‘Ẹ Máa Pọ̀ Sí i Ninu Ìmọ̀ Pípéye’
Ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Joh. 17:3) A ní láti máa ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Jehofa. (Kol. 1:9, 10) Bẹ̀rẹ̀ láti April 29, a óò bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Kì í ṣe pé òye wa nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun yóò sunwọ̀n sí i nìkan ni, ṣùgbọ́n a óò tún mú wa gbara dì dáradára sí i láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. A óò bù kún ìwọ àti ìdílé rẹ, bí ẹ bá múra sílẹ̀ ṣáájú, tí ẹ ń pésẹ̀, tí ẹ sì ń kópa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tí ẹ sì ń lo àwọn ìsọfúnni yẹn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.