ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/00 ojú ìwé 1
  • Gbogbo Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Ni Yóò Ní Ìmúṣẹ!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Ni Yóò Ní Ìmúṣẹ!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn Yóò Lọ Ìwọ Ńkọ́?
    Jí!—1999
  • Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Fúnni Ní Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998 sí 1999 Ti Sún Mọ́lé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 2/00 ojú ìwé 1

Gbogbo Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Ni Yóò Ní Ìmúṣẹ!

1 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ìdí nìyẹn tí inú wá fi dùn nígbà tí a gbọ́ pé ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ àgbègbè ti ọdún 1999 wọ ọdún 2000 yóò jẹ́ “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run.” A hára gàgà láti mọ ohun tí Jèhófà ní nípamọ́ fún wa gẹ́gẹ́ bí ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ (Mát. 24:45) Jèhófà ò sì já wa kulẹ̀.

2 Àwọn Kókó Àpéjọpọ̀: Lájorí àsọyé lọ́jọ́ Friday, tí a pè ní, “Máa Fiyè sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run,” jẹ́ ìjíròrò tí ń lani lóye lórí àkọsílẹ̀ nípa ìyípadà ológo náà. (Mát. 17:1-9) Ó ṣàlàyé pé ní báyìí, a wà ní bèbè àkókò tó dára jù lọ, nítorí pé àkókò òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, ètò tuntun ló sì ti dé tán yìí! Ọ̀nà pàtàkì kan tí a ní láti gbà fiyè sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni nípa kíkà á déédéé. Àpínsọ àsọyé tí a pè ní, “Ní Ìdùnnú Nínú Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” pèsè àwọn àbá táa lè lò láti mú kí Bíbélì kíkà wa túbọ̀ mérè wá sí i, kó sì túbọ̀ gbádùn mọ́ wa.

3 Ní ọ̀sán ọjọ́ Saturday, a gbọ́ àwọn ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí. Ǹjẹ́ o lè rántí gbogbo wọn? Láàárọ̀ ọjọ́ Sunday, àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù túbọ̀ nítumọ̀ sí wa bí a ṣe wá mọ̀ pé ọjọ́ wa ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọjọ́ tiẹ̀, àti pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì máa tó wáyé nígbà tí Jèhófà yóò pa àwọn ẹni ibi run, tí yóò sì dáàbò bo àwọn olódodo. Ǹjẹ́ o lóye ẹ̀kọ́ tí ń bẹ nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé karí Bíbélì nípa Jékọ́bù àti Ísọ̀? A gbọ́dọ̀ máa fi taratara wá ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà, kí a dènà ẹ̀mí ìdágunlá àti àìka-nǹkan-sí.

4 Ìwé Tuntun Kan Tó Fani Mọ́ra: Inú wa dùn gidigidi láti gba ìwé tuntun tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Kò síyèméjì pé wàá ti máa ka ìwé tó gbàfiyèsí yìí. Olùbánisọ̀rọ̀ tó ṣèfilọ̀ ìmújáde rẹ̀ sọ pé: “Yàtọ̀ sí ìwọ̀nba àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mélòó kan, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì ló ti nímùúṣẹ.” Ǹjẹ́ ìyẹn ò tẹnu mọ́ ọn pé àkókò tó jẹ́ kánjúkánjú la wà yìí?

5 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà ti jẹ́ ká túbọ̀ ní ìdánilójú pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run tí kò tíì ní ìmúṣẹ ni yóò ṣẹ. A ru wá sókè láti máa bá a nìṣó ní pípolongo ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́