ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/99 ojú ìwé 1
  • Ṣé Ìrísí Nìkan Lo Máa Ń Wò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìrísí Nìkan Lo Máa Ń Wò?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbogbo Onírúurú Èèyàn La Ó Gbà Là
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Má Ṣe Máa Fi Ìrísí Dáni Lẹ́jọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • “Ó Ń Wo Ohun Tí Ọkàn-Àyà Jẹ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Fi Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ṣe Àwòkọ́ṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 6/99 ojú ìwé 1

Ṣé Ìrísí Nìkan Lo Máa Ń Wò?

1 Bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba wa, ohun táa bá kọ́kọ́ rò nípa àwọn èèyàn kan lè mú ká lọ́ tìkọ̀ láti ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú wọn. Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe bí ọkùnrin kan tí ojú rẹ̀ le koko bá ń wò ọ́ ṣáá bí o bá lọ sọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ tó fìfẹ́ hàn nínú òtítọ́? Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan tí èyí ṣẹlẹ̀ sí pinnu láti lọ bá ọkùnrin náà kó sì bá a sọ̀rọ̀. Ọkùnrin náà kí i lọ́nà ìwọ̀sí. Ṣùgbọ́n, ó yani lẹ́nu pé ó tẹ́tí sí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì, inú rẹ̀ sì dùn láti tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́. Nítorí pé arábìnrin yìí kò wo ìrísí, ọ̀nà ṣí sílẹ̀ fún ọkùnrin yìí àti aya rẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

2 Arábìnrin mìíràn wà tó jẹ́ pé ìrísí ọ̀dọ́kùnrin onírun gígùn kan kọ́kọ́ dẹ́rù bà á, ṣùgbọ́n arábìnrin yìí kò dẹwọ́ jíjẹ́rìí fún un ní ṣókí nígbàkígbà tí ọ̀dọ́kùnrin náà bá wá sí ilé ìtajà tí arábìnrin yìí ti ń ṣiṣẹ́. Ìsapá arábìnrin yìí yọrí sí rere, ọ̀dọ́kùnrin náà sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí ó ti ṣe batisí báyìí. Kí ló lè mú wa dènà fífi ìkánjú pinnu pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní gbọ́ wa?

3 Fífarawé Àpẹẹrẹ Jésù: Jésù mọ̀ pé òun yóò fi ẹ̀mí òun lélẹ̀ fún gbogbo èèyàn. Nítorí náà, kò jẹ́ kí ìrísí àwọn kan lé òun sá. Ó mọ̀ pé àwọn tí kò ní ìwà rere pàápàá lè fẹ́ láti yí padà bí a bá ràn wọ́n lọ́wọ́, tí a sì sún wọn ṣiṣẹ́ lọ́nà yíyẹ. (Mát. 9:9-13) Àti ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì ló ràn lọ́wọ́. (Mát. 11:5; Máàkù 10:17-22) Ǹjẹ́ kí a má ṣe wo ìrísí àwọn tí a ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ká má ṣe dijú wa sí nǹkan tó lè wá jẹ́ ọkàn-àyà rere. (Mát. 7:1; Jòh. 7:24) Kí ló lè mú wa fara wé àpẹẹrẹ títayọ ti Jésù?

4 Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, a ti wá mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti yí ìrònú, ìwà, àti àkópọ̀ ìwà ẹni padà. (Éfé. 4:22-24; Héb. 4:12) Nítorí náà, ó yẹ ká ní ìṣarasíhùwà tó dára, ká sì fi ìyókù sílẹ̀ fún Jèhófà, Ẹni tó mọkàn ẹ̀dá èèyàn.—1 Sám. 16:7; Ìṣe 10:34, 35.

5 Ǹjẹ́ kí bí a ṣe ń ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú gbogbo onírúurú èèyàn láìṣojúsàájú, láìwo ìrísí wọn, fi kún iṣẹ́ ìkórè kíkàmàmà ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.—1 Tím. 2:3, 4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́