“Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Nínú Olúwa”
1 Pọ́ọ̀lù lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí láti ṣàpèjúwe Tírífénà àti Tírífósà, àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́kára nínú ìjọ Róòmù. Ó tún sọ nípa obìnrin mìíràn tí ń jẹ́ Pésísì pé: “Ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò nínú Olúwa.” Bákan náà, ó sọ̀rọ̀ Fébè dáadáa pé ó jẹ́ “olùgbèjà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.” (Róòmù 16:2, 12) Nínú Ìwé Mímọ́, a fi Dọ́káàsì hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó “pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.” (Ìṣe 9:36) Ìbùkún gidi mà ni irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí, jẹ́ fún ìjọ o!
2 Ǹjẹ́ a mọrírì àwọn arábìnrin tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ wa? Àwọn ló ń ṣe apá tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ ìwàásù, àwọn ló ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó pọ̀ jù lọ, wọ́n sì ń ran ọ̀pọ̀ ẹni tuntun lọ́wọ́. Wọ́n tún ń lo àkókò púpọ̀ láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́, kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àwọn obìnrin Kristẹni ń ṣe ipa tiwọn láti gbé ẹ̀mí ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, àti ìtara ró nínú ìjọ. Wọ́n máa ń ṣètìlẹ́yìn lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà kí ọkọ wọn àti àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
3 Àwọn Arábìnrin Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún: Àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì wà lára àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa, ọ̀pọ̀ ti kópa nínú mímú kí iṣẹ́ náà gbèrú ní àwọn ilẹ̀ òkèèrè. Nínú àwọn ìjọ tí àwọn ọkọ wọn ń bẹ̀ wò, aya àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń kún fún iṣẹ́ pẹrẹwu nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, wọ́n a sì máa fún ọ̀pọ̀ arábìnrin níṣìírí. A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn arábìnrin tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, tí wọ́n ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ ní ìtìlẹyìn fún ètò àjọ Jèhófà. Àwọn arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé náà wà níbẹ̀ o, wọ́n ń ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, nípasẹ̀ ìsapá tí wọ́n ń fi òótọ́ ọkàn ṣe nínú yíyin Ọlọ́run.
4 Àwọn arábìnrin olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ń rí ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ nínú ọ̀nà ìgbésí ayé ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ń tọ̀. (1 Tím. 6:6, 8) Wọ́n yẹ lẹ́ni tí a ń gbóríyìn fún, wọ́n sì yẹ fún ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn èyíkéyìí tí a bá lè fún wọn.
5 Gbogbo obìnrin Kristẹni ló wúlò gidigidi fún ètò àjọ Jèhófà, wọ́n ń fi òótọ́ ọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn tó jẹ́ ìbùkún fún gbogbo wa. Ẹ jẹ́ kí a máa bá a nìṣó láti mọrírì irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀, kí a sì máa gbàdúrà pé kí ìbùkún Jèhófà máa bá wọn bí wọ́n ṣe ń bá a nìṣó láti máa “ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa.”