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, . . . tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.
Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ń tù wá nínú nígbà ìṣòro.