Bí Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé Ṣe Máa Ń Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Nípìn-ín Kíkún—Nínú Àwọn Ìpàdé Ìjọ
1 Àwọn ìdílé Kristẹni gbọ́dọ̀ kọbi ara sí àṣẹ náà láti máa péjọpọ̀ ní àwọn ìpàdé ìjọ. (Héb. 10:24, 25) Bí wọ́n bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, gbogbo ìdílé lè ṣàṣeyọrí láti múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé, kí wọ́n pésẹ̀ síbẹ̀, kí wọ́n sì kópa nínú wọn. Àyíká ipò ìdílé lè yàtọ̀ síra, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wà tí Kristẹni ọkọ, aya tó jẹ́ onígbàgbọ́, tàbí òbí anìkàntọ́mọ lè ṣe láti gbé pípéjọpọ̀ ìdílé lárugẹ nínú àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí, láìka iye àwọn ọmọ tó wà nínú ilé àti ọjọ́ orí wọn sí.—Òwe 1:8.
2 Ẹ Wáyè Múra Sílẹ̀: Àwọn mẹ́ńbà ìdílé máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ lọ́nà yíyẹ. Ọ̀pọ̀ máa ń jùmọ̀ ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn kan máa ń múra sílẹ̀ fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tàbí kí wọ́n ka Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan. Ète náà ni pé kí wọ́n lè fi àwọn kókó pàtàkì sọ́kàn kí wọ́n tó lọ sí àwọn ìpàdé yẹn. Lọ́nà yìí, gbogbo ìdílé yóò túbọ̀ jàǹfààní láti inú ohun tí wọ́n bá gbọ́, wọn óò sì gbára dì láti kópa nígbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀.—1 Tím. 4:15.
3 Wéwèé Láti Kópa: Gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ìdílé gbọ́dọ̀ fi í ṣe góńgó wọn láti polongo ìrètí wọn níwájú àwọn ẹlòmíràn nípa dídáhùn ní àwọn ìpàdé. (Héb. 10:23) Ǹjẹ́ mẹ́ńbà ìdílé kan wà tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ tàbí ìṣírí láti ṣe èyí? Ìrànwọ́ wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan ń fẹ́ láti múra àwọn iṣẹ́ àyànfúnni sílẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run? Àwọn aya máa ń mọrírì rẹ̀ nígbà tí ọkọ wọn bá lo ìdánúṣe bóyá tí ó dábàá èrò kan nípa àpèjúwe tí ó bá a mu tàbí ìgbékalẹ̀ kan tó gbéṣẹ́. Kò yẹ kí àwọn òbí ronú pé àwọn ló gbọ́dọ̀ máa múra iṣẹ́ fún àwọn ọmọ wọn kéékèèké. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣèdíwọ́ fún ọmọ náà láti lo ìdánúṣe. Ṣùgbọ́n àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn kéékèèké lọ́wọ́ kí wọ́n sì tẹ́tí sí wọn bí wọ́n ṣe ń fi iṣẹ́ wọn dánra wò ní sísọ̀rọ̀ sókè ketekete.—Éfé. 6:4.
4 Ẹ Ṣètò Láti Wà Níbẹ̀: A lè kọ́ àwọn ọmọ láti kékeré pé kí wọ́n máa múra kí wọ́n sì ṣe tán láti kúrò nílé lọ sí ìpàdé ní àkókò tí a ti yàn. Ó yẹ kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú bíbójútó àwọn iṣẹ́ ilé kí ó má bàa sí ìdádúró.—Wo àwọn àbá tó wà nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 112, àti nínú ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, ojú ìwé 316 àti 317.
5 Àwọn òbí àti àwọn ọmọ lè fẹ̀sọ̀ ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ Jóṣúà ìgbàanì, tó sọ pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” Lẹ́yìn náà, kí wọ́n pinnu láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti nípìn-ín kíkún nínú àwọn ìpàdé ìjọ.—Jóṣ. 24:15.