ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/99 ojú ìwé 1
  • Ké Sí Wọn Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ké Sí Wọn Wá
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Lílọ sí Ìpàdé Ń Sọ Nípa Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • “Ẹ̀mí Àti Ìyàwó Ń Bá A Nìṣó Ní Sísọ Pé: ‘Máa Bọ̀!’”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 3/99 ojú ìwé 1

Ké Sí Wọn Wá

1 Ìkésíni kan tí a ṣe lọ́pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni a ń ṣe ní ilẹ̀ tí iye rẹ̀ jẹ́ igba àti mẹ́tàlélọ́gbọ̀n kárí ayé báyìí pé: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà, . . . òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” (Aísá. 2:3) Dídarí àwọn ènìyàn sínú ètò Jèhófà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, èyí tí ń ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun.

2 Àwọn akéde kan lè lọ́ tìkọ̀ láti ké sí àwọn ènìyàn wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba títí di ìgbà tí wọ́n bá tó fi ìtẹ̀síwájú dáadáa hàn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé wọn. Ṣùgbọ́n, nígbà mìíràn, àwọn kan máa ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ ṣáájú kí a tó bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pàápàá. Kò yẹ ká fi fífi ọ̀yàyà ké sí àwọn ènìyàn kí a sì fún wọn níṣìírí láti máa wá sí àwọn ìpàdé falẹ̀.

3 Ohun Tó Yẹ Kí O Ṣe: Lo ìwé ìléwọ́, tí ń fi àwọn ìpàdé ìjọ tí a máa ń ṣe tó àwọn ènìyàn létí, lọ́nà rere. Sọ fún wọn pé ọ̀fẹ́ ni àwọn ìpàdé náà àti pé a kì í gba ìdáwó. Ṣàlàyé bí a ṣe ń darí àwọn ìpàdé náà. Ṣàlàyé pé wọ́n jẹ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ti gidi àti pé a máa ń pèsè àkójọ ọ̀rọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ kí gbogbo ènìyàn lè máa fojú bá a lọ. Ṣàlàyé pé ipò àtilẹ̀wá àwọn tí ń wá yàtọ̀ síra, wọ́n sì ń wá láti apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Mẹ́nu kàn án pé àwọn tí ń wá síbẹ̀ ń wá láti àgbègbè náà àti pé a ń fẹ́ kí àwọn ọmọdé pẹ̀lú wá láìka ọjọ́ orí wọn sí. Kí a máa ké sí àwọn táa ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́, kí a yọ̀ǹda láti ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́nà èyíkéyìí láti máa wá.

4 Ọ̀kan nínú àwọn nǹkan tí a ṣàkọsílẹ̀ kẹ́yìn nínú Bíbélì ni ìkésíni ọlọ́yàyà náà láti ṣàjọpín àwọn ìpèsè Jèhófà fún ìyè pé: “Àti ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ . . . Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 22:17) Kò sí ohun tí a lè fi dípò kíké sí àwọn ènìyàn pé kí wọ́n wá sí àwọn ìpàdé wa.

5 Lọ́nà alásọtẹ́lẹ̀, Aísáyà 60:8 ṣàpèjúwe ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùyìn tuntun tí wọ́n ń wá sínú ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà tí “ń fò bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà, àti bí àdàbà sí ihò ilé ẹyẹ wọn.” Gbogbo wa lè ké sí àwọn ẹni tuntun wá sí àwọn ìpàdé wa kí a sì mú kí ara tù wọ́n. Lọ́nà yìí, a óò máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà bí òun ṣe ń mú kí iṣẹ́ ìkójọpọ̀ náà yára kánkán.—Aísá. 60:22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́