ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/00 ojú ìwé 3-4
  • Ǹjẹ́ O Ń Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Ń Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìpàdé Tó Ń Fún “Wa Níṣìírí Láti Ní Ìfẹ́ àti Láti Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Rere”
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Bí A Ṣe Ń Pàdé Pọ̀ Láti Jọ́sìn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ìpàdé Máa Ń Ṣe Àwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Tó Kún Rẹ́rẹ́ Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 8/00 ojú ìwé 3-4

Ǹjẹ́ O Ń Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní?

1 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lónìí máa ń fẹ́ láti mọ bí àwọn ṣe lè borí ìṣòro kí àwọn sì máa gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀. Wọ́n máa ń ka àwọn ìwé báyìí-làá-ṣe-é tàbí kí wọ́n yíjú sí àwọn ẹgbẹ́ tàbí àjọ kan fún ìmọ̀ràn lórí bí àwọn ṣe lè mú kí ìgbésí ayé àwọn sunwọ̀n sí i. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan tọ́ka sí àǹfààní bíi mélòó kan tí wọ́n ti rí jẹ. Síbẹ̀, tí a bá ní ká wo ibi tí ìgbésí ayé dára mọ lónìí, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn ní gbogbo gbòò ti mọ bí wọ́n ṣe lè gbádùn ìgbésí ayé alálàáfíà, tí ń tẹ́ni lọ́run látinú àwọn ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ènìyàn ṣe? Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá!—1 Kọ́r. 3:18-20.

2 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Ẹlẹ́dàá wa ń pèsè ìtọ́ni tó ń ṣèrànwọ́ jù lọ fún gbogbo àwọn tó bá fetí sílẹ̀, kò sì béèrè kọ́bọ̀ lọ́wọ́ wa. Jèhófà fẹ́ kí olúkúlùkù wa máa jàǹfààní látinú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ òun. Ó fi ìwà ọ̀làwọ́ pèsè Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí láti máa ṣe amọ̀nà aráyé ní ọ̀nà títọ́, ó sì ti mú kí a polongo ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé. (Sm. 19:7, 8; Mát. 24:14; 2 Tím. 3:16) Ìgbésí ayé tó jẹ́ aláyọ̀ ní tòótọ́ ni èyí tó bá jẹ́ pé ó wé mọ́ fífiyè sí àwọn àṣẹ Jèhófà ní tààràtà.—Aísá. 48:17, 18.

3 Ìtọ́sọ́nà Jèhófà níye lórí fíìfíì ju ìwé báyìí-làá-ṣe-é èyíkéyìí lọ, ó sì tún níye lórí ju ètò bí ènìyàn ṣe lè fọwọ́ ara rẹ̀ mú nǹkan sunwọ̀n sí i, èyí tí ayé lè ṣe lọ. A lè rí ojúlówó ìrànwọ́ àti àwọn àǹfààní pípẹ́ títí bí a bá lo àwọn ìpèsè Jèhófà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí ètò àjọ rẹ̀ sì ń fi kọ́ni.—1 Pét. 3:10-12.

4 Máa Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní Nínú Àwọn Ìpàdé Ìjọ: Lónìí, Jèhófà ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn nínú fífi ọ̀nà rẹ̀ kọ́ wa, a sì ń ṣe ara wa láǹfààní nípa fífiyè sí ìtọ́ni rẹ̀. Àwọn ìpàdé márùn-ún tí a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà ń fi ìfẹ́ ṣàníyàn nípa wa. Nígbà tí a bá lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, ìmọ̀ tí a ní nípa Ọlọ́run yóò máa pọ̀ sí i. A ń kọ́ bí a ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ ohun búburú nípa sísún mọ́ Jèhófà. Ní ọ̀nà yìí, ipò tẹ̀mí wa túbọ̀ ń sunwọ̀n sí i.

5 Kò tán síbẹ̀ o. Ní àwọn ìpàdé ìjọ, ó máa ń ṣeé ṣe fún wa láti “gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́r. 6:13) Lára rẹ̀ ní pé a máa ń lè mọ àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. A máa ń jàǹfààní látinú ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ìṣírí, irú èyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ nípa rẹ̀ nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Róòmù. (Róòmù 1:11, 12) Nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn ará Hébérù, ó kìlọ̀ gidigidi fún àwọn tí wọ́n ti lè bẹ̀rẹ̀ sí dáṣà kíkọ ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni sílẹ̀.—Héb. 10:24, 25.

6 Fífi ìfẹ́ hàn nínú ire àwọn ẹlòmíràn yóò jẹ́ ká ní ìtẹ́lọ́rùn tí ń mú ìdùnnú wá. A fún wa níṣìírí pé kí a máa wá ọ̀nà láti fi kún ayọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà, àǹfààní olúkúlùkù wa àti ti àwọn tí a ń bá kẹ́gbẹ́ lọ́nà gbígbámúṣé ni àwọn ìpàdé Kristẹni tí a máa ń ṣe wà fún. Fífi tọkàntọkàn kópa nínú wọn ló ń béèrè.

