ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/05 ojú ìwé 3
  • Gbogbo Onírúurú Èèyàn La Ó Gbà Là

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Onírúurú Èèyàn La Ó Gbà Là
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìrísí Nìkan Lo Máa Ń Wò?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Má Ṣe Máa Fi Ìrísí Dáni Lẹ́jọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń wo Àwọn Èèyàn Lo Fi Ń Wò Wọ́n?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìrísí Tó Dára
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 9/05 ojú ìwé 3

Gbogbo Onírúurú Èèyàn La Ó Gbà Là

1. Kí ló máa mú kí Ọlọ́run kà wá yẹ fún ìgbàlà?

1 Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti rí ìgbàlà. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Kì í ṣe orírun wa, ipò wa láwùjọ, ohun tá a lè ṣe, tàbí ìrísí wa ló máa mú kí Ọlọ́run kà wá yẹ fún ìgbàlà, bí kò ṣe lílò tá a bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jòh. 3:16, 36) Nítorí pé alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá, a gbọ́dọ̀ mú ẹ̀tanú èyíkéyìí kúrò lọ́kàn wa, ká má bàa bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra àwọn èèyàn tó wu Jèhófà pé kóun tẹ́wọ́ gbà.

2, 3. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa fojú báwọn èèyàn ṣe rí lóde ara wò wọ́n?

2 Má Ṣe Dáni Lẹ́jọ́: Ohun táwọn èèyàn jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ni Jèhófà máa ń wò, láìsí kùnrùngbùn tàbí ojúṣàájú. (1 Sám. 16:7) Ó tún máa ń wo ohun tí wọ́n lágbára láti ṣe. Nítorí náà, olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni Ọlọ́run máa ń kà sí ohun fífani lọ́kàn mọ́ra. (Hág. 2:7) Ṣé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn èèyàn làwa náà fi ń wò wọ́n?

3 Ìrísí àwọn èèyàn kan tá à ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ṣàjèjì sí wa. Wọ́n lè múra wúruwùru tàbí lọ́nà tí kò bójú mu, irun orí wọn tàbí irùngbọ̀n wọn lè rí wúruwùru. Àwọn kan lè jẹ́ asùnta. Àwọn kan lè máa kanra mọ́ wa. Dípò tá a ó fi máa ronú pé bóyá ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè di ìránṣẹ́ Jèhófà láéláé, ṣe ló yẹ ká máa ro rere nípa wọn, “nítorí àwa pàápàá nígbà kan rí jẹ́ òpònú, aláìgbọràn, [àti] ẹni tí a ṣì lọ́nà.” (Títù 3:3) Bá a bá ń rántí pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyí, ṣe ni yóò máa wù wá pé ká wàásù fún olúkúlùkù èèyàn, kódà àwọn tó jẹ́ pé ṣe ni ìrísí wọn lóde ara ń léni sá.

4, 5. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù àti ti Pọ́ọ̀lù?

4 Àpẹẹrẹ Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní: Kristi wá àkókò láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó ṣeé ṣe káwọn èèyàn ti kà sẹ́ni tí kò lè di olùjọ́sìn Jèhófà mọ́. (Lúùkù 8:26-39) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò fara mọ́ ìwà tó burú, ó mọ̀ pé àwọn èèyàn lè ṣàdéédéé dẹni tó ń gbé ìgbé ayé réderède. (Lúùkù 7:37, 38, 44-48) Nítorí náà, ó fi òye bá àwọn èèyàn lò, níwọ̀n bí “àánú wọ́n [ti] ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Máàkù 6:34) Ǹjẹ́ a lè máa fara wé àpẹẹrẹ rẹ̀ ní kíkún sí i?

5 Wọ́n sọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n lù ú, wọ́n sì sọ ọ́ sínú túbú. (Ìṣe 14:19; 16:22, 23) Ǹjẹ́ àwọn ìrírí líle koko bí èyí mú kó di òǹrorò ẹ̀dá kó sì parí èrò pé ńṣe lòun wulẹ̀ ń fi àkókò tóun ń lò ṣòfò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kan àtàwọn ẹ̀yà míì? Rárá o. Ó mọ̀ pé òun lè rí àwọn èèyàn tí wọ́n lọ́kàn rere látinú ẹ̀yà gbogbo, ó sì múra tán láti wá wọn rí. Ṣé ojú táwa náà fi ń wo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa nìyẹn, àwọn tí wọ́n wá láti ìlú míì tí àṣà ìbílẹ̀ wọn sì yàtọ̀ sí tiwa?

6. Ipa wo ni ìwà wa lè ní lórí àwọn ẹni tuntun tí wọ́n bá wá sí ìpàdé ìjọ?

6 Fífi Ọ̀yàyà Kí Àwọn Èèyàn Káàbọ̀ Lónìí: Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Ọlọ́run ni inú wọn ń dùn pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń fọ̀yàyà kí àwọn káàbọ̀ sínú ìjọ Ọlọ́run, láìfi ti ìrísí àwọn pè. Ṣe ló dà bí ọkùnrin kan báyìí tó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan nílẹ̀ Jámánì, irùngbọ̀n rẹ̀ rí wúruwùru, irun orí rẹ̀ gùn dé èjìká, ó sì wọ aṣọ tó dọ̀tí. Kò lórúkọ rere ládùúgbò. Síbẹ̀ náà, wọ́n fọ̀yàyà kí i káàbọ̀ sí ìpàdé. Inú ẹ̀ dùn débi pé ó padà wá lọ́sẹ̀ kan lẹ́yìn náà. Láìpẹ́ láìjìnnà, ó túnra ṣe, kò mu sìgá mọ́, òun àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ sì fi orúkọ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Ká tó wí ká tó fọ̀, àwọn méjèèjì àtàwọn ọmọ wọn ti ń sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìdílé tó wà ní ìṣọ̀kan.

7. Báwo la ṣe lè fara wé Ọlọ́run wa tí kì í ṣe ojúṣàájú?

7 Bá a ti ń ṣàfarawé Ọlọ́run wa tí kì í ṣe ojúṣàájú, ẹ jẹ́ kí àwa náà máa ké sí àwọn èèyàn láti wá jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ti Ọlọ́run ń fi hàn sí gbogbo èèyàn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́