Ìpinnu Wa—Láti Máa Rìn ní Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Jèhófà Fẹ́
1 Ọ̀kan lára ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ní Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ni ìpinnu tí a ṣe nínú ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kẹ́yìn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpolongo yìí: “Àwa . . . fi tọkàntọkàn gbà pé ọ̀nà Ọlọ́run ni ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ.” Rántí àwọn kókó pàtàkì mélòó kan nínú ìpinnu náà tí gbogbo wa dáhùn sí pé, “BẸ́Ẹ̀ NI!”
2 Ìpinnu wa ni pé a óò máa jẹ́ mímọ́ lójú Jèhófà, láìlábààwọ́n nínú ayé. A óò máa bá a lọ láti fi ìfẹ́ Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí ayé wa. Bí a ti ń lo Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amọ̀nà, a kò ní yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì, a óò sì tipa báyìí jẹ́rìí sí i pé ọ̀nà Ọlọ́run dára gan-an ju ọ̀nà ayé lọ.
3 Ayé lápapọ̀ kò ka ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ sí, wọ́n sì ń rí àbájáde rẹ̀. (Jer. 10:23) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti jẹ́ ẹni tí Jèhófà, Atóbilọ́lá Olùfúnninítọ̀ọ́ni wa, ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ẹni tó sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísá. 30:21) Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀nà ìgbésí ayé tí Jèhófà fẹ́ ni ó dára jù lọ ní gbogbo ọ̀nà. Láti lè máa rìn ní ọ̀nà yẹn, ó pọndandan pé ká lo àǹfààní gbogbo ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa.
4 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tí Ó Dára Jù Lọ Tí Ó Jẹ́ ti Jèhófà: Jèhófà ń kọ́ wa ni ohun tó jẹ́ ète gidi nínú ìgbésí ayé àti bí a ṣe lè lo ìwàláàyè wa lọ́nà tó dára jù lọ. Ó ń kọ́ wa báa ṣe lè mú kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i ní ti èrò orí, ní ti ìwà híhù, àti nípa tẹ̀mí. Ó ń kọ́ wa báa ṣe lè máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa, pẹ̀lú àwọn ìdílé wa, àti pẹ̀lú ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa. Ó ń ṣe èyí nípasẹ̀ ìwé rẹ̀, Bíbélì, àti nípasẹ̀ ètò rẹ̀.
5 Àwọn ìpàdé ìjọ wa ṣe pàtàkì nínú èyí. Bí a ṣe ń lọ sí gbogbo ìpàdé márààrún déédéé táa sì ń kópa nínú wọn, a ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kíkúnrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere, a sì ń gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó kúnjú òṣùwọ̀n nínú ìgbésí ayé Kristẹni. (2 Tím. 3:16, 17) Atóbilọ́lá Olùfúnninítọ̀ọ́ni wa tún ń pèsè ẹ̀kọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run síwájú sí i nípasẹ̀ àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀. Ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ góńgó wa ni pé a kì yóò pàdánù ìpàdé kan tàbí ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan bí ìlera àti àwọn àyíká ipò wa bá gbà wá láyè.
6 Ǹjẹ́ kí a máa fi aápọn bá a nìṣó ní àwọn ọjọ́ tí ń bẹ níwájú ní rírìn ní ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́, sí ìyìn Jèhófà àti àǹfààní àìnípẹ̀kun wa!—Aísá. 48:17.