Ẹ Máa Gbé Èrò Inú Yín Ka Àwọn Nǹkan Ti Òkè
1 Ní sísọ̀rọ̀ nípa ìran tí ó yí wa ká, àti ojú ìwòye rẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The New York Times ti December 31, 1994, sọ pé: “Wọ́n ń bẹ̀rù nípa ọjọ́ ọ̀la. Wọ́n ń bẹ̀rù rẹ̀ ní ti iṣẹ́, ní ti àrùn, ní ti ọrọ̀ ajé, ní ti ipò inú ayé.” Ibi yòówù kí a yíjú sí, àwọn ènìyàn kò ní ìdánilójú nípa ìgbésí ayé. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa ń mú kí a bá àwọn ènìyàn tí ó nímọ̀lára lọ́nà yìí pàdé lójoojúmọ́. Bí a tilẹ̀ ń dojú kọ irú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ, ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú àwọn ìlérí tí ó dájú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti ní ojú ìwòye yíyàtọ̀ pátápátá nípa ìgbésí ayé àti ọjọ́ ọ̀la aráyé.—Isa. 65:13, 14, 17.
2 Ojú ìwòye ọjọ́ ọ̀la yóò dára àti ti ìrètí dídájú tí a ní, ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn olótìítọ́ ọkàn fetí sílẹ̀ sí ìhìn iṣẹ́ tí a ń mú tọ̀ wọ́n lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sorí kọ́, tí a sì tẹ̀ lórí ba, ń rí i pé bíbá wa sọ̀rọ̀ máa ń tu àwọn nínú. Nítorí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n ń gbọ́, àwọn kan gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wa. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ènìyàn lè fẹ́ kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòrò wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè lo àkókò díẹ̀ láti tẹ́tí sí àwọn àníyàn tí ẹnì kan ní, kò yẹ kí a gbàgbé ète wa, tí ó jẹ́ láti fi àwọn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ń gbéni ró kọ́ àwọn ènìyàn.
3 Dájúdájú, a fẹ́ bá àwọn tí ẹrù wọ̀ lọ́rùn kẹ́dùn. Jesu fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, nígbà tí ó sọ ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú Matteu 11:28 pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.” A fẹ́ fún àwọn ènìyàn níṣìírí ní ọ̀nà kan náà. Bí ó ti wù kí ó rí, kíyè sí i pé, ní òpin ẹsẹ 28, Jesu sọ pé: “Dájúdájú emi yoo sì tù yín lára.” Ète wa nìyẹn. A ń ṣe èyí, nípa ṣíṣàjọpín àwọn ìlérí títuni lára tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Jíjẹ́ ẹni tí ń tẹ́tí sílẹ̀ dáradára ń fi ìfẹ́ àti àníyàn wa nínú ẹni náà hàn, ó sì ṣe kókó láti lè mú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà ṣẹ, ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé, Ìjọba náà nìkan ṣoṣo ni ó lè yanjú gbogbo ìṣòro aráyé.—Matt. 24:14.
4 Iṣẹ́ wa kì í ṣe ti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùbójútó ìlera. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ bí aposteli Paulu ti ṣàlàyé nínú 1 Timoteu 4:6, iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó pọkàn pọ̀ sórí “ẹ̀kọ́ àtàtà,” àwọn ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. A lè fún àwọn tí ó ní ìṣòro ara ẹni tàbí ti ìmọ̀lára níṣìírí láti gbára lé Jehofa. Kọ́ wọn láti ‘máa gbé èrò-inú wọn ka awọn nǹkan ti òkè’—àwọn nǹkan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìrètí Ìjọba. (Kol. 3:2) Nígbà tí àwọn ènìyàn bá pọkàn pọ̀ sórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ipa alágbára tí ó ń ní nínú ìgbésí ayé wọn lè gbé wọn ró.—Heb. 4:12.
5 Nítorí náà, góńgó wa jẹ́ láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa ìrònú wọn pọ̀ sórí àwọn ohun tí ó jẹ́ ‘òdodo, mímọ́níwà, tí ó dára ní fífẹ́, tí ó sì yẹ fún ìyìn.’ (Filip. 4:8) Bí wọ́n bá pọkàn pọ̀ sórí ìrètí Ìjọba, a óò bù kún wọn ní ọ̀nà kan náà tí a gbà ń bù kún wa. Àwọn pẹ̀lú yóò gbádùn ìdùnnú tí ń bá mímọ̀ pé Jehofa yóò yanjú gbogbo ìṣòro wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ rìn.—Orin Da. 145:16.