7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ tó jọ èyí nínú ìmọ̀ràn rẹ̀ sí Tímótì nígbà tó kọ̀wé pé: “Máa kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.” (1 Tím. 4:7) A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo ń kọ́ ara mi? Ṣé mo ń kẹ́kọ̀ọ́ láti jàǹfààní látinú ohun tí mo ń gbọ́ nínú àwọn ìpàdé ìjọ?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ni àwọn ìdáhùn wa yóò jẹ́ bí a bá ń fiyè sí ohun tí a ń gbọ́ ní àwọn ìpàdé, tí a sì ń sakun láti fi àwọn ohun tí a ń kọ́ sílò. A gbọ́dọ̀ lè fi ojú ìgbàgbọ́ rí i pé kì í ṣe àwọn arákùnrin tí ń sọ̀rọ̀ yẹn ló ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, kí a sì rí i pé Jèhófà ni Olùkọ́ni Atóbilọ́lá tí ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.—Aísá. 30:20.

8 Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn: Àwọn ìpàdé méjì wọ̀nyí wà fún ríràn wá lọ́wọ́ kí a lè di ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ohun tí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ń ṣe gan-an nìyẹn—ilé ẹ̀kọ́ tó ní àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa ń gba ìtọ́ni àti ìmọ̀ràn déédéé. O ní àǹfààní láti fi ìlọsíwájú rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni. Ṣùgbọ́n láti jèrè dáadáa nínú ilé ẹ̀kọ́ náà, o ní láti forúkọ sílẹ̀, kí o máa wá sí ilé ẹ̀kọ́, kí o máa kópa nínú rẹ̀ déédéé, kí o sì máa fọkàn sí iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún ọ. Gbígba ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ọ àti fífi í sílò yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú.

9 Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn máa ń fi ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni kọ́ wa, ó sì ń fi bí a ṣe lè kópa nínú iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn hàn wá. Ǹjẹ́ ìwọ àti ìdílé rẹ máa ń jàǹfààní ní kíkún látinú àwọn ohun tí a fi ń kọ́ni nínú ìpàdé méjèèjì wọ̀nyí bí? Tọkọtaya Kristẹni kan sọ pé: “Ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan, a gbọ́ pé ó yẹ kí a máa ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan. A kì í ṣe èyí tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n a ti ń ṣe é báyìí.” Báwo ni wọ́n ṣe ṣe ara wọn láǹfààní? Wọ́n wí pé: “A rí i pé ìjíròrò wa nídìí tábìlì oúnjẹ túbọ̀ ń gbádùn mọ́ wa. Kò sí pé ká tún máa jiyàn mọ́ lákòókò oúnjẹ alẹ́.” Ǹjẹ́ àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá tilẹ̀ ń jàǹfààní nínú àwọn ìpàdé? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìyá wọn sọ pé: “Ó hàn gbangba pé àwọn ìpàdé ní ipa gidigidi lórí àwọn ọmọ wa. Ní ọ̀sẹ̀ kan báyìí, a gbá ọmọkùnrin wa ọlọ́dún mẹ́fà mú pé ó parọ́. Ṣùgbọ́n lọ́sẹ̀ yẹn, ọ̀rọ̀ ìtọ́ni ní ìpàdé sọ nípa irọ́ pípa. Bí ojú ọmọkùnrin wa ti fi hàn pé ọkàn rẹ̀ ń dá a lẹ́bi, ó wo ojú bàbá rẹ̀, ojú sì tì í gidigidi. Èyí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, kò sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn.”

10 Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan sọ pé inú òun dùn pé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, wọ́n máa ń fún wa ní ìmọ̀ràn nípa bí a ṣe lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. Kí ló dé tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣàlàyé pé: “Ohun kan náà ni mo máa ń sọ ní gbogbo ìgbà. Ìgbà mìíràn wà tí mo máa ń ronú pé ohun tí wọ́n dámọ̀ràn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba wa kò ní ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo gbọ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn pé ká gbìyànjú rẹ̀ wò, mo kún fún ìtara láti fi àwọn ìmọ̀ràn yẹn sílò. Ó mu kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa gbádùn mọ́ mi gidigidi!” Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó ti ń fi ìmọ̀ràn lórí pé kí ó gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà ìjẹ́rìí àkọ́kọ́ sílò, ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan nígbà tó jẹ́rìí fún ọmọdébìnrin kan ní ìgbà àkọ́kọ́, ẹni tó ti ń gbàdúrà fún ìrànwọ́.

