ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/96 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 1
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 29
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 4/96 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún April

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 1

Orin 132

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Mẹ́nu kan ìròyìn títayọ èyíkéyìí nípa ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí yín.

20 min: “Jẹ́ ‘Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà’ ní April!” Kárí ìpínrọ̀ 1 sí 10 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Ṣàlàyé (1) ohun tí ẹ ti wéwèé ní àdúgbò yín fún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá tí a mú gbòòrò sí i ní April, (2) bí a ṣe lè ran gbogbo àwùjọ lọ́wọ́ láti kópa, àti (3) bí àwọn ẹni tuntun àti àwọn èwe ṣe lè nípìn-ín.

15 min: “Wá Àwọn Tí Ó Ní Ìtẹ̀sí Ọkàn Títọ́ Rí.” Ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá, kí o sì jẹ́ kí á ṣe àṣefihàn méjì tí ń fi bí a ṣe lè lò wọ́n hàn. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, sọ díẹ̀ nínú àwọn àbá fún fífi ìwé ìròyìn lọni, tí ó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, March 1996, ojú ìwé 5.

Orin 20 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 8

Orin 72

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Jíròrò àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí a lè gbà ran àwọn ẹni tuntun, tí wọ́n pésẹ̀ sí Ìṣe Ìrántí, lọ́wọ́ láti túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ṣàyẹ̀wò Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1991, ojú ìwé 9 sí 12.

15 min: “Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Tọ̀sán Tòru.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 5 àti 6.

15 min: “Jẹ́ ‘Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà’ ní April!” Kárí ìpínrọ̀ 11 sí 15 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò àyíká ipò ara ẹni wọn, kí wọ́n sì wá ọ̀nà láti mú kí ìtìlẹyìn wọn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá pọ̀ sí i.

Orin 113 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 15

Orin 133

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó; mẹ́nu kan ìfọpẹ́hàn tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ Society fún ọrẹ. Rán àwùjọ létí nípa àkànṣe ọ̀rọ̀ àsọyé ìtagbangba ní April 21, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Wíwà Láìlẹ́bi Láàárín Ìran Oníwà Wíwọ́ Kan.” Fún ṣíṣe àfikún ìsapá láti ran gbogbo ènìyàn lọ́wọ́ láti pésẹ̀ níṣìírí.

15 min: “Ìgbà Ti Yí Padà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ gbígbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́nà tí ó kúnjú àìní tí ó kan àwọn ènìyàn gbọ̀ngbọ̀n jù lọ. Dábàá àwọn ọ̀ràn ìdílé àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tí ó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1994, ojú ìwé 22, 23.

18 min: “Ìgbàgbọ́ Ń Tẹ̀lé Ohun Tí A Gbọ́.” Jíròrò bí a ṣe lè lo fífi ìwé ìròyìn sóde láti mú ọkàn-ìfẹ́ tí ó lè ṣamọ̀nà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nínú ìwé Ìmọ̀ dàgbà. Jẹ́ kí á ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta.

Orin 204 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 22

Orin 6

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì àkànṣe ọ̀rọ̀ àsọyé tí a sọ ní òpin ọ̀sẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá yìí. Jíròrò bí ìṣílétí yìí ṣe lè sún àwọn olùfìfẹ́hàn láti mú ìdúró gbọnyingbọnyin fún ìjọsìn tòótọ́. Síwájú sí i, pe àfiyèsí sí “Ẹ Máa Pọ̀ Sí i Ninu Ìmọ̀ Pípéye,” kí o sì tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàki lílọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ déédéé.

12 min: Àpótí Ìbéèrè. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà. Ṣàlàyé ìdí tí ó fi yẹ kí àwọn arákùnrin tí ń darí ìpàdé yẹra fún àgbéré nínú pípe àwọn ènìyàn, nípa lílo orúkọ àbísọ wọn nìkan.

18 min: Ìjíròrò láàárín alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Ìdílé Olùṣèfẹ́ Ọlọrun ní Ìgbà Àtijọ́—Àpẹẹrẹ Àwòkọ́ṣe fún Ọjọ́ Wa,” tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1995, ojú ìwé 20 sí 23. Ṣe ìfisílò ṣíṣeé múlò tí yóò ṣàǹfààní fún àwọn ìdílé ládùúgbò.

Orin 143 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 29

Orin 144

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn kan ṣàpèjúwe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀ya ìsìn” tàbí “ẹgbẹ́ awo,” ní ṣíṣi àwọn ènìyàn lọ́nà nípa ìgbòkègbodò àti ète wa. Ní lílo ìwé Reasoning, ojú ìwé 202, ṣàlàyé ní ṣókí bí ó ṣe yẹ kí á fi ẹ̀sùn yìí hàn pé ó jẹ́ èké.

10 min: “Àwọn Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka gbogbo ìpínrọ̀.

12 min: Fífún Gbogbo Ìpínlẹ̀ Wa ní Àfiyèsí Kan Náà. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Ó lè jẹ́ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni a ń ṣe àwọn àgbègbè tí kò wà pa pọ̀ tàbí tí ó jìnnà. Àwọn kan lè mọ̀ọ́nmọ̀ yẹra fún àwọn àgbègbè tí àwọn ènìyàn ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí tí wọ́n jẹ́ onísìn. A lè ti yẹra fún ìpínlẹ̀ ìṣòwò. Àwọn akéde kan lè máa béèrè déédéé fún àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí dípò àwọn tí ó yẹ láti kárí ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìsapá láti kárí àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò tí ì ṣe. Àsìkò ẹ̀rùn máa ń pèsè àǹfààní rere láti ṣe àwọn àgbègbè ìgbèríko jíjìnnà; bóyá ẹ lè ṣètò ohun ìrìnnà. Ẹ rí i dájú pé, ẹ kárí àwọn ìpínlẹ̀ yín dáradára, títí kan àwọn kò-sí-nílé, kí ẹ tó dá káàdì yín padà. Fúnni ní àwọn àbá gbígbéṣẹ́ mìíràn tí ń fi bí gbogbo àwùjọ ṣe lè ṣèrànwọ́ nínú kíkárí àwọn ìpínlẹ̀ yín lọ́nà dídára jù lọ hàn.

13 min: Fi àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà lọni ní May. Gbé àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà jáde lákànṣe. Níbi tí a kò bá ti gba àsansílẹ̀-owó, fi ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tí ó bá a mu lọni. Pa àkọsílẹ̀ gbogbo ìfisóde mọ́, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Tẹnu mọ́ àǹfààní wíwà pẹ́ títí tí ìpínkiri ìwé ìròyìn ní gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ọ̀nà gbígbéṣẹ́ jù lọ láti mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn. Rí i dájú pé a ní wọn lọ́wọ́ nígbà tí a bá lọ sí iṣẹ́ ìsìn; fi wọ́n lọni ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Ìṣètò ara ẹni fún Ọjọ́ Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tí ó dára láti gbà mú kí fífi ìwé ìròyìn sóde pọ̀ sí i. Iṣẹ́ ìjẹ́rìí láti ìsọ̀ dé ìsọ̀ àti ìjẹ́rìí òpópónà pẹ̀lú ìwé ìròyìn tún ń méso jáde pẹ̀lú. Ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ tí a fi hàn nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò tí a pète láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní lílo ìwé Ìmọ̀. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn ṣókí kan tàbí méjì tí ń fi ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni, bóyá ní lílo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ojú ìwé 3, ìpínrọ̀ 3 sí 5.

Orin 195 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́