Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Fara Hàn Kedere
1 Ronú padà sẹ́yìn sí ìgbà tí o kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Òtítọ́ rírọrùn ru ìfẹ́ ọkàn rẹ sókè fún ìmọ̀ àti òye. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí o fi rí ìdí láti ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ, nítorí pé ọ̀nà Jehofa ga fíìfíì ju ọ̀nà rẹ lọ. (Isa. 55:8, 9) O tẹ̀ síwájú, o ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́, o sì ṣe batisí.
2 Àní lẹ́yìn títẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí pàápàá, o ṣì ní àwọn àìlera kan tí o ní láti ṣẹ́pá. (Romu 12:2) Bóyá o ní ìbẹ̀rù ènìyàn, tí ó ń mú kí o lọ́ tìkọ̀ láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Tàbí bóyá o kò mú àwọn èso tẹ̀mí Ọlọrun dàgbà tó bí ó ṣe yẹ. Dípò fífà sẹ́yìn, o pinnu láti tẹ̀ síwájú nípa gbígbé àwọn góńgó ìṣàkóso Ọlọrun kalẹ̀ fún ara rẹ.
3 Ọ̀pọ̀ ọdún lè ti kọjá nísinsìnyí, láti ìgbà tí o ti ṣèyàsímímọ́. Ní bíbojú wẹ̀yìn, ìlọsíwájú wo ni o lè rí nínú ara rẹ? O ha ti lé díẹ̀ lára àwọn góńgó rẹ bá bí? O ha ṣì ní ìtara tí o “ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” bí? (Heb. 3:14) Timoteu jẹ́ Kristian tí ó dàgbà dénú, pẹ̀lú ìrírí ọ̀pọ̀ ọdún, nígbà tí Paulu rọ̀ ọ́ pé: “Sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí awọn nǹkan wọnyi; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè farahàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tim. 4:15.
4 A Nílò Àyẹ̀wò Ara Ẹni Kínníkínní: Nígbà tí a bá sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ wa àtẹ̀yìnwá, a ha ń rí i pé a ṣì ní díẹ̀ lára àwọn àìlera tí a ní nígbà tí a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ bí? A ha ti kùnà láti lé díẹ̀ lára àwọn góńgó tí a gbé kalẹ̀ bá bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìdí rẹ̀? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní ète tí ó dára, a lè ti fònídónìí fọ̀ladọ́la. Bóyá a ti yọ̀ọ̀da fún àníyàn ìgbésí ayé tàbí àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí láti fà wá sẹ́yìn.—Luku 17:28-30.
5 Nígbà tí a kò lè ṣe ohunkóhun nípa ohun tí ó ti kọjá, dájúdájú, a lè ṣe nǹkan nípa ọjọ́ iwájú. A lè gbé ara wa sórí òṣùwọ̀n, kí a pinnu ibi tí ó kù-díẹ̀-kí-à-tó sí, kí a sì sapá gidigidi láti ṣe dáradára sí i. A lè fẹ́ láti ṣe dáradára sí i nínú mímú àwọn èso ẹ̀mí Ọlọrun, irú bí ìkóra-ẹni-níjàánu, ìwà tútù, tàbí ìpamọ́ra, dàgbà. (Gal. 5:22, 23) Bí a bá níṣòro wíwà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tàbí fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, ó ṣe pàtàkì pé kí a mú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn dàgbà.—Filip. 2:2, 3.
6 A ha lè jẹ́ kí ìlọsíwájú wa fara hàn kedere nípa nínàgà fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bí? Ó ṣeé ṣe fún àwọn arákùnrin láti tóótun láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, pẹ̀lú àfikún ìsapá. Ó lè ṣeé ṣe fún díẹ̀ lára wa láti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Fún ọ̀pọ̀ mìíràn, ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè jẹ́ góńgó tí ọwọ́ lè tẹ̀. Àwọn mìíràn lè sakun láti mú àṣà ìdákẹ́kọ̀ọ́ wọn sunwọ̀n sí i, láti di olùkópa aláápọn nínú àwọn ìpàdé ìjọ, tàbí láti jẹ́ akéde ìjọ tí ó túbọ̀ ń méso jáde.
7 Dájúdájú, ó kù sí ọwọ́ oníkálùkù wa láti pinnu ibi tí a ti nílò ìlọsíwájú. Ìdánilójú wà pé, ìsapá àtọkànwá wa láti “tẹ̀síwájú sí ìdàgbàdénú” yóò fi kún ìdùnnú wa gidigidi, yóò sì mú kí a di mẹ́ḿbà ìjọ tí ń méso jáde sí i.—Heb. 6:1.