Ìgbà Ti Yí Padà
1 Bibeli sọ fún wa pé “ìrísí ìran ayé yii ń yípadà.” (1 Kor. 7:31) Ẹ wo bí ìyẹ́n ti jẹ́ òtítọ́ tó lónìí! Kódà, lẹ́nu ìgbà tí a dáyé, a ti rí ìyípadà pípabanbarì nínú ìrònú àti ìwà àwọn ènìyàn nínú gbogbo ìpele àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Bí a óò bá ṣàṣeyọrí ní mímú kí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà wọ̀ wọ́n lọ́kàn, ọ̀nà tí a gbà ń gbé e kalẹ̀ gbọ́dọ̀ máa bá ìgbà mu. A fẹ́ gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ lọ́nà kan tí yóò fa àwọn ènìyàn mọ́ra, tí yóò sì dé inú ọkàn wọn.
2 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, iṣẹ́ ìjẹ́rìí yàtọ̀ nítorí pé, ní apá ibi tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn ènìyàn gbé ìgbésí ayé alálàáfíà, wọ́n sì ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ìsìn jọ wọ́n lójú gidigidi. Wọ́n fi ojú tí ó nípọn wo Bibeli. Ní ayé ìgbà yẹn, ìjẹ́rìí wa ní gbogbo ìgbà sábà máa ń dá lórí jíjádìí irọ́ tí ń bẹ nídìí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́. Lónìí, ìgbésí ayé àwọn ènìyàn wà nínú pákáǹleke. Ìsìn kò já mọ́ nǹkan kan mọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. Àwọn ènìyàn kéréje ló ní ìgbàgbọ́ nínú Bibeli. Ní àwọn ibi wọ̀nyí, àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n ti ba ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọrun jẹ́.
3 Alábòójútó arìnrìn àjò kan sọ pé: “Nísinsìnyí, ó dà bíi pé, ìgbésí ayé àwọn ènìyàn kún fún ìṣòro àti ìnira débi pé a ní láti kọ́ wọn bí wọn yóò ṣe máa gbé ìgbésí ayé wọn.” Ohun tí ó kan àwọn ènìyàn gbọ̀ngbọ̀n lọ́nà ti ẹ̀dá rọ̀gbà yíká ara àwọn fúnra wọn, ìdílé wọn, àti àníyàn wọn. Ìwọ̀nyí ní àwọn nǹkan tí wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jù nígbà tí wọ́n bá pé jọ. A ní láti fi ìyẹn sọ́kàn nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí wa.
4 Ìjọba Ọlọrun Ni Ìrètí Kan Ṣoṣo Tí Ó Dájú fún Ọjọ́ Ọ̀la: Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò ní ìgbọ́kànlé nínú ìjọba ènìyàn. Wọ́n ronú pé kò sí ìfojúsọ́nà fún rírí ayé sísàn jù kan nígbà ayé wọn. Ìsìn èké ti kùnà láti fún wọn ní ìpìlẹ̀ èyíkéyìí fún ìrètí. Ìdí nìyẹn tí àìní aráyé tí ó ga jù lọ fi jẹ́ gbígbọ́ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọrun. Fi bí yóò ti pèsè ojútùú nígbẹ̀yìngbẹ́yín sí gbogbo àwọn ìṣòro tí ń dojú kọ aráyé hàn.
5 Bibeli Ni Orísun Ṣíṣeé Gbára Lé Kan Ṣoṣo fún Ìtọ́sọ́nà: Àwọn aṣáájú tí wọ́n gbára lé ọgbọ́n ẹ̀dá ènìyàn àti àbá èrò orí ti ayé ti ṣi ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ìwòyí lọ́nà. Àwọn ènìyàn kò tí ì mọ̀ síbẹ̀ pé “kò sí ní ipá ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Jer. 10:23) Ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye jù lọ tí wọ́n lè kọ́ ní pé kí wọ́n ‘fi gbogbo àyà wọn gbẹ́kẹ̀ lé Oluwa, kí wọ́n má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara wọn.’ (Owe 3:5) Bí ìgbà tilẹ̀ ń yí padà, Bibeli kò yí padà. Nítorí ìdí èyí, a gbọ́dọ̀ máa gbé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nígbà gbogbo, ní kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn láti mọrírì ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá rẹ̀ tí a mí sí. (2 Tim. 3:16, 17) Láti ṣàṣeparí ète yẹn, a gbọ́dọ̀ fi ìjẹ́pàtàkì Bibeli hàn lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nípa títọ́ka sí i nínú àwọn ìgbékalẹ̀ wa, ní lílò ó láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọn, àti ṣíṣalágbàwí bí ó ti yẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kí a sì lo ọgbọ́n rẹ̀ tí ó gbéṣẹ́.
6 Àní pẹ̀lú ìgbà tí ń yí padà lónìí, ète ìlépa wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣì jẹ́ ọ̀kan náà. A ní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, kí á gbé ìgbàgbọ́ ró nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kí á sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti rí ìdí tí ó fi yẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wa. Ohun tí a óò sọ gbọ́dọ̀ jẹ mọ́ àìní lọ́ọ́lọ́ọ́ ti àwọn tí a ń jẹ́rìí fún. Nípa ṣíṣe èyí, a lè dí alájọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kí a sì tipa báyìí jèrè ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn.—1 Kor. 9:19, 23.