Ṣíṣàjọpín Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
1 Ìdílé ni apá tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, ìdílé ni ó sì para pọ̀ di abúlé, ìlú, ìpínlẹ̀, àti odindi orílẹ̀-èdè. Lónìí, ìdílé kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ pákáǹleke ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àwọn ipá lílágbára wà lẹ́nu iṣẹ́ ní híhalẹ̀mọ́ wíwà ìgbésí ayé ìdílé gan-an. Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó pé Jèhófà, Olùpète ìṣètò ìdílé, ti pèsè ìtọ́ni fún wa kí ọwọ́ wa baà lè tẹ ayọ̀ ìdílé! Àwọn tí ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ rí i pé ìṣòro ń dín kù, ìdílé aláṣeyọrí sì ń jẹ yọ. Ní oṣù September, a ní àǹfààní láti ṣàjọpín ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Lo ìdánúṣe láti tọ àwọn ènìyàn lọ lórí kókó tí ó jẹ́ ti ìgbésí ayé ìdílé. Yá mọ́ni, fojú sọ́nà fún rere, kí o sì lo ìfòyemọ̀. Kí ni o lè sọ?
2 O lè bẹ̀rẹ̀ nípa gbígbé ìbéèrè kan dìde, irú bí:
◼ “O ha ti ṣàkíyèsí pé ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ ìdílé láti fara da àwọn pákáǹleke ìgbésí ayé bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìròyìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń nírìírí àwọn ìṣòro nínú ilé. Kí ni o gbà gbọ́ pé yóò ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti rí okun àti ayọ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni ó gbé ìṣètò ìdílé kalẹ̀, kì yóò ha bọ́gbọ́n mu láti ṣàyẹ̀wò ìtọ́sọ́nà tí òun pèsè? [Ka Tímótì Kejì 3:16, 17.] A to irú ìtọ́ni ṣíṣàǹfààní bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé yìí, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.” Lẹ́yìn náà, béèrè lọ́wọ́ ẹni náà nípa ohun tí ó rò pé ó jẹ́ ìṣòro tí ó wọ́pọ̀ nínú ìdílé, fi orí tí ó jíròrò ìṣòro yẹn hàn án, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún ọrẹ ₦55.
3 Nígbà ìpadàbẹ̀wò, o lè lépa góńgó bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa sísọ pé:
◼ “Mo ronú nípa ohun tí o sọ lórí kókó tí ó jẹ́ ti ìgbésí ayé ìdílé, mo sì mú ohun kan wá fún ọ tí mo ronú pé ìwọ yóò gbádùn. [Fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè hàn án, ṣí i sí ojú ìwé 16, kí o sì ka àwọn ìbéèrè mẹ́fà tí ó wà lókè.] Ní kedere, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé gbọ́dọ̀ ṣe ipa tirẹ̀ láti fi kún ayọ̀ ìdílé. Bí o bá ní ìṣẹ́jú díẹ̀ péré, èmi yóò fi hàn ọ́ bí o ṣe lè jàǹfààní jù lọ láti inú ìsọfúnni yìí.” Lẹ́yìn náà, bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ 8. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ fún ọrẹ ₦15.
4 Ọ̀nà míràn láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò ni láti mẹ́nu kan ìṣòro kan, bóyá nípa sísọ pé:
◼ “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olúkúlùkù ń fẹ́ láti nímọ̀lára ànító àti ìtẹ́lọ́rùn, ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ ìdílé kò tíì ṣe àṣeyọrí nínú èyí ní ti gidi. Kí ni o rò pé yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ tòótọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, Bíbélì sọ irú àwọn ìṣòro tí a óò máa rí nínú ìdílé lónìí. [Ka Tímótì Kejì 3:1-3.] Ṣùgbọ́n, Bíbélì tún sọ fún àwọn ìdílé nípa ohun tí wọ́n lè ṣe láti yanjú ìṣòro wọ̀nyí, kí wọ́n sì jèrè ayọ̀ pípẹ́ títí. Ìlànà rẹ̀ ni a tò lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé yìí, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.” Lẹ́yìn náà, fi àpótí àtúnyẹ̀wò ní òpin orí tí ó bá a mu hàn án, kà á, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún iye ọrẹ rẹ̀.
5 Nígbà tí o bá pa dà lọ, lo ìwé pẹlẹbẹ “Béèrè” láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. O lè sọ pé:
◼ “Ìmúratán rẹ láti ṣàyẹ̀wò ìlànà Bíbélì tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdílé wú mi lórí. Ìrírí ti fi hàn pé a máa ń rí àbájáde tí ó dára jù lọ nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tí ó wà nínú Bíbélì. Àlàyé rírọrùn kan nìyí níhìn-ín nípa ìdí tí ìyẹn fi rí bẹ́ẹ̀.” Ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ti ẹ̀kọ́ 1 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, àti yálà Orin Dáfídì 1:1-3 tàbí Aísáyà 48:17, 18. Bí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀, ṣàyẹ̀wò ìyókù ẹ̀kọ́ náà, kí o sì fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ fún iye ọrẹ rẹ̀. Sọ pé ìwọ yóò pa dà wá kí ẹ lè jọ kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
6 Kó Ìtẹ̀jáde Tí Ó Tó Dání: Aṣáájú ọ̀nà kan fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ ọkùnrin kan tí wọ́n jọ ń rìrìn àjò lọ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan náà. Ohun tí ọkùnrin náà kà ní ẹ̀kọ́ 10 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà gún un ní kẹ́ṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi dá iye owó tabua tí ó jí nínú àpò ẹlòmíràn nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà pa dà. Ó ya gbogbo àwọn tí ó wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà lẹ́nu, wọ́n sì béèrè fún ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Ó fi ẹ̀dà márùn-ún mìíràn fún gbogbo èrò inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà. Èyí fi hàn bí ó ti bọ́gbọ́n mu tó láti máa kó ìtẹ̀jáde tí ó tó dání nígbà gbogbo.
7 Nípa Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa: Fojú sọ́nà fún rere nígbà tí o bá ń béèrè fún ọrẹ fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Ọrẹ tí a ń béèrè fún àwọn ìtẹ̀jáde wa kéré jọjọ sí ohun tí pípèsè wọn ń náni. Fífojúsọ́nà fún rere túmọ̀ sí pé a kì yóò ti dé orí èrò ṣáájú pé onílé kò lè lágbára láti gba ìtẹ̀jáde náà. Ìrọni díẹ̀ sí láti ọ̀dọ̀ wa lè ṣe púpọ̀ láti mú àbájáde rere wá. Fífi tí a bá fojú sọ́nà fún rere yóò ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti ṣe ìtọrẹ iye owó táṣẹ́rẹ́ tí a ń fi ìtẹ̀jáde wa lọni.
8 Ẹ jẹ́ kí a ṣe gbogbo ìsapá tí a lè ṣe láti ṣàjọpín àṣírí tí ń ṣamọ̀nà sí ayọ̀ ìdílé pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn—ní títẹ̀lé ìtọ́ni tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Orin Dá. 19:7-10.