Àpótí Ìbéèrè
◼ Ta ló lẹrù iṣẹ́ mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní?
Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bá mọ́ tónítóní tó sì dùn-ún wò máa ń buyì kún ìhìn tí a ń wàásù. (Fi wé 1 Pétérù 2:12.) Mímú kí gbọ̀ngàn bójú mu kí ó sì mọ́ ṣe kókó, gbogbo wa ló sì lè kópa nínú títọ́jú rẹ̀. Kò yẹ kí a retí pé àwọn èèyàn díẹ̀ ni kó máa dá a ṣe. Bó ti sábà máa ń rí, a máa ń ṣètò ìmọ́tótó náà ní ìbámu pẹ̀lú àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, tí Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tàbí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ yóò sì mú ipò iwájú. Ní àwọn gbọ̀ngàn tí ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ ti ń ṣèpàdé, àwọn alàgbà yóò ṣètò kí gbogbo ìjọ wọ̀nyẹn lè máa kópa nínú ìtọ́jú náà.
Ọ̀nà wo ló dára jù lọ láti gbà bójú tó ẹrù iṣẹ́ yìí? A gbọ́dọ̀ máa ṣètọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò tó ṣe déédéé. Àwọn nǹkan èlò gbọ́dọ̀ wà fún ṣíṣe ìmọ́tótó. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn nǹkan tí a gbọ́dọ̀ ṣe ni ó yẹ kí a fi sí ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ti lè yẹ̀ ẹ́ wò fún ìtọ́sọ́nà. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè wà, ọ̀kan fún ìmọ́tótó ráńpẹ́ tí a máa ń ṣe ní gbogbo gbòò lẹ́yìn ìpàdé kọ̀ọ̀kan, èkejì yóò sì wà fún ìmọ́tótó gidi tí a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kí Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣètò ìmọ́tótó gidi náà sí ọjọ́ àti àkókò tí yóò rọgbọ fún gbogbo àwọn tí a yàn láti ṣe é. Kí a tún máa bójú tó ilẹ̀ àyíká gbọ̀ngàn, àwọn òdòdó, àti àwọn igi déédéé. Kí a máa mú kí ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ àti ibi ìgbọ́kọ̀sí mọ́ tónítóní. Lọ́dọọdún, ó yẹ kí a máa ṣe ìmọ́tótó gidigidi, bóyá ṣáájú Ìṣe Ìrántí. Lára ohun tí a lè ṣe ni fífọ àwọn fèrèsé àti ògiri, fífọ ilẹ̀, àti fífọ kọ́tìnnì.
Àmọ́ ṣá o, gbogbo wa ló lè mú kí iṣẹ́ náà rọrùn nípa ṣíṣàìju bébà, ṣingọ́ọ̀mù, tàbí àwọn nǹkan mìíràn sínú gbọ̀ngàn tàbí síta rẹ̀. Ó yẹ kí a tún ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ṣe lẹ́yìn tí a bá lò ó tán, kí a mú kí ó wà ní mímọ́ fún ẹlòmíràn tí yóò tún lò ó. Kíyè sára kí o má bàa fọ́ àwọn nǹkan èlò tàbí kí o má bàa ba àwọn àga tàbí tábìlì jẹ́. Kíyè sí ìdọ̀tí tó bá wà lára kápẹ́ẹ̀tì, àwọn àga tó bà jẹ́, àwọn ọ̀pá agbómikiri tó ti bẹ́, àwọn gílóòbù tó ti jó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, kí o sì fi èyí tó arákùnrin tó ń bójú tó ìtọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba létí ní kánmọ́.
Kí gbogbo wa múra tán láti ṣe ipa tiwa. Èyí máa ń jẹ́ ká ní ilé ìjọsìn tó fani mọ́ra, ó sì ń fi wá hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí èèyàn mímọ́ tí ń bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run.—1 Pét. 1:16.