ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 6/8 ojú ìwé 32
  • Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn Yóò Lọ Ìwọ Ńkọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn Yóò Lọ Ìwọ Ńkọ́?
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Kò Ní Fẹ́ Ṣàìlọ!
    Jí!—2000
  • A Kí I Yín Káàbọ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”!
    Jí!—2001
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998 sí 1999 Ti Sún Mọ́lé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 6/8 ojú ìwé 32

Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn Yóò Lọ Ìwọ Ńkọ́?

Ó MÁA ń lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ènìyàn tó ń lọ sí ìpàdé àgbègbè tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́dọọdún. Láti October 1999 títí di January 2000, a ó ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” mọ́kàndínláàádọ́fà, ọlọ́jọ́ mẹ́ta, ní Nàìjíríà. Ó ṣeé ṣe kí a ṣe ọ̀kan nítòsí ibi tí o ń gbé. A rọ̀ ọ́ láti wà níbẹ̀ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin ní agogo mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú lówùúrọ̀ ọjọ́ Friday.

Ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ àti lájorí àsọyé náà “Máa Fiyè sí Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” yóò wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀. Ní ọ̀sán, àpínsọ àsọyé náà, “Ní Inú Dídùn sí Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” yóò fúnni ní àwọn àbá tó gbéṣẹ́ lórí bí a ṣe lè mú kí Bíbélì kíkà máa ṣeni láǹfààní kí ó sì gbádùn mọ́ni. Àsọyé tí yóò gbẹ̀yìn lọ́jọ́ náà, “Àwọn Tí Ń Bá Ọlọ́run Jà Kò Ní Borí,” yóò ṣàgbéyẹ̀wò ìjà tí a ń bá àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run jà lóde òní.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Saturday yóò gbé ìjíròrò lórí ìrìbọmi jáde lákànṣe, a óò sì fún àwọn tó tóótun láǹfààní láti ṣèrìbọmi. Tó bá di ọ̀sán, a óò ka àwọn ìròyìn tí ń fúnni níṣìírí nípa bí àwọn ènìyàn ṣe ń dáhùn padà sí òtítọ́ Bíbélì lọ́nà àgbàyanu ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Látìn Amẹ́ríkà, Áfíríkà, àti Ìlà Oòrùn Yúróòpù, àti ní orílẹ̀-èdè títóbi náà, Kazakhstan, ní Éṣíà. A fún apá yìí ní àkọlé náà “‘Àwọn Ohun Fífani-Lọ́kàn-Mọ́ra’ Ń Kún Ilé Jèhófà.” A óò parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Saturday pẹ̀lú àsọyé méjì náà, “Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Alásọtẹ́lẹ̀ Ń Ta Wá Lólobó Láti Kíyè Sára” àti “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ní Àkókò Òpin.” Èyí tó kẹ́yìn yóò dá lórí ìwé Dáníẹ́lì, yóò sì ṣàlàyé ìdí tí a fi ní láti fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

Lówùúrọ̀ ọjọ́ Sunday, àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta kan tí a óò fi wákàtí kan sọ, tó ní àkọlé náà, “Àwọn Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ fún Àkókò Tí A Yàn Kalẹ̀” yóò jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù. Wàá rí bí ìwé kúkúrú inú Bíbélì yìí ṣe ń fún àwọn Kristẹni níṣìírí tó lónìí. Lẹ́yìn náà, àwòkẹ́kọ̀ọ́ ti ìgbàanì tí yóò gbé àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Jékọ́bù àti Ísọ̀ jáde, yóò ṣàlàyé àkọlé náà, “Mímọrírì Ogún Tẹ̀mí Táa Ní.” A óò parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday pẹ̀lú àsọyé tí ń runi sókè náà, “Kí Ni Ogún Ṣíṣeyebíye Táa Ní Túmọ̀ Sí fún Ọ?” Lẹ́yìn náà, tó bá di ọ̀sán, ìwọ yóò gbádùn àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Sísọ Ohun Gbogbo Di Tuntun—Gẹ́gẹ́ Bí A Ti Sọ Tẹ́lẹ̀.”

Bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò nísinsìnyí láti lọ. Láti mọ ibi tó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé yìí. A to gbogbo ibi tí a óò ti ṣe àpéjọpọ̀ náà ní Nàìjíríà sínú ìwé ìròyìn wa tó ṣìkejì èyí, Ilé Ìṣọ́, ti May 1, 1999.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́