Fi Ìháragàgà Wàásù Ìhìn Rere Náà
1 “Aáyun ń yun mí láti rí yín . . . Ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere pẹ̀lú fún [yín].” Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde ní ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tó kọ sáwọn ará tó wà ní Róòmù nìyí. Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi hára gàgà láti bẹ̀ wọ́n wò? Ó wí pé: “Kí n lè rí èso díẹ̀ pẹ̀lú láàárín yín . . . Nítorí èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà.”—Róòmù 1:11-16.
2 Pọ́ọ̀lù tún fi irú ìháragàgà yìí hàn nígbà tó ń bá àwọn àgbà ọkùnrin Éfésù sọ̀rọ̀. Ó rán wọn létí pé: ‘Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo dé sí àgbègbè Éṣíà . . . , èmi kò ti fà sẹ́yìn kúrò . . . nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì.’ (Ìṣe 20:18-21) Ní gbogbo ìpínlẹ̀ tí a yàn fún Pọ́ọ̀lù, ohun tó gbà á lọ́kàn ni láti tan ìhìn rere ìgbàlà náà kálẹ̀ àti láti rí àwọn èso Ìjọba náà. Ẹ̀mí rere tó yẹ ká fara wé mà lèyí jẹ́ o!
3 A lè béèrè lọ́wọ́ ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń fi irú ìháragàgà kan náà hàn nínú pípolongo ìhìn rere lágbègbè mi? Dípò tí n óò fi ka iṣẹ́ ìwàásù sí ojúṣe lásán, mo ha ń hára gàgà láti wàásù ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó? Ǹjẹ́ mo tiẹ̀ ti gbé ipò mi yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà? Ṣé mo ti lo gbogbo àǹfààní tó ń jẹ yọ ní ìpínlẹ̀ wa, irú bí wíwàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, ní òpópónà, ní àgbègbè iṣẹ́ ajé, nípasẹ̀ tẹlifóònù, àti jíjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà?’
4 Fi Ìháragàgà Wàásù Lóṣù April: Oṣù April jẹ́ oṣù tó dára púpọ̀ fún wa láti mú kí ìpín tí a ń ní nínú iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i. Wákàtí tí a ń béèrè tó ti wá dín kù báyìí yóò mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bóyá ipò rẹ lè jẹ́ kí o sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nínú oṣù April àti May. Ó sì lè jẹ́ pé àyípadà tó dé bá wákàtí tí a ń béèrè yìí yóò mú kí o lè forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bóo bá jẹ́ akéde ìjọ, ǹjẹ́ o lè lo àkókò púpọ̀ sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ ìsìn lóṣù yìí àtoṣù tó ń bọ̀, nípa kíkọ́wọ́ ti àwọn tó lè ṣe aṣáájú ọ̀nà lẹ́yìn? Ìyẹn á mà mú inú Jèhófà dùn gan-an o!
5 Àwọn akéde Ìjọba gbọ́dọ̀ ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù ní bíbá a nìṣó láti fi ìháragàgà hàn nípa mímú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i. Ṣíṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà yóò mú kí a ní ayọ̀ tòótọ́. Pọ́ọ̀lù ní ayọ̀ yìí nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ ọlọ́wọ̀. Yóò dára púpọ̀ bí a bá lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ tó pegedé.—Róòmù 11:13; 1 Kọ́r. 4:16.