11 Nígbà tí o bá gbọ́ àsọyé tó sọ nípa àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn yíyàn tí o máa ń ṣe fúnra rẹ, ǹjẹ́ o máa ń mọ̀ pé Jèhófà ló ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní tààràtà? Arákùnrin kan ronú bẹ́ẹ̀. Ó wí pé: “Ní ìpàdé kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, arákùnrin kan sọ àsọyé kan tó ti jíròrò irú eré ìnàjú tó yẹ fún àwọn Kristẹni àti irú èyí tí kò yẹ fún wọn. Mo fẹ́ràn láti máa wo bí wọ́n ṣe ń kan ẹ̀ṣẹ́ lórí tẹlifíṣọ̀n. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìpàdé yẹn, mo pinnu pé eré ìdárayá yẹn jẹ́ irú eré ìnàjú tí kò yẹ fún Kristẹni. Nítorí náà, mi ò wò ó mọ́.” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin yìí ní ìfẹ́ gidigidi fún nǹkan tí ó jẹ́ ìwà ipá yìí, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ kọbi ara sí ìtọ́sọ́nà Jèhófà.—Sm. 11:5.

12 Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn, Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ: Àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí a máa ń gbọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ máa ń kárí onírúurú kókó ọ̀rọ̀ Bíbélì. Kí lo ń rí jèrè nínú àwọn àsọyé wọ̀nyí? Kristẹni ọkọ kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní tí òun ti rí gbà, ó ní: “Àsọyé fún gbogbo ènìyàn kan sọ̀rọ̀ nípa gbogbo èso ti ẹ̀mí. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ nípa ara rẹ̀ pé, kí ó lè ṣeé ṣe fún òun láti ní àwọn èso tẹ̀mí wọ̀nyẹn, ṣe lòun ń mú ànímọ́ kan ní pàtó, tí òun á sì gbìyànjú láti fi ìyẹn sílò fún ọ̀sẹ̀ kan. Lópin ọ̀sẹ̀ yẹn, òun á ronú nípa bí òun ṣe fi èso tẹ̀mí yẹn hàn nínú ìgbòkègbodò òun ojoojúmọ́. Bó bá tún di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, òun á tún gbìyànjú láti fi ànímọ́ mìíràn sílò. Mó fẹ́ràn ohun tó ṣe yẹn, èmi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é.” Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tó dáa ló gbà fi ohun tó kọ́ sílò!

13 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ń kọ́ wa ní bí a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú onírúurú àwọn ipò ní ìgbésí ayé. Èyí ń mú kí ara wa ṣe wọ̀ọ̀, ká sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn lójú àwọn àníyàn ìgbésí ayé. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tún máa ń jẹ́ ká mọ ibi tí òtítọ́ tẹ̀ síwájú dé. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a kò jàǹfààní látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́, May 1, 1999, tí a pe àkọlé wọn ní: “Nǹkan Wọ̀nyí Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀,” “Kí Òǹkàwé Lo Ìfòyemọ̀” àti “Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ sì Jẹ́ Aláápọn!” Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí ṣe ní ipa lórí ìwọ fúnra rẹ? Ǹjẹ́ ìṣe rẹ fi hàn pé o ń fi ìkìlọ̀ Jésù nípa ọjọ́ ọ̀la sọ́kàn? Ǹjẹ́ o ń múra sílẹ̀ fún àwọn ìdánwò tó ń bẹ níwájú nígbà tí a óò rí “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́”? (Mát. 24:15-22) Ǹjẹ́ àwọn góńgó àti ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ ń fi hàn pé kì í ṣe kíkó àwọn ohun ìní jọ ló ṣe pàtàkì jù lọ fún ọ, bí kò ṣe sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́? A kò ha ń kọ́ wa nípa bí a ṣe lè ṣe ara wa láǹfààní nísinsìnyí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ bí?

14 Ronú nípa ọ̀pọ̀ ohun tí a ń kọ́ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lọ́wọ́lọ́wọ́, a ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì náà, Dáníẹ́lì. Lẹ́nu oṣù mẹ́rin tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì yìí, ǹjẹ́ kì í ṣe ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa ń lágbára sí i? Gẹ́gẹ́ bíi ti wòlíì tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ náà, Dáníẹ́lì, a ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun kí a lè fara dà á.

15 Jèhófà Ń Kọ́ Wa Láti Máa Fi Ayọ̀ Gbé Ìgbé Ayé Wa: A máa ń dènà ọ̀pọ̀ ọgbẹ́ ọkàn nígbà tí a bá ń fiyè sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run. Síwájú sí i, a ń nírìírí ohun tó wé mọ́ fífi ayọ̀ gbé ìgbé ayé. Bí a ti ń tẹ̀ lé ìdarí Jèhófà, a ń kópa nínú iṣẹ́ rẹ̀, kì í ṣe pé a wulẹ̀ ń wòran lásán. Aláyọ̀ sì làwọn èèyàn tó ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 3:9; Ják. 1:25.

16 Ronú dáadáa nípa bí o ṣe lè fi àwọn ohun tí o bá gbọ́ ní àwọn ìpàdé ìjọ sílò. (Jòh. 13:17) Máa fi ìtara sin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ. Ìdùnnú rẹ yóò pọ̀ jọjọ. Ìgbésí ayé rẹ yóò túbọ̀ ládùn, yóò sì túbọ̀ nítumọ̀. Dájúdájú, ìwọ yóò ṣe ara rẹ láǹfààní.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́