Ṣé O Lè Ṣèrànwọ́?
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn mẹ́ńbà ìjọ níṣìírí láti “ní aájò kan náà fún ara wọn.” (1 Kọ́r. 12:25) Nítorí náà, ó yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ká sì ṣe tán láti fi ìfẹ́ ṣèrànwọ́ nígbà tó bá yẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arábìnrin wa kan nípa tẹ̀mí, tí wọ́n ń bẹ láàárín wa ń dá tọ́ àwọn ọmọ wọn ni. Àwọn arábìnrin wọ̀nyí ló ń gbé gbogbo ẹrù dídá àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí. Ó dájú pé wọ́n yẹ lẹ́ni tí à bá fi inú rere fún níṣìírí ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ti gidi “ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn.” (Róòmù 12:13) Ǹjẹ́ o lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
2 Àwọn Ọ̀nà Tí O Lè Gbà Ṣèrànwọ́: Yíyọ̀ǹda láti gbé àwọn tó jẹ́ pé ọkọ̀ èrò ni wọ́n máa ń wọ lọ sí ìpàdé àti àpéjọ lè dín ìnáwó ìdílé náà kù gidigidi. Ríran ìyá kan lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké ní ìpàdé lè túmọ̀ sí pé yóò túbọ̀ lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà. Bákan náà, yíyọ̀ǹda láti ràn án lọ́wọ́ nígbà tó bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ wá sóde ẹ̀rí lè mú kára tù ú díẹ̀. Fífi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú àwọn ọmọ náà—ṣíṣọ̀rẹ́ wọn—lè ṣe bẹbẹ láti ní ipa tó dára lórí àwọn èwe wa. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kíké sí ìdílé anìkàntọ́mọ láti dara pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín yóò pèsè ìṣírí tẹ̀mí tí ń tuni lára.
3 Jẹ́ Olóye: A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe fi dandan gbọ̀n-ọ̀n ṣèrànwọ́ fún ẹni tó fi hàn pé òun kò nílò ìrànwọ́ wa. Bẹ́ẹ̀ sì ni a kò gbọ́dọ̀ ṣàtojúbọ̀ ọ̀ràn ìdílé ẹlòmíràn nígbà tí a bá ń ṣèrànwọ́ tó yẹ. Dájúdájú, àwọn arábìnrin àti tọkọtaya ló wà nípò tó dára jù lọ láti ran arábìnrin kan tó wà ní ipò àìní lọ́wọ́.
4 A fún gbogbo Kristẹni níṣìírí láti “máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò” lọ́nà tí wọ́n ń gbà bá ara wọn lẹ́ni kìíní-kejì lò. (Róòmù 12:13b) Ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tẹ̀mí jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà púpọ̀ tí a ń gbà fi ìfẹ́ bíi ti Kristi tí a ní láàárín ara wa hàn.—Jòh. 13:35.