“Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?”
1 Ìhìn iṣẹ́ ẹlẹ́wà, tí ń runi lọ́kàn sókè, tí ó sì ń múni lọ́kàn yọ̀ ni a óò polongo jákèjádò ayé ní 169 èdè. Kí ni ìhìn iṣẹ́ yìí jẹ́? Báwo sì ni a óò ṣe jẹ́ ẹ?
2 Ìhìn iṣẹ́ náà jẹ́ nípa ìfẹ́ aládùúgbò. A lè rí i nínú Ìròyìn Ìjọba No. 35, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?” Ìròyìn Ìjọba yìí ṣàyẹ̀wò ipò àwọn nǹkan ní lọ́ọ́lọ́ọ́ jákèjádò ayé ní ṣókí, ó fi hàn pé àìsí ìfẹ́ láàárín àwọn ènìyàn ni okùnfà làásìgbò àti ìrora tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ó ṣàlàyé ìdí tí ìfẹ́ aládùúgbò fi tutù ní ọjọ́ wa ní pàtàkì àti ohun tí èyí túmọ̀ sí fún ọjọ́ ọ̀la.
3 Ní ọwọ́ kan náà, Ìròyìn Ìjọba No. 35 fi hàn pé ìfẹ́ aládùúgbò tòótọ́ wà láàárín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ń gbé ayé lónìí. Ó fi àwọn tí ń nípìn-ín nínú ìmúsọjí ìsìn Kristẹni ìjímìjí—ìjọsìn ọ̀rúndún kìíní, èyí tí ìfẹ́ aládùúgbò sàmì sí gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ti fi kọ́ni hàn.—Lúùkù 10:25-37.
4 Ìròyìn Ìjọba No. 35 parí pẹ̀lú àlàyé bí gbogbo ìran aráyé yóò ṣe máa fi ìfẹ́ aládùúgbò ṣèwà hù láìpẹ́ lábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọ́run láti ọwọ́ Kristi. Àwọn tí ń ka ìhìn iṣẹ́ yìí ni a fún níṣìírí láti gba ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, kí wọ́n sì kọ́ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ apá kan ìṣètò onífẹ̀ẹ́ kárí ayé yìí tí a ṣàpèjúwe ní kúlẹ̀kúlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
5 Ta Ni Yóò Jẹ́ Ìhìn Iṣẹ́ Yìí Fúnni? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé yóò máa ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ ti ìfẹ́ aládùúgbò yí pẹ̀lú àwọn ojúlùmọ̀, aládùúgbò, àti àwọn ìbátan wọn ní oṣù October àti November. Gbogbo àwọn tí ó bá tóótun ni a fún níṣìírí láti nípìn-ín nínú pípín Ìròyìn Ìjọba No. 35 fún gbogbo ènìyàn.
6 Góńgó ìgbétásì yí ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ni láti ru ọkàn ìfẹ́ àwọn ènìyàn sókè nínú ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí nínú ìwé Ìmọ̀. Ní àfikún sí i, ìsapá tọkàntọkàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá ṣe yóò yọrí sí ìjẹ́rìí gígọntíọ sí Ọlọ́run ìfẹ́, Jèhófà, àti sí Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi.